Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 9

Máa Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Bíi Ti Jésù

Máa Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Bíi Ti Jésù

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” ​—ÌṢE 20:35.

ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn nǹkan tó dáa wo làwa èèyàn Jèhófà ń ṣe lónìí?

 ỌJỌ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa “yọ̀ǹda ara wọn tinútinú” láti ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, Jésù Ọmọ rẹ̀ lá sì máa darí wọn. (Sm. 110:3) Ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti ń ṣẹ báyìí. Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù wákàtí làwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A kì í gba owó fún iṣẹ́ yìí, tọkàntọkàn la fi ń ṣe é. Bákan náà, a máa ń pèsè ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nílò, a máa ń fún wọn níṣìírí, a sì máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára. Ọ̀pọ̀ wákàtí làwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń lò láti fi múra iṣẹ́ tí wọ́n ní nípàdé, tí wọ́n sì tún ń lò láti fi ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn ará. Kí ló ń mú ká ṣe gbogbo ohun tá à ń ṣe yìí? Ìfẹ́ ni. Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àtàwọn èèyàn ló ń mú ká ṣe bẹ́ẹ̀.​—Mát. 22:37-39.

2. Bó ṣe wà nínú Róòmù 15:1-3, àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀?

2 Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé ó máa ń gbọ́ tàwọn èèyàn ṣáájú tiẹ̀. A sì máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. (Ka Róòmù 15:1-3.) Ọ̀pọ̀ ìbùkún làwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù máa gbà. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jésù yááfì kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ àti bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan táá jẹ́ kó túbọ̀ máa wù wá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

MÁA TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ JÉSÙ

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Jésù, kí ló ṣe nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn wá bá a? (Wo ìpínrọ̀ 4)

4. Báwo ni Jésù ṣe gbọ́ tàwọn èèyàn ṣáájú tiẹ̀?

4 Jésù ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kódà nígbà tó rẹ̀ ẹ́. Ẹ ronú nípa ohun tí Jésù ṣe nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn wá bá a níbi òkè kan tó ṣeé ṣe kó wà nítòsí ìlú Kápánáúmù. Gbogbo òru ni Jésù fi gbàdúrà. Torí náà, á ti rẹ̀ ẹ́ gan-an. Àmọ́ nígbà tó rí àwọn aláìní àtàwọn tó ń ṣàìsàn, àánú wọn ṣe é. Torí náà, ó wò wọ́n sàn, ṣùgbọ́n kò fi mọ síbẹ̀, ó tún wàásù fún wọn, ó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Ìwàásù yẹn la wá mọ̀ sí Ìwàásù orí Òkè.​—Lúùkù 6:12-20.

Báwo la ṣe lè máa gbọ́ tàwọn míì ṣáájú tiwa bíi ti Jésù? (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Báwo làwọn olórí ìdílé ṣe ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jésù kódà nígbà tó bá ti rẹ̀ wọ́n?

5 Bí àwọn olórí ìdílé ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé ó ti rẹ olórí ìdílé kan tẹnutẹnu nígbà tó dé látibiṣẹ́, ó lè máa ṣe é bíi pé káwọn má ṣe Ìjọsìn Ìdílé tí wọ́n máa ń ṣe nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Àmọ́, ó bẹ Jèhófà pé kó fún òun lókun láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Jèhófà dáhùn àdúrà ẹ̀, wọ́n sì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́jọ́ yẹn. Àwọn ọmọ náà kẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan lọ́jọ́ yẹn, ẹ̀kọ́ náà sì ni pé ìjọsìn Jèhófà làwọn òbí wọn kà sí pàtàkì jù.

