Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 44

Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?

Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?

“Ìfẹ́ [Jèhófà] tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”​—SM. 136:1.

ORIN 108 Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe?

INÚ Jèhófà máa ń dùn láti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. (Hós. 6:6) Ó sì rọ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Míkà sọ fún wa pé ká “fẹ́ràn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.” (Míkà 6:8, àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, ó hàn gbangba pé ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́.

2. Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀?

2 Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Gbólóhùn náà “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” fara hàn nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n (230) ìgbà. Àmọ́ kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Bí “Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì” yìí ṣe sọ, ó ń tọ́ka sí “ìfẹ́ tí ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin àti adúrótini ní sáwọn èèyàn. Bíbélì sábà máa ń lò ó fún ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwa èèyàn, àmọ́ ó tún jẹ́ ìfẹ́ táwa èèyàn ní sí èèyàn bíi tiwa.” Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ká fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwa èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe lè tè lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ká sì máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn.

‘ÌFẸ́ JÈHÓFÀ TÍ KÌ Í YẸ̀ PỌ̀ GIDIGIDI’

3. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí Mósè mọ irú ẹni tóun jẹ́?

3 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fún Mósè. Ó sọ pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini.” (Ẹ́kís. 34:6, 7) Àwọn ànímọ́ tí Jèhófà sọ fún Mósè pé òun ní yìí jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀ lòun jẹ́. Torí náà, kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀?

4-5. (a) Irú ẹni wo ni Jèhófà sọ pé òun jẹ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

4 Nígbà tí Jèhófà ń sọ irú ẹni tí òun jẹ́, kò kàn sọ pé òun ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ nìkan, àmọ́ ohun tó sọ ni pé ‘ìfẹ́ òun tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ Gbólóhùn yìí tún fara hàn níbi mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì. (Nọ́ń. 14:18; Neh. 9:17; Sm. 86:15; 103:8; Jóẹ́lì 2:13; Jónà 4:2) Kò sẹ́ni tá a máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún àfi Jèhófà nìkan ṣoṣo. Ẹ ò rí i pé bí Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ ànímọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀ lòun jẹ́. Torí náà, ó dájú pé ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì lójú ẹ̀. * Abájọ tí Ọba Dáfídì fi sọ nípa Jèhófà pé: “Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga dé ọ̀run . . . Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ mà ṣeyebíye o, Ọlọ́run! Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ ni àwọn ọmọ èèyàn fi ṣe ibi ààbò.” (Sm. 36:5, 7) Bíi ti Dáfídì, ṣé àwa náà mọyì ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀?

5 Ká lè túbọ̀ lóye ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè méjì yìí yẹ̀ wò: Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀?

ÀWỌN WO NI JÈHÓFÀ MÁA Ń FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÍ?

6. Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí?

6 Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí? Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan la lè nífẹ̀ẹ́, irú bí “iṣẹ́ àgbẹ̀,” “wáìnì àti òróró,” “ẹ̀kọ́,” “ìmọ̀,” “ọgbọ́n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (2 Kíró. 26:10; Òwe 12:1; 21:17; 29:3) Àmọ́ ṣá o, a kì í ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sáwọn nǹkan yìí, àwa èèyàn nìkan ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn sí àfi àwọn tó bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run máa ń jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn ohun rere kan wà tó fẹ́ ṣe fún wọn, ìgbà gbogbo lá sì máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn.

Jèhófà ń pèsè ọ̀pọ̀ ohun rere fún aráyé títí kan àwọn tí kò jọ́sìn rẹ̀(Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn?

7 Gbogbo aráyé ni Jèhófà ti fi ìfẹ́ hàn sí. Jésù sọ fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nikodémù pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ [aráyé] gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòh. 3:1, 16; Mát. 5:44, 45.

Àwọn ohun tí Ọba Dáfídì àti wòlíì Dáníẹ́lì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí tí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ (Wo ìpínrọ̀ 8-9)

8-9. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

8 Bá a ṣe sọ níṣàájú, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nìkan ló máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí. Ohun tí Ọba Dáfídì àti wòlíì Dáníẹ́lì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé: “Máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sí àwọn tó mọ̀ ọ́.” “Àmọ́ ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí ayé sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.” Dáníẹ́lì ní tiẹ̀ sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, [ẹni tó] ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Sm. 36:10; 103:17; Dán. 9:4) Bí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, ìdí tí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Torí náà, àwọn tó bá ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tọ́ nìkan ló máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí.

9 Kó tó di pé a di ìránṣẹ́ Jèhófà la ti ń gbádùn ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí aráyé. (Sm. 104:14) Àmọ́, lẹ́yìn tá a di ìránṣẹ́ rẹ̀, a wá ń gbádùn ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Kódà, Jèhófà fi dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé: “Ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Àìsá. 54:10) Dáfídì rí bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ yìí hàn sí òun, ó sọ pé: “Jèhófà máa ṣìkẹ́ ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Sm. 4:3) Torí náà, kí ló yẹ ká ṣe bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń bójú tó wa lọ́nà àrà ọ̀tọ̀? Onísáàmù sọ pé: “Ẹni tó bá gbọ́n yóò kíyè sí àwọn nǹkan yìí, yóò sì fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.” (Sm. 107:43) Jèhófà fẹ́ ká fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà mẹ́ta táwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà ń jàǹfààní ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

BÁWO LA ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ TÍ KÌ Í YẸ̀?

