Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 28

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!

“Ìjọba ayé ti di Ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀.”​—ÌFI. 11:15.

ORIN 22 Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ló dá wa lójú, kí sì nìdí?

 TÓ O bá ń wo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí, ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti gbà pé nǹkan ṣì máa dáa? Àwọn tó wà nínú ìdílé kan náà ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Àwọn èèyàn túbọ̀ ń hùwà ipá, tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, wọ́n sì máa ń bínú sódì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn ò fọkàn tán àwọn aláṣẹ mọ́. Àmọ́, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí yẹ kó fi wá lọ́kàn balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn á máa ṣe ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí làwọn èèyàn ń ṣe gẹ́lẹ́. (2 Tím. 3:1-5) Kò sí olóòótọ́ èèyàn kan tó lè sọ pé ọ̀rọ̀ yìí kò rí bẹ́ẹ̀, torí bí àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ṣe ń ṣẹ jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Kristi Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Àmọ́ èyí kàn jẹ́ ọ̀kan péré lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣẹ báyìí. Ìgbàgbọ́ wa máa túbọ̀ lágbára tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó ṣẹ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.

Bí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì àti ìwé Ìfihàn ṣe tan mọ́ ara wọn, tí wọ́n sì ń ṣẹ jẹ́ ká mọ ibi táwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ dé àtàwọn tí ò tíì ṣẹ (Wo ìpínrọ̀ 2)

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, kí sì nìdí? (Ṣàlàyé àwòrán iwájú ìwé.)

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa (1) àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jẹ́ ká mọ ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, (2) àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run lọ́run àtàwọn (3) àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa pa àwọn tí ò fara mọ́ Ìjọba ẹ̀ run yán-án yán-án. A máa rí i bí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ń ṣẹ tẹ̀ lé ara wọn àti bí ìyẹn ṣe jẹ́ ká mọ ibi táwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ dé.

BÍ A ṢE MỌ ÌGBÀ TÍ ÌJỌBA NÁÀ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í ṢÀKÓSO

3. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì 7:13, 14 fi dá wa lójú nípa Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

3 Àsọtẹ́lẹ̀ inú Dáníẹ́lì 7:13, 14 fi dá wa lójú pé Kristi Jésù ni ẹni tó dáa jù láti jẹ́ Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run. Inú àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè máa dùn láti “sìn ín,” a ò sì ní fi Alákòóso míì rọ́pò rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú ìwé Dáníẹ́lì sọ pé Jésù máa gba Ìjọba lẹ́yìn tí ìgbà méje bá parí. Ṣé ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ ìgbà tí Jésù di Ọba?

4. Ṣàlàyé bí Dáníẹ́lì 4:10-17 ṣe jẹ́ ká mọ ọdún tí Kristi bẹ̀rẹ̀ sí í jọba. (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

4 Ka Dáníẹ́lì 4:10-17. “Ìgbà méje” yẹn jẹ́ 2,520 ọdún. Ìgbà méje yẹn bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 607 Ṣ.S.K., nígbà tí àwọn ará Bábílónì mú ọba tó jẹ kẹ́yìn lórí ìtẹ́ Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù kúrò. Ìgbà méje náà sì parí lọ́dún 1914 S.K., nígbà tí Jèhófà fi Jésù “ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin” jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run. *​—Ìsík. 21:25-27.

5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìgbà méje” náà ṣe máa ṣe wá láǹfààní?

5 Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe máa ṣe wá láǹfààní? Tá a bá mọ̀ nípa “ìgbà méje” yẹn, á jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa ń mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ lákòókò tó yẹ. Bó ṣe jẹ́ kí Ìjọba ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ lásìkò tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa jẹ́ kí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó kù náà ṣẹ lásìkò tó yẹ. Ó dájú pé ọjọ́ Jèhófà “kò ní pẹ́ rárá!”​—Háb. 2:3.

BÁ A ṢE MỌ̀ PÉ KRISTI TI DI ỌBA ÌJỌBA ỌLỌ́RUN

6. (a) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìfihàn 6:2-8 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ni?

6 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ láyé tó máa jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ mọ ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run. Ara ohun tó sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni ogun, ìyàn àti ìmìtìtì ilẹ̀. Ó tún sọ pé àjàkálẹ̀ àrùn tàbí àìsàn máa wà “láti ibì kan dé ibòmíì,” ọ̀kan lára ẹ̀ ni àrùn Kòrónà tó ń bá gbogbo aráyé fínra. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn wà lára ohun tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ “àmì” pé Kristi ti wà níhìn-ín. (Mát. 24:3, 7; Lúùkù 21:7, 10, 11) Lẹ́yìn ọgọ́ta (60) ọdún tí Jésù ti kú tó sì ti pa dà sọ́run, Jésù jẹ́ kí àpọ́sítélì Jòhánù rí àwọn ìran kan tó fi hàn pé àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀. (Ka Ìfihàn 6:2-8.) Gbogbo àwọn nǹkan yìí ló sì ti ń ṣẹlẹ̀ látìgbà tí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní 1914.

7. Kí nìdí tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ láyé látìgbà tí Jésù ti ń ṣàkóso?

7 Kí nìdí tí nǹkan fi burú sí í láyé nígbà tí Jésù di Ọba? Ìfihàn 6:2 sọ kókó pàtàkì kan fún wa. Ó sọ pé iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí Jésù máa ṣe tó bá di Ọba ni pé kó jagun. Àmọ́, ta ló máa bá jagun? Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ló máa bá jagun. Ìfihàn orí 12 sọ pé Sátánì fìdí rẹmi nínú ogun náà, Jésù sì ju òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù sí ayé. Inú wá ń bí Èṣù gan-an, ó ń fi ìkanra mọ́ gbogbo aráyé, ìyẹn ló sì mú kí wàhálà pọ̀ láyé.​—Ìfi. 12:7-12.

Inú wa kì í dùn tá a bá gbọ́ ìròyìn burúkú, àmọ́ bá a ṣe ń rí i táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso (Wo ìpínrọ̀ 8)

8. Àǹfààní wo là ń rí bá a ṣe ń rí i táwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìjọba náà ń ṣẹ?

8 Àǹfààní wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣe wá? Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé àti bí ìwà àwọn èèyàn ṣe ń burú sí i jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ti di Ọba. Torí náà, kò yẹ ká máa bínú táwọn èèyàn bá ń hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan, tí wọ́n sì ń hùwà ìkà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa rántí pé ìwà wọn ń fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ. Ẹ ò rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso! (Sm. 37:1) Ó sì dájú pé ṣe ni nǹkan á máa burú sí i bí Amágẹ́dọ́nì ṣe ń sún mọ́lé. (Máàkù 13:8; 2 Tím. 3:13) Ṣé kò yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa pé ó jẹ́ ká mọ ìdí táwọn nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí?

BÍ ÀWỌN Ọ̀TÁ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN ṢE MÁA PA RUN

9. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Dáníẹ́lì 2:28, 31-35 ṣe jẹ́ ká mọ ìjọba alágbára tó máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn, ìgbà wo ló sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?

9 Ka Dáníẹ́lì 2:28, 31-35. A ti rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ lónìí. Àlá tí Nebukadinésárì lá sọ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” lẹ́yìn tí Kristi bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìjọba alágbára tó máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn máa wà lára àwọn ọ̀tá Jésù, òun ló sì ṣàpẹẹrẹ ‘òkè ẹsẹ̀ àti ìka ẹsẹ̀ tó jẹ́ irin àti amọ̀.’ Ìjọba alágbára yìí ló ń ṣàkóso ayé lọ́wọ́ báyìí. Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló para pọ̀ di ìjọba náà, wọ́n sì wá ń pè é ní ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa ère inú àlá Nebukadinésárì tún sọ nǹkan méjì tó máa jẹ́ kí ìjọba yìí yàtọ̀ sí àwọn ìjọba tó ti ṣàkóso kọjá.

10. (a) Kí ni Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà tó ń ṣàkóso ayé máa jẹ́? (b) Ewu wo ló yẹ ká yẹra fún? (Wo àpótí náà “ Má Ṣe Dara Pọ̀ Mọ́ Amọ̀ Náà!”)

10 Àkọ́kọ́, bó ṣe wà nínú ìran tí Dáníẹ́lì rí, ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ò dà bí àwọn ìjọba alágbára tó ti ṣàkóso ayé kọjá, àmọ́ Bíbélì sọ pé ìjọba náà máa jẹ́ irin àti amọ̀, kì í ṣe wúrà àti fàdákà. Amọ̀ náà ṣàpẹẹrẹ “ọmọ aráyé” tàbí àwọn mẹ̀kúnnù. (Dán. 2:43, àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lónìí fi hàn pé àwọn mẹ̀kúnnù ń kó ipa tó lágbára lórí ọ̀rọ̀ ìbò, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ìwọ́de àtàwọn àjọ òṣìṣẹ́. Ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà lágbára láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.

11. Bá a ṣe rí i tí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ń ṣàkóso ayé, báwo nìyẹn ṣe jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àkókò òpin là ń gbé yìí?

11 Ìkejì, bó ṣe jẹ́ pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló ṣàpẹẹrẹ òkè ẹsẹ̀ àti ìka ẹsẹ̀ ère ńlá yẹn, òun ni Bíbélì sọ pé ó máa jẹ́ ìjọba alágbára tó máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn. Kò ní sí ìjọba èèyàn kankan tó máa dìde lẹ́yìn ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Ìjọba Ọlọ́run máa pa á run pẹ̀lú gbogbo ìjọba èèyàn tó kù. *​—Ìfi. 16:13, 14, 16; 19:19, 20.

12. Ẹ̀rí míì wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì sọ tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó sì jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa?

12 Àǹfààní wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣe wá? Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì jẹ́ ká rí ẹ̀rí míì tó fi hàn pé àkókò òpin là ń gbé. Ó ju ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ ọdún lọ (2,500) tí Dáníẹ́lì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìjọba alágbára mẹ́rin míì máa dìde lẹ́yìn Bábílónì, wọ́n sì máa pọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run lójú. Dáníẹ́lì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló máa ṣàkóso ayé kẹ́yìn lára àwọn ìjọba alágbára mẹ́rin náà. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó sì jẹ́ ká máa retí pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa pa gbogbo ìjọba èèyàn run, á sì máa ṣàkóso aráyé.​—Dán. 2:44.

13. Kí ni “ọba kẹjọ” àti “ọba mẹ́wàá” tí Ìfihàn 17:9-12 sọ ṣàpẹẹrẹ, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ?

13 Ka Ìfihàn 17:9-12. Torí pé Ogun Àgbáyé Kìíní fi ẹ̀mí ṣòfò tó sì ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́, ìyẹn mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì ṣẹ pé a ti wà ní ọjọ́ ìkẹyìn. Àwọn alákòóso ayé fẹ́ mú kí àlàáfíà wà kárí ayé. Torí náà, ní January 1920, wọ́n dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, àmọ́ wọ́n fi Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé rọ́pò ẹ̀ ní October 1945. Àjọ yìí ni Bíbélì pè ní “ọba kẹjọ.” Àmọ́ àjọ náà kì í ṣe ìjọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé. Àwọn ìjọba tó ń tì í lẹ́yìn ló ń fún un lágbára. Àwọn ìjọba yẹn ni Bíbélì pè ní “ọba mẹ́wàá.”

14-15. (a) Kí ni Ìfihàn 17:3-5 sọ nípa “Bábílónì Ńlá”? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ìsìn èké nígbà tí wọn ò bá tì í lẹ́yìn mọ́?

14 Ka Ìfihàn 17:3-5. Nígbà tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Jòhánù nínú ìran kan, ó rí aṣẹ́wó kan, ìyẹn “Bábílónì Ńlá” tó ṣàpẹẹrẹ àpapọ̀ gbogbo ìsìn èké ayé. Báwo ni ìran náà ṣe máa ṣẹ? Ọjọ́ pẹ́ táwọn ìsìn èké ti ń da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọba ayé, tí wọ́n sì ń tì wọ́n lẹ́yìn. Àmọ́ láìpẹ́, Jèhófà máa fi sọ́kàn àwọn ìjọba ayé “láti ṣe ohun tí òun fẹ́.” Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀? Àwọn ìjọba yẹn, ìyẹn “ọba mẹ́wàá” máa gbéjà ko àwọn ìsìn èké, wọ́n á sì pa wọ́n run.​—Ìfi. 17:1, 2, 16, 17.

