Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 13

Ìjọsìn Tòótọ́ Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Láyọ̀

Ìjọsìn Tòótọ́ Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Láyọ̀

“Jèhófà, Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo àti ọlá àti agbára.”—ÌFI. 4:11.

ORIN 31 Bá Ọlọ́run Rìn!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Kí ló máa jẹ́ kí inú Jèhófà dùn sí ìjọsìn wa?

 KÍ LÓ máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ìjọsìn”? Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú nípa arákùnrin kan tó kúnlẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì ẹ̀, tó sì ń fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà kó tó lọ sùn. Tàbí kó o ronú nípa ìdílé kan tínú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

2 Ìjọsìn làwọn tá a mẹ́nu bà nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí ń ṣe. Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ yìí? Inú ẹ̀ máa dùn sí i tí wọ́n bá ṣe é lọ́nà tó fẹ́, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un. A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an, a sì mọ̀ pé òun ló yẹ ká máa jọ́sìn. Torí náà, ọ̀nà tó dáa jù la fẹ́ gbà jọ́sìn ẹ̀.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà nígbà àtijọ́ àti nǹkan mẹ́jọ tó fẹ́ ká máa ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀ lónìí. Bá a ṣe ń gbé àwọn nǹkan yìí yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká máa ronú lórí bá a ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú ìjọsìn wa kí Jèhófà lè tẹ́wọ́ gbà á. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọsìn tòótọ́ ṣe ń mú ká láyọ̀.

ÌJỌSÌN TÍ JÈHÓFÀ TẸ́WỌ́ GBÀ NÍGBÀ ÀTIJỌ́

4. Báwo làwọn tó jọ́sìn Jèhófà kí Jésù tó wá sáyé ṣe fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?

4 Kí Jésù tó wá sáyé, àwọn ọkùnrin olóòótọ́ bí Ébẹ́lì, Nóà, Ábúráhámù àti Jóòbù fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, àwọn sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ṣe? Wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà, wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, wọ́n sì rúbọ sí i. Bíbélì ò sọ gbogbo nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú ìjọsìn wọn. Àmọ́, gbogbo nǹkan tí wọ́n lè ṣe láti bọlá fún Jèhófà ni wọ́n ṣe, Jèhófà sì tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn. Nígbà tó yá, Jèhófà fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní Òfin Mósè. Àwọn nǹkan pàtó tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n máa ṣe nínú ìjọsìn òun ló wà nínú òfin yẹn.

5. Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ máa jọ́sìn ẹ̀ lẹ́yìn tí Jésù kú, tó sì jíǹde?

5 Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, Jèhófà ò fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun tẹ̀ lé Òfin Mósè mọ́. (Róòmù 10:4) Òfin tuntun, ìyẹn “òfin Kristi” ló fẹ́ káwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé. (Gál. 6:2) Jèhófà ò fẹ́ kí wọ́n há “òfin” náà sórí tàbí kí wọ́n máa tẹ̀ lé òfin ṣe-tibí-má-ṣe-tọ̀hún. Ohun tó fẹ́ ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àtohun tó fi ń kọ́ni. Bákan náà lónìí, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi. Ohun tá à ń ṣe yìí ń múnú Jèhófà dùn, ó sì ń mára tù wá.—Mát. 11:29.

6. Kí ló máa mú ká jàǹfààní látinú àpilẹ̀kọ yìí?

6 Bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mò ń sunwọ̀n sí i ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?’ O tún lè bi ara ẹ pé, ‘Ṣé mo lè ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn mi?’ Jẹ́ kínú ẹ máa dùn bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú, àmọ́ ó tún yẹ kó o bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.

ÀWỌN NǸKAN WO LÀ Ń ṢE NÍNÚ ÌJỌSÌN WA?

7. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tá a bá gbàdúrà sí i látọkàn wá?

7 Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, à ń jọ́sìn ẹ̀ nìyẹn. Bíbélì fi àdúrà tá à ń gbà sí Jèhófà wé tùràrí tí wọ́n fara balẹ̀ ṣe, tí wọ́n ń lò nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì. (Sm. 141:2) Òórùn dídùn tí tùràrí náà máa ń ní máa ń múnú Jèhófà dùn. Lọ́nà kan náà, àdúrà àtọkànwá tá à ń gbà sí Jèhófà “máa ń múnú” rẹ̀ dùn, kódà tí àdúrà náà ò bá tiẹ̀ gùn. (Òwe 15:8; Diu. 33:10) Èyí jẹ́ ká rí i pé inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá gbàdúrà àtọkànwá sí i, tá a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ torí àwọn nǹkan tó ti ṣe fún wa. Jèhófà fẹ́ ká máa sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn fún òun, ohun tá a fẹ́ àtohun tá à ń retí pé kó ṣe fún wa. Torí náà, kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, á dáa kó o kọ́kọ́ ronú nípa ohun tó o máa sọ. Tó o bá ṣẹ bẹ́ẹ̀, àdúrà tó ò ń gbà sí Bàbá rẹ ọ̀run máa dà bíi “tùràrí” tó ń mú òórùn dídùn tó dáa jù lọ jáde.

8. Àwọn ìgbà wo ló yẹ ká máa yin Ọlọ́run?

8 Tá a bá ń yin Jèhófà, à ń jọ́sìn ẹ̀ nìyẹn. (Sm. 34:1) Tá a bá ń sọ fáwọn èèyàn nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà àtàwọn iṣẹ́ rere rẹ̀, à ń yìn ín nìyẹn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Torí náà, tá a bá mọyì gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ lójoojúmọ́. Tá a bá ń wàásù, ṣe là ń ‘rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run, ìyẹn èso ètè wa.’ (Héb. 13:15) Bá a ṣe máa ń fara balẹ̀ ronú nípa ohun tá a máa sọ ká tó gbàdúrà sí Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa fara balẹ̀ ronú nípa ohun tá a máa sọ fáwọn tá a fẹ́ lọ wàásù fún torí “ẹbọ ìyìn” tó dáa jù lọ la fẹ́ rú sí Jèhófà. Torí náà, tá a bá wàásù òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, ó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

9. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń pé jọ láti jọ́sìn Jèhófà bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà àtijọ́? Sọ àǹfààní tó o ti rí.

9 Tá a bá ń wá sípàdé déédéé, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Kí gbogbo ọkùnrin rẹ máa fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún ní ibi tó bá yàn.” (Diu. 16:16) Èyí fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ilé àti oko wọn sílẹ̀ láìsí ẹni táá máa bá wọn ṣọ́ ọ. Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé: ‘Ilẹ̀ yín ò ní wọ ẹnikẹ́ni lójú nígbà tí ẹ bá ń gòkè lọ rí ojú Jèhófà Ọlọ́run yín.’ (Ẹ́kís. 34:24) Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n lè lọ síbi àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni wọ́n sì rí níbi àjọyọ̀ náà torí ó jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ àwọn Òfin Jèhófà, ó jẹ́ kí wọ́n ronú lórí àwọn nǹkan rere tó ti ṣe fún wọn, ó tún fún wọn láǹfààní láti rí ìṣírí gbà bí wọ́n ṣe wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. (Diu. 16:15) Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwa náà máa jàǹfààní tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa wá sípàdé déédéé. Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó, tó bá rí i pé a múra sílẹ̀ dáadáa fún ìpàdé kí ìdáhùn wa lè gbé àwọn ará ró.

10. Kí nìdí tí orin kíkọ fi ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn wa?

10 Tá a bá ń kọrin pẹ̀lú àwọn ará, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. (Sm. 28:7) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà pé orin kíkọ ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. Ọba Dáfídì yan igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́jọ (288) àwọn ọmọ Léfì láti máa kọrin nínú tẹ́ńpìlì. (1 Kíró. 25:1, 6-8) Bákan náà lónìí, tá a bá ń kọrin ìyìn sí Jèhófà, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìyẹn. Àmọ́ kò di dandan ká lẹ́bùn orin kíkọ ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná, tá a bá ń sọ̀rọ̀, “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà,” ṣùgbọ́n a ò ní torí ìyẹn sọ pé a ò ní sọ̀rọ̀ tá a bá wà nípàdé tàbí òde ẹ̀rí. (Jém. 3:2) Lọ́nà kan náà, a ò ní sọ pé torí ohùn wa ò dáa, a ò ní kọrin ìyìn sí Jèhófà.

11. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 48:13, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣètò àkókò tá a máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìdílé wa?

11 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń kọ́ àwọn ọmọ wa nípa Jèhófà, à ń jọ́sìn ẹ̀ nìyẹn. Lọ́jọ́ Sábáàtì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣiṣẹ́ kankan, ṣe ni wọ́n máa ń lo ọjọ́ náà láti jẹ́ kí àjọṣe àwọn àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. (Ẹ́kís. 31:16, 17) Àwọn tó ń pa Sábáàtì yẹn mọ́ láàárín wọn máa ń lo àkókò náà láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan rere tó ti ṣe fún wọn. Bákan náà lónìí, ó yẹ ká máa wáyè ka Bíbélì, ká sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn nìyẹn, ó sì ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Sm. 73:28) Yàtọ̀ síyẹn, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀, àwọn òbí máa lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run.—Ka Sáàmù 48:13.

12. Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó rí iṣẹ́ táwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ṣe nínú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́?

12 Tá a bá ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, tá a sì ń tún wọn ṣe, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. Bíbélì sọ pé “iṣẹ́ mímọ́” ni gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn àtàwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe sínú ẹ̀. (Ẹ́kís. 36:1, 4) Bákan náà lónìí, tá a bá ń kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé ètò Ọlọ́run míì, Jèhófà á kà á sí iṣẹ́ mímọ́. Ọ̀pọ̀ àkókò làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan máa ń lò lẹ́nu iṣẹ́ yìí. A mà mọyì iṣẹ́ ribiribi táwọn ará yìí ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba náà o! Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn kan lára wọn tiẹ̀ lè fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àwọn alàgbà náà lè fi hàn pé àwọn ń ti iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run lẹ́yìn. Tí wọ́n bá rí i pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé gba fọ́ọ̀mù aṣáájú-ọ̀nà déédéé, tí wọ́n sì rí i pé wọ́n kúnjú ìwọ̀n, ó yẹ kí wọ́n tètè fọwọ́ sí i. Bóyá akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni wá lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa pátápátá la lè kó ipa tó jọjú láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àtàwọn ilé ètò Ọlọ́run míì wà ní mímọ́ tónítóní, kó sì dùn ún wò.

13. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ọrẹ tá a fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?

13 Tá a bá ń fi ọrẹ ṣètìlẹyìn, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣe àjọyọ̀, Jèhófà ò retí pé kí wọ́n wá síwájú òun lọ́wọ́ òfo. (Diu. 16:16) Ohun tí agbára kálukú wọn bá gbé ni Jèhófà retí pé kí wọ́n mú wá. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á fi hàn pé àwọn mọyì gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wọn. Báwo làwa náà ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún ìnáwó ìjọ àti iṣẹ́ kárí ayé bí agbára wa bá ṣe gbé e tó. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Tó bá ti jẹ́ pé ó yá èèyàn lára, á túbọ̀ ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ìyẹn tó bá jẹ́ ohun tí èèyàn ní ló fi ṣe é, kì í ṣe ohun tí èèyàn kò ní.” (2 Kọ́r. 8:4, 12) Torí náà, inú Jèhófà máa ń dùn tó bá ń rí i pé ohun tá a fi ṣètọrẹ wá látọkàn wa, bó tiẹ̀ kéré.—Máàkù 12:42-44; 2 Kọ́r. 9:7.

14. Bó ṣe wà nínú Òwe 19:17, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tá a bá ran àwọn ará tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́?

14 Tá a bá ń ran àwọn ará tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn. Jèhófà ṣèlérí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá ṣojúure sáwọn aláìní, òun máa bù kún wọn. (Diu. 15:7, 10) Gbogbo ìgbà tá a bá ran arákùnrin tàbí arábìnrin wa kan tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́, inú Jèhófà máa ń dùn torí ó mọ̀ pé òun là ń ṣe é fún. (Ka Òwe 19:17.) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ará ní Fílípì fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ó pè é ní “ẹbọ tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tó sì wu Ọlọ́run gidigidi.” (Fílí. 4:18) Ṣé ìwọ náà lè wo àwọn ará ìjọ tó o wà, kó o sì bi ara ẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ẹnì kan wà níbẹ̀ tí mo lè ràn lọ́wọ́?’ Inú Jèhófà máa dùn tó bá ń rí i pé à ń lo àkókò wa, okun wa, àwọn ẹ̀bùn tá a ní, àtàwọn ohun ìní wa láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Torí náà, tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, à ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn.—Jém. 1:27.

ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́ MÁA Ń JẸ́ KÁ LÁYỌ̀

15. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìjọsìn tòótọ́ máa ń gba àkókò àti ìsapá, kí nìdí tí kò fi nira?

15 Ìjọsìn tòótọ́ máa ń gba àkókò àti ìsapá. Àmọ́ kò nira. (1 Jòh. 5:3) Kí nìdí? Ìdí ni pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló mú ká máa jọ́sìn ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Ká sọ pé ọmọ kan fẹ́ fún bàbá ẹ̀ lẹ́bùn. Ó lè lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti ya àwòrán kan fún un. Síbẹ̀, kò ní kábàámọ̀ ọ̀pọ̀ àkókò tó fi ya àwòrán náà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ bàbá ẹ̀, inú ẹ̀ sì dùn pé òun fẹ́ fún un lẹ́bùn. Lọ́nà kan náà, torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tọkàntọkàn la fi ń lo àkókò àti okun wa nínú ìjọsìn ẹ̀.

16. Bó ṣe wà nínú Hébérù 6:10, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó bá rí i pé à ń ṣe ohun tó ń múnú ẹ̀ dùn?

16 Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn kì í retí pé ohun kan náà làwọn ọmọ àwọn á máa ṣe fáwọn. Wọ́n mọ̀ pé àwọn ọmọ wọn ò rí bákan náà àti pé ohun tí wọ́n mọ̀ ọ́n ṣe yàtọ̀ síra. Lọ́nà kan náà, Bàbá wa ọ̀run mọ ohun tí agbára ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbé. Ó ṣeé ṣe kó o mọ nǹkan kan ṣe ju àwọn èèyàn ẹ kan tó o mọ̀, tó o sì fẹ́ràn. Ó sì lè jẹ́ pé o ò lè ṣe tó àwọn míì bóyá torí ọjọ́ ogbó, àìlera àti bó o ṣe máa pèsè fún ìdílé ẹ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má jẹ́ kó sú ẹ. (Gál. 6:4) Jèhófà ò ní gbàgbé iṣẹ́ tó o ṣe. Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, tó o sì ń ṣe é tọkàntọkàn, inú Jèhófà máa dùn gan-an. (Ka Hébérù 6:10.) Jèhófà mọ àwọn nǹkan tó wà lọ́kàn ẹ tó o fẹ́ ṣe. Torí náà, ó fẹ́ kí inú ẹ máa dùn bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé nínú ìjọsìn rẹ̀.

17. (a) Tí àwọn apá kan lára ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn wa bá nira fún ẹ, kí lo lè ṣe? (b) Àǹfààní wo lo ti rí nígbà tó o ṣe ọ̀kan lára àwọn nǹkan tó wà nínú àpótí náà “ Máa Ṣe Àwọn Nǹkan Táá Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Láyọ̀”?

17 Kí la lè ṣe tó bá nira fún wa láti máa ṣe apá kan lára ìjọsìn wa bíi dídá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ká lọ wàásù níbi térò pọ̀ sí? Tó o bá ń gbìyànjú láti ṣe apá kan lára ìjọsìn wa tí kò rọrùn fún ẹ, wàá rí i pé bó o ṣe túbọ̀ ń ṣe é, á mọ́ ẹ lára, á sì ṣe ẹ́ láǹfààní. A lè fi àkókò tá a fi ń jọ́sìn wé àsìkò tá a fi ń ṣe eré ìmárale tàbí tá a fi ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò ìkọrin kan. Tó bá jẹ́ pé ẹ̀kọ̀ọ̀kan là ń ṣe é, ó lè má tètè mọ́ wa lára, a sì lè má tètè mọ̀ ọ́n lò. Àmọ́ a lè pinnu pé àá máa ṣe é lójoojúmọ́. Ó lè jẹ́ pé ìṣẹ́jú mélòó kan làá máa lò tá a bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àmọ́ tó bá yá, a lè fi kún un. Tá a bá rí i pé ó ti ń mọ́ wa lára, tá a sì ti ń mọ̀ ọ́n ṣe, á máa wù wá láti ṣe é, àá sì máa gbádùn ẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ ìjọsìn wa náà ṣe rí nìyẹn.

18. Kí ló ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè fi ìgbésí ayé wa ṣe, àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀?

18 Ohun tó dáa jù lọ tá a lè fi ìgbésí ayé wa ṣe ni pé ká máa jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa láyọ̀, ìgbé ayé wa máa dáa, àá sì tún láǹfààní láti máa sin Jèhófà títí láé. (Òwe 10:22) Ọkàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà máa ń ran àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ tá a bá wà nínú ìṣòro. (Àìsá. 41:9, 10) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe fún wa tó jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń jọ́sìn ẹ̀. Torí náà, òun ló tọ́ sí “láti gba ògo àti ọlá”!—Ìfi. 4:11.

ORIN 24 Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà

^ ìpínrọ̀ 5 Jèhófà ló yẹ ká máa jọ́sìn torí pé òun ló dá gbogbo nǹkan. Jèhófà máa tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa tá a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, tá a sì ń jẹ́ kí ìlànà ẹ̀ máa darí wa. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́jọ tá a máa ń ṣe láti jọ́sìn Jèhófà. A tún máa kọ́ nípa bá a ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan mẹ́jọ yìí àti bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀.