Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mò Ń Wá Bí Mo Ṣe Lè Gbé Ìgbé Ayé Tó Dáa

Mò Ń Wá Bí Mo Ṣe Lè Gbé Ìgbé Ayé Tó Dáa

NÍGBÀ tí mo wà nínú ọkọ̀ mi láàárín agbami Òkun Mẹditaréníà, ó yà mí lẹ́nu gan-an pé omi rẹpẹtẹ ń rọ́ wọnú ọkọ̀ mi. Lẹ́yìn náà, ìjì líle bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́. Ẹ̀rù bà mí gan-an, mo sì gbàdúrà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti gbàdúrà kẹ́yìn. Kí ló gbé mi dórí agbami òkun yìí? Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìgbésí ayé mi látìbẹ̀rẹ̀.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méje, orílẹ̀-èdè Brazil ni ìdílé wa ń gbé

Ọdún 1948 ni wọ́n bí mi lórílẹ̀-èdè Netherlands. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ìdílé wa ṣí lọ sí São Paulo, lórílẹ̀-èdè Brazil. Àwọn òbí mi máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé, gbogbo wa sì jọ máa ń ka Bíbélì lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́. Nígbà tó di ọdún 1959, a ṣí kúrò níbi tá a wà lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a wá ń gbé ní ìpínlẹ̀ Massachusetts.

Àwa mẹ́jọ la wà nínú ìdílé wa, bàbá wa sì máa ń ṣiṣẹ́ kára gan-an láti bójú tó wa. Oríṣiríṣi iṣẹ́ ni bàbá mi ṣe, wọ́n bá ilé iṣẹ́ kan tajà, wọ́n tún bá ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ọ̀nà ṣiṣẹ́. Nígbà tó yá, wọ́n bá ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú kan ṣiṣẹ́. Inú gbogbo wa dùn gan-an nígbà tí wọ́n ríṣẹ́ sílé iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú torí ìyẹn á jẹ́ ká lè máa lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.

Nígbà tí mo wà nílé ẹ̀kọ́ girama, mo sábà máa ń bi ara mi pé, ‘Kí ni màá fi ayé mi ṣe tí mo bá dàgbà?’ Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ pé àwọn máa lọ sí yunifásítì, nígbà táwọn kan sọ pé àwọn máa lọ ṣe iṣẹ́ ológun. Àmọ́ ní tèmi, mi ò fẹ́ ṣiṣẹ́ ológun torí pé mi ò nífẹ̀ẹ́ sí kéèyàn máa ṣe awuyewuye, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kéèyàn lọ máa jà lójú ogun. Torí náà, mo pinnu láti lọ sí yunifásítì dípò kí n lọ ṣiṣẹ́ ológun. Ohun tó wù mí lọ́kàn mi ni pé kí n máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ torí ìyẹn máa jẹ́ kí n gbé ìgbé ayé tó dáa.

ÌGBÉSÍ AYÉ MI NÍ YUNIFÁSÍTÌ

Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ń wá bí màá ṣe gbé ìgbé ayé tó dáa

Nígbà tí mo wà ní yunifásítì, ẹ̀kọ́ nípa èèyàn ló wù mí torí mo fẹ́ mọ ibi tí ìwàláàyè èèyàn ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n pé èèyàn kàn ṣàdédé wà ni, àwọn olùkọ́ wa sì fẹ́ ká gbà á gbọ́. Ní tèmi, àwọn àlàyé wọn kan ò bọ́gbọ́n mu, kò sí ẹ̀rí tó fìdí ọ̀rọ̀ wọn múlẹ̀, ìyẹn ò sì bá ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì mu.

Nígbà tí wọ́n ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, wọn ò kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ ìwà rere. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n máa ń kọ́ wa ni bá a ṣe máa di ẹni ńlá. Mo máa ń lọ sí òde àríyá pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi, mo sì máa ń lo oògùn olóró, ìyẹn ló ń fún mi láyọ̀, àmọ́ ayọ̀ yẹn ò tọ́jọ́. Mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ṣé ìgbésí ayé tó dáa ni mò ń gbé yìí?’

Nígbà tó yá, mo ṣí lọ sí ìlú Boston mo sì wọlé sí yunifásítì kan tó wà níbẹ̀. Tá a bá ti wà ní ọlidé mo máa ń ṣiṣẹ́ kí n lè rówó ilé ẹ̀kọ́ mi san. Ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ni mo ti kọ́kọ́ pàdé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Ó ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìgbà méje” tó wà nínú Dáníẹ́lì orí kẹrin fún mi, ó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé a ti wà ní ọjọ́ ìkẹyìn. (Dán. 4:13-17) Mo rí i pé tá a bá ń bá ọ̀rọ̀ wa lọ nínú Bíbélì, tí mo sì gba ohun tó ń kọ́ mi gbọ́, màá yí ìgbésí ayé mi pa dà. Torí náà, mi ò bá a sọ̀rọ̀ mọ́, mo sì yẹra fún un pátápátá.

Nígbà tí mo wà ní yunifásítì, mo kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ kan tó máa jẹ́ kí n lè ṣiṣẹ́ ìrànwọ́ fáwọn èèyàn ní South America. Mo rò pé tí mo bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà, ó máa jẹ́ kí n gbé ìgbé ayé tó dáa. Àmọ́ mo wá rí i pé gbogbo nǹkan yìí kọ́ ló máa jẹ́ kí n gbé ìgbé ayé aláyọ̀. Gbogbo ẹ̀ tojú sú mi, ni mo bá fi yunifásítì sílẹ̀ ní òpin sáà yẹn.

MO WÁ BÍ ÌGBÉ AYÉ MI ṢE MÁA DÁA LỌ SÍ ILẸ̀ ÒKÈÈRÈ

Ní May 1970, mo ṣí lọ sí ìlú Amsterdam, lórílẹ̀-èdè Netherlands, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfúrufú tí bàbá mi ti ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ yìí máa ń gbé mi rìnrìn àjò lọ sí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tó wà ní Áfíríkà, ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Yúróòpù àti Éṣíà. Lẹ́yìn tí mo ti lọ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè yẹn, mo wá rí i pé gbogbo wọn ló ní ìṣòro ńláńlá, wọn ò sì lè yanjú àwọn ìṣòro yẹn. Torí pé ó ṣì ń wù mí kí n gbé nǹkan ńlá ṣe láyé mi, mo pa dà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo sì pa dà sí yunifásítì tó wà ní Boston.

Nígbà tí mo pa dà sí yunifásítì, kò pẹ́ tí mo fi rí i pé àwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ wa ní kíláàsì ò dáhùn àwọn ìbéèrè mi nípa ìgbésí ayé. Nígbà tí mi ò mọ nǹkan tí màá ṣe, mo lọ bá ọ̀kan lára àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pé kó gbà mí nímọ̀ràn. Ohun tó sọ yà mí lẹ́nu, ó sọ pé: “Kí ló dé tó o ṣì ń kẹ́kọ̀ọ́? O ò ṣe kúkú fi ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì sílẹ̀?” Kíákíá ni mo ṣe ohun tó sọ. Bí mo ṣe fi ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ nìyẹn, tí mi ò sì pa dà síbẹ̀ mọ́.

Ó ṣì ń ṣe mí bíi pé mi ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tó dáa. Torí náà, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tí ò fara mọ́ àṣà tó wọ́pọ̀ láwùjọ, àmọ́ tí wọ́n ń gbé àlàáfíà àti ìfẹ́ lárugẹ. Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi kan rìnrìn àjò káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a sì tún lọ sí ìlú Acapulco, lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. A bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pẹ̀lú àwọn tó ń gbé ìgbésí ayé bó ṣe wù wọ́n, tó sì dà bíi pé wọn ò níṣòro. Àmọ́ nígbà tí mò ń gbé pẹ̀lú wọn, kò pẹ́ tí mo fi rí i pé ìgbésí ayé wọn ò dáa, wọn ò sì ní ayọ̀ tòótọ́. Ìwà àìṣòótọ́ kún ọwọ́ wọn, wọn kì í sì í ṣe ọ̀rẹ́ gidi.

MO LO ỌKỌ̀ ÒKUN LÁTI WÁ BÍ MÀÁ ṢE GBÉ ÌGBÉ AYÉ TÓ DÁA

Èmi àti ọ̀rẹ́ mi ń wá erékùṣù kan tó rẹwà kiri

Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tí mo sọ pé mo fẹ́ fayé mi ṣe nígbà tí mo wà ní kékeré. Ó wù mí kí n jẹ́ awakọ̀ òkun, àmọ́ kì í ṣe awakọ̀ lásán, ọ̀gá awakọ̀ òkun ló wù mí kí n jẹ́. Àmọ́ ohun tó lè jẹ́ kí n di ọ̀gá ni pé kí n ní ọkọ̀ òkun tèmi fúnra mi. Mo ní ọ̀rẹ́ kan tó ń jẹ́ Tom tóun náà fẹ́ di ọ̀gá awakọ̀ òkun. Torí náà, a pinnu pé àá jọ máa rìnrìn àjò lórí omi káàkiri ayé. Ohun tó wù mí ni kí n rí erékùṣù kan tó rẹwà níbi tí kò ti ní sí òfin kankan táá máa darí mi.