6. Sọ àpẹẹrẹ ìgbà kan tí Jésù lo àkókò tó yẹ kó fi dá wà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

6 Jésù lo àkókò tó yẹ kó fi dá wà láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Báwo lẹ ṣe rò pé ó máa rí lára Jésù nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti bẹ́ orí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Jòhánù Onírìbọmi? Ó dájú pé ìròyìn yẹn máa ba Jésù nínú jẹ́ gan-an. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí Jésù gbọ́ [pé wọ́n ti pa Jòhánù], ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tó dá, kó lè dá wà.” (Mát. 14:10-13) Gbogbo wa la sì mọ ìdí tó fi fẹ́ dá wà. Ọ̀pọ̀ lára wa ló máa ń fẹ́ dá wà tí inú wa ò bá dùn. Àmọ́ Jésù ò láǹfààní yẹn. Ìdí sì ni pé kó tó dé ibi tó ń lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ti débẹ̀ ṣáájú ẹ̀. Kí ni Jésù wá ṣe? Ó ronú nípa àwọn èèyàn náà, “àánú wọn sì ṣe é.” Ó rí i pé ó wù wọ́n láti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé wọ́n nílò ìtùnú, ohun tí Jésù sì ṣe fún wọn gan-an nìyẹn. “Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan.”​—Máàkù 6:31-34; Lúùkù 9:10, 11.

7-8. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ báwọn alàgbà ṣe ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jésù tẹ́nì kan nínú ìjọ bá fẹ́ ká ran òun lọ́wọ́.

7 Bí àwọn alàgbà ṣe ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jésù. A mọyì báwọn alàgbà ṣe ń ṣiṣẹ́ kára nítorí wa. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde tó wà nínú ìjọ ni ò mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe yìí. Bí àpẹẹrẹ, tí ara ẹnì kan ò bá yá nínú ìjọ, tó sì ti di ọ̀rọ̀ pàjáwìrì, àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn máa rí i dájú pé àwọn ṣe gbogbo ohun táwọn lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, òru nirú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́ torí pé wọ́n máa ń káàánú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn, wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn àti ìdílé wọn kọ́kọ́ bójú tó ohun tó máa mú kí ara tu àwọn ará.

8 Àwọn alàgbà tún máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé míì tí ètò Ọlọ́run ń lò, wọ́n sì tún máa ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ wákàtí làwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ wa máa ń lò láti fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì fún wa níṣìírí. Gbogbo àwọn arákùnrin yìí àtàwọn ìdílé wọn ló yẹ ká máa gbóríyìn fún. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bù kún wọn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ kárakára! Àmọ́, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má bàa di pé ojúṣe kan á máa pa òmíì lára. Wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ò jẹ́ kí àkókò táwọn ń lò nídìí iṣẹ́ Ọlọ́run dí àwọn lọ́wọ́ débi tí wọn ò fi ní ráyè bójú tó ìdílé wọn bó ṣe yẹ.

BÁ A ṢE LÈ MÁA GBỌ́ TÀWỌN MÍÌ ṢÁÁJÚ TIWA

9. Bó ṣe wà nínú Fílípì 2:4, 5, irú èrò wo ló yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni ní?

9 Ka Fílípì 2:4, 5. Lóòótọ́, gbogbo wa kọ́ ni alàgbà, àmọ́ gbogbo wa la lè máa gbọ́ tàwọn míì ṣáájú tiwa bíi ti Jésù. Bíbélì sọ pé Jésù “gbé ìrísí ẹrú wọ̀.” (Fílí. 2:7) Ẹ wo ohun tá a lè kọ́ látinú ohun tí Jésù ṣe yẹn. Ohun tó máa ń jẹ́ kí ọ̀gá kan mọyì ẹrú ẹ̀ ni pé ẹrú náà mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́, ó sì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kínú ọ̀gá ẹ̀ lè dùn sí i. Lọ́nà kan náà, ẹrú Jèhófà ni gbogbo wa, a sì ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́, ó dájú pé a máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àtàwọn ará wa. A máa lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fi àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí sílò.

10. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?

10 Ronú nípa ojú tó o fi ń wo nǹkan. Ó yẹ kó o bi ara ẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé ó máa ń yá mi lára láti lo àkókò àti okun mi kí n lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́? Kí ni màá ṣe tí wọ́n bá ní kí n lọ kí arákùnrin àgbàlagbà kan níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú ẹ̀ tàbí tí wọ́n bá ní kí n gbé arábìnrin àgbàlagbà kan lọ sípàdé? Ṣé mo máa ń tètè yọ̀ǹda ara mi tí wọ́n bá ní ká wá ṣiṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tàbí ká wá tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe?’ Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ṣèlérí pé a máa lo gbogbo ohun tá a ní nínú ìjọsìn ẹ̀. Ó fẹ́ ká lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa láti fi ran àwọn míì lọ́wọ́. Torí náà, inú ẹ̀ máa ń dùn tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ látọkàn wá. Tá a bá wá rí i pé ó yẹ ká ṣàtúnṣe, kí ló yẹ ká ṣe?

