Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Alábàáṣiṣẹ́ Rere Ni Ẹ́?

Ṣé Alábàáṣiṣẹ́ Rere Ni Ẹ́?

“MO WÀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́. . . . Inú mi sì ń dùn níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 8:30) Ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run nìyẹn ní gbogbo àìmọye ọdún tó fi bá Bàbá rẹ̀ ṣiṣẹ́ lọ́run kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí tún sọ bí nǹkan ṣe rí lára Jésù ní gbogbo àsìkò tó bá Jèhófà ṣiṣẹ́, ó ní ‘inú rẹ̀ ń dùn’ níwájú Jèhófà.

Nígbà tí Jésù wà lọ́run, ó kọ́ àwọn ànímọ́ tó jẹ́ kó di alábàáṣiṣẹ́ rere. Torí náà, nígbà tó wá sáyé, àpẹẹrẹ rere ló jẹ́ fáwọn tó bá ṣiṣẹ́. Kí la kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jésù? Tá a bá gbé àpẹẹrẹ Jésù yẹ̀ wò dáadáa, a máa rí àwọn ìlànà mẹ́ta tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ tó dáa. Àwọn ìlànà yìí máa jẹ́ ká wà níṣọ̀kan, ká sì máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará tá à ń bá ṣiṣẹ́.

Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, kó o máa sọ àwọn ohun tó o ti kọ́ àtohun tó o mọ̀ fáwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́

ÌLÀNÀ 1: ‘Ẹ MÁA BU ỌLÁ FÚN ARA YÍN’

Alábàáṣiṣẹ́ rere máa ń lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó gbà pé àwọn tóun ń bá ṣiṣẹ́ ṣe pàtàkì, kì í sì í pe àfiyèsí sí ara ẹ̀. Ara Jèhófà ni Jésù ti kọ́ ìrẹ̀lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà nìkan ni a lè pè ní Ẹlẹ́dàá, síbẹ̀ ó jẹ́ káwọn míì mọ iṣẹ́ ribiribi tí Jésù Ọmọ ẹ̀ ṣe nígbà tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ohun tí Jèhófà sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Jẹ́ dá èèyàn ní àwòrán wa.” (Jẹ́n. 1:26) Ó dájú pé Jésù mọyì ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní nígbà tóun fúnra ẹ̀ gbọ́ ohun tí Bàbá rẹ̀ sọ.​—Sm. 18:35.

Jésù náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà táwọn èèyàn ń yìn ín torí àwọn nǹkan tó ṣe, Jèhófà ló gbé gbogbo ọpẹ́ náà fún. (Máàkù 10:17, 18; Jòh. 7:15, 16) Jésù ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀, ṣe ló mú wọn bí ọ̀rẹ́, kò mú wọn bí ẹrú. (Jòh. 15:15) Kódà, ó fọ ẹsẹ̀ wọn kó lè kọ́ wọn nírẹ̀lẹ̀. (Jòh. 13:5, 12-14) Ó yẹ káwa náà ṣe bíi Jésù, ká mọyì àwọn tá à ń bá ṣiṣẹ́, dípò kó jẹ́ pé tara wa nìkan làá máa rò. Tá a bá ń ‘bu ọlá fún’ àwọn míì, a ò ní máa da ara wa láàmú pé ẹlòmíì ló máa gba oríyìn tó yẹ ká gbà, ìyẹn ló sì máa jẹ́ ká gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe.​—Róòmù 12:10.

Ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tún máa ń gbà pé “nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ agbani-nímọ̀ràn, àṣeyọrí [máa ń] wà.” (Òwe 15:22) Ó yẹ ká máa rántí pé kò sí bá a ṣe ní ìrírí tó tàbí tá a mọ nǹkan ṣe tó, kò séèyàn tó mọ gbogbo nǹkan tán. Kódà, Jésù gan-an gbà pé àwọn nǹkan kan wà tóun ò mọ̀. (Mát. 24:36) Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ́ mọ ohun táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ń rò nípa òun bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n. (Mát. 16:13-16) Kò yà wá lẹ́nu pé ara àwọn tó bá a ṣiṣẹ́ máa ń balẹ̀ lọ́dọ̀ ẹ̀! Torí náà, tá a bá ń fi sọ́kàn pé kì í ṣe gbogbo nǹkan la mọ̀, tá a sì ń jẹ́ káwọn míì dá sí iṣẹ́ náà, àlàáfíà máa wà láàárín wa, àá sì jọ ṣe iṣẹ́ náà ní “àṣeyọrí.”

Bíi ti Jésù, ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn alàgbà máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn bí wọ́n ṣe ń bá àwọn alàgbà míì ṣiṣẹ́. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé alàgbà èyíkéyìí ni ẹ̀mí mímọ́ lè mú kó sọ tàbí ṣe ohun tó máa ran ìgbìmọ̀ náà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Ní ìpàdé àwọn alàgbà, wọ́n máa ń sapá láti jẹ́ kára tu gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀, kó sì rọrùn fún wọn láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á jọ ṣe ìpinnu tó máa ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní.

ÌLÀNÀ 2: “Ẹ JẸ́ KÍ GBOGBO ÈÈYÀN RÍ I PÉ Ẹ̀ Ń FÒYE BÁNI LÒ”

Alábàáṣiṣẹ́ rere máa ń fòye bá àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ lò. Kì í rin kinkin mọ́ èrò ara ẹ̀, ó sì máa ń gba tàwọn míì rò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ti kíyè sí bí Bàbá rẹ̀ ṣe gba tàwọn míì rò. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà rán an láti wá gba aráyé sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú tá a jogún.​—Jòh. 3:16.

Jésù máa ń gba tàwọn èèyàn rò. Ẹ rántí bó ṣe ran obìnrin ará Foníṣíà kan lọ́wọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé Ísírẹ́lì ni Jèhófà rán an sí. (Mát. 15:22-28) Ó tún gba tàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ rò. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Pétérù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ sọ pé òun ò mọ̀ ọ́n rí níṣojú àwọn èèyàn, Jésù dárí jì í. Nígbà tó sì yá, ó gbé àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan fún Pétérù. (Lúùkù 22:32; Jòh. 21:17; Ìṣe 2:14; 8:14-17; 10:44, 45) Àpẹẹrẹ Jésù jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń “fòye báni lò,” àá máa gba tàwọn èèyàn rò.​—Fílí. 4:5.

Tá a bá ń fòye báni lò, àlàáfíà máa wà láàárín àwa àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, láìka irú ẹni tí wọ́n jẹ́ sí. Jésù ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn débi pé àwọn ọ̀tá tó ń jowú ẹ̀ pè é ní “ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀” tí wọ́n tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀. (Mát. 11:19) Bíi ti Jésù, ṣé àwa náà lè bá àwọn tí ìwà wọn yàtọ̀ sí tiwa ṣiṣẹ́ láìsí wàhálà? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Arákùnrin Louis sọ. Ó ti bá oríṣiríṣi èèyàn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣiṣẹ́ nígbà tó jẹ́ alábòójútó àyíká àti nígbà tó wà ní Bẹ́tẹ́lì. Ó ní: “Mo máa ń fi àwọn tí mò ń bá ṣiṣẹ́ wé ògiri kan tá a fi òkúta tó tóbi jura wọn lọ kọ́. Tá a bá tún àwọn òkúta kan nínú ẹ̀ tò, ògiri náà á wá gún régé. Èmi náà máa ń ṣe àwọn àtúnṣe kan fúnra mi kí n lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tí mò ń bá ṣiṣẹ́, ká sì lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí.” Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn!

