Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 6

Ṣé O Gbà Pé Ohun Tó Tọ́ Ni Jèhófà Máa Ń Ṣe?

Ṣé O Gbà Pé Ohun Tó Tọ́ Ni Jèhófà Máa Ń Ṣe?

“Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, torí ó ń ṣe ìdájọ́ òdodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀. Ọlọ́run olóòótọ́, tí kì í ṣe ojúsàájú; olódodo àti adúróṣinṣin ni.”​—DIU. 32:4.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. (a) Kí nìdí tó fi ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí láti fọkàn tán àwọn aláṣẹ? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

 LÓDE òní ó máa ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti fọkàn tán àwọn aláṣẹ. Wọ́n ti rí i pé àwọn adájọ́ àtàwọn olóṣèlú máa ń ṣojúure sáwọn olówó àtàwọn èèyàn pàtàkì láwùjọ, wọ́n sì máa ń fi ẹ̀tọ́ àwọn tálákà dù wọ́n. Èyí jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé: “Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” (Oníw. 8:9) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn olórí ẹ̀sìn kan máa ń hùwà burúkú, ìyẹn ni ò jẹ́ káwọn èèyàn kan fọkàn tán Ọlọ́run mọ́. Torí náà, tẹ́nì kan bá gbà pé ká kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kì í rọrùn fún wa láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè fọkàn tán Jèhófà àtàwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò rẹ̀.

2 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ló yẹ kó mọ bá a ṣe lè fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀. Àwa tá a ti ń sin Jèhófà bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún náà yẹ kó fọkàn tán Jèhófà pé kò sígbà tí kì í ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́. Àmọ́ nígbà míì, àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ tó máa ń dán ìgbàgbọ́ wa wò bóyá a fọkàn tán Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mẹ́ta tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò: (1) tá a bá ń ka ìtàn Bíbélì kan tí kò yé wa, (2) tí ètò Ọlọ́run bá ní ká ṣe ohun kan àti (3) tá a bá dojú kọ wàhálà lọ́jọ́ iwájú.

FỌKÀN TÁN JÈHÓFÀ NÍGBÀ TÓ O BÁ Ń KA BÍBÉLÌ

3. Báwo làwọn ìtàn Bíbélì kan ṣe lè dán wa wò bóyá a fọkàn tán Jèhófà?

 3 Tá a bá ń ka Bíbélì, àwọn ìbéèrè kan lè wá sí wa lọ́kàn nípa ohun tí Jèhófà ṣe sáwọn èèyàn kan àti ìdí tó fi ṣe àwọn ìpinnu kan. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Nọ́ńbà, a kà nípa bí Jèhófà ṣe ní kí wọ́n pa ọmọ Ísírẹ́lì kan torí pé ó ń ṣa igi lọ́jọ́ Sábáàtì. Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún méjì lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nínú Sámúẹ́lì kejì pé Jèhófà dárí ji Ọba Dáfídì tó bá ìyàwó oníyàwó sùn, tó sì tún pa ọkọ ẹ̀. (Nọ́ń. 15:32, 35; 2 Sám. 12:9, 13) Torí náà, a lè máa rò pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi dárí ji Dáfídì tó ṣàgbèrè tó sì tún pààyàn, àmọ́ tó ní kí wọ́n pa ọkùnrin tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó jọ pé kò tó nǹkan?’ Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́ta tó yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń ka Bíbélì.

4. Báwo ni Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21 àti Diutarónómì 10:17 ṣe jẹ́ ká túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà pé ìdájọ́ tó dáa ló máa ń ṣe?

4 Bíbélì kì í sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn kan. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ fún wa pé nígbà tí Dáfídì dẹ́ṣẹ̀, ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (Sm. 51:2-4) Àmọ́ irú èèyàn wo ni ọkùnrin tó rú òfin Sábáàtì yẹn? Ṣé ó kábàámọ̀ ohun tó ṣe? Ṣé ó ti máa ń rú àwọn òfin Jèhófà tẹ́lẹ̀? Tí wọ́n bá kìlọ̀ fún un, ṣé ó máa ń gbọ́? Bíbélì ò sọ fún wa. Ṣùgbọ́n ohun kan tó dájú ni pé Jèhófà “kì í ṣe ojúsàájú.” (Diu. 32:4) Ohun tí Jèhófà bá rí i pé ó jóòótọ́ ló fi máa ń ṣèdájọ́ àwọn èèyàn, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn bá sọ tàbí ìkórìíra tó ń mú káwọn èèyàn ní èrò tí ò dáa nípa ẹnì kan. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21; Diutarónómì 10:17.) Bá a bá ṣe túbọ̀ ń mọ Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa fọkàn tán Jèhófà nígbà tó bá ṣèdájọ́. Tá a bá ka ìtàn Bíbélì kan tá a sì láwọn ìbéèrè, àmọ́ tá ò tíì rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè náà, gbogbo nǹkan tá a mọ̀ nípa Jèhófà jẹ́ kó dá wa lójú pé ó jẹ́ “adúróṣinṣin nínú gbogbo ohun tó ń ṣe.”​—Sm. 145:17.

