Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Rí Ohun Tó Dáa Ju Iṣẹ́ Dókítà Lọ

Mo Rí Ohun Tó Dáa Ju Iṣẹ́ Dókítà Lọ

“OHUN tẹ́ ẹ̀ ń sọ yìí ló wà lọ́kàn mi láti kékeré!” Ọdún 1971 ni mo sọ̀rọ̀ yẹn nígbà tí tọkọtaya kan wá gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ mi. Ìgbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ dókítà nílé ìwòsàn tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Ẹ lè máa wò ó pé àwọn wo ni tọkọtaya yẹn, kí ló sì wà lọ́kàn mi láti kékeré? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ tá a jọ sọ yìí ṣe yí ohun tí mo kà sí pàtàkì nígbèésí ayé mi pa dà àti ìdí tí mo fi gbà pé ohun tó wà lọ́kàn mi láti kékeré máa tó ṣẹlẹ̀.

Ìlú Paris lórílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1941, àwọn òbí mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ lówó. Inú mi máa ń dùn gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ ẹ wo bó ṣe máa rí lára mi nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn lọ́mọ ọdún mẹ́wàá. Ikọ́ ẹ̀gbẹ ló ń ṣe mí, torí náà, mi ò lè lọ sílé ìwé mọ́. Àwọn dókítà ní mi ò gbọ́dọ̀ kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì nítorí ẹ̀dọ̀fóró mi tí ò lágbára mọ́. Mo lo oṣù mélòó kan nílé ìwòsàn, ṣe ni mò ń fi gbogbo àkókò mi ka ìwé atúmọ̀ èdè, tí mo sì ń gbọ́ ètò lórí rédíò tó ń jẹ́ Radio Sorbonne ní Yunifásítì Paris. Inú mi dùn gan-an nígbà tí dókítà sọ fún mi pé ara mi ti yá báyìí, mo sì lè pa dà sílé ìwé. Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Iṣẹ́ ńlá làwọn dókítà ń ṣe o!’ Àtìgbà yẹn ló ti wà lọ́kàn mi láti di dókítà. Gbogbo ìgbà tí bàbá mi bá ti bi mí pé, iṣẹ́ wo ni mo máa fẹ́ ṣe tí n bá dàgbà, ohun tí mo máa ń sọ ni pé, “iṣẹ́ dókítà ni.” Torí náà, bí mo ṣe máa di dókítà ló ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé mi.

ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ JẸ́ KÍ N TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN

Ẹ̀sìn Kátólíìkì ni ìdílé wa ń ṣe. Àmọ́, mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run. Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí mi ò tíì rí ìdáhùn wọn. Ẹ̀yìn ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ dókítà ní yunifásítì ni mo tó wá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà.

Mo rántí ìgbà tí mo kọ́kọ́ fi awò amú-nǹkan-tóbi wo sẹ́ẹ̀lì inú ewéko, ó yà mí lẹ́nu gan-an láti rí bí àwọn sẹ́ẹ̀lì náà ṣe máa ń dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ ooru àti òtútù. Mo tún kíyè sí bí àwọn sẹ́ẹ̀lì náà ṣe máa ń súnkì nígbà tí iyọ̀ bá kàn wọ́n lára tí wọ́n sì máa ń pa dà tóbi tí wọ́n bá bọ́ sínú omi tí ò níyọ̀. Agbára tí wọ́n ní yìí fi hàn pé àwọn ohun alààyè tíntìntín lè máa gbé níbikíbi tí wọ́n bá bá ara wọn. Nígbà tí mo rí i pé àwọn sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan ní apá tó pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ gan-an, tí wọ́n sì lágbára, ó wá dá mi lójú pé àwọn nǹkan ò ṣàdédé wà, ẹnì kan ló dá wọn.

Nígbà tí mò ń lo ọdún kejì lọ nílé ẹ̀kọ́ dókítà, mo tún rí ẹ̀rí púpọ̀ sí i pé Ọlọ́run wà. Nígbà tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ara èèyàn, a mọ bí apá ṣe máa ń jẹ́ kí àwọn ìka ọwọ́ wa tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún. Ohun ìyanu gbáà ló jẹ́ bí àwọn iṣan àti egungun ṣe lọ́ mọ́ra wọn, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n kọ́ wa pé iṣan ńlá kan ló so àwọn iṣan tó wà ní apá wa mọ́ eegun ọmọ ìka kejì tó wà ní ọwọ́ wa. Iṣan ńlá yìí pín sí méjì, ó sì jẹ́ kí iṣan ńlá míì gba inú òun kọjá lọ sí orí ọmọ ìka. Àwọn iṣan yìí máa ń lẹ̀ mọ́ egungun ìka ọwọ́. Ká sọ pé àwọn iṣan yìí ò sí nínú ìka ọwọ́ wa ni, ọwọ́ wa ò ní lè tẹ̀ síbí tẹ̀ sọ́hùn-ún, wọn ò sì ní lè ṣiṣẹ́ dáadáa. Ó ti wá yé mi dáadáa báyìí pé ẹnì kan tó gbọ́n ló ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan yìí sínú ara wa.

Mo túbọ̀ mọyì iṣẹ́ Ọlọ́run gan-an nígbà tí mo mọ bí ọmọ ìkókó ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í mí nígbà tí wọ́n bá bí i. Inú iṣẹ́ dókítà ni mo ti wá mọ̀ pé tí ọmọ bá wà nínú ìyá ẹ̀, afẹ́fẹ́ tí ọmọ náà ń lò máa ń wá látara ìyá ẹ̀, á sì gba inú ìdodo ọmọ náà wọlé sí i lára. Nígbà yẹn, kò tíì lè mí fúnra ẹ̀ torí pé àwọn àpò afẹ́fẹ́ tó wà nínú ẹ̀dọ̀fóró ẹ̀ kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́. Àmọ́ ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan kí wọ́n tó bí i, ọ̀rá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan máa ń wà nínú àwọn àpò afẹ́fẹ́ náà. Lẹ́yìn tí wọ́n bá bí i, àwọn ohun ìyanu kan máa ń ṣẹlẹ̀ tọ́mọ náà bá fẹ́ kọ́kọ́ mí fúnra ẹ̀. Ihò tó wà nínú ọkàn ọmọ náà máa padé, ìyẹn á sì jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn lọ sínú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀. Lákòókò yẹn, àwọn ọ̀rá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yẹn ni ò ní jẹ́ káwọn àpò afẹ́fẹ́ náà lẹ̀ pọ̀, afẹ́fẹ́ á sì wá wọlé sínú àwọn àpò náà. Lésẹ̀kẹsẹ̀, ọmọ náà á bẹ̀rẹ̀ sí í mí fúnra ẹ̀.

Mo fẹ́ mọ ẹni tó dá àwọn ohun àgbàyanu yẹn. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì gan-an. Ó jọ mí lójú gan-an nígbà tí mo rí òfin ìmọ́tótó tó wà nínú májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dá ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọdún sẹ́yìn. Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa bo ìgbẹ́ wọn mọ́lẹ̀, kí wọ́n máa fọwọ́, kí wọ́n sì máa wẹ̀. Ó tún sọ fún wọn pé kí wọ́n sé ẹni tó ní àrùn tó lè ranni mọ́lé. (Léf. 13:50; 15:11; Diu. 23:13) Ó ti pẹ́ tí Bíbélì ti jẹ́ ká mọ bí àrùn ṣe máa ń tàn káàkiri káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wá mọ̀ nípa ẹ̀ ní nǹkan bí àádọ́jọ (150) ọdún sẹ́yìn. Ó tún yé mi pé òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìbálópọ̀ nínú ìwé Léfítíkù mú kí ara wọn dá ṣáṣá. (Léf. 12:1-6; 15:16-24) Mo gbà pé Ẹlẹ́dàá fún wọn láwọn òfin yẹn kó lè ṣe wọ́n láǹfààní, ó sì bù kún àwọn tó tẹ̀ lé e. Ó wá dá mi lójú pé Ọlọ́run ló darí àwọn tó kọ Bíbélì. Àmọ́ mi ò tíì mọ orúkọ Ọlọ́run náà nígbà yẹn.

MO PÀDÉ ÌYÀWÓ MI, MO SÌ TÚN MỌ JÈHÓFÀ

Èmi àti Lydie lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa, April 3, 1965

Ìgbà tí mò ń kọ́ṣẹ́ dókítà ní yunifásítì ni mo pàdé ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Lydie, mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1965, nígbà yẹn mo ti bá ẹ̀kọ́ mi dé ìdajì ní yunifásítì. Nígbà tó fi máa di ọdún 1971, a ti bí ọmọ mẹ́ta nínú ọmọ mẹ́fà tá a bí. Lydie ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an nínú iṣẹ́ dókítà mi àti nínú ìdílé wa.

Ọdún mẹ́ta ni mo fi ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn kan kí n tó dá ilé ìwòsàn tèmi sílẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni tọkọtaya tí mo sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ wá gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ mi. Nígbà tí mo fẹ́ kọ oògùn tí ọkọ máa lò, ìyàwó sọ pé: “Dókítà, ẹ jọ̀ọ́, a ò fẹ́ oògùn tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ ṣe o.” Ẹnu yà mí gan-an, ni mo bá béèrè pé: “Kí ló dé tẹ́ ò fẹ́?” Ló bá sọ pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.” Mi ò gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, bẹ́ẹ̀ sì ni mi ò mọ ọwọ́ tí wọ́n fi mú ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀. Obìnrin náà mú Bíbélì rẹ̀ jáde, ó sì fi ṣàlàyé ìdí táwọn kì í fi í lo oògùn tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ ṣe. (Ìṣe 15:28, 29) Lẹ́yìn náà, òun àti ọkọ ẹ̀ sọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe, wọ́n ní ó máa mú ìyà, àìsàn àti ikú kúrò láyé. (Ìfi. 21:3, 4) Ni mo bá sọ pé, “Ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ yìí ló wà lọ́kàn mi láti kékeré! Nítorí kí n lè mú ìyà kúrò ni mo ṣe di dókítà.” Inú mi dùn gan-an débi pé wákàtí kan ààbọ̀ la fi sọ̀rọ̀. Nígbà tí tọkọtaya yìí máa fi kúrò lọ́dọ̀ mi, mi ò fẹ́ ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì mọ́. Wọ́n tún kọ́ mi pé Ẹlẹ́dàá tí mo fẹ́ràn gan-an ní orúkọ kan. Jèhófà ni orúkọ rẹ̀!

Ìgbà mẹ́ta ni tọkọtaya yẹn wá sílé ìwòsàn mi. Gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti wá la máa ń fi ohun tó lé ní wákàtí kan sọ̀rọ̀. Mo ní kí wọ́n wá sílé mi ká lè túbọ̀ ráyè sọ̀rọ̀ Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Lydie gbà láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, kò gbà pé irọ́ làwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì kan tá a ti mọ̀. Torí náà, mo pe àlùfáà kan wá sílé wa. A fi Bíbélì ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì títí di alẹ́. Àwọn ohun tá a jíròrò yẹn ló mú kí Lydie gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fi òtítọ́ kọ́ni. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà Ọlọ́run ń pọ̀ sí i débi tá a fi ṣèrìbọmi lọ́dún 1974.

MO FI JÈHÓFÀ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́

Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé, ó mú kí n yí ohun tí mo fi sípò àkọ́kọ́ pa dà. Èmi àti Lydie fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. A pinnu pé ìlànà Bíbélì la máa fi tọ́ àwọn ọmọ wa. Ìlànà tá a fi kọ́ wọn ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn, ìyẹn sì mú kí ìṣọ̀kan wà nínú ìdílé wa.​—Mát. 22:37-39.

Ẹ̀rín sábà máa ń pa èmi àti Lydie tá a bá rántí pé àwọn ọmọ wa mọ̀ pé ẹnu àwa òbí wọn ṣọ̀kan. Wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ là ń tẹ̀ lé nínú ilé wa. Ìyẹn, ‘Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín, Bẹ́ẹ̀ ni jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.’ (Mát. 5:37) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin wa wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17), Lydie ò jẹ́ kó tẹ̀ lé àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ kan lọ ṣeré, ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ yẹn bá sọ fún ọmọ wa pé, “Tí ìyá ẹ ò bá jẹ́ kó o bá wa lọ, sọ fún bàbá ẹ!” Àmọ́ ọmọ wa fèsì pé: “Ohun kan náà ni wọ́n máa sọ. Ọ̀rọ̀ wọn kì í yàtọ̀.” Ó dájú pé àwọn ọmọ wa mẹ́fẹ̀ẹ̀fà mọ̀ pé ẹnu àwa òbí wọn ṣọ̀kan, a sì máa ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì. A dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà pé ọ̀pọ̀ lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa ló ń sin Jèhófà lónìí.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ti yí ohun tí mo kà sí pàtàkì pa dà, ó ṣì ń wù mí kí n fi iṣẹ́ dókítà tí mo fẹ́ràn ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́. Torí náà, mo yọ̀ǹda ara mi láti ṣiṣẹ́ dókítà ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Paris àti nígbà tó yá ní Bẹ́tẹ́lì tuntun tó wà ní Louviers. Ó ti tó nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún tí mo ti ń tilé lọ sí Bẹ́tẹ́lì. Ní gbogbo àkókò yẹn, mo ti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ láàárín ìdílé Bẹ́tẹ́lì, àwọn kan lára wọn sì ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún báyìí. Lọ́jọ́ kan inú mi dùn gan-an, ó sì tún yà mí lẹ́nu nígbà tí mo pàdé ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Bẹ́tẹ́lì. Mo wá mọ̀ pé èmi ni mo gbẹ̀bí ẹ̀ ní nǹkan bí ogún (20) ọdún sẹ́yìn!

MO TI RÍ I PÉ JÈHÓFÀ MÁA Ń BÓJÚ TÓ ÀWỌN ÈÈYÀN Ẹ̀ DÁADÁA

Láti àwọn ọdún yìí wá, ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà ń pọ̀ sí i, mo sì ti rí bó ṣe ń tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà tó sì ń dáàbò bò wọ́n nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Ní nǹkan bí ọdún 1980, Ìgbìmọ̀ Olùdarí dá ètò kan sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó máa jẹ́ káwọn dókítà mọ ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀.

Lẹ́yìn náà lọ́dún 1988, Ìgbìmọ̀ Olùdarí dá ẹ̀ka tuntun kan sílẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n ń pè ní Ẹ̀ka Tó Ń Pèsè Ìsọfúnni fún Àwọn Ilé Ìwòsàn. Níbẹ̀rẹ̀, ẹ̀ka yìí ń bójú tó Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn (HLC) tí wọ́n dá sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìtọ́jú tó dára gbà. Nígbà tí wọ́n dá Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn sílẹ̀ kárí ayé, wọ́n dá ọ̀kan sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Faransé. Orí mi wú gan-an nígbà tí mo rí bí ètò Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó ń ṣàìsàn!

MO ṢE OHUN TÓ WÀ LỌ́KÀN MI LÁTI KÉKERÉ

À ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, a sì ń gbádùn iṣẹ́ náà

Iṣẹ́ dókítà ni mo fẹ́ràn jù. Àmọ́ nígbà tí mo ronú nípa ohun tó yẹ kí n fi sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé mi, mo wá mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni kí n máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, Orísun ìyè, kí wọ́n sì máa sìn ín. Ìyẹn sì ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ dókítà lọ. Lẹ́yìn tí mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, èmi àti Lydie di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn àwọn tó ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lóṣooṣù láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn. Títí di báyìí, à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà.

Èmi àti Lydie lọ́dún 2021

Mo ṣì ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ran àwọn aláìsàn lọ́wọ́ kí ara lè tù wọ́n, àmọ́ mo mọ̀ pé kò sí bí dókítà kan ṣe lè mọṣẹ́ tó tá á lè wo gbogbo àrùn tàbí kó dènà ikú. Torí náà, mò ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí kò ní sí ìrora, àìsàn àti ikú mọ́. Nínú ayé tuntun tí ò ní pẹ́ dé mọ́ yẹn, títí láé ni màá máa kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, títí kan ọ̀nà àgbàyanu tó gbà dá ara èèyàn. Ó dájú pé gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi láti kékeré ló máa ṣẹ torí mo mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa!