Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 24

Kò Sẹ́ni Tó Lè Dárí Jini Bíi Ti Jèhófà

Kò Sẹ́ni Tó Lè Dárí Jini Bíi Ti Jèhófà

“Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini; ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè ọ́ pọ̀ gidigidi.”​SM. 86:5.

ORIN 42 Àdúrà Ìránṣẹ́ Ọlọ́run

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Òótọ́ ọ̀rọ̀ wo ni Ọba Sólómọ́nì sọ nínú Oníwàásù 7:20?

 ỌBA Sólómọ́nì sọ pé: “Kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníw. 7:20) Òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí! Gbogbo wa la máa ń dẹ́ṣẹ̀. (1 Jòh. 1:8) Torí náà, a máa ń fẹ́ kí Ọlọ́run àtàwọn èèyàn dárí jì wá.

2. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ọ̀rẹ́ wa kan bá dárí jì wá?

2 Ṣé o rántí ìgbà kan tó o ṣẹ ọ̀rẹ́ ẹ kan? Àmọ́, o fẹ́ kẹ́ ẹ jọ yanjú ọ̀rọ̀ náà kẹ́ ẹ lè pa dà máa ṣọ̀rẹ́, torí náà o bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí jì ẹ́. Báwo ló ṣe rí lára ẹ nígbà tó dárí jì ẹ́? Ó dájú pé ara tù ẹ́, inú ẹ sì dùn!

3. Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 A fẹ́ kí Jèhófà jẹ́ ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Àmọ́ nígbà míì, a máa ń sọ ohun tó dun Jèhófà, a sì máa ń ṣe ohun tí kò fẹ́. Torí náà, báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wá? Ìyàtọ̀ wo ló wà nínú bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá àti bí àwa èèyàn ṣe ń dárí ji ara wa? Àwọn wo ni Jèhófà sì máa ń dárí jì?

JÈHÓFÀ ṢE TÁN LÁTI DÁRÍ JÌ WÁ

4. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wá?

4 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wá. Nígbà tí Jèhófà ń sọ ẹni tí òun jẹ́ fún Mósè ní Òkè Sínáì, ó gbẹnu áńgẹ́lì kan sọ pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini.” (Ẹ́kís. 34:6, 7) Ọlọ́run aláàánú àti onínúure ni Jèhófà, ó sì ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà.​—Neh. 9:17; Sm. 86:15.

Jèhófà mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa wa àti gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wa (Wo ìpínrọ̀ 5)

5. Kí ni Sáàmù 103:13, 14 sọ pé Jèhófà mọ̀ nípa àwa èèyàn, kí nìyẹn sì mú kó ṣe?

5 Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, kò sóhun tí ò mọ̀ nípa wa. Ó yà wá lẹ́nu nígbà tá a mọ̀ pé Jèhófà mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa gbogbo èèyàn tó wà láyé. (Sm. 139:15-17) Torí náà, Jèhófà mọ gbogbo àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Kódà, Jèhófà mọ àwọn nǹkan tó ń mú ká ṣe àwọn ohun tá à ń ṣe. Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà mọ̀ yìí jẹ́ kó ṣe? Ó ń mú kó fàánú hàn sí wa.​—Sm. 78:39; ka Sáàmù 103:13, 14.

6. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ṣe tán láti dárí jì wá?

6 Jèhófà fi hàn pé òun ṣe tán láti dárí jì wá. Ó mọ̀ pé ìdí tá a fi ń dẹ́ṣẹ̀ tá a sì ń kú ni pé a ti jogún àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Kò sóhun tá a lè ṣe láti gba ara wa tàbí àwọn míì sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Sm. 49:7-9) Àmọ́ torí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó ṣàánú wa, ó sì ṣe ohun tó jẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Kí lohun tó ṣe? Jòhánù 3:16 sọ pé Jèhófà rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kó lè kú nítorí wa. (Mát. 20:28; Róòmù 5:19) Jésù jìyà, ó sì kú nítorí wa, kí gbogbo àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè rí ìgbàlà. (Héb. 2:9) Ẹ ò rí i pé ó máa dun Jèhófà gan-an nígbà tó rí bí Ọmọ ẹ̀ ṣe ń joró, tó sì kú ikú ọ̀daràn! Ká sòótọ́, tí kì í bá ṣe pé ó wu Jèhófà kó dárí jì wá ni, kò ní gbà kí Ọmọ ẹ̀ kú nítorí wa.

7. Àpẹẹrẹ àwọn wo ló wà nínú Bíbélì tí Jèhófà dárí jì fàlàlà?