5. Báwo ni àìpé ṣe máa ń jẹ́ ká ṣèdájọ́ lọ́nà tí kò tọ́? (Wo àpótí náà, “ Àìpé Kì Í Jẹ́ Ká Lóye Àwọn Nǹkan Kan Lọ́nà Tó Tọ́.”)

5 Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, a ò lè ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́. Torí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán ara rẹ̀, ó máa ń wù wá ká ṣe ohun tó tọ́ sáwọn èèyàn. (Jẹ́n. 1:26) Àmọ́ torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè ṣi ẹjọ́ dá tá a bá tiẹ̀ rò pé a mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ẹ rántí pé inú Jónà ò dùn nígbà tí Jèhófà fàánú hàn sáwọn ará Nínéfè? (Jónà 3:10–4:1) Àmọ́ kí lohun tí Jèhófà ṣe yìí yọrí sí? Èyí jẹ́ kí àwọn ará ìlú Nínéfè tí iye wọn ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) lọ, tí wọ́n sì ti ronú pìwà dà rí ìgbàlà! Ẹ ò rí i pé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Jónà ló ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tí kò tọ́, kì í ṣe Jèhófà.

6. Kí nìdí tí ò fi pọn dandan kí Jèhófà ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan?

6 Kò pọn dandan kí Jèhófà ṣàlàyé fáwa èèyàn ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan. Lóòótọ́, Jèhófà fàyè gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà àtijọ́ láti sọ èrò wọn lórí ohun tó ṣe tàbí ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣe. (Jẹ́n. 18:25; Jónà 4:2, 3) Àmọ́ nígbà míì, ó máa ń sọ ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan fún wọn. (Jónà 4:10, 11) Síbẹ̀, kò pọn dandan kí Jèhófà ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe àwọn ohun tó ṣe. Torí pé Jèhófà ló dá wa, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní máa béèrè lọ́wọ́ wa bóyá a fọwọ́ sóhun tóun fẹ́ ṣe tàbí ohun tóun ti ṣe.​—Àìsá. 40:13, 14; 55:9.

FỌKÀN TÁN JÈHÓFÀ TÍ ÈTÒ RẸ̀ BÁ NÍ KÁ ṢE OHUN KAN

7. Kí ló lè jẹ́ ìṣòro wa, kí sì nìdí?

7 Láìsí iyè méjì, gbogbo ọkàn la fi gbà pé Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo. Àmọ́, ó lè ṣòro fún wa láti fọkàn tán àwọn tí Jèhófà ní kó máa ṣàbójútó wa. A lè máa rò ó pé, ṣé ohun tí Jèhófà ní káwọn tó ń ṣàbójútó wa nínú ètò rẹ̀ máa ṣe ni wọ́n ń ṣe, àbí ohun tó wù wọ́n? Irú èrò yìí kan náà ló ṣeé ṣe káwọn kan ní nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ tá a sọ ní  ìpínrọ̀ kẹta yẹ̀ wò. Mọ̀lẹ́bí ọkùnrin tó rú òfin Sábáàtì náà lè rò pé, ṣé lóòótọ́ ni Mósè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ kó tó ní kí wọ́n pa ọkùnrin náà? Nígbà tí Dáfídì bá ìyàwó Ùráyà ọmọ Hétì ṣàgbèrè, ọ̀rẹ́ Ùráyà kan lè rò pé ṣe ni Dáfídì lo ipò ọba rẹ̀ láti dọ́gbọ́n sí i kí wọ́n má bàa pa á. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a ò lè fọkàn tán Jèhófà tá ò bá fọkàn tán àwọn tó ní kó máa ṣàbójútó nínú ètò rẹ̀ torí pé Jèhófà ti fọkàn tán wọn.

