Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 18

Bó O Ṣe Lè Ní Àfojúsùn Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run Kí Ọwọ́ Ẹ sì Tẹ̀ Ẹ́

Bó O Ṣe Lè Ní Àfojúsùn Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run Kí Ọwọ́ Ẹ sì Tẹ̀ Ẹ́

“Máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí; jẹ́ kó gbà ọ́ lọ́kàn, kí gbogbo èèyàn lè rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú.”​—1 TÍM. 4:15.

ORIN 84 Wá Wọn Lọ

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Àwọn àfojúsùn wo la lè ní nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

 ÀWA Kristẹni tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ó sì máa ń wù wá pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Àmọ́ tá a bá fẹ́ lo àwọn ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa dáadáa, ó yẹ ká láwọn àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa hùwà tó yẹ Kristẹni, ká kọ́ṣẹ́ tá a lè lò nínú ètò Ọlọ́run, ká sì wo bá a ṣe lè túbọ̀ yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ará lọ́wọ́. *

2. Kí nìdí tó fi yẹ ká láwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ká sì ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ wọ́n?

2 Kí nìdí tó fi yẹ kó wù wá pé ká tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà? Ìdí ni pé a fẹ́ múnú Jèhófà Bàbá wa ọ̀run dùn. Inú Jèhófà máa ń dùn tó bá ń rí i pé à ń lo àwọn ẹ̀bùn wa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ìdí míì ni pé a fẹ́ túbọ̀ yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́. (1 Tẹs. 4:9, 10) Bó ti wù ká pẹ́ tó nínú ètò Ọlọ́run, gbogbo wa ló yẹ ká máa tẹ̀ síwájú. Ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè ṣe é.

3. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nínú 1 Tímótì 4:12-16?

3 Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí Tímótì, Tímótì ti di alàgbà nígbà yẹn. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbà á níyànjú pé kó ṣì máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Ka 1 Tímótì 4:12-16.) Bó o ṣe ń ka ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba Tímótì, wàá rí i pé nǹkan méjì ló fẹ́ kó ṣe. Àkọ́kọ́, ó fẹ́ kó túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, kó ní ìgbàgbọ́, kó sì ní ìwà mímọ́. Ìkejì, ó fẹ́ kó tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ, kó túbọ̀ máa gbani níyànjú, kó sì máa kọ́ni lọ́nà tó já fáfá. Bá a ṣe ń gbé àpẹẹrẹ Tímótì yẹ̀ wò, a máa rí i pé tá a bá láwọn àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run, a máa tẹ̀ síwájú. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tá a lè ṣe ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

4.Fílípì 2:19-22 ṣe sọ, kí ló mú kí Tímótì wúlò fún Jèhófà?

4 Kí ló jẹ́ kí Tímótì wúlò fún Jèhófà? Ohun tó jẹ́ kó wúlò ni pé ó máa ń hùwà tó yẹ Kristẹni gan-an. (Ka Fílípì 2:19-22.) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Tímótì jẹ́ ká mọ̀ pé Tímótì nírẹ̀lẹ̀, olóòótọ́ ni, ó máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó sì ṣe é fọkàn tán. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, ó sì máa ń bójú tó wọn gan-an. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi nífẹ̀ẹ́ Tímótì, tó sì gbé àwọn iṣẹ́ tí ò rọrùn láti bójú tó nínú ìjọ fún un. (1 Kọ́r. 4:17) Lọ́nà kan náà, táwa náà bá ń hùwà tínú Jèhófà dùn sí, ó máa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, àá sì wúlò gan-an nínú ìjọ.​—Sm. 25:9; 138:6.

Mọ ìwà Kristẹni tó yẹ kó o túbọ̀ máa hù (Wo ìpínrọ̀ 5-6)

5. (a) Kí lo lè ṣe táá mú kí ìwà Kristẹni kan tó o ní túbọ̀ dáa sí i? (b) Bá a ṣe rí i nínú àwòrán yẹn, báwo ni arábìnrin ọ̀dọ́ yẹn ṣe fi hàn pé òun ń ṣiṣẹ́ kára láti gba tàwọn èèyàn rò?

