Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 14

Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Fara Wé Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù

Ẹ̀yin Alàgbà, Ẹ Máa Fara Wé Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù

“Ẹ máa fara wé mi.”—1 KỌ́R. 11:1.

ORIN 99 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Àwa Ará

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1-2. Báwo ni àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ lónìí?

 ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, ó sì ṣiṣẹ́ kára gan-an nítorí wọn. (Ìṣe 20:31) Àwọn ará náà sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ torí pé ó ń ṣiṣẹ́ kára. Nígbà táwọn alàgbà tó wà ní Éfésù gbọ́ pé àwọn ò ní rí Pọ́ọ̀lù mọ́, ṣe ni wọ́n “bú sẹ́kún.” (Ìṣe 20:37) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ wa nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. (Fílí. 2:16, 17) Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn fáwọn alàgbà láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Kí ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ wọn yanjú?

2 Ẹ̀yin alàgbà lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. (1 Kọ́r. 11:1) Èèyàn bíi tiwa ni. Aláìpé lòun náà, kódà kì í rọrùn fún un láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà míì. (Róòmù 7:18-20) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún kojú onírúurú ìṣòro. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kíyẹn mú kóun rẹ̀wẹ̀sì tàbí banú jẹ́. Táwọn alàgbà bá ń fara wé Pọ́ọ̀lù, wọ́n á lè ṣiṣẹ́ wọn yanjú, wọ́n á sì máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń sin Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe lè ṣe é.

3. Kí làwọn nǹkan tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́rin tí kì í jẹ́ kí iṣẹ́ àwọn alàgbà rọrùn: (1) kì í rọrùn fún wọn láti ráyè wàásù kí wọ́n sì tún ṣe àwọn iṣẹ́ míì nínú ìjọ, (2) kì í rọrùn fún wọn láti fìfẹ́ bójú tó àwọn ará, (3) wọ́n ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn, (4) kì í rọrùn fún wọn láti fara da àìpé àwọn ará. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Pọ́ọ̀lù ṣe borí àwọn nǹkan yìí àti báwọn alàgbà ṣe lè fara wé e.

KÌ Í RỌRÙN LÁTI RÁYÈ WÀÁSÙ, KÍ WỌ́N SÌ TÚN ṢE ÀWỌN IṢẸ́ MÍÌ NÍNÚ ÌJỌ

4. Kí ni kì í jẹ́ kó rọrùn fáwọn alàgbà láti máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé?

4 Ohun tó lè mú kó ṣòro. Àwọn alàgbà láwọn iṣẹ́ míì nínú ìjọ yàtọ̀ sí pé kí wọ́n máa lọ sóde ẹ̀rí déédéé. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ lára wọn ló máa ń darí ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀, wọ́n sì tún máa ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń múra àwọn àsọyé tí wọ́n ní sílẹ̀. Wọ́n tún máa ń dá àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́, inú wọn sì máa ń dùn láti fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ níṣìírí. (1 Pét. 5:2) Àwọn alàgbà kan máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé míì tí ètò Ọlọ́run ń lò, wọ́n sì máa ń tún un ṣe. Bíi tàwọn ará ìjọ yòókù, iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù tó yẹ káwọn alàgbà máa ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ wọn máa ń dí gan-an.—Mát. 28:19, 20.

5. Àpẹẹrẹ tó dáa wo ni Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

5 Ohun tí ẹ̀yin alàgbà lè kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Ohun tó jẹ́ kí Pọ́ọ̀lù ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yanjú wà nínú Fílípì 1:10 níbi tó ti gbà wá níyànjú pé ká “máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀ náà fi ìmọ̀ràn yẹn sílò. Jèhófà gbé iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lé e lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi ṣe iṣẹ́ náà torí ohun tó kà sí pàtàkì jù nígbèésí ayé ẹ̀ nìyẹn. Ó wàásù “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 20:20) Gbogbo ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń wàásù, kò ní àkókò pàtó kan tó fi ń wàásù lójúmọ́, kì í sì í ṣe ọjọ́ kan péré lọ́sẹ̀ ló fi ń wàásù. Gbogbo ìgbà tó bá ti ní àǹfààní láti wàásù ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń dúró de àwọn tí wọ́n jọ ń wàásù ní Áténì, ó wàásù fún àwọn gbajúmọ̀ kan níbẹ̀, àwọn kan sì fetí sí i. (Ìṣe 17:16, 17, 34) Kódà nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà nínú “ẹ̀wọ̀n,” ó wàásù fún àwọn tó wà pẹ̀lú ẹ̀.—Fílí. 1:13, 14; Ìṣe 28:16-24.