8. Kí ló wà nínú Ìṣe 16:4, 5 tó jọ bí ìjọ Kristẹni ṣe ń ṣe nǹkan lónìí?

8 Lónìí, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni Jèhófà ń lò láti darí àwa èèyàn ẹ̀. (Mát. 24:45) Bíi ti ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ẹrú yìí ló ń ṣàbójútó àwa èèyàn Ọlọ́run kárí ayé, wọ́n sì ń fún àwọn alàgbà ní ìtọ́sọ́nà. (Ka Ìṣe 16:4, 5.) Àwọn alàgbà á sì rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà náà nínú ìjọ. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run àti tàwọn alàgbà ìjọ, ìyẹn á fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ń ṣe ohun tó tọ́.

9. Ìgbà wo ló lè ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe, kí sì nìdí?

9 Nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ ìjọ àti àyíká la ti tún tò. Láwọn ibì kan, àwọn alàgbà sọ fún àwọn akéde kan pé kí wọ́n lọ dara pọ̀ mọ́ àwọn ará ìjọ míì kí wọ́n lè lo àyè tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà tán. Tí wọ́n bá ní ká lọ dara pọ̀ mọ́ ìjọ tuntun kan, ó lè ṣòro fún wa láti fi àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé wa sílẹ̀. Ṣé Jèhófà ló sọ ìjọ táwọn alàgbà yẹn máa yan akéde kọ̀ọ̀kan sí? Rárá. Torí náà, ìyẹn lè jẹ́ kó ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ. Àmọ́ Jèhófà fọkàn tán àwọn alàgbà yẹn pé wọ́n á ṣe ìpinnu tó tọ́ nírú àwọn ipò yẹn, ó sì yẹ káwa náà fọkàn tán wọn. *

10.Hébérù 13:17 ṣe sọ, kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé ohun táwọn alàgbà bá sọ?

10 Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé ohun táwọn alàgbà bá sọ, kódà tí ìpinnu tí wọ́n ṣe ò bá tẹ́ wa lọ́rùn? Ìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, á jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run. (Éfé. 4:2, 3) Tí gbogbo àwọn ará bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé ìpinnu ìgbìmọ̀ alàgbà ìjọ wọn, ìyẹn á jẹ́ kí ìjọ túbọ̀ lágbára. (Ka Hébérù 13:17.) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà tá a bá fọkàn tán àwọn tó ní kó máa ṣàbójútó wa, tá a sì ń tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ.​—Ìṣe 20:28.

11. Kí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ fọkàn tán àwọn alàgbà tí wọ́n bá ní ká ṣe ohun kan?

11 Táwọn alàgbà bá ní ká ṣe ohun kan, ohun tó máa jẹ́ ká túbọ̀ fọkàn tán wọn ni tá a bá ń rántí pé wọ́n máa ń gbàdúrà kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó kan ìjọ. Wọ́n tún máa ń fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ìpinnu tí wọ́n fẹ́ ṣe mu, wọ́n sì máa ń wo àwọn ìlànà tí ètò Ọlọ́run ti fún wa pé ká máa tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ ṣe àwọn nǹkan kan. Bí wọ́n ṣe máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, tí wọ́n á sì bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ lohun tó jẹ wọ́n lógún. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí mọ̀ pé àwọn máa jíhìn fún Ọlọ́run nítorí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe iṣẹ́ àbójútó wọn. (1 Pét. 5:2, 3) Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, nínú ayé lónìí, ẹ̀yà, ẹ̀sìn àti òṣèlú ti pín àwọn èèyàn yẹ́lẹyẹ̀lẹ, àmọ́ àwa èèyàn Jèhófà ń jọ́sìn rẹ̀ níṣọ̀kan. Ohun tó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe ni pé Jèhófà ń ti ètò ẹ̀ lẹ́yìn!

12. Àwọn nǹkan wo làwọn alàgbà máa wò tí wọ́n á fi mọ̀ pé ẹnì kan ti ronú pìwà dà?

12 Jèhófà ti gbé iṣẹ́ ńlá kan lé àwọn alàgbà lọ́wọ́ pé kí wọ́n jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Tí Kristẹni kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, Jèhófà fẹ́ káwọn alàgbà wò ó bóyá ẹni náà ṣì lè wà nínú ìjọ. Ara ohun tó yẹ kí wọ́n tún wò ni bóyá onítọ̀hún ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Ó lè sọ pé òun ti ronú pìwà dà, àmọ́ ṣé lóòótọ́ ló kórìíra ẹ̀ṣẹ̀ tó dá? Ṣé ó ti pinnu pé òun ò ní dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́? Tó bá jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ burúkú tó ń bá rìn ló mú kó dá ẹ̀ṣẹ̀ náà, ṣé ó ti pinnu pé òun máa fi àwọn ọ̀rẹ́ náà sílẹ̀? Àwọn alàgbà máa gbàdúrà sí Jèhófà, wọ́n á gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, wọ́n á wo ohun tí Bíbélì sọ lórí ẹ̀, wọ́n á sì wò ó bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ náà kábàámọ̀ ohun tó ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n á pinnu bóyá oníwà àìtọ́ náà ṣì lè wà nínú ìjọ. Láwọn ipò kan, wọ́n á yọ onítọ̀hún kúrò nínú ìjọ.​—1 Kọ́r. 5:11-13.

13. Àníyàn wo ló lè gbà wá lọ́kàn tí wọ́n bá yọ ọ̀rẹ́ wa tàbí mọ̀lẹ́bí wa kan kúrò nínú ìjọ?

13 Kí ló lè dán wa wò bóyá a fọkàn tán àwọn alàgbà? A tètè máa ń fara mọ́ ìpinnu táwọn alàgbà bá ṣe tó bá jẹ́ pé ẹni tí wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ tàbí mọ̀lẹ́bí wa. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹni tó sún mọ́ wa gan-an ni wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ ńkọ́? A lè máa rò ó pé wọn ò gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa tàbí ká máa rò pé wọn ò dá ẹjọ́ náà bí Jèhófà ṣe fẹ́. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara mọ́ ohun táwọn alàgbà bá ṣe?

14. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tí wọ́n bá yọ èèyàn wa kan kúrò nínú ìjọ?

14 Ó yẹ ká rántí pé Jèhófà ló ṣètò pé kí wọ́n yọ ẹni tó bá hùwà àìtọ́ kúrò nínú ìjọ, èyí sì máa ṣe ìjọ àti oníwà àìtọ́ náà láǹfààní. Tí wọ́n bá gba oníwà àìtọ́ láyè láti wà nínú ìjọ, ó lè mú káwọn ẹlòmíì máa dẹ́ṣẹ̀. (Gál. 5:9) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè má mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ tóun dá ṣe burú tó, ó tiẹ̀ lè má ronú láti ṣàtúnṣe kó lè pa dà rí ojúure Jèhófà. (Oníw. 8:11) Ohun kan tó dájú ni pé táwọn alàgbà bá fẹ́ pinnu bóyá kí wọ́n yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ, wọ́n máa ń ronú dáadáa kí wọ́n tó ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé bíi tàwọn onídàájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ‘kì í ṣe èèyàn ni wọ́n ń ṣojú fún tí wọ́n bá ń dájọ́, Jèhófà ni.’​—2 Kíró. 19:6, 7.

FỌKÀN TÁN JÈHÓFÀ NÍSINSÌNYÍ KÓ O LÈ FỌKÀN TÁN AN LỌ́JỌ́ IWÁJÚ

Nígbà ìpọ́njú ńlá, tí àwọn tó ń ṣàbójútó wa bá ní ká ṣe ohun kan, kí ló máa jẹ́ ká fọkàn tán wọn, ká sì ṣègbọràn? (Wo ìpínrọ̀ 15)

15. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán Jèhófà, ká sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

15 Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe ń sún mọ́lé, ó yẹ ká fọkàn tán Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé ohun tó tọ́ ló máa ń ṣe. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Nígbà ìpọ́njú ńlá, ètò Ọlọ́run lè ní ká ṣe ohun kan tó jọ pé kò bọ́gbọ́n mu tàbí tí kò yé wa. A mọ̀ pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ò ní bá wa sọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ àwọn tó ń ṣàbójútó ètò rẹ̀ ló máa lò láti bá wa sọ̀rọ̀. Ìgbà yẹn kọ́ ló yẹ ká máa ṣiyèméjì pé ṣóhun tí wọ́n sọ fún wa jóòótọ́ tàbí ká máa rò pé, ‘Ṣé Jèhófà ló sọ bẹ́ẹ̀ ni àbí èrò tiwọn ni wọ́n sọ fún wa?’ Ṣé o máa fọkàn tán Jèhófà àti ètò rẹ̀ lákòókò tí nǹkan bá nira yẹn? Irú ojú tó o fi ń wo ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ fún wa ní báyìí máa fi hàn bóyá wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà yẹn. Tó o bá ń tẹ̀ lé ohun tí wọ́n ń sọ fún wa báyìí, tó o sì ń ṣègbọràn, wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá.​—Lúùkù 16:10.

16. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti fara mọ́ ìdájọ́ tí Jèhófà máa ṣe láìpẹ́?

16 Nǹkan míì tó yẹ ká ronú lé lórí ni ìdájọ́ tí Jèhófà máa ṣe nígbà tó bá pa ayé búburú yìí run. Ní báyìí, a retí pé àwọn èèyàn tí ò sin Jèhófà títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa máa wá jọ́sìn ẹ̀ kí òpin tó dé. Àmọ́ nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Jèhófà máa lo Jésù láti pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Mát. 25:31-33; 2 Tẹs. 1:7-9) Àwa kọ́ la máa pinnu ẹni tí Jèhófà máa fàánú hàn sí àti ẹni tí kò ní fàánú hàn sí. (Mát. 25:34, 41, 46) Ṣé a máa fara mọ́ ìdájọ́ tí Jèhófà bá ṣe, àbí ṣé ìyẹn máa mú ká má sin Jèhófà mọ́? Torí náà, ó yẹ ká túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà báyìí ká lè fọkàn tán an pátápátá lọ́jọ́ iwájú.

17. Àǹfààní wo la máa rí nígbà tí Jèhófà bá ṣèdájọ́ ayé yìí tó sì pa á run?

17 Ẹ wo bó ṣe máa rí lára wa nínú ayé tuntun nígbà tí Jèhófà bá mú gbogbo nǹkan burúkú inú ayé yìí kúrò. Ìsìn èké àtàwọn jẹgúdújẹrá oníṣòwò ò ní sí mọ́, títí kan àwọn olóṣèlú tó ti fi ìyà jẹ àwọn èèyàn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Kò ní sí àìsàn àti ọjọ́ ogbó mọ́, àwọn èèyàn wa náà ò sì ní kú mọ́. Jèhófà máa fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù sínú ẹ̀wọ̀n fún ẹgbẹ̀rún ọdún kan. Jèhófà sì máa ṣàtúnṣe gbogbo aburú tí wọ́n ti fà. (Ìfi. 20:2, 3) Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó nígbà yẹn pé a fara mọ́ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan!

18. Bó ṣe wà nínú Nọ́ńbà 11:4-6 àti 21:5, ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe?

18 Nínú ayé tuntun, àwọn nǹkan kan lè mú kó ṣòro fún wa láti fara mọ́ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì. Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn pé àwọn ò rí oúnjẹ táwọn ń gbádùn ní Íjíbítì jẹ mọ́, wọn ò sì mọyì mánà tí Jèhófà pèsè fún wọn. (Ka Nọ́ńbà 11:4-6; 21:5.) Ṣé àwa náà lè nírú èrò yẹn lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá ti kọjá? A ò mọ bí iṣẹ́ tá a máa ṣe ti máa pọ̀ tó ká tó lè sọ ayé di Párádísè. Ó ṣeé ṣe kí iṣẹ́ tá a máa ṣe pọ̀ gan-an, nǹkan sì lè má rọrùn fún wa níbẹ̀rẹ̀. Ṣé àwa náà máa ráhùn nípa nǹkan tí Jèhófà bá pèsè fún wa nígbà yẹn? Ohun kan tó dájú ni pé: Tá a bá mọyì àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa báyìí, á rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá dìgbà yẹn.

19. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

19 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe ohun tó tọ́. Ó sì yẹ kí ìyẹn dá wa lójú. Ó tún yẹ ká fọkàn tán àwọn tí Jèhófà ń lò láti bá wa sọ̀rọ̀. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa rántí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu wòlíì Àìsáyà sọ pé: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”​—Àìsá. 30:15.

ORIN 98 Ọlọ́run Ló Mí sí Ìwé Mímọ́

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà àtàwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá fọkàn tán wọn báyìí àti bí èyí ṣe lè múra wa sílẹ̀ de àwọn ìṣòro ọjọ́ iwájú.

^ ìpínrọ̀ 9 Nígbà míì, ipò ẹnì kan tàbí ìdílé kan lè gba pé kí wọ́n má kúrò ní ìjọ tí wọ́n wà. Wo “Àpótí Ìbéèrè” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2002.