5 Ní ohun kan lọ́kàn tó o fẹ́ ṣe. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o mọ àwọn ìwà tó yẹ kó o ṣàtúnṣe ẹ̀. Lẹ́yìn náà, mú ìwà kan tó o máa ṣiṣẹ́ lé. Bí àpẹẹrẹ, o lè pinnu pé wàá túbọ̀ máa gba tàwọn ará rò tàbí kó o pinnu pé gbogbo ohun tó bá gbà lo máa ṣe kó o lè ran àwọn ará lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, o lè pinnu pé wàá túbọ̀ jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín ìwọ àtàwọn ará, wàá sì túbọ̀ máa dárí jì wọ́n. O lè ní kí ọ̀rẹ́ ẹ kan sọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe táá jẹ́ kí ìwà ẹ dáa sí i.​—Òwe 27:6.

6. Báwo lo ṣe lè ṣiṣẹ́ kára kó o lè ṣàtúnṣe ìwà kan tó kù díẹ̀ káàtó?

6 Ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ nǹkan náà. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Ohun kan tó o lè ṣe ni pé kó o ṣèwádìí nípa ìwà ẹ tó o fẹ́ mú kó dáa sí i. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ó wù ẹ́ kó o túbọ̀ máa dárí ji àwọn èèyàn, o lè kọ́kọ́ kà nípa àwọn tó dárí ji àwọn èèyàn nínú Bíbélì àtàwọn tí ò ṣe bẹ́ẹ̀, kó o sì ronú lórí ohun tó o kà. Wo àpẹẹrẹ Jésù. Ó máa ń dárí ji àwọn èèyàn fàlàlà. (Lúùkù 7:47, 48) Yàtọ̀ síyẹn, kì í wo àṣìṣe wọn, ibi tí wọ́n dáa sí ló máa ń wò. Àmọ́ àwọn Farisí ò dà bíi Jésù torí wọ́n máa ń “ka àwọn míì sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan.” (Lúùkù 18:9) Lẹ́yìn tó o bá ti ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ yẹn, bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo máa ń kíyè sí lára àwọn èèyàn? Ṣé ìwà wọn tó dáa ni mo máa ń wò àbí ìwà wọn tó kù díẹ̀ káàtó?’ Tí kò bá rọrùn fún ẹ láti dárí ji ẹnì kan, kọ àwọn ìwà tó dáa tẹ́ni náà ní sílẹ̀. Lẹ́yìn náà bi ara ẹ pé: ‘Ojú wo ni Jésù fi ń wo ẹni yìí? Ṣé Jésù máa dárí jì í?’ Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti dárí ji ẹni náà. Ó lè kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá. Àmọ́ tá a bá ń sapá tá ò sì jẹ́ kó sú wa, tó bá yá, á rọrùn fún wa láti máa dárí ji àwọn èèyàn.

KỌ́ IṢẸ́ TÓ O LÈ LÒ

Yọ̀ǹda ara ẹ láti kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣàtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba (Wo ìpínrọ̀ 7) *

7.Òwe 22:29 ṣe sọ, báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú ètò rẹ̀ lónìí?

7 Ohun míì tó o lè fi ṣe àfojúsùn ẹ ni pé kó o kọ́ iṣẹ́ tó o lè lò nínú ètò Ọlọ́run. O lè ronú nípa iye àwọn òṣìṣẹ́ tá a fẹ́ kó yọ̀ǹda ara wọn láti bá wa kọ́ àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì wa, àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ yìí ló di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ torí pé wọ́n bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó mọṣẹ́ gan-an ṣiṣẹ́. Bá a ṣe rí i nínú àwòrán yẹn, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yẹn ń fojú síṣẹ́ kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa tún àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ṣe. Ọ̀nà yìí àtàwọn ọ̀nà míì ni Jèhófà “Ọba ayérayé” àti Jésù Kristi “Ọba àwọn ọba” ń gbà gbé àwọn ohun ńlá ṣe nípasẹ̀ àwọn tó kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́. (1 Tím. 1:17; 6:15; ka Òwe 22:29.) A fẹ́ ṣiṣẹ́ kára, ká sì lo àwọn ohun tá a mọ̀ ọ́n ṣe láti fi yin Jèhófà lógo, kì í ṣe láti fi gbé ara wa lárugẹ.​—Jòh. 8:54.