7 Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló wà nínú Bíbélì tí Jèhófà dárí jì fàlàlà. (Éfé. 4:32) Ta lẹni tó wá sí ẹ lọ́kàn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Ọba Mánásè. Èèyàn burúkú ni Ọba Mánásè, ó sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì sí Jèhófà. Ó jọ́sìn òrìṣà, ó sì ní kí àwọn èèyàn ẹ̀ náà máa bọ̀rìṣà. Ó pa àwọn ọmọ ẹ̀, ó sì fi wọ́n rúbọ sí àwọn ọlọ́run èké. Kódà, ó kọjá àyè ẹ̀ débi pé ó gbé àwọn òrìṣà wá sínú tẹ́ńpìlì mímọ́ Jèhófà. Bíbélì sọ nípa Mánásè pé: “Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.” (2 Kíró. 33:2-7) Ṣùgbọ́n nígbà tí Mánásè ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà dárí jì í, Jèhófà sì tún jẹ́ kó pa dà di ọba. (2 Kíró. 33:12, 13) Ẹlòmíì tó ṣeé ṣe kó wá sí ẹ lọ́kàn ni Ọba Dáfídì. Ó dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì lójú Jèhófà, lára wọn ni àgbèrè àti ìpànìyàn. Àmọ́ nígbà tí Dáfídì gbà pé òun ṣàṣìṣe, tó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà dárí ji òun náà. (2 Sám. 12:9, 10, 13, 14) Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé ó máa ń wu Jèhófà láti dárí jì wá fàlàlà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí i pé bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jini yàtọ̀ pátápátá sí bí àwa èèyàn ṣe máa ń dárí ji ara wa.

JÈHÓFÀ MÁA Ń DÁRÍ JINI LỌ́NÀ TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀

8. Kí ló mú kí Jèhófà jẹ́ Adájọ́ tó dáa jù?

8 Jèhófà ni “Onídàájọ́ gbogbo ayé.” (Jẹ́n. 18:25) Adájọ́ tó dáa máa ń mọ òfin dáadáa. Bọ́rọ̀ Jèhófà ṣe rí náà nìyẹn torí yàtọ̀ sí pé òun ni Adájọ́ wa, òun tún ni Afúnnilófin wa. (Àìsá. 33:22) Kò sẹ́ni tó mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó dáa àtohun tí ò dáa bíi ti Jèhófà. Kí ni nǹkan míì tó yẹ kí adájọ́ ṣe? Ó yẹ kó ṣàyẹ̀wò gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa ẹjọ́ kan kó tó dá ẹjọ́ náà. Torí náà, Jèhófà ni Adájọ́ tó dáa jù torí gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ ló mọ̀.

9. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ pinnu bóyá kóun dárí jì wá?

9 Jèhófà yàtọ̀ sáwọn adájọ́ tó jẹ́ èèyàn torí gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa ẹjọ́ kan ló máa ń mọ̀. (Jẹ́n. 18:20, 21; Sm. 90:8) Kì í ṣe ohun táwọn èèyàn bá rí tàbí ohun tí wọ́n bá sọ ló máa fi ń dájọ́. Ó mọ ohun tó máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ ó mọ bí òun ṣe ṣẹ̀dá wa, irú ilé tá a ti wá, ibi tá a dàgbà sí, bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti ìlera wa. Jèhófà tún máa ń mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Ó mọ ìdí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi ń ṣe ohun tá à ń ṣe. Kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Jèhófà. (Héb. 4:13) Torí náà, tí Jèhófà bá dárí ji ẹnì kan, ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀.

Olódodo ni Jèhófà, ó máa ń dájọ́ lọ́nà tó tọ́, kì í sì í ṣe ojúsàájú. Kò sẹ́ni tó lè fún un ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 10)

10. Kí ló mú ká gbà pé Jèhófà máa ń dájọ́ lọ́nà tó tọ́? (Diutarónómì 32:4)

10 Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣèdájọ́ òdodo, ó sì máa ń dájọ́ lọ́nà tó tọ́. Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú rárá. Kì í ṣe bí ẹnì kan ṣe rí, bó ṣe lówó tó, bó ṣe gbajúmọ̀ tó tàbí bó ṣe mọ nǹkan ṣe tó ni Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí ji ẹni náà. (1 Sám. 16:7; Jém. 2:1-4) Ìdí sì ni pé kò sẹ́ni tó lè fúngun mọ́ Jèhófà tàbí kó fún un ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀. (2 Kíró. 19:7) Jèhófà kì í fìyà jẹ ẹnì kan torí pé inú ń bí i tàbí torí pé ọ̀rọ̀ onítọ̀hún ti sú u. Bákan náà, kì í ṣàánú ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. (Ẹ́kís. 34:7) Kò sí àní-àní pé Jèhófà ni Adájọ́ tó dáa jù lọ torí pé ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan wa àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa.​—Ka Diutarónómì 32:4.

11. Kí ló mú kí ìdáríjì Jèhófà yàtọ̀ sí tàwa èèyàn?

11 Àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù gbà pé bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá ṣàrà ọ̀tọ̀. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé láwọn ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, wọ́n lo ọ̀rọ̀ Hébérù tó jẹ́ pé “ibi tí wọ́n bá ti ń sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan nìkan ni wọ́n ti máa ń lo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Wọn kì í lò ó tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa bí ẹnì kan ṣe dárí ji ẹlòmíì.” Jèhófà nìkan ló lágbára láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà pátápátá. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tí Jèhófà bá dárí jì wá?

12-13. (a) Àǹfààní wo lẹnì kan máa rí tí Jèhófà bá dárí jì í? (b) Ṣé tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ó ṣì máa fìyà ẹ̀ jẹ wá?

12 Tá a bá gbà pé lóòótọ́ ni Jèhófà ti dárí jì wá, a máa gbádùn “àwọn àsìkò ìtura,” ọkàn wa á balẹ̀, àá sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Kò sẹ́ni tó lè dárí jì wá lọ́nà bẹ́ẹ̀ àfi “Jèhófà fúnra rẹ̀.” (Ìṣe 3:19) Tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ó máa ń jẹ́ ká pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀ bíi pé a ò tiẹ̀ ṣẹ̀ ẹ́ rárá.

13 Tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, kò ní fẹ̀sùn yẹn kàn wá mọ́ tàbí kó tún fìyà ẹ̀ jẹ wá. (Àìsá. 43:25; Jer. 31:34) “Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn,” bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà máa ń jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí òun. * (Sm. 103:12) Tá a bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá pátápátá, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un. (Sm. 130:4) Àmọ́ àwọn wo ni Jèhófà máa ń dárí jì?

ÀWỌN WO NI JÈHÓFÀ MÁA Ń DÁRÍ JÌ?

14. Kí la ti kọ́ nípa ohun tó máa ń jẹ́ kí Jèhófà dárí jini?

14 Bá a ṣe sọ, kì í ṣe bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan dá ṣe burú tó tàbí bó ṣe kéré tó ni Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí ji ẹni náà. Yàtọ̀ síyẹn, a ti rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà mọ̀ nípa wa torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ni Afúnnilófin wa, òun sì ni Onídàájọ́ wa. Torí náà, àwọn nǹkan tí Jèhófà mọ̀ yìí ló máa ń lò tó bá fẹ́ pinnu bóyá kóun dárí ji ẹnì kan tàbí kóun má dárí jì í. Àmọ́, àwọn nǹkan wo ni Jèhófà máa ń wò?

15. Kí ni Lúùkù 12:47, 48 sọ pé Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí ji ẹnì kan?

15 Jèhófà máa ń wò ó bóyá ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà mọ̀ pé ohun tóun ṣe ò dáa. Jésù jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ohun tó sọ nínú Lúùkù 12:47, 48. (Kà á.) Tí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan tí ò dáa tàbí nǹkan tó burú, tó sì mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí nǹkan náà, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ló dá yẹn. Tẹ́nì kan bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà lè má dárí jì í. (Máàkù 3:29; Jòh. 9:41) Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé nígbà míì, a máa ń ṣe ohun tá a mọ̀ pé kò dáa. Ṣé Jèhófà máa dárí jì wá tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ nǹkan míì tún wà tí Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí jì wá.

Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn (Wo ìpínrọ̀ 16-17)

16. Kí ni ìrònúpìwàdà, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ronú pìwà dà tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?

16 Nǹkan míì tí Jèhófà máa ń wò ni bóyá ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Kí ló ń fi hàn pé ẹnì kan ti ronú pìwà dà? Ìrònúpìwàdà túmọ̀ sí kéèyàn “yí èrò ẹ̀, ìwà ẹ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe pa dà.” Ara ohun tó yẹ kó ṣe ni pé kó kábàámọ̀ tàbí kó banú jẹ́ nítorí àwọn nǹkan tí ò dáa tó ti ṣe tàbí torí pé ó mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó ṣe àmọ́ tí ò ṣe é. Tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà, kì í ṣe àwọn nǹkan tí ò dáa tó ṣe nìkan ló máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá a. Ó tún máa ń banú jẹ́ torí pé kò fọwọ́ gidi mú àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn ló sì kó o síṣòro. Ẹ rántí pé Ọba Mánásè àti Ọba Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, síbẹ̀ Jèhófà dárí ji àwọn méjèèjì torí pé wọ́n ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (1 Ọba 14:8) Torí náà, Jèhófà gbọ́dọ̀ rí i pé a ti ronú pìwà dà kó tó dárí jì wá. Ká kàn kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tá a dá nìkan ò tó. A gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀. * Ìyẹn sì ni nǹkan míì tí Jèhófà máa ń wò tó bá fẹ́ dárí jì wá.