Jèhófà máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere fáwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 10-16) *

10. Báwo ni ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ tó wà títí láé ṣe ń ṣe wá láǹfààní? (Sáàmù 31:7)

10 Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà títí láé. Ìgbà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni gbólóhùn náà ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà títí láé fara hàn nínú Sáàmù kẹrìndínlógóje (136), ìyẹn sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an. Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú orí yìí kà pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.” (Sm. 136:1) Ní ẹsẹ kejì sí kẹrìndínlọ́gbọ̀n (26), gbólóhùn náà “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fara hàn ní ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Bá a ṣe ń ka àwọn ẹsẹ tó kù nínú Sáàmù kẹrìndínlógóje (136) yìí, ó yà wá lẹ́nu bá a ṣe ń rí i pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn. Gbólóhùn náà “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fi dá wa lójú pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwa èèyàn rẹ̀ kì í yí pa dà. Ẹ ò rí i bó ṣe múnú wa dùn tó pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀! Kì í fi àwọn tó ń sìn ín sílẹ̀, ńṣe ló máa ń dúró tì wọ́n pàápàá nígbà ìṣòro. Àǹfààní tó ń ṣe wá: Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ ń jẹ́ ká máa láyọ̀, ó sì ń jẹ́ ká lókun láti máa fara da àwọn ìṣòro wa, ká sì máa rìn ní ọ̀nà ìyè.​—Ka Sáàmù 31:7.

11. Sáàmù 86:5 ṣe sọ, kí ló máa ń mú kí Jèhófà dárí jini?

11 Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ló ń mú kó dárí jì wá. Tí Jèhófà bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ronú pìwà dà, tí kò sì pa dà dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ máa mú kó dárí ji ẹni náà. Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa, kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.” (Sm. 103:8-11) Dáfídì mọ bó ṣe máa ń rí tí ìbànújẹ́ bá dorí ẹni kodò torí ẹ̀rí ọkàn tó ń dáni lẹ́bi. Àmọ́ ó tún mọ̀ pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini.” Kí ló ń mú kí Jèhófà máa dárí jini? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú Sáàmù 86:5. (Kà á.) Bí Dáfídì ṣe sọ nínú àdúrà rẹ̀ ló rí, Jèhófà máa ń dárí jini torí pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè é pọ̀ gidigidi.

12-13. Tí ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá sẹ́yìn bá ń mú kó o máa dá ara rẹ lẹ́bi, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

12 Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ ká kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ ká ronú pìwà dà, ká sì gbégbèésẹ̀ láti ṣàtúnṣe. Àmọ́, àwọn kan lára ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣì máa ń dára wọn lẹ́bi torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá ṣẹ́yìn. Ọkàn wọn tó ṣì ń dá wọn lẹ́bi ń mú kí wọ́n rò pé Jèhófà ò lè dárí ji àwọn láé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ronú pìwà dà tí wọn ò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹ, á sì mú kó o borí èrò náà.

13 Àǹfààní tó ń ṣe wá: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìpé, a ṣì lè máa fi ayọ̀ sin Jèhófà pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Èyí ṣeé ṣe torí pé ‘ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.’ (1 Jòh. 1:7) Tí àwọn àṣìṣe ẹ bá ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, rántí pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì ẹ́ tó o bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Wo ohun tí Dáfídì sọ tó fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló ń mú kí Ọlọ́run dárí jini. Ó sọ pé: “Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga. Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.” (Sm. 103:11, 12) Ká sòótọ́, Jèhófà ṣe tán láti “dárí jini fàlàlà.”​—Àìsá. 55:7

14. Báwo ni Dáfídì ṣe ṣàlàyé bí ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ṣe ń dáàbò bò wá?

14 Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ kò ní jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Nínú àdúrà kan tí Dáfídì gbà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Ìwọ ni ibi ìfarapamọ́ mi; wàá dáàbò bò mí nínú wàhálà. Wàá fi igbe ayọ̀ ìgbàlà yí mi ká. . . . Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé E ká.” (Sm. 32:7, 10) Bí wọ́n ṣe máa ń mọ odi yí ìlú kan ká láyé àtijọ́ láti dáàbò bo àwọn ará ìlú, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ yí wa ká, kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fà wá mọ́ra.​—Jer. 31:3.

