Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 8

Ṣé Bó O Ṣe Ń Gba Àwọn Èèyàn Nímọ̀ràn ‘Máa Ń Mú Ọkàn Wọn Yọ̀?’

Ṣé Bó O Ṣe Ń Gba Àwọn Èèyàn Nímọ̀ràn ‘Máa Ń Mú Ọkàn Wọn Yọ̀?’

“Òróró àti tùràrí máa ń mú ọkàn yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni adùn ọ̀rẹ́ máa ń wá látinú ìmọ̀ràn àtọkànwá.”​—ÒWE 27:9.

ORIN 102 Ran Àwọn Aláìlera Lọ́wọ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ni arákùnrin kan kọ́ nípa bó ṣe yẹ ká máa fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn?

 NÍ Ọ̀PỌ̀ ọdún sẹ́yìn, alàgbà méjì kan lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arábìnrin kan tí kò wá sípàdé déédéé mọ́. Alàgbà tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n débẹ̀ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó jẹ́ kí arábìnrin náà mọ ìdí tó fi yẹ ká máa wá sípàdé déédéé. Ó rò pé ọ̀rọ̀ táwọn sọ wọ arábìnrin yẹn lọ́kàn, àmọ́ bí òun àti alàgbà kejì ṣe fẹ́ máa lọ, arábìnrin náà sọ pé, “Mi ò rò pé ẹ mọ ìṣòro tó ń bá mi fínra rárá.” Àwọn arákùnrin méjèèjì yẹn ò béèrè ìdí tí arábìnrin yẹn fi ń pa ìpàdé jẹ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì fún un. Torí náà, ìbẹ̀wò wọn ò ṣe arábìnrin yẹn láǹfààní.

2 Nígbà tí alàgbà tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbẹ̀ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ó kọ́kọ́ ṣe mí bíi pé arábìnrin yẹn rín wa fín. Àmọ́ nígbà tí mo ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, mo rí i pé kì í ṣe àwọn ẹsẹ Bíbélì tí mo fẹ́ fi ran arábìnrin yẹn lọ́wọ́ ló yẹ kí n kọ́kọ́ kà. Ohun tó yẹ kí n kọ́kọ́ ṣe ni pé kí n bi í láwọn ìbéèrè bíi, ‘Báwo ni nǹkan ṣe ń lọ sí?’ ‘Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ràn yín lọ́wọ́?’ ” Alàgbà yẹn ò lè gbàgbé ohun tó kọ́ lọ́jọ́ yẹn. Ní báyìí, ó ti ń gba tàwọn èèyàn rò, ó sì ń fún wọn nímọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

3. Àwọn wo ló lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nínú ìjọ?

 3 Torí pé àwọn alàgbà ló ń bójú tó àwọn ará nínú ìjọ, àwọn ló yẹ kó máa fún àwọn ará nímọ̀ràn nígbà tó bá yẹ. Ṣùgbọ́n, àwọn míì nínú ìjọ náà lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè fún ọ̀rẹ́ ẹ̀ nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. (Sm. 141:5; Òwe 25:12) Arábìnrin àgbàlagbà kan sì lè “gba àwọn ọ̀dọ́bìnrin níyànjú” kí wọ́n lè máa ṣe ohun tó wà nínú Títù 2:3-5. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa bá àwọn ọmọ wọn wí, kí wọ́n sì máa gbà wọ́n nímọ̀ràn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà la dìídì ṣe àpilẹ̀kọ yìí fún, gbogbo wa pátá la máa jàǹfààní tá a bá ronú lórí bá a ṣe lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn lọ́nà tó máa ṣe wọ́n láǹfààní, tó máa jẹ́ kí wọ́n gba ìmọ̀ràn náà, tó sì ‘máa mú ọkàn wọn yọ̀.’​—Òwe 27:9.

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn ìbéèrè mẹ́rin nípa bá a ṣe lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn: (1) Kí nìdí tá a fi fẹ́ gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn? (2) Ṣé ó pọn dandan ká fún ẹni náà nímọ̀ràn? (3) Ta ló yẹ kó gba ẹni náà nímọ̀ràn? (4) Báwo la ṣe lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn lọ́nà tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́?

KÍ NÌDÍ TÁ A FI FẸ́ GBA ÀWỌN ÈÈYÀN NÍMỌ̀RÀN?

5. Kí nìdí tó fi yẹ kí alàgbà kan fìfẹ́ gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn? (1 Kọ́ríńtì 13:4, 7)

5 Àwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ. Àmọ́ nígbà míì, ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún ẹnì kan tó fẹ́ ṣi ẹsẹ̀ gbé ló máa fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. (Gál. 6:1) Àmọ́ kí alàgbà kan tó lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ó yẹ kó ronú lórí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìfẹ́. Ó ní: “Ìfẹ́ máa ń ní sùúrù àti inú rere. . . . Ó máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó máa ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó máa ń retí ohun gbogbo, ó máa ń fara da ohun gbogbo.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4, 7.) Tó bá ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ó máa jẹ́ kó mọ ìdí tí òun fi fẹ́ lọ gba ẹni náà nímọ̀ràn àti bóun ṣe lè ṣe é lọ́nà tó máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Tí ẹni tí wọ́n fẹ́ gbà nímọ̀ràn bá rí i pé alàgbà náà nífẹ̀ẹ́ òun, ó máa rọrùn fún un láti gba ìmọ̀ràn náà.​—Róòmù 12:10.

6. Àpẹẹrẹ tó dáa wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀?

6 Alàgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àpẹẹrẹ tó dáa ló sì fi lélẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rí i pé ó yẹ kóun gba àwọn ará ní Tẹsalóníkà nímọ̀ràn, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn, ó kọ́kọ́ gbóríyìn fún wọn nítorí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ìsapá wọn àti ìfaradà wọn. Pọ́ọ̀lù tún ronú nípa ohun tí wọ́n ń dojú kọ àti bí wọ́n ṣe ń fara da inúnibíni. (1 Tẹs. 1:3; 2 Tẹs. 1:4) Kódà, ó sọ fáwọn ará yẹn pé àpẹẹrẹ tó dáa ni wọ́n jẹ́ fáwọn Kristẹni míì. (1 Tẹs. 1:8, 9) Ẹ wo bí inú wọn ṣe máa dùn tó bí wọ́n ṣe ń ka lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù fi gbóríyìn fún wọn! Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará yẹn gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi lè gbà wọ́n nímọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú lẹ́tà méjèèjì tó kọ sí wọn.​—1 Tẹs. 4:1, 3-5, 11; 2 Tẹs. 3:11, 12.

7. Kí ló lè mú kẹ́nì kan má gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un?

7 Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá ò bá gba ẹnì kan nímọ̀ràn bó ṣe yẹ? Alàgbà kan tó ti ń sìn tipẹ́ sọ pé: “Ìdí táwọn kan kì í fi í gba ìmọ̀ràn ni pé ẹni tó fún wọn nímọ̀ràn náà ò sọ ọ́ lọ́nà tó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í ṣe pé ìmọ̀ràn náà ò dáa.” Kí la lè kọ́ látinú ohun tí alàgbà yìí sọ? Ó máa rọrùn fún ẹnì kan láti gba ìmọ̀ràn tá a bá fún un tó bá jẹ́ pé ọ̀nà tá a gbà sọ ọ́ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kì í ṣe pé a kórìíra ẹ̀.

ṢÉ Ó PỌN DANDAN KÁ FÚN ẸNI NÁÀ NÍMỌ̀RÀN?

8. Kí ló yẹ kí alàgbà kan bi ara ẹ̀ kó tó pinnu pé òun máa gba ẹnì kan nímọ̀ràn?

8 Ó yẹ káwọn alàgbà máa fara balẹ̀ ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ kí wọ́n tó lọ gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Kí alàgbà kan tó lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ó yẹ kó bi ara ẹ̀ pé: ‘Ṣé ó tiẹ̀ pọn dandan kí n lọ gbà á nímọ̀ràn? Ṣé ó dá mi lójú pé ohun tó ń ṣe ò dáa? Ṣé ó ti ṣe ohun tí kò bá ìlànà Bíbélì mu? Ṣé kì í ṣe pé mi ò kàn nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan tó ń ṣe, tí nǹkan náà ò sì burú?’ Àwọn alàgbà máa fi hàn pé ọlọgbọ́n ni àwọn tí wọ́n bá ń “ronú [kí wọ́n] tó sọ̀rọ̀.” (Òwe 29:20) Tí kò bá dá alàgbà kan lójú pé ó yẹ kóun lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ó lè fọ̀rọ̀ náà lọ alàgbà míì kí wọ́n sì jọ wò ó bóyá ẹni náà ń ṣe ohun tí kò bá ìlànà Bíbélì mu lóòótọ́.​—2 Tím. 3:16, 17.