11. Kí ló máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti ran àwọn ará lọ́wọ́?

11 Gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà. Ká ní o rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe àwọn nǹkan kan nígbèésí ayé ẹ, àmọ́ tí kò rọrùn fún ẹ, kí ló yẹ kó o ṣe? Ṣe ni kó o bẹ Jèhófà taratara nínú àdúrà. Má fi nǹkan kan pa mọ́ fún un. Sọ bó ṣe rí lára ẹ fún Jèhófà, ó máa ‘mú kó wù ẹ́ láti gbé ìgbésẹ̀, á sì fún ẹ ní agbára láti ṣe é.’​—Fílí. 2:13.

12. Kí ló yẹ kẹ́yin ọ̀dọ́ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi máa ṣe nínú ìjọ?

12 Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́ arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi ni ẹ́, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn alàgbà tó wà níbẹ̀ pọ̀ ju àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ló sì ti dàgbà. Bá a ṣe ń pọ̀ sí i nínú ètò Ọlọ́run, a túbọ̀ nílò àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ kí wọ́n lè máa ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run. Tó o bá múra tán láti ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá ní kó o ṣe, inú ẹ máa dùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé wàá múnú Jèhófà dùn, àwọn ará máa rí i pé o ṣe tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, inú ẹ á sì dùn bó o ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́.

Àwọn Kristẹni tó wá láti Jùdíà sá, wọ́n sọdá Odò Jọ́dánì lọ sílùú Pẹ́là. Àwọn tó kọ́kọ́ débẹ̀ ń pín oúnjẹ fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé (Wo ìpínrọ̀ 13)

13-14. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

13 Máa kíyè sí ohun táwọn míì nílò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó jẹ́ Hébérù níyànjú pé: “Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.” (Héb. 13:16) Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n yẹn ṣe wọ́n láǹfààní gan-an. Ìdí ni pé kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n gba lẹ́tà yìí, àwọn ará ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í sá kúrò nílé wọn, wọ́n fi iṣẹ́ wọn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kì í ṣe Kristẹni sílẹ̀, wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí àwọn òkè.” (Mát. 24:16) Kò sí àní-àní pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ lásìkò yẹn. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ti ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò ṣáájú àkókò yẹn pé kí wọ́n máa ran ara wọn lọ́wọ́, ó máa rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ níbi tuntun tí wọ́n lọ.

14 Kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn ará wa máa ń sọ nǹkan tí wọ́n nílò fún wa. Bí àpẹẹrẹ, ìyàwó arákùnrin kan lè kú, kó wá di pé ọkọ ẹ̀ nìkan ló ń dá ṣe nǹkan. Ó yẹ ká bi ara wa pé, ṣé ó ń wá ẹni táá bá òun se oúnjẹ àbí ẹni táá bá a ṣiṣẹ́ ilé, ṣé ó ń wá ẹni tó máa fi mọ́tò gbé e lọ síbi tó bá fẹ́ lọ? Ó lè má sọ nǹkan kan fún wa torí pé kò fẹ́ yọ wá lẹ́nu. Àmọ́, ó máa mọyì ẹ̀ gan-an tó bá jẹ́ pé fúnra wa la pinnu láti ràn án lọ́wọ́ kó tiẹ̀ tó sọ fún wa rárá. Kò yẹ ká ronú pé gbogbo nǹkan á máa lọ geerege fún un àti pé tó bá nílò nǹkan, ó máa jẹ́ ká gbọ́. Torí náà, bi ara ẹ pé, ‘Tó bá jẹ́ èmi nirú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, kí ni màá fẹ́ káwọn èèyàn ṣe fún mi?’

15. Tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lóòótọ́, kí ló yẹ ká ṣe?

15 Jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́. Ó dájú pé o mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ ẹ tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Wọn kì í jẹ́ ká rò pé à ń yọ àwọn lẹ́nu. A mọ̀ pé wọ́n ṣeé fọkàn tán àti pé kò sígbà tá a ní kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ tí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì dájú pé àwa náà máa fẹ́ ṣe bíi tiwọn! Alàgbà kan tó ń jẹ́ Alan ti lé lógójì (40) ọdún, ó sì fẹ́ túbọ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé sún mọ́. Nígbà tó ronú nípa àpẹẹrẹ tó dáa tí Jésù fi lélẹ̀, ó sọ pé: “Ọwọ́ Jésù máa ń dí gan-an, síbẹ̀ tọmọdé tàgbà ló máa ń fẹ́ wà lọ́dọ̀ ẹ̀, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀ láti sọ fún un pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Wọ́n rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn lóòótọ́. Mo fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti dà bíi Jésù, mo sì fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé mo ṣeé sún mọ́ àti pé mo nífẹ̀ẹ́ àwọn.”

16. Tá a bá ń ṣe ohun tó wà nínú Sáàmù 119:59, 60, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí?

16 Kò yẹ ká banú jẹ́ tá ò bá lè ṣe bí Jésù ti ṣe gẹ́lẹ́. (Jém. 3:2) Ẹnì kan tó ń kọ́ṣẹ́ lè má lè ṣe gbogbo nǹkan gẹ́lẹ́ lọ́nà tí ọ̀gá ẹ̀ ń gbà ṣe nǹkan. Àmọ́ bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àṣìṣe tó ṣe, tó sì ń ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe láti mọ bí ọ̀gá ẹ̀ ṣe ń ṣe nǹkan, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, á máa mọṣẹ́ náà sí i. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń fi ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì sílò, tá a sì ń sapá láti sunwọ̀n sí i, á rọrùn fún wa láti túbọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù.​—Ka Sáàmù 119:59, 60.

ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ Ń GBỌ́ TÀWỌN MÍÌ ṢÁÁJÚ TIWA

Bí àwọn alàgbà ṣe ń gbọ́ tàwọn míì ṣáájú tiwọn jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fáwọn ọ̀dọ́ (Wo ìpínrọ̀ 17) *

17-18. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbọ́ tàwọn míì ṣáájú tiwa bíi ti Jésù?

17 Tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àwọn míì náà á máa ṣe bẹ́ẹ̀. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Tim sọ pé: “A láwọn ọ̀dọ́ arákùnrin kan tó ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí wọ́n tó pé ogún (20) ọdún. Lára ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé wọ́n ń rí bí àwọn míì ṣe ń yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àwọn náà sì fẹ́ máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àwọn ọ̀dọ́ yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn míì lọ́wọ́ ń mú kí nǹkan tẹ̀ síwájú nínú ìjọ, ó sì ń jẹ́ kí iṣẹ́ àwọn alàgbà túbọ̀ rọrùn.”

18 Àwọn tó mọ tara wọn nìkan ló pọ̀ jù nínú ayé lónìí. Àmọ́ àwa èèyàn Jèhófà yàtọ̀ sí wọn. A ti kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù pé kò mọ tara ẹ̀ nìkan, tàwọn èèyàn ló máa ń gbọ́ ṣáájú tiẹ̀, a sì ti pinnu pé àá máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. Lóòótọ́, a ò lè tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù lọ́nà tó pé, àmọ́ a lè “tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pét. 2:21) Torí náà bíi ti Jésù, tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ dípò kó jẹ́ pé tara wa nìkan làá máa rò, àwa náà máa láyọ̀ torí a mọ̀ pé inú Jèhófà ń dùn sí wa.

ORIN 13 Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

^ ìpínrọ̀ 5 Jésù ò mọ tara ẹ̀ nìkan, bó ṣe máa kọ́kọ́ gbọ́ tàwọn míì ló máa ń rò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bíi ti Jésù.

^ ìpínrọ̀ 57 ÀWÒRÁN: Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Dan ń wo àwọn alàgbà méjì tó wá kí bàbá ẹ̀ nílé ìwòsàn. Ohun táwọn alàgbà yẹn ṣe wọ Dan lọ́kàn, ìdí nìyẹn tóun náà fi fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú ìjọ. Arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Ben ń wo bí Dan ṣe ń bójú tó àwọn míì. Àpẹẹrẹ Dan mú kí Ben náà bẹ̀rẹ̀ sí í tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe.