Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 17

Ẹ̀yin Ìyá, Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Yùníìsì

Ẹ̀yin Ìyá, Ẹ Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Yùníìsì

‘Má pa ẹ̀kọ́ ìyá rẹ tì. Ó dà bí adé ẹwà fún orí rẹ àti ohun ọ̀ṣọ́ tó rẹwà fún ọrùn rẹ.’​—ÒWE 1:8, 9.

ORIN 137 Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

Inú Yùníìsì ìyá Tímótì àti Lọ́ìsì ìyá rẹ̀ àgbà dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń wò ó lọ́jọ́ tó ṣèrìbọmi (Wo ìpínrọ̀ 1)

1-2. (a) Irú èèyàn wo ni Yùníìsì, kí ló sì jẹ́ kó ṣòro fún un láti kọ́ ọmọ ẹ̀ nípa Jèhófà àti Jésù? (b) Kí lo lè sọ nípa àwòrán iwájú ìwé.

 LÓÒÓTỌ́, Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbà tí Tímótì ṣèrìbọmi, àmọ́ ó dájú pé inú Yùníìsì ìyá ẹ̀ máa dùn gan-an lọ́jọ́ yẹn. (Òwe 23:25) Ẹ fojú inú wo ayọ̀ tó máa wà lójú Yùníìsì bí Tímótì ṣe dúró sínú omi nígbà tí wọ́n fẹ́ rì í bọmi. Ńṣe ni Yùníìsì ń rẹ́rìn-ín bí Lọ́ìsì ìyá ẹ̀ ṣe gbá a mọ́ra. Yùníìsì rọra mí kanlẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ri Tímótì bọnú omi. Nígbà tí wọ́n gbé Tímótì sókè pa dà látinú omi, inú Tímótì dùn gan-an, omijé ayọ̀ sì ń bọ́ lójú ìyá ẹ̀. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Yùníìsì ṣàṣeyọrí láti kọ́ Tímótì kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù Kristi. Àwọn ìṣòro wo ló borí kó tó lè ṣàṣeyọrí tó ṣe yìí?

2 Ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn òbí Tímótì ń ṣe. Gíríìkì ni bàbá ẹ̀, àmọ́ Júù ni ìyá ẹ̀ àti ìyá ẹ̀ àgbà. (Ìṣe 16:1) Ó ṣeé ṣe kí Tímótì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ nígbà tí Yùníìsì àti Lọ́ìsì di Kristẹni. Àmọ́ bàbá rẹ̀ kì í ṣe Kristẹni. Ẹ̀sìn wo ni Tímótì máa wá ṣe báyìí? Tímótì ti dàgbà tó ẹni tó lè dá ìpinnu ṣe nígbà yẹn. Ṣé ẹ̀sìn bàbá ẹ̀ ló máa wá ṣe ni àbí ẹ̀sìn àwọn Júù tí wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà? Àbí kẹ̀, ṣé ó máa di ọmọlẹ́yìn Jésù?

3. Báwo ni ohun tí Òwe 1:8, 9 sọ ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo iṣẹ́ táwọn ìyá ń ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

3 Àwọn ìyá tó jẹ́ Kristẹni lónìí náà nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn gan-an. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wọn ni bí wọ́n ṣe máa ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Jèhófà sì mọyì iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe. (Ka Òwe 1:8, 9.) Jèhófà ti ran ọ̀pọ̀ ìyá lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè sìn ín.

4. Àwọn ìṣòro wo làwọn ìyá ń dojú kọ lónìí?

4 Nígbà míì, ọkàn àwọn ìyá kì í balẹ̀ torí wọn ò mọ̀ bóyá àwọn ọmọ wọn á sin Jèhófà bíi ti Tímótì. Ó ṣe tán, àwọn òbí mọ̀ pé oríṣiríṣi nǹkan làwọn ọmọ wọn ń dojú kọ nínú ayé Sátánì yìí. (1 Pét. 5:8) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìyá ló ń dá tọ́mọ torí pé wọn ò lọ́kọ mọ́ tàbí torí pé ọkọ wọn ò sin Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Christine * sọ pé: “Èèyàn dáadáa lọkọ mi, ó sì máa ń tọ́jú wa gan-an, àmọ́ kò fẹ́ kí n kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí wọ́n má bàa sin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi sunkún torí mi ò mọ̀ bóyá àwọn ọmọ mi máa láǹfààní láti sin Jèhófà láé.”

5. Àwọn nǹkan wo la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?

5 Ẹ̀yin ìyá, ẹ̀yin náà lè tọ́ àwọn ọmọ yín yanjú bíi ti Yùníìsì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bẹ́ ẹ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀, kẹ́ ẹ sì fi ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa ràn yín lọ́wọ́.

MÁA FI Ọ̀RỌ̀ ẸNU Ẹ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ LẸ́KỌ̀Ọ́

6.2 Tímótì 3:14, 15 ṣe sọ, báwo ni Tímótì ṣe di Kristẹni?

6 Nígbà tí Tímótì wà lọ́mọdé, ìyá ẹ̀ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti kọ́ ọ ní “ìwé mímọ́” bíi tàwọn Júù tó kù. Ìyá Tímótì ò fi bẹ́ẹ̀ ní ìmọ̀ púpọ̀ torí kò mọ ohunkóhun nípa Jésù Kristi. Àmọ́ ohun tí Tímótì kọ́ látinú Ìwé Mímọ́ máa jẹ́ kó lè pinnu bóyá òun máa di Kristẹni àbí òun ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ṣé ó di Kristẹni? Torí pé ó ti dàgbà nígbà yẹn, òun fúnra ẹ̀ ló máa pinnu bóyá òun fẹ́ di Kristẹni. Ó dájú pé iṣẹ́ àṣekára tí ìyá Tímótì ṣe wà lára ohun tó mú kí Tímótì “gba” òtítọ́ nípa Jésù “gbọ́.” (Ka 2 Tímótì 3:14, 15.) Yùníìsì náà sì mọyì bí Jèhófà ṣe ran òun lọ́wọ́ láti tọ́ Tímótì yanjú kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Orúkọ Yùníìsì wá látinú ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “ìṣẹ́gun,” ó sì ṣẹ́gun lóòótọ́. Ẹ ò rí i pé orúkọ ẹ̀ rò ó gan-an!

7. Lẹ́yìn tí Tímótì ṣèrìbọmi, báwo ni Yùníìsì ṣe ràn án lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú?

7 Ìgbésẹ̀ pàtàkì ni Tímótì gbé nígbà tó ṣèrìbọmi, àmọ́ ọkàn Yùníìsì ò balẹ̀. Ó lè máa ṣàníyàn pé kí lọmọ òun máa fi ìgbésí ayé ẹ̀ ṣe? Ṣé ó máa kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́? Ṣé ó máa lọ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa èrò orí ní Áténì? Ṣé ó máa fi àkókò, okun àti ìgbà ọ̀dọ́ ẹ̀ lépa owó? Yùníìsì ò lè ṣèpinnu fún Tímótì, àmọ́ ó lè ràn án lọ́wọ́ kó lè ṣèpinnu tó dáa. Báwo ló ṣe máa ṣe é? Á máa ṣiṣẹ́ kára láti máa kọ́ Tímótì kó lè nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà àti Jésù, kó sì mọyì gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe fún ìdílé wọn. Inú ìdílé tí ọkọ tàbí aya kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan kọ́ ló ti ṣòro láti tọ́ àwọn ọmọ kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Kódà táwọn òbí méjèèjì bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í rọrùn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè di olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Torí náà, kí lẹ̀yin òbí lè kọ́ lára Yùníìsì?

8. Báwo ni ìyá kan ṣe lè ran ọkọ ẹ̀ tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà?

8 Máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀yin ìyá tí ọkọ yín wà nínú òtítọ́, Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ ran ọkọ yín lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè mọ Jèhófà. Ọ̀nà kan tẹ́ ẹ lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kẹ́ ẹ máa rí i pé nǹkan kan ò dí Ìjọsìn Ìdílé yín lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ni wọ́n máa rí tẹ́ ẹ bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé, kẹ́ ẹ sì wo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe kára gbogbo yín lè balẹ̀ níbẹ̀ kẹ́ ẹ lè gbádùn ẹ̀. Tó bá ṣeé ṣe, o lè ran ọkọ ẹ lọ́wọ́ láti ṣètò ohun tẹ́ ẹ máa ṣe nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín. Bákan náà, táwọn ọmọ yín bá ti tó kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! o lè ran ọkọ ẹ lọ́wọ́. Lọ́nà wo? Rí i pé o ò jẹ́ kí ohunkóhun dí àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn.

9. Àwọn nǹkan wo ló lè ran ìyá kan tí ọkọ ẹ̀ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́?

9 Àwọn ìyá kan ló máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì torí pé wọn ò lọ́kọ tàbí torí pé ọkọ wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, fọkàn balẹ̀, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Lo àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ti ṣe tó máa jẹ́ kó o lè kọ́ àwọn ọmọ ẹ dáadáa. Á dáa kó o gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó ti tọ́mọ yanjú kó o lè mọ bó o ṣe máa lo àwọn ìwé yìí láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ nígbà ìjọsìn ìdílé yín. * (Òwe 11:14) Jèhófà tún máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ bí wàá ṣe máa bá àwọn ọmọ ẹ sọ̀rọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè lo ìbéèrè láti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn. (Òwe 20:5) Tó o bá bi ọmọ ẹ ní ìbéèrè kékeré kan bíi ‘Kí ló máa ń dà ẹ́ láàmú jù nílé ìwé?,’ ìyẹn á jẹ́ kó o mọ nǹkan tó wà lọ́kàn ẹ̀.

10. Nǹkan míì wo lo lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ nípa Jèhófà?

10 Máa lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ nípa Jèhófà. Máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣe fún ẹ. (Diu. 6:6, 7; Àìsá. 63:7) Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀ tó ò bá lè kọ́ àwọn ọmọ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ déédéé nílé. Christine tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àkókò tí mo lè fi bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀ Bíbélì ò tó nǹkan rárá, torí náà gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ ni mo máa ń lò. A jọ máa ń rìn jáde tàbí ká wa ọkọ̀ lọ sójú omi ká lè ráyè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá àtàwọn nǹkan míì nípa ìjọsìn Jèhófà. Nígbà táwọn ọmọ mi dàgbà díẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra wọn.” Bákan náà, máa sọ nǹkan tó dáa nípa Jèhófà àtàwọn ará. Má sọ̀rọ̀ àwọn alàgbà láìdáa. Ohun tó o bá sọ nípa àwọn alàgbà ló máa pinnu bóyá àwọn ọmọ ẹ á lọ bá wọn nígbà ìṣòro àbí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀.

11.Jémíìsì 3:18 ṣe sọ, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ilé wa?

11 Jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ilé yín. Máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ọkọ ẹ àtàwọn ọmọ ẹ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Má sọ̀rọ̀ ọkọ ẹ láìdáa, máa bọ̀wọ̀ fún un, kó o sì kọ́ àwọn ọmọ ẹ pé káwọn náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, wàá jẹ́ kó rọrùn fáwọn ọmọ ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Ka Jémíìsì 3:18.) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jozsef tó ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní Romania. Nígbà tó ń dàgbà, bàbá ẹ̀ jẹ́ kó nira gan-an fún òun, ìyá ẹ̀, ẹ̀gbọ́n ẹ̀ àtàwọn àbúrò ẹ̀ láti sin Jèhófà. Jozsef sọ pé: “Ìyá mi ṣiṣẹ́ kára gan-an kí àlàáfíà lè wà nínú ilé wa. Bí bàbá mi ṣe ń burú sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìyá mi túbọ̀ ń finúure hàn sí i. Tí ìyá mi bá ti rí i pé a ò bọ̀wọ̀ fún bàbá wa, tá ò sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu, ó máa ń ka Éfésù 6:1-3 fún wa, àá sì jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà dáadáa tí bàbá wa ní àti ìdí tó fi yẹ ká mọyì ẹ̀. Ohun tí ìyá wa máa ń ṣe yìí ló jẹ́ kí àlàáfíà wà nínú ilé wa.”

MÁA FI ÌṢE RẸ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ LẸ́KỌ̀Ọ́

12.2 Tímótì 1:5 ṣe sọ, báwo ni àpẹẹrẹ Yùníìsì ṣe ran Tímótì lọ́wọ́?

12 Ka 2 Tímótì 1:5. Yùníìsì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún Tímótì. Á ti kọ́ Tímótì pé tèèyàn bá ní ìgbàgbọ́, ìwà ẹ̀ gbọ́dọ̀ fi hàn bẹ́ẹ̀. (Jém. 2:26) Ó dájú pé Tímótì á ti rí i nínú ìwà ìyá ẹ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ó sì tún rí i pé inú ìyá òun ń dùn bó ṣe ń sin Jèhófà. Báwo ni àpẹẹrẹ Yùníìsì ṣe ran Tímótì lọ́wọ́? Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, Tímótì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bíi ti ìyá ẹ̀. Tímótì ò ṣàdédé ní ìgbàgbọ́ tó ní yìí. Ó ti rí àpẹẹrẹ ìyá ẹ̀, ó sì fara wé e. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ ìyá lónìí ti ran àwọn ìdílé wọn lọ́wọ́ “láìsọ ohunkóhun.” (1 Pét. 3:1, 2) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

13. Kí nìdí tó fi yẹ kí ìyá kan fi àjọṣe òun àti Jèhófà sípò àkọ́kọ́?

13 Fi àjọṣe ìwọ àti Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́. (Diu. 6:5, 6) Bíi ti ọ̀pọ̀ ìyá, ìwọ náà ti gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe. O ti lo àkókò ẹ, owó àtàwọn nǹkan míì láti fi tọ́jú àwọn ọmọ ẹ. Ìgbà míì sì rèé, o ò kì í sùn kó o lè bójú tó wọn. Àmọ́ má jẹ́ kí ọwọ́ ẹ dí jù débi pé o ò ní ráyè ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. Máa ya àkókò sọ́tọ̀ tí wàá fi máa dá gbàdúrà àtèyí tí wàá fi máa dá kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa lọ sípàdé déédéé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe ìwọ àti Jèhófà á túbọ̀ lágbára, wàá sì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún ìdílé ẹ àtàwọn ẹlòmíì.

14-15. Kí lo rí kọ́ lára Leanne, Maria àti João?

14 Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́ kan yẹ̀ wò. Wọ́n kíyè sí àpẹẹrẹ ìyá wọn, ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Ọmọ Christine tó ń jẹ́ Leanne sọ pé: “A kì í lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí bàbá wa bá wà nílé. Àmọ́ ìyá wa máa ń lọ sípàdé déédéé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nínú Bíbélì, àpẹẹrẹ rere tí ìyá wa fi lélẹ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé la ti mọ̀ pé òótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni.”

15 Ọ̀dọ́ míì ni Maria. Nígbà míì, bàbá ẹ̀ máa ń fìyà jẹ wọ́n tí wọ́n bá lọ sípàdé. Ó sọ pé: “Nínú gbogbo àwọn arábìnrin tí mo mọ̀, ìyá mi ló nígboyà jù lọ. Nígbà tí mo wà ní kékeré, ìgbà míì wà tí mi ò kì í fẹ́ ṣe àwọn nǹkan kan torí mo máa ń bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa sọ. Àmọ́ nígbà tí mo rí ìgboyà tí ìyá mi ní àti bó ṣe fi Jèhófà sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé ẹ̀, ìyẹn ràn mí lọ́wọ́, mi ò sì bẹ̀rù èèyàn mọ́.” Ẹlòmíì ni João. Bàbá ẹ̀ sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ Bíbélì nínú ilé wọn, ó sọ pé: “Ohun tó jẹ́ kí n pinnu pé màá sin Jèhófà ni pé kò sóhun tí bàbá mi fẹ́ láyé yìí tí ìyá mi ò ní ṣe, àmọ́ tó bá kan pé kó jáwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà, kò ní gbà láéláé.”

16. Báwo ni àpẹẹrẹ ìyá kan ṣe lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?

16 Ẹ̀yin ìyá, ẹ máa rántí pé àpẹẹrẹ tẹ́ ẹ bá fi lélẹ̀ lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Lọ́nà wo? Ẹ wo bí àpẹẹrẹ Yùníìsì ṣe ran àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Ó sọ pé ìgbàgbọ́ Tímótì kò ní ẹ̀tàn torí ‘ìyá rẹ̀ Yùníìsì ló kọ́kọ́ ní’ irú ìgbàgbọ́ náà. (2 Tím. 1:5) Ìgbà wo ni Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kíyè sí ìgbàgbọ́ tí Yùníìsì ní? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó rìnrìn àjò àkọ́kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì ló rí Lọ́ìsì àti Yùníìsì ní Lísírà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló wàásù fún wọn tí wọ́n fi di Kristẹni. (Ìṣe 14:4-18) Rò ó wò ná, nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù ṣì rántí ìgbàgbọ́ Yùníìsì, ó sì gbà wá níyànjú pé ká máa fara wé e! Ó dájú pé ohun tí Yùníìsì ṣe wú Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni míì lórí gan-an. Tó o bá ń dá tọ́mọ tàbí tí ọkọ ẹ kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mọ̀ dájú pé àpẹẹrẹ rere tó o fi lélẹ̀ ń fún àwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà lókun.

Ó máa ń gba àkókò láti tọ́ àwọn ọmọ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ! (Wo ìpínrọ̀ 17)

17. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá rí i pé ọmọ ẹ ò fẹ́ sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ti kọ́ ọ?

17 Tó o bá rí i pé ọmọ ẹ ò fẹ́ sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ti kọ́ ọ, kí ló yẹ kó o ṣe? Rántí pé ó máa ń gba àkókò láti tọ́ ọmọ kan yanjú. Bá a ṣe rí i nínú àwòrán yẹn, tó o bá gbin èso kan, o lè máa rò ó pé ṣé èso náà máa dàgbà di igi táá máa so èso? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o ò lè mọ̀ bóyá igi náà máa so èso, wàá máa bomi rin ín déédéé kó lè dàgbà dáadáa. (Máàkù 4:26-29) Lọ́nà kan náà, ìyá kan lè máa rò pé bóyá lòun ń ṣe gbogbo ohun tóun lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ òun kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. O ò lè pinnu ohun táwọn ọmọ ẹ máa ṣe. Àmọ́ tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti kọ́ wọn nípa Jèhófà, ìyẹn máa fún wọn láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.​—Òwe 22:6.

JẸ́ KÍ JÈHÓFÀ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

18. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ran àwọn ọmọ ẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọ̀rẹ́ ẹ̀?

18 Àtìgbà tí wọ́n ti kọ Bíbélì ni Jèhófà ti ń ran àìmọye ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Sm. 22:9, 10) Jèhófà máa ran àwọn ọmọ ẹ náà lọ́wọ́ láti di ọ̀rẹ́ ẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 3:6, 7) Kódà, tí àwọn ọmọ ẹ ò bá fi gbogbo ọkàn wọn sin Jèhófà mọ́, á ṣì máa fìfẹ́ hàn sí wọn. (Sm. 11:4) Tí Jèhófà bá rí i pé ó wù wọ́n láti fi ‘òótọ́ ọkàn’ sin òun, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìṣe 13:48; 2 Kíró. 16:9) Jèhófà máa jẹ́ kó o sọ ohun tó yẹ fún àwọn ọmọ ẹ ní àkókò tó yẹ kó o sọ ọ́. (Òwe 15:23) Jèhófà tún lè lo arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ wọn nínú ìjọ láti máa tọ́ wọn sọ́nà. Kódà lẹ́yìn táwọn ọmọ ẹ bá ti dàgbà, Jèhófà lè jẹ́ kí wọ́n rántí àwọn nǹkan tó o ti kọ́ wọn. (Jòh. 14:26) Tó o bá ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ àti àpẹẹrẹ ẹ kọ́ àwọn ọmọ ẹ, Jèhófà máa jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí.

19. Kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé wàá rí ojú rere Jèhófà?

19 Ìpinnu táwọn ọmọ ẹ bá ṣe kọ́ ló máa sọ bóyá Jèhófà máa nífẹ̀ẹ́ ẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ torí pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Tó o bá jẹ́ ìyá tó ń dá tọ́mọ, Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jẹ́ Bàbá àwọn ọmọ ẹ àti Ẹni táá máa dáàbò bò ọ́. (Sm. 68:5) Àwọn ọmọ ẹ ló máa pinnu bóyá àwọn máa sin Jèhófà tàbí àwọn ò ní sìn ín. Àmọ́ tó o bá jẹ́ kí Jèhófà ràn ẹ́ lọ́wọ́, tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, wàá rí ojú rere ẹ̀.

ORIN 134 Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀kọ́ táwọn ìyá tó jẹ́ Kristẹni lè kọ́ lára Yùníìsì ìyá Tímótì àti bí wọ́n ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 4 A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ ìpínrọ̀ 9 Bí àpẹẹrẹ, wo ẹ̀kọ́ 50 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! àti àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Àbá Tó Lè Wúlò fún Yín Nígbà Ìjọsìn Ìdílé àti Ìdákẹ́kọ̀ọ́,” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2011, ojú ìwé 6-7.