8. Báwo lo ṣe lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé?

8 Ní ohun kan lọ́kàn tó o fẹ́ ṣe. Kí ló yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé? Béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ ẹ tàbí alábòójútó àyíká yín pé àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá sọ pé kó o ṣiṣẹ́ lórí bó o ṣe ń sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń kọ́ni, o lè sọ pé kí wọ́n jẹ́ kó o mọ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n fẹ́ kó o ṣiṣẹ́ lé. Lẹ́yìn náà, ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n bá ẹ sọ. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

9. Báwo lo ṣe lè ṣiṣẹ́ kára kó o lè túbọ̀ mọ bí wọ́n ṣe ń kọ́ni?

9 Ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ nǹkan náà. Ká sọ pé o fẹ́ jẹ́ kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni dáa sí i. Fara balẹ̀ ka ìwé Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni. Tí wọ́n bá fún ẹ níṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀, o lè ṣiṣẹ́ náà fún arákùnrin kan tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ ṣáájú ọjọ́ yẹn, kó o sì ní kó fún ẹ nímọ̀ràn tó máa jẹ́ kó o sunwọ̀n sí i. Máa múra iṣẹ́ ẹ sílẹ̀ dáadáa káwọn ará lè gbádùn ẹ̀, kí wọ́n sì rí i pé o ṣe é gbára lé.​—Òwe 21:5; 2 Kọ́r. 8:22.

10. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè mú kí ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni túbọ̀ dáa sí i.

10 Ká sọ pé nǹkan tó o fẹ́ ṣiṣẹ́ lé ò rọrùn fún ẹ ńkọ́? Má jẹ́ kó sú ẹ! Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Garry ò lè kàwé dáadáa. Ó sọ pé àwọn ìgbà kan wà tí ojú máa ń ti òun tóun bá ti fẹ́ kàwé fún ìjọ. Àmọ́ kò jẹ́ kó sú òun. Ó sọ pé torí wọ́n ti dá òun lẹ́kọ̀ọ́, òun ti ń sọ àsọyé nípàdé, láwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè!

11. Bíi ti Tímótì, kí ló máa jẹ́ ká ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

11 Ṣé Tímótì di sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́ tàbí olùkọ́ tó ta yọ? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́ Tímótì ń tẹ̀ síwájú, ó sì fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún un torí ó tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù. (2 Tím. 3:10) Táwa náà bá ṣe bíi ti Tímótì, tá a mú ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ni dáa sí i, ìyẹn á jẹ́ ká kúnjú ìwọ̀n láti gba àwọn iṣẹ́ míì nínú ètò Ọlọ́run.

MÁA YỌ̀ǸDA ARA Ẹ LÁTI RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́

12. Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà táwọn ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́?

12 Gbogbo wa la máa ń jàǹfààní táwọn ẹlòmíì bá ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá wà nílé ìwòsàn, inú wa máa ń dùn táwọn alàgbà tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tàbí Àwùjọ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò bá wá kí wa. Tá a bá dojú kọ ìṣòro kan nígbèésí ayé wa, inú wa máa dùn tí alàgbà kan bá tẹ́tí sí wa, tó sì tù wá nínú. Tá a bá fẹ́ kẹ́nì kan ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́, inú wa máa dùn tí aṣáájú-ọ̀nà kan bá tẹ̀ lé wa lọ tó sì fún wa nímọ̀ràn tó máa ran ẹni náà lọ́wọ́. Inú gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí máa ń dùn láti ràn wá lọ́wọ́, ó sì yẹ káwa náà yọ̀ǹda ara wa láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kínú tiwọn náà lè dùn. Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Tíwọ náà bá fẹ́ máa ran àwọn ará lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà yìí tàbí láwọn ọ̀nà míì, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

13. Tó o bá ní ohun kan lọ́kàn tó o fẹ́ ṣe, kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn?

13 Má kàn sọ pé o fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i, ní ohun kan pàtó lọ́kàn tó o fẹ́ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé, ‘Mo fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ.’ Àmọ́, ó lè ṣòro fún ẹ láti mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an, o sì lè má mọ̀ tọ́wọ́ ẹ bá ti tẹ ohun tó ò ń wá. Torí náà, mọ nǹkan pàtó tó o fẹ́ ṣe. Kódà, o lè kọ ohun tó o fẹ́ ṣe sílẹ̀ àti bó o ṣe máa ṣe é.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ju àfojúsùn kan ṣoṣo lọ?

14 Tá a bá fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, ó yẹ ká ní ju àfojúsùn kan ṣoṣo lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé nǹkan lè má rí bá a ṣe rò. Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ sílẹ̀ nílùú Tẹsalóníkà. Ó dájú pé ó ni lọ́kàn láti dúró síbẹ̀ kó sì máa ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni lọ́wọ́. Àmọ́ àwọn alátakò lé Pọ́ọ̀lù kúrò nílùú náà. (Ìṣe 17:1-5, 10) Ká sọ pé Pọ́ọ̀lù ò kúrò níbẹ̀ ni, á fi ẹ̀mí àwọn ará wewu. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù ṣì ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe nípò tó bá ara ẹ̀. Nígbà tó yá, ó ní kí Tímótì lọ sí Tẹsalóníkà kó lè ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni lọ́wọ́. (1 Tẹs. 3:1-3) Ó dájú pé inú àwọn ará Tẹsalóníkà dùn gan-an pé Tímótì yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá ti ní kó lọ sìn.

15. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa ṣe lè yí iṣẹ́ ìsìn tá a fẹ́ ṣe pa dà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

15 Àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù nílùú Tẹsalóníkà. A lè ní iṣẹ́ ìsìn kan lọ́kàn tá a fẹ́ ṣe, àmọ́ nígbà tí ipò wa yí pa dà, ọwọ́ wa ò lè tẹ̀ ẹ́. (Oníw. 9:11) Tó bá jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ nìyẹn, ńṣe ni kó o wá iṣẹ́ ìsìn míì tó o lè ṣe. Ohun tí tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Ted àti Hiedi ṣe nìyẹn. Nígbà tí ọ̀kan lára wọn ṣàìsàn, wọ́n kúrò ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n wá iṣẹ́ ìsìn míì tí wọ́n lè ṣe. Ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe ni pé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run sọ wọ́n di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, wọ́n sì dá Ted lẹ́kọ̀ọ́ kó lè di adelé alábòójútó àyíká. Lẹ́yìn náà, ètò Ọlọ́run sọ pé tí ọjọ́ orí àwọn alábòójútó àyíká bá ti pé iye ọdún kan, wọn ò ní lè máa bá iṣẹ́ náà lọ mọ́. Torí náà, Ted àti Hiedi rí i pé àwọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ ìsìn náà mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dùn wọ́n, wọ́n mọ̀ pé àwọn lè sin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míì. Ted sọ pé, “Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa ti jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe apá iṣẹ́ ìsìn kan ṣoṣo la ti lè sin Jèhófà.”

16. Kí la rí kọ́ nínú Gálátíà 6:4?

16 A ò lè pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Torí náà, kò yẹ ká fi iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe díwọ̀n bá a ṣe wúlò fún Jèhófà tó tàbí ká máa fi wé iṣẹ́ ìsìn táwọn ẹlòmíì ń ṣe. Hiedi sọ pé: “O ò ní láyọ̀ mọ́ tó o bá ń fi ara ẹ wé ẹlòmíì.” (Ka Gálátíà 6:4.) Torí náà, ó yẹ ká wo àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ká sì máa sin Jèhófà nìṣó. *

17. Kí lo lè ṣe kó o lè kúnjú ìwọ̀n láti gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan?

17 Tó o bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn, tó ò sì tọrùn bọ gbèsè, á rọrùn fún ẹ láti gba àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run. Ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ ẹ lè tètè tẹ̀, ìyẹn sì máa jẹ́ kó o mọ bí ọwọ́ ẹ ṣe máa tẹ àwọn àfojúsùn tó máa gba àkókò díẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá wù ẹ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, o lè kọ́kọ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún àwọn oṣù kan. Tó bá wù ẹ́ láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, máa lo àkókò tó pọ̀ sí i lóde ẹ̀rí, kó o sì máa lọ wo àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ń ṣàìsàn níjọ yín. Àwọn nǹkan tó ò ń ṣe yìí máa jẹ́ kó o lè gba iṣẹ́ ìsìn tó pọ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, pinnu pé wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún ẹ.​—Róòmù 12:11.

Nǹkan tó o mọ̀ pé ọwọ́ ẹ lè tẹ̀ ni kó o fi ṣe àfojúsùn ẹ (Wo ìpínrọ̀ 18) *

18. Kí lo rí kọ́ lára Arábìnrin Beverley? (Tún wo àwòrán yẹn.)

18 Kò sẹ́ni tó dàgbà jù láti ní àwọn ohun kan lọ́kàn tó fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arábìnrin Beverley tó jẹ́ ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75). Àìsàn tó ń ṣe é máa ń jẹ́ kó nira fún un láti rìn. Àmọ́, ó wù ú pé kóun náà pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Torí náà, ó fi ṣe àfojúsùn ẹ̀. Nígbà tí ọwọ́ Beverley tẹ àfojúsùn náà, inú ẹ̀ dùn gan-an. Nígbà táwọn míì rí ohun tó ṣe, àwọn náà ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Jèhófà mọyì gbogbo nǹkan táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ti dàgbà ń ṣe, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́ mọ́.​—Sm. 71:17, 18.

19. Àwọn nǹkan wo la lè fi ṣe àfojúsùn wa nínú ìjọsìn Ọlọ́run?

19 Àwọn nǹkan tó o mọ̀ pé ọwọ́ ẹ lè tẹ̀ ni kó o fi ṣe àfojúsùn ẹ. Máa hùwà tó máa jẹ́ kínú Jèhófà dùn sí ẹ. Kọ́ iṣẹ́ tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ wúlò fún Ọlọ́run àti ètò rẹ̀. Túbọ̀ máa yọ̀ǹda ara ẹ láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ lọ́wọ́. * Torí náà bíi ti Tímótì, Jèhófà máa bù kún ẹ, “gbogbo èèyàn [sì máa] rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú.”​—1 Tím. 4:15.

ORIN 38 Yóò Sọ Ọ́ Di Alágbára

^ ìpínrọ̀ 5 Kò sí àní-àní pé Tímótì mọ bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere dáadáa. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣì gbà á níyànjú pé kó máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Tí Tímótì bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gbà á, á túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àtàwọn ará. Bíi ti Tímótì, ṣé ó wu ìwọ náà pé kó o túbọ̀ sin Jèhófà kó o sì yọ̀ǹda ara ẹ láti ran àwọn ará lọ́wọ́? Ó dájú pé ó wù ẹ́. Torí náà, àwọn nǹkan wo lo lè fi ṣe àfojúsùn ẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run? Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn náà?

^ ìpínrọ̀ 1 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Àfojúsùn ni àwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, tá a sì ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ẹ́. Ìyẹn lá jẹ́ ká ṣe púpọ̀ sí i, ká sì múnú Jèhófà dùn.

^ ìpínrọ̀ 16 Wo ìsọ̀rí náà, “Lílọ Síbi Tí Wọ́n Ti Nílò Oníwàásù Púpọ̀ Sí I” nínú ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 10, ìpínrọ̀ 6-9.

^ ìpínrọ̀ 63 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń kọ́ àwọn arábìnrin méjì bí wọ́n á ṣe máa tún àwọn ilé ètò Ọlọ́run ṣe, wọ́n sì ń lo ohun tí wọ́n kọ́ dáadáa.

^ ìpínrọ̀ 65 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan tí ò lè jáde nílé mọ́ ń fi fóònù pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.