Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 47

Ṣé O Ní Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Tó?

Ṣé O Ní Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Tó?

“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín. Ẹ ní ìgbàgbọ́.” ​—JÒH. 14:1.

ORIN 119 Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

ṢÉ ÀYÀ ẹ máa ń já tó o bá ń ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá pa ìsìn èké run àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Gọ́ọ̀gù ará Mágọ́gù bá gbéjà kò wá? Ṣé ẹ̀rù tún máa ń bà ẹ́ tó o bá ń ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì? Ṣé o ti bi ara ẹ rí pé, ‘tó bá dìgbà yẹn, ṣé màá lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?’ Tí irú èrò yìí bá ti wá sí ẹ lọ́kàn rí, ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé máa ràn ẹ̀ lọ́wọ́. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìdààmú bá ọkàn yín. Ẹ ní ìgbàgbọ́.” (Jòh. 14:1) Tá a bá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára báyìí, ọkàn wa máa balẹ̀ bá a ṣe ń retí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

2. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Tá a bá ń ronú nípa ohun tá à ń ṣe láti fara da ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ wa wò báyìí, àá mọ bá a ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára ká lè kojú àwọn àdánwò tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, á sì tún jẹ́ ká mọ àwọn ibi tó yẹ ká ti ṣàtúnṣe. Bá a ṣe ń borí àwọn àdánwò náà, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ máa lágbára. Ìyẹn lá jẹ́ ká fara da àwọn àdánwò tá a máa kojú lọ́jọ́ iwájú. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn nǹkan mẹ́rin tó ṣẹlẹ̀ tó fi hàn pé ó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbàgbọ́ sí i. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwa náà ṣe lè fara da irú àwọn ìṣòro yẹn lónìí àti bó ṣe lè múra wa sílẹ̀ fáwọn àdánwò tá a máa kojú lọ́jọ́ iwájú.

NÍGBÀGBỌ́ PÉ JÈHÓFÀ MÁA PÈSÈ OHUN TÓ O NÍLÒ

Tá ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, ìgbàgbọ́ tá a ní máa jẹ́ ká fi ìjọsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ (Wo ìpínrọ̀ 3-6)

3. Bó ṣe wà nínú Mátíù 6:30, 33, kí ni Jésù sọ pé ó yẹ ká ṣe kí ìgbàgbọ́ wa lè túbọ̀ lágbára?

3 Ojúṣe olórí ìdílé kan ni láti pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ilé fún ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí àkókò tó nira tá à ń gbé yìí. Láwọn ìgbà míì, iṣẹ́ máa ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará kan, ó sì máa ń pẹ́ kí wọ́n tó ríṣẹ́ míì bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sapá gan-an. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn míì ríṣẹ́, àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ táwa Kristẹni lè ṣe. Nírú àwọn ipò yìí, ó yẹ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, kó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa pèsè ohun táwa àti ìdílé wa nílò. Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ èyí nínú Ìwàásù orí Òkè. (Ka Mátíù 6:30, 33.) Tó bá dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀, àá pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bá a ṣe ń rí i tí Jèhófà ń pèsè àwọn ohun tá a nílò, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ìgbàgbọ́ wa á sì túbọ̀ lágbára.

4-5. Kí ló ran ìdílé kan lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan ò lọ dáadáa fún wọn?

4 Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ran ìdílé Castro tó ń gbé ní Fẹnẹsúélà lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan ò lọ dáadáa fún wọn. Nígbà kan, iṣẹ́ oko ni wọ́n ń ṣe láti gbọ́ bùkátà ara wọn. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn jàǹdùkú fipá gba ilẹ̀ wọn, bó ṣe di pé wọ́n sá kúrò níbẹ̀ nìyẹn. Miguel tó jẹ́ bàbá wọn sọ pé: “Ní báyìí nǹkan kékeré tá a bá rí lórí ilẹ̀ tá a yá la fi ń gbọ́ bùkátà ara wa. Àràárọ̀ ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó pèsè ohun tá a nílò lọ́jọ́ yẹn fún wa.” Lóòótọ́, nǹkan ò rọrùn fún ìdílé yìí rárá, àmọ́ torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọn kì í pa ìpàdé jẹ, wọ́n sì ń lọ sí òde ẹ̀rí déédéé. Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn, Jèhófà náà sì ń pèsè ohun tí wọ́n nílò.

5 Ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira fún wọn, Miguel àti ìyàwó ẹ̀ Yurai ń kíyè sí bí Jèhófà ṣe ń bójú tó wọn. Àwọn ìgbà kan wà tí Jèhófà lo àwọn ará láti bá Miguel wáṣẹ́, wọ́n sì tún pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún wọn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì ni Jèhófà lò láti pèsè ohun tí wọ́n nílò. Jèhófà ò fìgbà kankan fi wọ́n sílẹ̀. Bí wọ́n ṣe rọ́wọ́ Jèhófà láyé wọn yìí ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ìdílé wọn túbọ̀ lágbára. Ìgbà kan wà tí wọ́n sọ bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́, ọmọ wọn àgbà tó ń jẹ́ Yoselin wá sọ pé: “Inú wa ń dùn gan-an bá a ṣe ń rọ́wọ́ Jèhófà, mo mọ̀ pé ọ̀rẹ́ mi ni, ó sì ṣeé fọkàn tán.” Ó tún sọ pé: “Àwọn ìṣòro tí ìdílé wa fara dà ti múra wa sílẹ̀ de ìṣòro tá a máa kojú lọ́jọ́ iwájú.”

6. Kí lo lè ṣe láti mú kí ìgbàgbọ́ ẹ lágbára tí o ò bá fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́?

6 Ṣé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa fún ẹ báyìí, tó ò sì lówó lọ́wọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé nǹkan máa nira fún ẹ nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún ẹ báyìí, síbẹ̀ o ṣì lè lo àkókò yìí láti mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Gbàdúrà kó o sì ka ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:25-34, kó o wá ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà. O tún lè ronú nípa ìrírí àwọn ará tó fi hàn pé Jèhófà máa ń pèsè fún àwọn tó pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (1 Kọ́r. 15:58) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó ṣe ran àwọn ará yẹn lọ́wọ́. Ó mọ àwọn nǹkan tó o nílò, á sì pèsè wọn fún ẹ. Bí ìwọ náà ṣe ń rọ́wọ́ Jèhófà láyé ẹ, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára, wàá sì lè kojú àwọn àdánwò tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.​—Háb. 3:17, 18.

NÍGBÀGBỌ́ KÓ O LÈ FARA DA “ÌJÌ LÍLE”

Ìgbàgbọ́ tó lágbára tá a ní máa jẹ́ ká fara da ìjì líle tàbí àwọn ìṣòro ńlá (Wo ìpínrọ̀ 7-11)

7. Bó ṣe wà nínú Mátíù 8:23-26, báwo ni “ìjì líle” ṣe dán ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wò?

7 Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wà lórí òkun tí ìjì líle sì ń jà, Jésù lo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí láti jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n mú kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára sí i. (Ka Mátíù 8:23-26.) Nígbà tí ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà, tí omi sì ń rọ́ wọnú ọkọ̀ náà, ṣe ni Jésù ń sùn. Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn wá jí Jésù torí pé ẹ̀rù ti ń bà wọ́n, tí wọ́n sì sọ pé kó gba àwọn, Jésù rọra sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ń bà yín tó báyìí, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré?” Ó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ẹ̀rù ń bà yẹn mọ̀ pé Jèhófà lè dáàbò bo Jésù àti àwọn. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, àá lè fara da “ìjì líle” èyíkéyìí tàbí àwọn ìṣòro tó dà bí ìjì.

8-9. Kí ló dán ìgbàgbọ́ Anel wò, kí ló sì ràn án lọ́wọ́?

8 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tí ò lọ́kọ tó ń jẹ́ Anel láti Puerto Rico. Ìgbàgbọ́ ẹ̀ túbọ̀ lágbára lẹ́yìn tó fara da ìṣòro kan. “Ìjì líle” kan tó ń jẹ́ Hurricane Maria ló ba ilé Anel jẹ́ lọ́dún 2017. Lẹ́yìn ìjì líle yẹn, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Anel sọ pé: “Ní gbogbo àsìkò yẹn, ìdààmú bá mi. Àmọ́ bí mo ṣe ń gbàdúrà ni mo túbọ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí ìdààmú yẹn bò mí mọ́lẹ̀.”

9 Anel tún sọ pé ìgbọràn ló jẹ́ kóun lè fara da ìṣòro òun. Ó ní: “Bí mo ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí ètò Ọlọ́run fún wa jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. Jèhófà tún lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin láti ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sọ̀rọ̀ ìṣírí fún mi, wọ́n sì fún mi láwọn ohun tí mo nílò. Ohun tí Jèhófà pèsè fún mi kọjá ohun tí mo béèrè, ìyẹn sì ti mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára.”

10. Kí lo lè ṣe tó o bá dojú kọ ìṣòro tó dà bí “ìjì líle”?

10 Ṣé ò ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó dà bí “ìjì líle”? Ó lè jẹ́ àjálù kan ló dé bá ẹ. Ó sì lè jẹ́ àìsàn kan ló ń ṣe ẹ́, tó ò sì mọ ohun tó o máa ṣe. Nǹkan lè tojú sú ẹ nígbà míì, àmọ́ má ṣe jẹ́ kíyẹn dí ẹ lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Máa gbàdúrà déédéé kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Máa ronú nípa ìgbà tí Jèhófà ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ sẹ́yìn, ìyẹn máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. (Sm. 77:11, 12) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ báyìí, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ láé.

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká pinnu pé àá máa ṣègbọràn sáwọn tó ń ṣe àbójútó wa?

11 Kí ni nǹkan míì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro? Bí Anel ṣe sọ, ìgbọràn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ṣègbọràn sáwọn tí Jèhófà àti Jésù fọkàn tán. Láwọn ìgbà míì, àwọn tó ń ṣe àbójútó wa lè fún wa láwọn ìtọ́ni kan tó lè dà bíi pé kò mọ́gbọ́n dání lójú wa. Àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ìgbọràn wa ni Jèhófà ń wò, ó sì máa bù kún wa tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan tá a rí nínú Bíbélì àti ìrírí àwọn ará fi hàn pé ìgbọràn máa ń dáàbò bò wá. (Ẹ́kís. 14:1-4; 2 Kíró. 20:17) Máa ronú lórí irú àwọn àpẹẹrẹ yìí. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí ètò Ọlọ́run ń fún wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. (Héb. 13:17) Ìyẹn ò ní jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́ láti kojú àwọn àdánwò tó dà bí ìjì líle tó máa wáyé láìpẹ́.​—Òwe 3:25.

ÌGBÀGBỌ́ MÁA JẸ́ KÓ O FARA DA ÌWÀ ÌRẸ́JẸ

Tá a bá ń gbàdúrà kíkankíkan, ìgbàgbọ́ wa á túbọ̀ lágbára (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Kí ni Lúùkù 18:1-8 sọ nípa ìgbàgbọ́ àti béèyàn ṣe lè fara da ìwà ìrẹ́jẹ?

12 Jésù mọ̀ pé wọ́n máa rẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun jẹ, ìyẹn sì máa dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Torí náà, Jésù sọ àpèjúwe kan nínú ìwé Lúùkù tó máa jẹ́ kí wọ́n lè fara dà á. Jésù sọ ìtàn nípa opó kan tó ń lọ sọ́dọ̀ adájọ́ kan tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, kò sì fi adájọ́ náà lọ́rùn sílẹ̀. Ó dá a lójú pé lọ́jọ́ kan, adájọ́ náà máa dá ẹjọ́ òun bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Jèhófà kì í ṣe aláìṣòdodo. Jésù sọ pé: “Ṣé kò wá dájú pé Ọlọ́run máa mú kí a dájọ́ bó ṣe tọ́ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń ké pè é tọ̀sántòru?” (Ka Lúùkù 18:1-8.) Jésù wá fi kún un pé: “Tí Ọmọ èèyàn bá dé, ṣé ó máa bá ìgbàgbọ́ yìí ní ayé lóòótọ́?” Tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, àmọ́ tá a ṣe sùúrù tá a sì fara dà á, ìyẹn máa fi hàn pé a nígbàgbọ́ tó lágbára bíi ti opó yẹn. Tá a bá nírú ìgbàgbọ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa jà fún wa láìpẹ́. Bákan náà, ó yẹ ká gbà pé kò sí nǹkan tí àdúrà ò lè ṣe. Kódà nígbà míì, Jèhófà máa ń dáhùn àdúrà wa lọ́nà tá ò lérò.

13. Báwo ni àdúrà ṣe ran ìdílé kan lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n hùwà tí kò dáa sí wọn?

13 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Vero tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Democratic Republic of the Congo. Arábìnrin Vero àti ọkọ ẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ọmọbìnrin wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ní láti sá kúrò nílùú wọn. Ìdí ni pé àwọn ọmọ ogun tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba wá gbéjà ko abúlé wọn. Nígbà tí wọ́n ń sá lọ, wọ́n pàdé àwọn ọmọ ogun tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba yẹn, wọ́n sì sọ pé àwọn máa pa àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà tí Arábìnrin Vero bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún gan-an, ọmọ ẹ̀ gbàdúrà sókè, ó sì lo orúkọ Jèhófà léraléra nínú àdúrà ẹ̀, ìyẹn jẹ́ kára ìyá ẹ̀ balẹ̀. Nígbà tó parí àdúrà ẹ̀, ọ̀gá àwọn ológun yẹn bi í pé: “Ọmọ yìí, ta ló kọ́ ẹ bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà?” Ó dá a lóhùn pé: “Mọ́mì mi ló fi àdúrà Olúwa tó wà ní Mátíù 6:9-13 kọ́ mi bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà.” Ọ̀gágun náà wá sọ pé: “Ẹ máa lọ lálàáfíà, kí Jèhófà Ọlọ́run yín sì wà pẹ̀lú yín!”

14. Kí ló lè dán ìgbàgbọ́ wa wò, kí ló sì máa jẹ́ ká lè fara dà á?

14 Irú àwọn ìrírí yìí jẹ́ ká rí i pé àdúrà ṣe pàtàkì gan-an. Àmọ́ ká sọ pé Jèhófà ò tètè dáhùn àdúrà ẹ tàbí tí ò dáhùn ẹ̀ lọ́nà àrà ńkọ́? Bíi ti opó tó wà nínú àpèjúwe Jésù yẹn, máa gbàdúrà, kó o sì mọ̀ dájú pé Ọlọ́run ò ní fi ẹ́ sílẹ̀. Bópẹ́bóyá, Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà ẹ. Máa bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. (Fílí. 4:13) Máa fi sọ́kàn pé láìpẹ́, Jèhófà máa bù kún ẹ gan-an, o ò sì ní rántí gbogbo ìyà tó o ti jẹ sẹ́yìn mọ́. Tó o bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bó o ṣe ń fara da àwọn ìṣòro ẹ, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ lágbára, wàá sì lè fara da àwọn àdánwò tó o máa kojú lọ́jọ́ iwájú.​—1 Pét. 1:6, 7.

ÌGBÀGBỌ́ MÁA JẸ́ KÓ O BORÍ ÀWỌN ÌṢÒRO Ẹ

15. Ìṣòro wo ni Mátíù 17:19, 20 sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dojú kọ?

15 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé ìgbàgbọ́ ló máa jẹ́ kí wọ́n borí ìṣòro tí wọ́n máa ní. (Ka Mátíù 17:19, 20.) Ìgbà kan wà tí wọn ò lè lé ẹ̀mí èṣù kan jáde, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ láwọn ìgbà kan. Kí ló fà á? Jésù sọ pé ìgbàgbọ́ wọn kéré. Ó sọ fún wọn pé tí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, wọ́n á borí àwọn ìṣòro tó dà bí òkè. Bákan náà lónìí, àwa náà lè dojú kọ àwọn ìṣòro tó dà bí òkè, tó sì lè dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ.

A lè ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀, àmọ́ ìgbàgbọ́ máa jẹ́ ká tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn nǹkan míì nínú ìjọsìn Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe mú kí Geydi fara dà á lẹ́yìn tí wọ́n pa ọkọ ẹ̀?

16 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Geydi, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Guatemala. Lọ́jọ́ kan tí wọ́n ń bọ̀ láti ìpàdé, wọ́n pa Edi ọkọ ẹ̀. Báwo ni ìgbàgbọ́ tí Geydi ní ṣe mú kó fara da ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀? Ó sọ pé: “Tí mo bá ń gbàdúrà, mo máa ń sọ gbogbo ẹ̀dùn ọkàn mi fún Jèhófà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. Jèhófà lo ìdílé mi àtàwọn ọ̀rẹ́ tó wà nínú ìjọ láti bójú tó mi. Yàtọ̀ síyẹn, mo tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn nǹkan míì nínú ìjọ, ìyẹn jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn mi dín kù, kì í sì í jẹ́ kí n da àníyàn tọ̀la mọ́ tòní. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi, mo ti wá rí i pé kò sí àdánwò tó lè dé bá mi lọ́jọ́ iwájú tí mi ò ní lè fara dà, torí Jèhófà, Jésù àti ètò Ọlọ́run wà pẹ̀lú mi.”

17. Kí la lè ṣe tá a bá dojú kọ ìṣòro tó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ?

17 Ṣé o ní ẹ̀dùn ọkàn torí èèyàn ẹ kan tó kú? O lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára nínú ìrètí àjíǹde tó o bá ń kà nípa àwọn tá a jí dìde nínú Bíbélì. Àbí kẹ̀, ṣé ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìdílé ẹ ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣèwádìí kó lè dá ẹ lójú pé ọ̀nà tó dáa jù ni Jèhófà máa ń gbà bá wa wí. Ìṣòro yòówù kó o máa kojú, jẹ́ kó mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún Jèhófà, má ya ara ẹ sọ́tọ̀, ṣe ni kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará. (Òwe 18:1) Tó o bá ń rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, tíyẹn sì ń jẹ́ kó o máa sunkún, máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o fara dà á. (Sm. 126:5, 6) Máa lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, máa ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Bó o sì ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, ṣe ni ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára.

“FÚN WA NÍ ÌGBÀGBỌ́ SÍ I”

18. Tó o bá kíyè sí i pé ìgbàgbọ́ ẹ ò lágbára tó, kí ló yẹ kó o ṣe?

18 Tó o bá rí i pé àwọn ìṣòro tó o ní báyìí àbí àwọn èyí tó o ti dojú kọ sẹ́yìn fi hàn pé ìgbàgbọ́ ẹ ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, má ṣe jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Lo àǹfààní yìí láti ṣe nǹkan tó máa jẹ́ kígbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Ìwọ náà lè bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígbàgbọ́ sí i bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n sọ pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5) Yàtọ̀ síyẹn, máa ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Bíi ti Miguel àti Yurai, máa rántí àwọn ìgbà tí Jèhófà ti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bíi ti ọmọ Vero àti Anel, máa gbàdúrà kíkankíkan sí Jèhófà pàápàá tó o bá dojú kọ ìṣòro. Bíi ti Geydi, máa fi sọ́kàn pé ó lè jẹ́ àwọn ìdílé ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ nínú ìjọ ni Jèhófà máa lò láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń fara da àwọn ìṣòro tó o ní báyìí, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí àwọn àdánwò tó o máa dojú kọ lọ́jọ́ iwájú.

19. Kí ló dá Jésù lójú, kí ló sì yẹ kó dá ìwọ náà lójú?

19 Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí Jésù sọ pé ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò lágbára tó, àmọ́ ó dá a lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn àdánwò wọn lọ́jọ́ iwájú. (Jòh. 14:1; 16:33) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún dá Jésù lójú pé ìgbàgbọ́ tó lágbára ló máa mú káwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn la ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ já. (Ìfi. 7:9, 14) Ṣé ìwọ náà máa wà lára wọn? Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti wà lára wọn tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ní ìgbàgbọ́, tó o sì ń jẹ́ kígbàgbọ́ ẹ máa lágbára sí i báyìí!​—Héb. 10:39.

ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

^ ìpínrọ̀ 5 Gbogbo wa là ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ètò àwọn nǹkan yìí máa dópin. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé ṣé a máa ní ìgbàgbọ́ tó lágbára tó láti kojú àwọn ìṣòro tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìrírí àwọn ará wa àtàwọn nǹkan pàtó tá a lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára báyìí.