Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 25

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ń Dárí Jini

Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ń Dárí Jini

“Bí Jèhófà ṣe dárí jì yín ní fàlàlà, ẹ̀yin náà gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀.”​—KÓL. 3:13.

ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ni Jèhófà fi dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà lójú?

 BÓ TIẸ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, Afúnnilófin àti Onídàájọ́ wa, ó tún jẹ́ Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa. (Sm. 100:3; Àìsá. 33:22) Tá a bá ṣẹ Jèhófà, tá a sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn, kì í ṣe pé Jèhófà lè dárí jì wá nìkan ni, àmọ́ ó máa ń wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 86:5) Jèhófà fẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, torí náà ó gbẹnu wòlíì Àìsáyà sọ pé: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín.”​—Àìsá. 1:18.

2. Tá a bá fẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín àwa àtàwọn míì, kí ló yẹ ká ṣe?

2 Torí pé aláìpé ni gbogbo wa, kò sí ká má sọ tàbí ṣe nǹkan tó máa dun àwọn ẹlòmíì. (Jém. 3:2) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí àárín wa má gún. Ohun tó sì máa jẹ́ kí ìyẹn ṣeé ṣe ni pé ká máa dárí ji ara wa. (Òwe 17:9; 19:11; Mát. 18:21, 22) Tẹ́nì kan bá sọ tàbí ṣe nǹkan kékeré kan tó dùn wá, Jèhófà fẹ́ ká dárí jì í. (Kól. 3:13) Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣe tán, Jèhófà máa ń dárí jì wá “fàlàlà.”​—Àìsá. 55:7.

3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwa èèyàn aláìpé ṣe lè máa dárí ji ara wa bíi ti Jèhófà. Àmọ́, irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo ló yẹ ká fi tó àwọn alàgbà létí? Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà wá níyànjú pé ká máa dárí ji àwọn èèyàn? Kí la sì lè kọ́ lára àwọn ará wa kan tó ti jìyà gan-an torí ìwà burúkú táwọn míì hù sí wọn?

TÍ KRISTẸNI KAN BÁ DÁ Ẹ̀ṢẸ̀ ŃLÁ

4. (a) Tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, kí ló yẹ kó ṣe? (b) Kí làwọn alàgbà máa ṣe tí wọ́n bá fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀?

4 Tá a bá mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tẹ́nì kan dá, a gbọ́dọ̀ fi tó àwọn alàgbà létí. 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10 mẹ́nu ba irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀. Tí Kristẹni kan bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, ó ti tẹ òfin Ọlọ́run lójú. Torí náà, ó gbọ́dọ̀ gbàdúrà pé kí Jèhófà dárí ji òun, kó sì sọ fún àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ẹ̀. (Sm. 32:5; Jém. 5:14) Kí làwọn alàgbà máa wá ṣe? Jèhófà nìkan ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá pátápátá, ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ló sì mú kí ìyẹn ṣeé ṣe. * Síbẹ̀, Jèhófà ti yan àwọn alàgbà pé kí wọ́n máa lo Ìwé Mímọ́ láti pinnu bóyá kí wọ́n yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kúrò nínú ìjọ tàbí kí wọ́n má ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́r. 5:12) Kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú, ó yẹ kí wọ́n bi ara wọn láwọn ìbéèrè yìí: Ṣé ẹni náà mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ náà ni? Ṣé kì í ṣe pé ó ń bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀? Ṣé ó ti pẹ́ tó ti ń dá ẹ̀ṣẹ̀ náà? Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ṣé ẹ̀rí wà pé ó ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn? Ṣé ẹ̀rí wà tó fi hàn pé Jèhófà ti dárí ji ẹni náà?​—Ìṣe 3:19.

5. Àǹfààní wo là ń rí látinú iṣẹ́ táwọn alàgbà ń ṣe?

5 Tí àwọn alàgbà bá fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ìpinnu tí Jèhófà ṣe lọ́run nípa ẹni náà làwọn náà ṣe. (Mát. 18:18) Báwo làwọn ará ìjọ ṣe máa ń jàǹfààní látinú ètò yìí? Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ kí ìwà ẹ̀ má bàa ran àwọn ará yòókù. (1 Kọ́r. 5:6, 7, 11-13; Títù 3:10, 11) Ó tún máa ń jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ronú pìwà dà, kí Jèhófà lè dárí jì í. (Lúùkù 5:32) Àwọn alàgbà máa ń gbàdúrà fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà, wọ́n sì máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ẹni náà pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀.​—Jém. 5:15.

6. Ṣé Jèhófà lè dárí ji ẹni tí wọ́n yọ kúrò nínú ìjọ? Ṣàlàyé.

6 Ká sọ pé ẹnì kan ò ronú pìwà dà nígbà tí àwọn alàgbà gbọ́ ẹjọ́ ẹ̀, ṣe ni wọ́n máa yọ ẹni náà kúrò nínú ìjọ. Tó bá jẹ́ pé òfin ìjọba ló rú, àwọn alàgbà ò ní sọ pé kí ìjọba má fìyà jẹ ẹ́. Jèhófà gba àwọn alákòóso láyè láti ṣèdájọ́ kí wọ́n sì fìyà jẹ ẹnikẹ́ni tó bá rú òfin, bóyá ẹni náà ronú pìwà dà tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀. (Róòmù 13:4) Àmọ́, tí ẹni náà bá ronú pìwà dà, tó sì jáwọ́ nínú ìwà burúkú náà, Jèhófà máa dárí jì í. (Lúùkù 15:17-24) Kódà tí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹni náà dá bá burú jáì, Jèhófà ṣì máa dárí jì í.​—2 Kíró. 33:9, 12, 13; 1 Tím. 1:15.

7. Báwo la ṣe lè dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá?

7 Inú wa dùn pé àwa kọ́ ni Jèhófà ní ká máa pinnu bóyá kóun dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tàbí kóun má dárí jì í! Àmọ́ nígbà míì, nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ pé àwa la máa pinnu ohun tá a máa ṣe. Kí ni nǹkan náà? Ẹnì kan lè ṣẹ̀ wá, kódà nǹkan tó ṣe lè dùn wá gan-an, àmọ́ kó wá bẹ̀ wá pé ká dárí ji òun. Nígbà míì sì rèé, ẹni náà lè má bẹ̀ wá rárá. Síbẹ̀, kò yẹ ká di onítọ̀hún sínú, ṣe ló yẹ ká dárí jì í bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà lè dùn wá gan-an, kó sì múnú bí wa. Lóòótọ́, ó lè má rọrùn fún wa láti tètè dárí jì í, pàápàá tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣe ò dáa rárá. Ilé Ìṣọ́ September 15, 1994 sọ pé: “Tí o bá dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan, kò túmọ̀ sí pé o gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ náà. Àwa Kristẹni gbà pé tá a bá ti dárí ji ẹnì kan tọkàntọkàn, a ti fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́ nìyẹn. Òun ni Onídàájọ́ òdodo gbogbo ayé, ó sì máa mú ìdájọ́ òdodo ṣẹ ní àkókò tó tọ́.” Kí nìdí tí Jèhófà fi gbà wá níyànjú pé ká máa dárí ji ara wa, ká sì fi ìdájọ́ lé òun lọ́wọ́?

KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI GBÀ WÁ NÍYÀNJÚ PÉ KÁ MÁA DÁRÍ JI ARA WA?

8. Tá a bá ń dárí ji àwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe ń fi hàn pé a mọyì àánú Jèhófà?

8 Tá a bá ń dárí ji àwọn èèyàn, ìyẹn máa fi hàn pé a mọyì àánú Jèhófà. Nínú àkàwé kan tí Jésù ṣe, ó sọ̀rọ̀ nípa ẹrú kan tó jẹ ọ̀gá ẹ̀ ní gbèsè ńlá tí ò lè san pa dà, àmọ́ ọ̀gá náà fagi lé gbogbo gbèsè yẹn. Ṣùgbọ́n, ẹrú tí wọ́n dárí jì yẹn ò dárí ji ẹrú míì tó jẹ ẹ́ ní owó tó kéré. (Mát. 18:23-35) Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ ká kọ́? Tá a bá mọyì àánú tí Jèhófà ń fi hàn sí wa lóòótọ́, àwa náà máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. (Sm. 103:9) Ilé Ìṣọ́ kan sọ pé: “Kò sí iye ìgbà tá a dárí ji àwọn èèyàn tá a lè fi wé iye ìgbà tí Jèhófà ti dárí jì wá, tó sì fàánú hàn sí wa nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi.”

9. Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fàánú hàn sí? (Mátíù 6:14, 15)

9 Jèhófà máa dárí ji àwọn tó bá ń dárí jini. Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn tó bá ń ṣàánú àwọn ẹlòmíì. (Mát. 5:7; Jém. 2:13) Jésù jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ nígbà tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa gbàdúrà. (Ka Mátíù 6:14, 15.) Ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà náà jẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé àwọn tó bá ń fi àánú hàn, tí wọ́n sì ń dárí jini lòun máa fàánú hàn sí. Ọ̀rọ̀ burúkú táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ìyẹn Élífásì, Bílídádì àti Sófárì sọ sí i dùn ún gan-an. Àmọ́, Jèhófà sọ fún Jóòbù pé kó gbàdúrà fún wọn. Lẹ́yìn tó ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀.​—Jóòbù 42:8-10.

10. Tá a bá ń di àwọn èèyàn sínú, báwo nìyẹn ṣe máa pa wá lára? (Éfésù 4:31, 32)

10 Tá a bá ń di àwọn èèyàn sínú, ó máa pa wá lára. Tá a bá di ẹnì kan sínú, ṣe ló dà bí ìgbà tá a di ẹrù kan tó wúwo lé ara wa lórí. Jèhófà ò sì fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa. (Ka Éfésù 4:31, 32.) Ó gbà wá níyànjú pé ká “fi ìbínú sílẹ̀, kí [a] sì pa ìrunú tì.” (Sm. 37:8) Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ó máa fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni wá. Tá a bá ń di àwọn èèyàn sínú, ó lè ṣàkóbá fún ìlera wa. (Òwe 14:30) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mu omi tó ní májèlé, àwa ló máa pa lára kì í ṣe ẹlòmíì. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé tá a bá di ẹnì kan sínú, àwa ló máa pa lára kì í ṣe ẹni tó múnú bí wa. Torí náà, tá a bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, ara wa là ń ṣe láǹfààní. (Òwe 11:17) Ọkàn wa máa balẹ̀, á sì rọrùn fún wa láti máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó.

11. Kí ni Bíbélì sọ nípa kéèyàn máa gbẹ̀san? (Róòmù 12:19-21)

11 Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gbẹ̀san. Jèhófà ò gbà wá láyè láti gbẹ̀san tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá. (Ka Róòmù 12:19-21.) Torí pé aláìpé ni wá, kì í ṣe gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan la máa mọ̀, ìyẹn kì í sì í jẹ́ ká dájọ́ bó ṣe yẹ. (Héb. 4:13) Ìgbà míì sì wà tó jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára wa máa ń jẹ́ ká ṣi ẹjọ́ dá. Jèhófà mí sí Jémíìsì láti sọ pé: “Ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.” (Jém. 1:20) Torí náà, ó dájú pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà máa ṣe, ó sì máa rí i pé òun dá ẹjọ́ náà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

Má bínú, má sì di èèyàn sínú. Fi gbogbo ọ̀rọ̀ náà lé Ọlọ́run lọ́wọ́. Ó máa mú gbogbo aburú tí ẹ̀ṣẹ̀ ti fà kúrò (Wo ìpínrọ̀ 12)

12. Kí ló máa fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ṣèdájọ́ òdodo?

12 Tá a bá ń dárí ji àwọn èèyàn, ìyẹn á fi hàn pé a fọkàn tán Jèhófà pé ó máa ṣèdájọ́ òdodo. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá, àmọ́ tá a fi ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́, ìyẹn á fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa mú gbogbo ẹ̀dùn ọkàn tí ọ̀rọ̀ náà fà kúrò lọ́kàn wa. Nínú ayé tuntun, ọgbẹ́ ọkàn tí àìpé àwọn èèyàn ti fà “ò ní wá sí ìrántí, wọn ò sì ní wá sí ọkàn” wa mọ́ títí láé. (Àìsá. 65:17) Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ohun tẹ́nì kan ṣe dùn wá gan-an, ṣé a máa lè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ká má sì di onítọ̀hún sínú? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran àwọn kan lọ́wọ́ tí wọn ò fi di àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n sínú.

ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ Ń DÁRÍ JI ÀWỌN ÈÈYÀN

13-14. Kí lo kọ́ nínú bí Tony ṣe dárí ji José?

13 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló ti pinnu pé àwọn máa dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ṣe sí wọn dùn wọ́n gan-an. Àǹfààní wo ni wọ́n rí torí pé wọ́n dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n?

14 Ọ̀pọ̀ ọdún kí Tony * tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Philippines tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó gbọ́ pé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ José ló pa ẹ̀gbọ́n òun. Nígbà yẹn, Tony máa ń bínú gan-an, oníjàgídíjàgan sì ni, torí náà ó pinnu pé òun máa gbẹ̀san. Àmọ́, àwọn ọlọ́pàá mú José, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n torí ohun tó ṣe. Lẹ́yìn tí wọ́n dá José sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, Tony pinnu pé òun máa pa á. Torí náà, ó lọ ra ìbọn tó máa fi pa José. Àmọ́, ìgbà yẹn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Tony lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí i pé ó yẹ kí n ṣe àwọn ìyípadà kan títí kan bí mo ṣe máa ń bínú.” Nígbà tó yá, Tony ṣèrìbọmi, ó sì di ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára ẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé José náà ti ṣèrìbọmi, ó sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Nígbà táwọn méjèèjì ríra, wọ́n dì mọ́ra wọn, Tony sì sọ fún José pé òun ti dárí jì í. Tony sọ pé bí òun ṣe dárí ji José múnú òun dùn gan-an débi pé òun ò lè ṣàlàyé bó ṣe rí lára òun. Ẹ ò rí i pé Jèhófà bù kún Tony torí pé ó dárí ji José.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Peter àti Sue fi hàn pé a lè borí ìbínú, ká má sì di ẹnikẹ́ni sínú (Wo ìpínrọ̀ 15-16)

15-16. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Peter àti Sue?

15 Lọ́dún 1985, Peter àti Sue ìyàwó ẹ̀ wà nípàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà tí bọ́ǹbù kan bú gbàù lójijì. Ọkùnrin kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló lọ ri bọ́ǹbù náà sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Jàǹbá yẹn ṣàkóbá fún ojú Sue, kódà wọ́n ní láti ki ẹ̀rọ kan sínú etí ẹ̀ kó lè máa gbọ́rọ̀. Sue ò tún lè gbóòórùn mọ́. * Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Peter àti Sue máa ń bi ara wọn pé, ‘Irú èèyàn wo ló ṣe nǹkan tó burú tó yìí?’ Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọwọ́ ìjọba tẹ ọ̀daràn náà, wọ́n sì dájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére fún un. Nígbà tí wọ́n bi Peter àti Sue pé ṣé wọ́n ti dárí ji ọkùnrin náà, wọ́n sọ pé: “Jèhófà ti kọ́ wa pé tá a bá ń di èèyàn sínú, ó máa kó bá ìlera wa. Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí ọ̀rọ̀ yẹn ṣẹlẹ̀ la ti bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ká sì máa bá ìgbésí ayé wa lọ.”

16 Ṣé ó rọrùn fún wọn láti dárí ji ọkùnrin yẹn? Rárá. Wọ́n sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí Sue bá ti ń jẹ̀rora ni inú máa ń bí wa. Àmọ́ a kì í ronú nípa ẹ̀ títí lọ, torí náà a máa ń tètè gbé e kúrò lọ́kàn. Ká sòótọ́, tí ọ̀daràn yẹn bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú wa máa dùn sí i gan-an. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa ti jẹ́ ká rí i pé téèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, kò ní máa di àwọn èèyàn sínú, ó sì máa jẹ́ kọ́kàn èèyàn balẹ̀ ju bó ṣe rò lọ. Ohun míì tó ń tù wá nínú ni pé a mọ̀ pé láìpẹ́ Jèhófà máa mú gbogbo aburú tí jàǹbá náà ti fà kúrò.”

17. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Myra nípa ìdáríjì?

17 Ẹ̀yìn tí Myra bímọ méjì nílé ọkọ ló kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, ọkọ ẹ̀ ò kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nígbà tó yá, ọkọ ẹ̀ ṣàgbèrè, ó sì pa ìdílé ẹ̀ tì. Myra sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi fi èmi àtàwọn ọmọ wa méjèèjì sílẹ̀, ohun tó máa ń ṣe àwọn tí ọkọ wọn já jù sílẹ̀ ló ṣe mí. Jìnnìjìnnì bò mí, mi ò gbà pé òótọ́ lohun tó ṣẹlẹ̀, mo ní ọgbẹ́ ọkàn, mo kábàámọ̀, mo dá ara mi lẹ́bi, inú sì bí mi gan-an.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì ò fẹ́ra wọn mọ́, ọgbẹ́ ọkàn yẹn ò kúrò níbẹ̀. Myra tún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ oṣù ni mo fi ṣàníyàn tínú sì ń bí mi, mo wá rí i pé ó ń ṣàkóbá fún àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn èèyàn.” Àmọ́ ní báyìí, Myra sọ pé òun ò bínú mọ́, òun ò sì di ọkọ òun sínú mọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fẹ́ra mọ́. Ó gbà pé ó ṣì lè wá sin Jèhófà lọ́jọ́ kan. Myra gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Òun ló dá tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ méjèèjì, wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà. Ní báyìí, inú Myra ń dùn bó ṣe ń sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀ àtàwọn ìdílé wọn.

JÈHÓFÀ NI ONÍDÀÁJỌ́ TÓ DÁA JÙ LỌ

18. Kí ló dá wa lójú pé Jèhófà tó jẹ́ Onídàájọ́ Tó Ga Jù Lọ máa ṣe?

18 Inú wa dùn pé kì í ṣe àwa ni Jèhófà ní ká máa pinnu ìdájọ́ tẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa gbà! Jèhófà tó jẹ́ Onídàájọ́ Tó Ga Jù Lọ ló máa ṣiṣẹ́ pàtàkì yìí. (Róòmù 14:10-12) Ó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ṣèdájọ́ òdodo, ó sì máa dájọ́ lọ́nà tó tọ́. (Jẹ́n. 18:25; 1 Ọba 8:32) Òdodo ni Jèhófà máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà!

19. Kí ni Jèhófà tó jẹ́ Onídàájọ́ tó dáa jù lọ máa ṣe?

19 À ń retí ìgbà tí Jèhófà máa ṣàtúnṣe gbogbo aburú tí àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ àwa èèyàn ti fà. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àìlera àti ẹ̀dùn ọkàn ni Jèhófà máa mú kúrò. (Sm. 72:12-14; Ìfi. 21:3, 4) A ò ní rántí wọn mọ́ títí láé. Àmọ́ bá a ṣe ń dúró de ìgbà yẹn, inú wa dùn pé Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa dárí jini bíi tiẹ̀.

ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà

^ Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Torí pé Kristẹni ni wá, àwa náà fẹ́ máa dárí ji àwọn èèyàn bíi ti Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a lè dárí ẹ̀ ji àwọn èèyàn àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a gbọ́dọ̀ fi tó àwọn alàgbà létí. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká máa dárí ji àwọn èèyàn àti ìbùkún tá a máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.

^ Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, April 15, 1996.

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ Wo Jí! January 8, 1992, ojú ìwé 9-13 lédè Gẹ̀ẹ́sì. Tún wo fídíò Peter àti Sue Schulz: A Lè Borí Jàǹbá tó wà nínú JW Broadcasting®.