Alábàáṣiṣẹ́ rere kì í fi nǹkan pa mọ́ fáwọn tó yẹ kó sọ ọ́ fún, kì í sì í rò pé wọ́n á gba ipò mọ́ òun lọ́wọ́ tóun bá sọ fún wọn

Àwọn ìgbà wo ló yẹ ká fi hàn pé à ń gba tàwọn èèyàn rò nínú ìjọ wa? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù wa. Ó lè jẹ́ àwọn tí bùkátà ìdílé wọn pọ̀ ju tiwa lọ la máa bá ṣiṣẹ́, ó sì lè jẹ́ àwọn tó jù wá lọ tàbí àwọn tá a jù lọ la jọ máa ṣiṣẹ́. Ṣé a lè gba tiwọn rò, ká sì lo àwọn ọ̀nà míì tó tù wọ́n lára láti wàásù káwọn náà lè láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn?

ÌLÀNÀ 3: “ṢE TÁN LÁTI MÁA FÚNNI”

Alábàáṣiṣẹ́ rere máa ń ‘ṣe tán láti fúnni.’ (1 Tím. 6:18) Nígbà tí Jésù ń bá Bàbá ẹ̀ ṣiṣẹ́, ó dájú pé á ti kíyè sí i pé Jèhófà kì í fi nǹkan pa mọ́. Nígbà tí Jèhófà “dá ọ̀run,” Jésù “wà níbẹ̀,” ó sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Bàbá ẹ̀. (Òwe 8:27) Nígbà tó yá, inú Jésù dùn láti sọ àwọn “ohun [tó] gbọ́” látọ̀dọ̀ Bàbá ẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀. (Jòh. 15:15) Bíi ti Jèhófà àti Jésù, ẹ jẹ́ káwa náà máa sọ ohun tá a ti kọ́ fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Ó dájú pé alábàáṣiṣẹ́ rere kì í fi nǹkan pa mọ́ fáwọn tó yẹ kó sọ ọ́ fún, kì í sì í rò pé wọ́n á gba ipò mọ́ òun lọ́wọ́ tóun bá sọ fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ̀ máa ń dùn láti sọ àwọn ohun tó ti kọ́ fáwọn míì.

A tún lè sọ ọ̀rọ̀ ìṣírí fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́. Ṣé inú wa kì í dùn tẹ́nì kan bá kíyè sí nǹkan dáadáa tá a ṣe, tó sì gbóríyìn fún wa? Jésù náà sọ nǹkan dáadáa tó kíyè sí lára àwọn tó bá a ṣiṣẹ́. (Fi wé Mátíù 25:19-23; Lúùkù 10:17-20.) Kódà, ó sọ fún wọn pé wọ́n máa “ṣe àwọn iṣẹ́ tó tóbi ju” tòun lọ. (Jòh. 14:12) Ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ tó kú, ó gbóríyìn fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin lẹ ti dúró tì mí nígbà àdánwò.” (Lúùkù 22:28) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tó sọ fún wọn yìí máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn, á sì mú kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ náà! Táwa náà bá ń gbóríyìn fáwọn tá à ń bá ṣiṣẹ́, inú wọn á dùn, wọ́n á sì ṣe púpọ̀ sí i.

ÌWỌ NÁÀ LÈ JẸ́ ALÁBÀÁṢIṢẸ́ RERE

Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Kayode sọ pé: “Alábàáṣiṣẹ́ rere kì í ṣe ẹni pípé. Àmọ́, ó máa ń múnú àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ dùn, ó sì máa ń jẹ́ kíṣẹ́ náà rọrùn fún wọn.” Ṣé irú ẹni táwọn tó ò ń bá ṣiṣẹ́ mọ̀ ẹ́ sí nìyẹn? O ò ṣe bi àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pé báwo nìwà ẹ ṣe rí lẹ́nu iṣẹ́? Tí inú wọn bá ń dùn bí wọ́n ṣe ń bá ẹ ṣiṣẹ́ bí inú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù náà ṣe dùn nígbà tí wọ́n bá a ṣiṣẹ́, ìwọ náà á sọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “A jọ ń ṣiṣẹ́ [ká] lè máa láyọ̀.”​—2 Kọ́r. 1:24.