9. Àpẹẹrẹ wo ni Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa múra? (1 Tímótì 2:9, 10)

9 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná. Ká sọ pé alàgbà kan kọminú sí bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan ṣe ń múra. Alàgbà náà lè bi ara ẹ̀ pé, ‘Ṣé Bíbélì sọ nǹkan kan tó jẹ́ kí n mọ̀ pé bí ẹni yẹn ṣe ń múra ò dáa?’ Torí pé alàgbà náà ò ní fẹ́ fi èrò tiẹ̀ gba ẹni náà nímọ̀ràn, ó lè bi alàgbà kan tàbí akéde míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ pé kí ni wọ́n rò nípa ẹ̀. Wọ́n wá lè jọ wo ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wá nípa bó ṣe yẹ ká máa múra. (Ka 1 Tímótì 2:9, 10.) Pọ́ọ̀lù sọ àwọn ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé, ó ní ìmúra àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ bójú mu, kó mọ níwọ̀n, kó sì fi hàn pé a láròjinlẹ̀. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò ṣòfin máṣu mátọ̀ nípa ohun tó yẹ ká máa wọ̀ àtohun tí kò yẹ ká wọ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ará lè wọ ohun tó bá wù wọ́n, tí ohun tí wọ́n wọ̀ ò bá ṣáà ti lòdì sí ìlànà Bíbélì. Torí náà, táwọn alàgbà bá fẹ́ pinnu bóyá káwọn lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ó yẹ kí wọ́n wò ó bóyá ìmúra ẹni náà mọ níwọ̀n, ó sì bójú mu.

10. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ìpinnu táwọn míì bá ṣe?

10 Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé àwọn Kristẹni méjì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn lè ṣèpinnu tó yàtọ̀ síra, ìyẹn ò sì sọ pé ọ̀kan dáa ju èkejì lọ. Torí náà, kò yẹ ká máa fipá mú àwọn ará pé kí wọ́n ṣe ohun tá a rò pé ó bójú mu.​—Róòmù 14:10.

TA LÓ YẸ KÓ GBA ẸNI NÁÀ NÍMỌ̀RÀN?

11-12. Tó bá pọn dandan pé kí alàgbà kan gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ìbéèrè wo ló yẹ kó bi ara ẹ̀, kí sì nìdí?

11 Tó bá pọn dandan pé ká gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa ni pé, Ta ló yẹ kó gba ẹni náà nímọ̀ràn? Kí alàgbà kan tó lọ gba ọmọdé tàbí arábìnrin kan tó ti lọ́kọ nímọ̀ràn, ó yẹ kó kọ́kọ́ sọ fún olórí ìdílé wọn, ìyẹn sì lè sọ pé òun máa bójú tó ọ̀rọ̀ náà fúnra òun. * Olórí ìdílé náà sì lè sọ pé òun máa fẹ́ wà níbi tí alàgbà náà ti fẹ́ gbà wọ́n nímọ̀ràn. Bá a ṣe sọ ní  ìpínrọ̀ kẹta, àwọn ìgbà míì sì máa wà tó jẹ́ pé arábìnrin àgbàlagbà kan ló máa dáa jù pé kó lọ gba ọ̀dọ́bìnrin kan nímọ̀ràn.

12 Nǹkan míì tún wà tó yẹ ká ronú lé. Alàgbà kan lè bi ara ẹ̀ pé, ‘Kó lè rọrùn fún ẹni náà láti gba ìmọ̀ràn yẹn, ṣé èmi ló yẹ kí n lọ àbí ẹlòmíì ló máa dáa jù pé kó lọ?’ Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá fẹ́ lọ gba ẹnì kan tó ń wo ara ẹ̀ bíi pé òun ò já mọ́ nǹkan kan nímọ̀ràn, á rọrùn fún ẹni náà láti gbà á tó bá jẹ́ pé alàgbà tó ti nírú ìṣòro yẹn rí ló lọ bá a sọ̀rọ̀. Alàgbà tó ti nírú ìṣòro yẹn rí máa túbọ̀ lóye bí nǹkan ṣe rí lára ẹni náà, á sì mọ bóun ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ òun kalẹ̀ lọ́nà tó máa mú kí ẹni yẹn gba ìmọ̀ràn náà. Síbẹ̀, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé iṣẹ́ gbogbo àwọn alàgbà ni láti fún àwọn ará níṣìírí, kí wọ́n sì gbà wọ́n nímọ̀ràn láti ṣe àwọn àyípadà tí Ìwé Mímọ́ ní ká ṣe. Torí náà, tá a bá rí i pé ó pọn dandan ká gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká ṣe bẹ́ẹ̀ kódà tí alàgbà tó fẹ́ lọ gbà á nímọ̀ràn ò bá tiẹ̀ nírú ìṣòro tí ẹni náà ní.