17. Kí ni ìyípadà, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká yí pa dà tá ò bá fẹ́ tún ẹ̀ṣẹ̀ kan dá? (Àìsáyà 55:7)

17 Nǹkan pàtàkì míì tí Jèhófà tún máa ń wò ni ìyípadà. Ìyípadà túmọ̀ sí kéèyàn “yí pa dà.” Lédè míì, ẹni náà gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ń hù, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí. (Ka Àìsáyà 55:7.) Ẹni náà gbọ́dọ̀ yí èrò ẹ̀ pa dà kó lè máa ronú lọ́nà tí Jèhófà ń gbà ronú. (Róòmù 12:2; Éfé. 4:23) Ó gbọ́dọ̀ pinnu pé òun ò ní máa ro èròkerò, òun ò sì ní pa dà sídìí ìwà burúkú tóun hù mọ́. (Kól. 3:7-10) Lóòótọ́, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti dárí jì wá, kó sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́, ó dìgbà tí Jèhófà bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀ yẹn mọ́ la máa tó jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà.​—1 Jòh. 1:7.

GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ PÉ Ó MÁA DÁRÍ JÌ Ẹ́

18. Kí la ti kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa ń dárí jì wá?

18 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ ṣókí nípa àwọn kókó pàtàkì tá a ti jíròrò. Kò sẹ́ni tó lè dárí jini bíi ti Jèhófà. Kí ló mú ká sọ bẹ́ẹ̀? Àkọ́kọ́, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe tán láti dárí jì wá. Ìkejì, kò sí nǹkan tí kò mọ̀ nípa wa. Ó mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa irú ẹni tá a jẹ́ àtohun tó ń mú ká ṣe nǹkan. Torí náà, òun nìkan ló lè mọ̀ bóyá ẹnì kan ti ronú pìwà dà lóòótọ́ àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìkẹta, tí Jèhófà bá ti dárí jì wá, ó máa ń gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ náà pátápátá. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa, ká sì tún ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀.

19. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè ṣe ká má dẹ́ṣẹ̀ torí pé aláìpé ni wá, kí ló máa jẹ́ ká láyọ̀?

19 Òótọ́ kan ni pé tá a bá ṣì jẹ́ aláìpé, kò sí bá ò ṣe ní máa dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó wà nínú ìwé Insight on the Scriptures lédè Gẹ̀ẹ́sì, Ìdìpọ̀ kejì, ojú ìwé 771 máa tù wá nínú. Ó sọ pé: “Aláàánú ni Jèhófà, ó sì mọ̀ pé àìpé máa ń jẹ́ káwa èèyàn ṣe nǹkan tí ò dáa nígbà míì. Torí náà, kò yẹ ká wá máa banú jẹ́ ṣáá pé à ń ṣàṣìṣe torí pé a jẹ́ aláìpé. (Sm. 103:8-14; 130:3) Tá a bá ń ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe láti máa fi ìlànà Jèhófà sílò, a máa láyọ̀. (Fílí. 4:4-6; 1 Jòh. 3:19-22).” Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an!

20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

20 Inú wa dùn pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ṣe tán láti dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Àmọ́, báwo la ṣe lè máa dárí jini bíi ti Jèhófà? Báwo ni bí àwa èèyàn ṣe ń dárí ji ara wa ṣe jọ bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá, àmọ́ ìyàtọ̀ wo ló wà níbẹ̀? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

ORIN 45 Àṣàrò Ọkàn Mi

^ Nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun ṣe tán láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Àmọ́ nígbà míì, ó lè máa ṣe wá bíi pé a ò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń dárí jì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká gbà pé tá a bá ṣẹ̀, tá a sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa dárí jì wá.

^ ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: “Ìrònúpìwàdà” túmọ̀ sí kéèyàn yí èrò ẹ̀ pa dà, kó kábàámọ̀ gidigidi nípa bó ṣe lo ìgbésí ayé ẹ̀, kó kábàámọ̀ ìwà àìtọ́ tó hù tàbí ohun tó kọ̀ láti ṣe. Ìrònúpìwàdà tó wá látọkàn máa ń fi hàn pé ẹnì kan ti yí ìwà ẹ̀ pa dà.