6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́?

6 Pọ́ọ̀lù lo àkókò ẹ̀ lọ́nà tó dáa jù lọ. Ó máa ń pe àwọn míì pé káwọn jọ lọ wàásù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó rìnrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ àkọ́kọ́, ó mú Jòhánù Máàkù dání, nígbà tó sì lọ lẹ́ẹ̀kejì, ó mú Tímótì dání. (Ìṣe 12:25; 16:1-4) Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù dá àwọn ọkùnrin yìí lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan nínú ìjọ, bí wọ́n á ṣe máa fìfẹ́ bójú tó àwọn ará àti bí wọ́n ṣe máa di olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́.—1 Kọ́r. 4:17.

Ẹ máa wàásù nígbà gbogbo bíi ti Pọ́ọ̀lù (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa nínú Éfésù 6:14, 15?

7 Ohun tẹ́yin alàgbà lè rí kọ́. Ẹ̀yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tẹ́ ẹ bá ń lo gbogbo àǹfààní tó bá yọ láti wàásù fáwọn èèyàn, kì í ṣe tẹ́ ẹ bá ń wàásù láti ilé dé ilé nìkan. (Ka Éfésù 6:14, 15.) Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè wàásù tẹ́ ẹ bá lọ sọ́jà tàbí tẹ́ ẹ bá wà níbi iṣẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, tẹ́ ẹ bá lọ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ilé ètò Ọlọ́run míì, ẹ lè wàásù fáwọn tó wà ládùúgbò tàbí àwọn tó wá tajà fún yín. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ̀yin alàgbà tún lè lo àkókò tẹ́ ẹ bá fi wà pẹ̀lú àwọn ará lóde ẹ̀rí láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ títí kan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

8. Kí ló lè gba pé kẹ́yin alàgbà ṣe nígbà míì?

8 Kò yẹ kẹ́yin alàgbà jẹ́ kí iṣẹ́ ìjọ tàbí ti àyíká dí yín lọ́wọ́ débi tí ẹ ò fi ní ráyè lọ sóde ẹ̀rí. Kí ọ̀kan má bàa pa òmíì lára, ó lè gba pé kẹ́ ẹ kọ àwọn iṣẹ́ kan tí wọ́n bá fi lọ̀ yín. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ronú nípa ẹ̀ dáadáa, tẹ́ ẹ sì fi sádùúrà, ẹ lè wá rí i pé tẹ́ ẹ bá gba iṣẹ́ náà, kò ní jẹ́ kẹ́ ẹ ráyè fáwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. Àwọn nǹkan náà ni ìjọsìn ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, lílọ sóde ẹ̀rí àti dídá àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe ń wàásù. Kì í rọrùn fáwọn alàgbà kan láti kọ iṣẹ́ tí wọ́n bá fi lọ̀ wọ́n, àmọ́ ó yẹ kẹ́ ẹ fi sọ́kàn pé Jèhófà máa mọyì ẹ̀ gan-an tẹ́ ò bá jẹ́ kí iṣẹ́ kan pa òmíì lára.

KÌ Í RỌRÙN FÚN WỌN LÁTI FÌFẸ́ BÓJÚ TÓ ÀWỌN ARÁ

9. Kí ni kì í rọrùn fáwọn alàgbà láti ṣe torí pé ọwọ́ wọn máa ń dí?

9 Ohun tó lè mú kó ṣòro. Onírúurú ìṣòro làwa èèyàn Jèhófà máa ń kojú. Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, gbogbo wa la nílò ìṣírí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú. Ó sì máa ń gba pé ká ran àwọn kan lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa hùwà àìtọ́. (1 Tẹs. 5:14) Lóòótọ́, àwọn alàgbà ò lè yanjú gbogbo ìṣòro táwa èèyàn Jèhófà ní. Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ káwọn alàgbà ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti fún àwọn ará níṣìírí, kí wọ́n sì dáàbò bò wọ́n. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ àwọn alàgbà máa ń dí, báwo ni wọ́n ṣe lè máa wáyè láti ran àwọn ará lọ́wọ́ lásìkò tí wọ́n nílò ẹ̀ gan-an?

Máa gbóríyìn fáwọn ará kó o sì máa fún wọn níṣìírí (Wo ìpínrọ̀ 10, 12) *

10. Kí ni 1 Tẹsalóníkà 2:7 sọ pé Pọ́ọ̀lù ṣe láti bójú tó àwọn èèyàn Jèhófà?

10 Ohun tí ẹ̀yin alàgbà lè kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Gbogbo ìgbà ni Pọ́ọ̀lù máa ń gbóríyìn fáwọn ará tó sì máa ń fún wọn níṣìírí. Ẹ̀yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tẹ́ ẹ bá ń fìfẹ́ hàn sáwọn ará tẹ́ ẹ sì ń finúure hàn sí wọn. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7.) Pọ́ọ̀lù fi dá àwọn ará lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, Jèhófà náà sì nífẹ̀ẹ́ wọn. (2 Kọ́r. 2:4; Éfé. 2:4, 5) Pọ́ọ̀lù mú àwọn ará ìjọ lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì máa ń wà pẹ̀lú wọn. Pọ́ọ̀lù sọ àwọn nǹkan tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní fáwọn ará, ìyẹn sì fi hàn pé ó fọkàn tán wọn. (2 Kọ́r. 7:5; 1 Tím. 1:15) Síbẹ̀, bí Pọ́ọ̀lù ṣe máa ran àwọn ará lọ́wọ́ ló gbà á lọ́kàn, kì í ṣe bó ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro tiẹ̀.

11. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi bá àwọn ará tó wà níjọ Kọ́ríńtì wí?

11 Ìgbà kan wà tó di dandan pé kí Pọ́ọ̀lù bá àwọn ará kan wí. Àmọ́ kì í ṣe torí pé ó ń bínú sí wọn ló ṣe bá wọn wí. Ìdí tó fi bá wọn wí ni pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn, kò sì fẹ́ kí wọ́n kó síṣòro. Torí náà, nígbà tó kọ lẹ́tà sí wọn, ó kọ ọ́ lọ́nà tó máa yé wọn, ó sì fẹ́ kí wọ́n gba ìbáwí náà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará ìjọ Kọ́ríńtì ní ìbáwí tó le nínú lẹ́tà tó kọ sí wọn. Lẹ́yìn náà, ó rán Títù sí wọn kó lè mọ bí lẹ́tà náà ṣe rí lára wọn. Ẹ wo bínú ẹ̀ ṣe máa dùn tó nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó bá wọn sọ!—2 Kọ́r. 7:6, 7.

12. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè máa fún àwọn ará lókun?

12 Ohun tẹ́yin alàgbà lè rí kọ́. Ẹ̀yin alàgbà máa fi hàn pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tẹ́ ẹ bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará. Ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kẹ́ ẹ máa tètè dé sípàdé kẹ́ ẹ lè bá àwọn ará sọ̀rọ̀ dáadáa. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè má ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ tẹ́ ẹ máa fi gba arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó nílò ìṣírí níyànjú. (Róòmù 1:12; Éfé. 5:16) Alàgbà tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tún máa ń lo Bíbélì láti fún àwọn ará níṣìírí, ó sì fi ń dá wọn lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa ń ṣe ohun táá jẹ́ káwọn ará mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn. Ó máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé, ó sì máa ń gbóríyìn fún wọn. Tó bá fẹ́ gba ẹnì kan nímọ̀ràn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló máa ń lò. Ó máa jẹ́ kí ẹni náà mọ ohun tó yẹ kó ṣiṣẹ́ lé lórí, síbẹ̀, kò ní le koko jù kó lè rọrùn fún ẹni náà láti gba ìmọ̀ràn yẹn.—Gál. 6:1.

WỌ́N NÍ ÀWỌN KÙDÌẸ̀-KUDIẸ TIWỌN

13. Kí ni àìpé àwọn alàgbà lè mú kí wọ́n ṣe nígbà míì?

13 Ohun tó lè mú kó ṣòro. Àwọn alàgbà kì í ṣe ẹni pípé. Àwọn náà máa ń ṣàṣìṣe bíi tàwọn ará tó kù. (Róòmù 3:23) Nígbà míì, ó máa ń dùn wọ́n gan-an tí wọ́n bá ṣàṣìṣe torí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tí wọ́n ní. Tó bá jẹ́ pé kùdìẹ̀-kudiẹ wọn ni wọ́n ń ronú nípa ẹ̀ ṣáá, ó lè mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Àwọn kan sì lè má gbà pé àwọn láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n ṣàtúnṣe tó yẹ.

14.Fílípì 4:13 ṣe sọ, báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ ṣe mú kí Pọ́ọ̀lù borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní?

14 Ohun tí ẹ̀yin alàgbà lè kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Ìrẹ̀lẹ̀ mú kí Pọ́ọ̀lù gbà pé òun ò lè dá borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ òun, àfi kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Nígbà kan, alágídí ni Pọ́ọ̀lù, ó sì ṣenúnibíni tó burú gan-an sáwọn Kristẹni. Àmọ́ nígbà tó yá, ó gbà pé ohun tóun ṣe ò dáa, ó sì yí pa dà. (1 Tím. 1:12-16) Jèhófà ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, ó wá di alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, tó ń fàánú hàn sí wọn, tó sì nírẹ̀lẹ̀. Ó máa ń dun Pọ́ọ̀lù gan-an tó bá ń rántí àwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn. Àmọ́ ó mọ̀ pé Jèhófà ti dárí ji òun, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kó máa ronú ṣáá nípa àwọn àṣìṣe tó ti ṣe. (Róòmù 7:21-25) Ó mọ̀ pé òun kì í ṣe ẹni pípé. Torí náà, ó ṣiṣẹ́ kára kó lè túbọ̀ fìwà jọ Kristi, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa jẹ́ kóun ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun yanjú.—1 Kọ́r. 9:27; ka Fílípì 4:13.

Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti borí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó o ní (Wo ìpínrọ̀ 14-15) *

15. Ojú wo ló yẹ káwọn alàgbà máa fi wo kùdìẹ̀-kudiẹ tí wọ́n ní?

15 Ohun tẹ́yin alàgbà lè rí kọ́. Kì í ṣe torí pé àwọn alàgbà jẹ́ ẹni pípé ni Jèhófà fi yàn wọ́n. Àmọ́ tí wọ́n bá ṣàṣìṣe, Jèhófà fẹ́ kí wọ́n gbà pé àwọn ṣàṣìṣe, kí wọ́n sì ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí wọ́n lè túbọ̀ fìwà jọ Kristi. (Éfé. 4:23, 24) Ẹ̀yin alàgbà gbọ́dọ̀ máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara yín wò, kẹ́ ẹ lè ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa jẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀, ó sì máa jẹ́ kẹ́ ẹ ṣiṣẹ́ yín yanjú.—Jém. 1:25.

KÌ Í RỌRÙN FÚN WỌN LÁTI FARA DA ÀÌPÉ ÀWỌN ARÁ

16. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ará ni alàgbà kan ń wò?

16 Ohun tó lè mú kó ṣòro. Ó máa ń rọrùn fáwọn alàgbà láti mọ ibi táwọn ará kù sí torí pé wọ́n máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú wọn. Torí náà táwọn alàgbà ò bá ṣọ́ra, nǹkan lè sú wọn, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í kanra tàbí kí wọ́n máa bá àwọn ará wí láìnídìí. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé àwa Kristẹni ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ torí ohun tí Sátánì máa fẹ́ ká ṣe gan-an nìyẹn.—2 Kọ́r. 2:10, 11.

17. Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀?

17 Ohun tí ẹ̀yin alàgbà lè kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Ohun tó dáa ni Pọ́ọ̀lù máa ń rò nípa àwọn ará. Pọ́ọ̀lù mọ ibi táwọn ará yẹn kù sí, kódà wọ́n máa ń ṣe ohun tó dùn ún nígbà míì. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tẹ́nì kan bá ṣàṣìṣe, ìyẹn ò sọ ẹni náà dẹni burúkú. Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, ibi tí wọ́n dáa sí ló sì máa ń wò. Táwọn ará bá ṣe ohun tí kò tọ́, ó mọ̀ pé kò wù wọ́n kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó yẹ kóun ràn wọ́n lọ́wọ́.

18. Kí lo rí kọ́ látinú bí Pọ́ọ̀lù ṣe yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín Yúódíà àti Síńtíkè? (Fílípì 4:1-3)

18 Ẹ jẹ́ ká wo bí Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn arábìnrin méjì kan lọ́wọ́ ní ìjọ tó wà ní Fílípì. (Ka Fílípì 4:1-3.) Ó jọ pé èdèkòyédè kan wáyé láàárín Yúódíà àti Síńtíkè, ìyẹn ò sì jẹ́ kí àárín wọn gún mọ́. Pọ́ọ̀lù ò le koko mọ́ wọn, kò sì dá wọn lẹ́jọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ibi tí wọ́n dáa sí ló wò. Olóòótọ́ làwọn arábìnrin yìí, èèyàn dáadáa làwọn ará sì mọ̀ wọ́n sí. Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Ohun tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ nípa wọn yìí ló mú kó gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n yanjú aáwọ̀ náà kí àárín wọn lè pa dà gún. Torí pé ibi táwọn ará dáa sí ni Pọ́ọ̀lù máa ń wò, ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ láyọ̀, ó sì jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín òun àtàwọn ará túbọ̀ lágbára.

Máa fìfẹ́ bá àwọn ará wí tí wọ́n bá tiẹ̀ ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó (Wo ìpínrọ̀ 19) *

19. (a) Kí ló máa jẹ́ káwọn alàgbà máa wo ibi táwọn ará dáa sí? (b) Kí lo rí kọ́ lára alàgbà tó ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe nínú àwòrán yẹn?

19 Ohun tẹ́yin alàgbà lè rí kọ́. Ẹ̀yin alàgbà, ibi táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ yín dáa sí ni kẹ́ ẹ máa wò. Aláìpé ni wọ́n, síbẹ̀ gbogbo wọn ló ní ẹ̀bùn tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (Fílí. 2:3) Òótọ́ ni pé látìgbàdégbà, ó lè gba pé káwọn alàgbà máa tún èrò àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan ṣe. Àmọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù, kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí ò dáa táwọn ará sọ tàbí ohun tó kù díẹ̀ káàtó tí wọ́n ṣe ló yẹ káwọn alàgbà máa wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n máa wò ni ìfẹ́ tẹ́ni náà ní fún Jèhófà, bó ṣe ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ àti pé ó ṣì máa ṣe dáadáa lọ́jọ́ iwájú. Táwọn alàgbà bá ń wo ibi táwọn ará dáa sí, ìyẹn máa jẹ́ kára tu gbogbo àwọn ará tó wà nínú ìjọ.

Ẹ MÁA FARA WÉ PỌ́Ọ̀LÙ

20. Kí ló yẹ kẹ́yin alàgbà ṣe kẹ́ ẹ lè túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lára Pọ́ọ̀lù?

20 Ẹ̀yin alàgbà máa jàǹfààní gan-an tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìwé “Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná” Nípa Ìjọba Ọlọ́run orí kejìlá, ìpínrọ̀ 17-20 pẹ̀lú ojú ìwé 166-167 àti Ilé Ìṣọ́ September 15, 1986, ojú ìwé 12-13. Bí ẹ̀yin alàgbà ṣe ń ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀, ẹ bi ara yín pé, ‘Báwo ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe lè jẹ́ kí n túbọ̀ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi?’

21. Kí ló yẹ kó dá ẹ̀yin alàgbà lójú?

21 Ẹ̀yin alàgbà, ẹ máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ò retí pé kẹ́ ẹ jẹ́ ẹni pípé, ohun tó fẹ́ ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ olóòótọ́. (1 Kọ́r. 4:2) Jèhófà mọyì bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣiṣẹ́ kára tó sì jẹ́ olóòótọ́. Ó dájú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Torí náà ẹ̀yin alàgbà, Jèhófà ò ní “gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.”—Héb. 6:10.

ORIN 87 Ẹ Wá Gba Ìtura

^ ìpínrọ̀ 5 Inú wa dùn a sì ń jàǹfààní torí pé a láwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ wa, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ kára nítorí wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun mẹ́rin tí kì í jẹ́ kí iṣẹ́ àwọn alàgbà rọrùn. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe lè ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ wọn yanjú. Yàtọ̀ síyẹn, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká máa ti àwọn alàgbà lẹ́yìn, ká máa fìfẹ́ hàn sí wọn, ká sì máa ṣohun táá jẹ́ kíṣẹ́ wọn túbọ̀ rọrùn.

^ ìpínrọ̀ 61 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń wàásù fún ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ nígbà tí wọ́n ń lọ sílé.

^ ìpínrọ̀ 63 ÀWÒRÁN: Alàgbà kan ń fìfẹ́ gba arákùnrin kan níyànjú torí pé ó máa ń ya ara ẹ̀ sọ́tọ̀.

^ ìpínrọ̀ 65 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń bínú torí ohun kan tó ṣẹlẹ̀, arákùnrin míì wá ń gbà á nímọ̀ràn tó máa ràn án lọ́wọ́.

^ ìpínrọ̀ 67 ÀWÒRÁN: Nígbà tí arákùnrin kan yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣiṣẹ́, kò pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ náà, àmọ́ alàgbà tó wà níbẹ̀ ò bínú sí i.