Èmi àti Tom rìnrìn àjò lọ sí Arenys de Mar, nítòsí Barcelona, lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Ibẹ̀ la ti ra ọkọ̀ òkun kan tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31). Orúkọ tá a sọ ọkọ̀ náà ni Llygra. A bẹ̀rẹ̀ sí í tún ọkọ̀ náà ṣe kó lè gbé wa débi tá à ń lọ. Torí pé a ò kánjú, a yọ ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ náà kúrò. Àyè ibi tá a ti yọ ọ́ kúrò la sì ń pọn omi mímú sí. Ká lè débi tá à ń lọ, à ń fi àjẹ̀ tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìndínlógún (16) wa ọkọ̀ wa gba etíkun. Níkẹyìn, a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò gba orí Òkun Íńdíà lọ sí ìlú Seychelles. A pinnu pé a máa gbé ọkọ̀ wa gba ìwọ̀ oòrùn etíkun Áfíríkà àti etíkun kan tó ń jẹ́ Cape of Good Hope, lórílẹ̀-èdè South Africa. Ká má bàa sọ nù sórí òkun, a máa ń wo apá ibi tí ìràwọ̀ wà, à ń lo ìwé ajúwe ọ̀nà àti kọ́ńpáàsì ká lè débi tá à ń lọ. Mo wá ń rò ó pé báwo la ṣe máa mọ ọ̀nà débi tá à ń lọ?

Kò pẹ́ sígbà yẹn la mọ̀ pé a ò ní lè gbé ọkọ̀ òkun wa tó ti gbó yìí rìnrìn àjò torí pé omi ń wọnú ẹ̀. Omi gálọ́ọ̀nù mẹ́fà (tàbí lítà 22) ló ń rọ́ wọnú ọkọ̀ náà ní wákàtí kan! Bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ mi, nígbà tí ìjì bẹ̀rẹ̀ sí í jà, ẹ̀rù bà mí gan-an, mo sì gbàdúrà sí Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti ṣe bẹ́ẹ̀ kẹ́yìn. Mo sọ fún un pé tó bá lè jẹ́ ká gúnlẹ̀ láyọ̀, màá fẹ́ mọ ẹni tó jẹ́. Ni ìjì náà bá dáwọ́ dúró. Lọ́tẹ̀ yìí, mi ò jáfara láti mú ìlérí mi ṣẹ.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì nígbà tá a wà lórí òkun. Ẹ̀yin náà ẹ fojú inú wo bí mo ṣe wà láàárín Òkun Mẹditaréníà, tí àwọn ẹja ń tọ sókè títí kan ẹja dọ́fìn àti bí omi òkun ṣe lọ salalu. Ní alẹ́, mo rí oríṣiríṣi ìràwọ̀, ìyẹn sì mú kó dá mi lójú pé Ọlọ́run kan wà tó nífẹ̀ẹ́ aráyé.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tá a ti wà lórí òkun, a dé erékùṣù kan nílùú Alicante, lórílẹ̀-èdè Sípéènì. Nígbà tá a wà níbẹ̀, a sọ fáwọn èèyàn pé a fẹ́ ta ọkọ̀ wa ká lè rówó ra èyí tó dáa jùyẹn lọ. Kò yà wá lẹ́nu nígbà tá ò tètè rí oníbàárà torí ọkọ̀ wa ti gbó, kò ní ẹ́ńjìnnì, omi sì tún ń rọ́ wọnú ẹ̀. Àmọ́ mo rí i pé àkókò tó dáa jù lọ nìyẹn fún mi láti ka Bíbélì.

Bí mo ṣe ń ka Bíbélì sí i, bẹ́ẹ̀ ni mò ń rí i pé ìwé kan tó lè jẹ́ kí n gbé ìgbé ayé tó dára ni. Ohun tí mo kà nínú Bíbélì wú mi lórí gan-an torí ó jẹ́ kí n mọ bí mo ṣe lè gbé ìgbé ayé oníwà mímọ́. Àmọ́, ó yà mí lẹ́nu gan-an pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó pe ara wọn ní Kristẹni títí kan èmi fúnra mi ò tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ.

Mo wá pinnu pé màá ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé mi, torí náà mi ò lo oògùn olóró mọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé àwọn èèyàn kan máa wà tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ó sì ń wù mí kí n mọ̀ wọ́n. Mo gbàdúrà lẹ́ẹ̀kejì, mo sì sọ fún Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí n rí wọn.

MÒ Ń WÁ Ẹ̀SÌN TÒÓTỌ́ KIRI

Ní tèmi, mo rí i pé ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí n lọ yẹ ẹ̀sìn kọ̀ọ̀kan wò kí n lè mọ ẹ̀sìn tòótọ́. Bí mo ṣe ń rìn kiri àárín ìlú Alicante, mo rí ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀sìn. Àmọ́ púpọ̀ lára wọn ní àwọn ère ìjọsìn, ìyẹn jẹ́ kí n gbà pé wọn kì í ṣe ẹ̀sìn tòótọ́.

Ní ọ̀sán ọjọ́ Sunday kan, mo wà níbi òkè kan tí mo ti ń wo etíkun lọ́ọ̀ọ́kán, mo sì ń ka Jémíìsì 2:1-5. Ẹsẹ Bíbélì yẹn kìlọ̀ fún wa pé ìwà tí ò dáa ni tá a bá ń fojúure hàn sí ẹnì kan torí pé ó jẹ́ olówó. Nígbà tí mò ń pa dà lọ sí ibi tí ọkọ̀ òkun wa wà, mo rí ilé kan tó dà bí ilé ẹ̀sìn tí wọ́n gbé àkọlé kan síwájú ẹ̀ tó sọ pé: “Kingdom Hall of Jehovah’s Witnesses.”

Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Ó yẹ kí n dán àwọn ẹlẹ́sìn yìí wò, kí n wo bí wọ́n á ṣe ṣe sí mi.’ Torí náà, mo wọ ilé ìjọsìn wọn láìwọ bàtà, irùngbọ̀n mi kún, mo sì wọ ṣòkòtò tó ti ya. Ẹni tó ń bójú tó èrò mú mi lọ jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ obìnrin àgbàlagbà kan. Obìnrin yẹn ló bá mi ṣí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ tọ́ka sí. Lẹ́yìn tí ìpàdé parí, ó yà mí lẹ́nu gan-an pé gbogbo èèyàn ló ń fọ̀yàyà kí mi. Arákùnrin kan wá bá mi, ó sì sọ pé kí n wá sílé òun ká lè jọ sọ̀rọ̀. Àmọ́ torí pé mi ò tíì ka Bíbélì tán, mo sọ fún un pé, “Màá jẹ́ kẹ́ ẹ mọ ìgbà tí màá wá.” Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí gbogbo ìpàdé.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan, mo lọ sílé arákùnrin náà, ó sì fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè mi. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, ó kó àwọn aṣọ tó dáa kún inú àpò kan, ó sì gbé e fún mi. Ó wá sọ fún mi pé ẹni tó ni aṣọ náà wà lẹ́wọ̀n torí pé ó ń pa àṣẹ Bíbélì mọ́ tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa ká má sì lọ́wọ́ sí ogun. (Àìsá. 2:4; Jòh. 13:34, 35) Ó wá dá mi lójú pé mo ti rí àwọn èèyàn tí mò ń wá, tí wọ́n ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, tí wọ́n sì jẹ́ oníwà mímọ́! Bí mi ò ṣe wá erékùṣù tó rẹwà mọ́ nìyẹn. Àmọ́ mo wá pinnu pé màá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí n lè túbọ̀ lóye ẹ̀. Torí náà, mo pa dà sí orílẹ̀-èdè Netherlands.

MÒ Ń WÁ IṢẸ́ KIRI

Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi rìnrìn àjò kí n tó dé ìlú Groningen, lórílẹ̀-èdè Netherlands. Nígbà tí mo débẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá iṣẹ́ tí màá fi bójú tó ara mi. Ní ṣọ́ọ̀bù káfíńtà kan tí mo wáṣẹ́ dé, wọ́n fún mi ní fọ́ọ̀mù kan tó béèrè ẹ̀sìn tí mò ń ṣe. Mo kọ ọ́ síbẹ̀ pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí.” Nígbà tí oníṣọ́ọ̀bù náà ka ohun tí mo kọ sínú fọ́ọ̀mù náà, mo rí i pé ojú ẹ̀ le, ó wá sọ fún mi pé, “Màá pè ẹ́.” Àmọ́, kò pè mí.

Mo tún wáṣẹ́ lọ sí ṣọ́ọ̀bù káfíńtà míì. Mo wá béèrè lọ́wọ́ ẹni tó ni ṣọ́ọ̀bù náà bóyá ó fẹ́ gba èèyàn síṣẹ́. Ó béèrè ìwé ẹ̀rí mi àtàwọn ibi tí mo ti ṣiṣẹ́ sẹ́yìn. Mo sọ fún un pé mo ti tún ọkọ̀ òkun onígi kan ṣe rí. Èsì tó fún mi yà mí lẹ́nu, ó ní: O lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lọ́sàn-án yìí, àmọ́ ohun kan ni o ò gbọ́dọ̀ ṣe. O ò gbọ́dọ̀ fa ìjàngbọ̀n nínú ṣọ́ọ̀bù mi torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, ìlànà Bíbélì ni mo sì ń tẹ̀ lé. Ohun tó sọ yà mí lẹ́nu gan-an, ni mo bá fèsì pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi náà!” Àmọ́, nítorí pé irun orí mi àti irùngbọ̀n mi kún, ó sọ pé, “Màá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!” Inú mi dùn, mo sì gbà láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Mo wá rí ìdí tí oníṣọ́ọ̀bù àkọ́kọ́ yẹn ò fi pè mí pa dà. Mo sì mọ̀ pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà mi. (Sm. 37:4) Mo ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀bù arákùnrin yẹn fún ọdún kan, ó sì kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láàárín àsìkò yẹn. Lẹ́yìn náà, mo ṣèrìbọmi ní January 1974.

NÍGBẸ̀YÌN-GBẸ́YÍN, MO RÍ BÍ MO ṢE LÈ GBÉ ÌGBÉ AYÉ TÓ DÁA!

Oṣù kan lẹ́yìn tí mo ṣe ìrìbọmi, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, iṣẹ́ náà sì ń fún mi láyọ̀. Lóṣù tó tẹ̀ lé e, mo ṣí lọ sílùú Amsterdam láti lọ ṣèrànwọ́ fún àwùjọ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì. Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè Sípáníìṣì àti Potogí! Nígbà tó di May 1975, mo láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Lọ́jọ́ kan, arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń jẹ́ Ineke wá sí ìpàdé wa tá a ti ń sọ èdè Sípáníìṣì, ó sì fi ẹnì kan tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń sọ èdè Bòlífíà hàn wá. Èmi àti Ineke bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa ká lè túbọ̀ mọ ara wa, ìyẹn la fi mọ̀ pé ohun kan náà la fẹ́ fayé wa ṣe. Nígbà tó di ọdún 1976, a ṣègbéyàwó, a sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wa nìṣó títí di ọdún 1982 tí wọ́n pè wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti kíláàsì kẹtàléláàádọ́rin (73). Ó yà wá lẹ́nu gan-an, àmọ́ inú wa dùn nígbà tí wọ́n rán wa lọ sí Ìlà Oòrùn Áfíríkà, a sì lo ọdún márùn-ún nílùú Mombasa, lórílẹ̀-èdè Kenya! Lọ́dún 1987, wọ́n ní ká lọ sìn lórílẹ̀-èdè Tàǹsáníà, torí wọn ò fòfin de iṣẹ́ wa níbẹ̀ mọ́. Ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) la sì lò níbẹ̀ ká tó pa dà sórílẹ̀-èdè Kenya.

Bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ń fún èmi àti ìyàwó mi láyọ̀ gan-an

Bá a ṣe ń ran àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti jẹ́ ká gbé ìgbé ayé tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí mò ń wàásù nílùú Mombasa ni mo pàdé ọkùnrin tí mo kọ́kọ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tí mo fún un ní ìwé ìròyìn méjì, ó béèrè pé, “Tí mo bá ka àwọn ìwé ìròyìn méjì yìí tán, kí ni kí n ṣe?” Ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e la bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látinú ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe lédè Swahili. Lẹ́yìn ọdún kan, ó ṣèrìbọmi, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Látìgbà yẹn, òun àti ìyàwó ẹ̀ ti ran nǹkan bí ọgọ́rùn-ún èèyàn lọ́wọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà tí wọ́n sì ṣèrìbọmi.

Èmi àti Ineke ti fojú ara wa rí i pé Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé tó dáa

Nígbà tí mo wá mọ bí mo ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa, mo dà bí oníṣòwò kan tó ń rìnrìn àjò tó rí péálì kan tó dáa, tó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti rà á. (Mát. 13:45, 46) Torí náà, ohun tó wù mí ni pé kí n ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbé ìgbé ayé tó dáa. Èmi àti ìyàwó mi sì ti fojú ara wa rí i pé Jèhófà máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé tó dáa.