15. Báwo ni ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ṣe dà bí ibi ààbò?

15 Dáfídì lo àfiwé míì láti fi ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀. Ó sọ pé: “Ọlọ́run ni ibi ààbò mi, Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.” Dáfídì tún sọ nípa Jèhófà pé: “Òun ni ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ àti ibi ààbò mi, ibi gíga mi tó láàbò àti olùgbàlà mi, apata mi àti Ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò.” (Sm. 59:17; 144:2) Kí nìdí tí Dáfídì ṣe fi ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wé ibi ààbò àti odi ààbò? Ibi yóówù ká máa gbé láyé, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, ó máa dáàbò bò wá ní gbogbo ọ̀nà kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe tó dáa tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Ohun kan náà ni Jèhófà fi dá wa lójú nínú Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún (91). Ẹni tó kọ sáàmù yẹn sọ pé: “Màá sọ fún Jèhófà pé: ‘Ìwọ ni ibi ààbò mi àti odi ààbò mi.’ ” (Sm. 91:1-3, 9, 14) Mósè náà lo àfiwé kan tó jọ ọ́ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ibi ààbò. (Sm. 90:1, àlàyé ìsàlẹ̀) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí àkókò ikú Mósè ti sún mọ́lé, ó lo àfiwé míì tó ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò láti ìgbà àtijọ́, ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ.” (Diu. 33:27) Kí ni gbólóhùn náà “ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ” jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

16. Ọ̀nà méjì wo ni Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́? (Sáàmù 136:23)

16 Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bò wá, ọkàn wa máa balẹ̀. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú wa débi tá ò fi ní lókun mọ́. Nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, kí ni Jèhófà máa ń ṣe fún wa? (Ka Sáàmù 136:23.) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, ó máa rọra fi apá rẹ̀ gbé wa dìde, kò sì ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì mọ́. (Sm. 28:9; 94:18) Àǹfààní tó ń ṣe wá: Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn máa ń jẹ́ ká rántí pé ọ̀nà méjì ló ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, ibi yòówù ká máa gbé, a mọ̀ pé Jèhófà á máa dáàbò bò wá. Ìkejì, Bàbá wa ọ̀run ń fìfẹ́ bójú tó wa.

Ó DÁJÚ PÉ ỌLỌ́RUN Á MÁA FI ÌFẸ́ RẸ̀ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÍ WA

17. Kí ló dá wa lójú nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà fi ń hàn sí wa? (Sáàmù 33:18-22)

17 Látinú ohun tá a ti jíròrò, a ti rí i pé tá a bá kojú ìṣòro, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ má bàa bà jẹ́. (2 Kọ́r. 4:7-9) Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Nítorí ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ni ò jẹ́ ká ṣègbé, nítorí àánú rẹ̀ kò ní dópin láé.” (Ìdárò 3:22) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà á máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa nìṣó, torí onísáàmù fi dá wa lójú pé, “ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.”​—Ka Sáàmù 33:18-22.

18-19. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

18 Kí lohun tó yẹ ká fi sọ́kàn? Kó tó di pé a di ìránṣẹ́ Jèhófà la ti ń gbádùn ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí aráyé. Àmọ́, lẹ́yìn tá a di ìránṣẹ́ rẹ̀, a wá ń gbádùn ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa yìí ló jẹ́ kó fà wá mọ́ra, tó sì ń mú kó máa dáàbò bò wá. Jèhófà á máa wà pẹ̀lú wa nígbà gbogbo, á sì mú àwọn ìlérí tó ṣe fún wa ṣẹ. Ẹ ò rí i pé Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun títí láé! (Sm. 46:1, 2, 7) Torí náà, ìṣòro yòówù ká máa kojú, Jèhófà á fún wa lókun ká lè jẹ́ olóòótọ́.

19 A ti rí bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ohun tó ń fẹ́ káwa náà máa ṣe ni pé ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn. Báwo la ṣe máa fi ìfẹ́ yìí hàn? A máa jíròrò kókó pàtàkì yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

ORIN 136 “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Èrè” Látọ̀dọ̀ Jèhófà

^ ìpínrọ̀ 5 Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí, báwo sì ni àwọn tó fi ìfẹ́ yìí hàn sí ṣe ń jàǹfààní rẹ̀? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ méjì àkọ́kọ́ tá a ti máa jíròrò ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí.

^ ìpínrọ̀ 4 Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì míì, a tún sọ̀rọ̀ nípa bí ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ṣe pọ̀ gidigidi.​—Wo Nehemáyà 13:22; Sáàmù 69:13; 106:7; àti Ìdárò 3:32.

^ ìpínrọ̀ 54 ÀWÒRÁN: Gbogbo aráyé ni Jèhófà ń fi ìfẹ́ hàn sí títí kan àwa ìránṣẹ́ rẹ̀. Àwọn àwòrán tó wà lókè àwọn èèyàn yẹn ń fi ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa hàn. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lára nǹkan tí Ọlọ́run fún wa yìí ni Jésù ọmọ rẹ̀ tó kú nítorí wa.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sáwọn tó di ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Yàtọ̀ sí pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbádùn ìfẹ́ tó ń fi hàn sí gbogbo aráyé, a tún ń gbádùn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ń fi hàn sí wa. Àwọn kan lára nǹkan tá à ń gbádùn ló wà nínú àwọn àwòrán yẹn.