15 Báwo la ṣe mọ̀ pé Bábílónì Ńlá ò ní pẹ́ pa run? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ rántí pé alagbalúgbú omi Odò Yúfírétì ló yí ìlú Bábílónì ká, ó sì wà lára ohun tó ń dáàbò bò ó. Lọ́nà kan náà, ìwé Ìfihàn fi àìmọye èèyàn tó ń ti Bábílónì Ńlá lẹ́yìn wé “àwọn omi” tó ń dáàbò bò ó. (Ìfi. 17:15) Àmọ́, ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé omi náà máa “gbẹ,” tó fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ti àpapọ̀ gbogbo ìsìn èké ayé lẹ́yìn máa fi í sílẹ̀. (Ìfi. 16:12) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ lónìí torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń fi ìsìn èké sílẹ̀, wọ́n sì ti wá bí wọ́n ṣe máa yanjú ìṣòro wọn lọ sí ibòmíì.

16. Àǹfààní wo la rí nígbà tá a lóye àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe dá Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sílẹ̀ àti bí Bábílónì Ńlá ṣe máa pa run?

16 Àǹfààní wo làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣe wá? Bí wọ́n ṣe dá Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé sílẹ̀ àti bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń fi ìsìn èké sílẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí míì tó jẹ́ ká mọ̀ pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò ti Bábílónì Ńlá tó jẹ́ àpapọ̀ ẹ̀sìn èké lẹ́yìn mọ́, ìyẹn kọ́ ló máa pa àwọn ẹ̀sìn èké run, nǹkan míì ló máa pa wọ́n run. Bá a ṣe sọ níṣàájú, Jèhófà máa fi sí ọkàn “ọba mẹ́wàá” náà, ìyẹn àwọn ìjọba tó ń ti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé lẹ́yìn “láti ṣe ohun tí òun fẹ́.” Lójijì, àwọn orílẹ̀-èdè yẹn máa pa ìsìn èké run, ìparun ẹ̀ sì máa ya gbogbo ayé lẹ́nu. * (Ìfi. 18:8-10) Nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, gbogbo aráyé máa mọ̀ ọ́n lára, nǹkan sì lè nira fáwọn èèyàn, àmọ́ inú àwa èèyàn Ọlọ́run máa dùn nígbà yẹn. Ó kéré tán, ohun méjì lá jẹ́ kí inú wa máa dùn. Àkọ́kọ́, ìsìn èké tó jẹ́ ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run lọ́jọ́ tó ti pẹ́ ti pa run ráúráú. Ìkejì sì ni pé kò ní pẹ́ mọ́ tí Ọlọ́run máa gbà wá lọ́wọ́ ayé burúkú yìí!​—Lúùkù 21:28.

GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ PÉ Á DÁÀBÒ BÒ WÁ

17-18. (a) Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára? (b) Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

17 Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìmọ̀ tòótọ́” máa ‘pọ̀ gan-an.’ Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lónìí nìyẹn! A ti lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó dá lórí àkókò tá à ń gbé yìí. (Dán. 12:4, 9, 10) Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ láìkù síbì kan ń jẹ́ ká túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà àti Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Àìsá. 46:10; 55:11) Torí náà, tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, tó o sì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára. Ó máa dáàbò bo àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e, ó sì máa fún wọn ní “àlàáfíà tí kò lópin.”​—Àìsá. 26:3.

18 Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí ìjọ Kristẹni ní àkókò òpin yìí. A tún máa mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe jẹ́rìí sí i pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé. Yàtọ̀ síyẹn, a máa rí i pé Jésù Ọba wa ti ń ṣàkóso, òun ló sì ń darí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́.

ORIN 61 Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí

^ Àkókò táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ là ń gbé yìí! Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa wo díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà. Ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára, á sì tún jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.

^ Wo ẹ̀kọ́ 32, kókó 4 nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, kó o sì tún lọ sórí ìkànnì jw.org láti wo fídíò náà, Ọdún 1914 Ni Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣàkóso.

^ Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, wo Ilé Ìṣọ́ June 15, 2012, ojú ìwé 14-19.

^ Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, wo orí 21 nínú ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!