BÁWO LA ṢE LÈ GBA ÀWỌN ÈÈYÀN NÍMỌ̀RÀN LỌ́NÀ TÓ MÁA RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́?

Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́yin alàgbà máa “yára láti gbọ́rọ̀”? (Wo ìpínrọ̀ 13-14)

13-14. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn alàgbà máa fetí sílẹ̀?

13 Máa fetí sílẹ̀. Tí alàgbà kan bá fẹ́ lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, ó yẹ kó kọ́kọ́ bi ara ẹ̀ pé: ‘Kí ni mo mọ̀ tí arákùnrin tàbí arábìnrin náà ń bá yí? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí i báyìí? Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kó ní tí mi ò mọ̀ nípa ẹ̀? Kí ni nǹkan tó dáa jù tí mo lè ṣe fún un báyìí?’

14 Ó dájú pé ìlànà tó wà nínú Jémíìsì 1:19 kan àwọn tó ń gbani nímọ̀ràn. Jémíìsì sọ pé: “Ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára láti gbọ́rọ̀, kí wọ́n lọ́ra láti sọ̀rọ̀, kí wọ́n má sì tètè máa bínú.” Alàgbà kan lè ronú pé òun ti mọ gbogbo nǹkan tó yẹ kóun mọ̀ nípa ẹni náà, àmọ́ ṣé òótọ́ ni? Òwe 18:13 rán wa létí pé: “Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀rọ̀ láì tíì gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, ìwà òmùgọ̀ ni, ó sì ń kó ìtìjú báni.” Ohun tó dáa jù ni pé ká gbọ́rọ̀ lẹ́nu onítọ̀hún fúnra ẹ̀. Ìyẹn sì máa gba pé ká fetí sílẹ̀ dáadáa ká tó mọ ohun tá a máa sọ. Ṣé ẹ rántí ohun tí alàgbà tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé òun kọ́? Ó sọ pé dípò kó jẹ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì tóun ti múra sílẹ̀ ni òun máa kọ́kọ́ kà, ṣe ló yẹ kóun bi arábìnrin náà láwọn ìbéèrè bíi: “Báwo ni nǹkan ṣe ń lọ sí?” “Ọ̀nà wo ni mo lè gbà ràn yín lọ́wọ́?” Táwọn alàgbà bá ń fara balẹ̀ wádìí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará kí wọ́n tó lọ gbà wọ́n nímọ̀ràn, á rọrùn fún wọn láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin lọ́wọ́, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí.

15. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi ìlànà tó wà nínú Òwe 27:23 sílò?

15 Ó yẹ kó o mọ àwọn ará ní àmọ̀dunjú. Bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, kéèyàn gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó máa ṣe wọ́n láǹfààní kọjá ká kàn ka àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan tàbí ká fún wọn láwọn àbá kan. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa gbọ́dọ̀ rí i pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn, a lóye àwọn àti pé a fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ka Òwe 27:23.) Torí náà, ó yẹ kẹ́yin alàgbà ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti mú àwọn ará lọ́rẹ̀ẹ́.

Kí ló máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ̀yin alàgbà láti gba àwọn ará nímọ̀ràn? (Wo ìpínrọ̀ 16)

16. Kí ló máa jẹ́ kẹ́yin alàgbà fún àwọn ará nímọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́?

16 Ó yẹ kẹ́yin alàgbà ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe kí àwọn ará má bàa ronú pé ìgbà tí ẹ bá fẹ́ gba àwọn nímọ̀ràn nìkan lẹ máa ń bá àwọn sọ̀rọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kẹ́ ẹ máa bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo, kẹ́ ẹ sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Alàgbà kan tó ti ń sìn tipẹ́ sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ máa di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ará. Tó bá di pé ẹ fẹ́ bá wọn wí tàbí gbà wọ́n nímọ̀ràn, ó máa rọrùn gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀.” Yàtọ̀ síyẹn, ó máa rọrùn fún ẹni tẹ́ ẹ fẹ́ gbà nímọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tẹ́ ẹ bá bá a sọ.

Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́yin alàgbà máa ní sùúrù, kẹ́ ẹ sì máa fi inúure hàn nígbà tẹ́ ẹ bá ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn? (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Ìgbà wo ló ṣe pàtàkì jù pé kí alàgbà kan ní sùúrù, kó sì fi inúure hàn sáwọn ará?

17 Máa ní sùúrù, kó o sì máa fi inúure hàn. Ó yẹ kẹ́yin alàgbà máa fi inúure hàn kẹ́ ẹ sì máa ní sùúrù, pàápàá tí ẹni tẹ́ ẹ fún nímọ̀ràn ò bá gba ìmọ̀ràn náà. Alàgbà kan ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí inú bí òun tí ẹni tó fún nímọ̀ràn ò bá gba ìmọ̀ràn náà tàbí tí kò tètè ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù pé: “Kò ní fọ́ esùsú kankan tó ti ṣẹ́, kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú.” (Mát. 12:20) Torí náà, tí alàgbà náà bá ń dá gbàdúrà, ó lè bẹ Jèhófà pé kó ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè rí ìdí tí wọ́n fi ń gba òun nímọ̀ràn àti ìdí tó fi yẹ kóun ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀. Ó lè gba pé kó fún ẹni náà ní àkókò díẹ̀ kó lè ronú lórí ohun tó bá a sọ. Tí alàgbà náà bá ní sùúrù tó sì fi inúure hàn, ẹni tó gbà nímọ̀ràn náà ò ní wo ọ̀nà tó gbà bá òun sọ̀rọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn tó fún un ló máa gbájú mọ́. Síbẹ̀, ó yẹ kí alàgbà náà fi sọ́kàn pé Ìwé Mímọ́ ló yẹ kóun máa fi gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nígbà gbogbo.

18. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn? (b) Bá a ṣe rí i nínú àwòrán àti àpótí yẹn, kí làwọn òbí yẹn ń bá ara wọn sọ?

18 Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó o ti ṣe. Torí pé aláìpé ni wá, kò sí bá a ṣe lè fi gbogbo ìmọ̀ràn tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí sílò délẹ̀délẹ̀. (Jém. 3:2) A máa ṣàṣìṣe, àmọ́ tó bá ti ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀. Táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa bá rí i pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ó máa rọrùn fún wọn láti dárí jì wá tá a bá ṣẹ̀ wọ́n tàbí tá a sọ ohun kan tí kò bá wọn lára mu.​—Tún wo àpótí náà “ Ọ̀rọ̀ Rèé O Ẹ̀yin Òbí!

KÍ LA TI KỌ́?

19. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe táá mú káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa láyọ̀?

19 Bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, kò rọrùn láti fún ẹnì kan nímọ̀ràn tó máa ràn án lọ́wọ́. Aláìpé ni wá, aláìpé sì làwọn tá à ń gbà nímọ̀ràn. Torí náà, máa fi àwọn nǹkan tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí sọ́kàn. Rí i dájú pé o mọ ìdí tó o fi fẹ́ gba ẹnì kan nímọ̀ràn. Bákan náà, kó o tó lọ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, rí i dájú pé ó pọn dandan àti pé ìwọ ló yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í gba ẹni náà nímọ̀ràn, bi í láwọn ìbéèrè tó yẹ, kó o sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí i kó o lè mọ àwọn ìṣòro tó ń bá yí. Fi ara ẹ sí ipò ẹni náà, kó o sì fara balẹ̀, kó lè rọrùn fún ẹ láti mú àwọn ará lọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà, má gbàgbé ìdí tá a fi ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn: A fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àmọ́ a tún fẹ́ “mú ọkàn [wọn] yọ̀.”​—Òwe 27:9.

ORIN 103 Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

^ ìpínrọ̀ 5 Kì í rọrùn láti fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn. Àmọ́, tó bá pọn dandan ká ṣe bẹ́ẹ̀, báwo la ṣe lè ṣe é lọ́nà tó máa ṣe ẹni náà láǹfààní tó sì máa tù ú lára? Àpilẹ̀kọ yìí máa dìídì ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti fún àwọn ará nímọ̀ràn lọ́nà tó máa jẹ́ kí wọ́n gba ìmọ̀ràn náà.

^ ìpínrọ̀ 11 Wo àpilẹ̀kọ náà “Mọyì Ipò Orí Tí Jèhófà Ṣètò Nínú Ìjọ” nínú Ilé Ìṣọ́ February 2021.