Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Gbádùn Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà àti Bí Mo Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Nípa Ẹ̀

Mo Gbádùn Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà àti Bí Mo Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Nípa Ẹ̀

ÌLÚ Easton ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni mo dàgbà sí, mo sì pinnu pé màá lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga kí n lè di èèyàn pàtàkì. Mo gbádùn kí n máa kẹ́kọ̀ọ́, mo sì mọ ìṣirò àti ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì dáadáa. Lọ́dún 1956, àjọ kan tó ń jà fún ẹ̀tọ́ aráàlú fún mi ní dọ́là mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) torí pé èmi ni mo mọ̀wé jù láàárín àwọn ọmọ ilé ìwé aláwọ̀ dúdú. Nígbà tó yá, mo pinnu pé ọ̀tọ̀ ni nǹkan tí mo fẹ́ fayé mi ṣe. Àmọ́, kí ló jẹ́ kí n yí èrò mi pa dà?

BÍ MO ṢE KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA JÈHÓFÀ

Láàárín ọdún 1940 àti 1944, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn òbí mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró, màmá mi ṣì máa ń gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Lọ́dún 1950, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe Àpéjọ Àgbáyé kan nílùú New York City, wọ́n pe ìdílé wa síbẹ̀, a sì lọ.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Arákùnrin Lawrence Jeffries bẹ̀rẹ̀ sí í wá sílé wa. Ó gbìyànjú gan-an láti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi sọ̀rọ̀, mi ò fara mọ́ ohun tó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú àti ogun. Mo sọ fún un pé tó bá jẹ́ gbogbo èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló sọ pé àwọn ò jagun, ṣé àwọn ọ̀tá ò ní wá gba gbogbo ìlú mọ́ wọn lọ́wọ́? Arákùnrin Jeffries fi sùúrù dá mi lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ pé gbogbo èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń sin Jèhófà, kí lo rò pé Jèhófà máa ṣe táwọn ọ̀tá bá wá gbógun jà wọ́n?” Ohun tó sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí àtàwọn ọ̀rọ̀ míì jẹ́ kí n rí i pé ọ̀rọ̀ mi ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ wù mí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ọjọ́ tí mo ṣèrìbọmi

Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo fi ka àwọn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí màmá mi tọ́jú sínú àjàalẹ̀ ilé wa. Nígbà tó yá, mo rí i pé òtítọ́ ni wọ́n ń kọ́ mi, torí náà mo gbà kí Arákùnrin Jeffries kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé déédéé. Mo mọyì ohun tí mò ń kọ́, torí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí mo mọ̀ pé “ọjọ́ ńlá Jèhófà [ti] sún mọ́lé,” mo pinnu pé ọ̀tọ̀ lohun tí mo máa fayé mi ṣe. (Sef. 1:14) Dípò kí n lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, mo pinnu pé màá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mo kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ girama ní June 13, 1956, ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ni mo sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká kan tá a ṣe. Mi ò mọ̀ rárá pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ni Jèhófà máa fún mi torí mo pinnu pé màá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, màá sì kọ́ àwọn èèyàn nípa ẹ̀.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́, MO SÌ KỌ́ ÀWỌN ÈÈYÀN NÍPA JÈHÓFÀ NÍGBÀ TÍ MO DI AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ

Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àpilẹ̀kọ kan jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ December 1956 tó sọ pé “Ṣó O Lè Lọ Sìn Níbí Tí Wọ́n Ti Nílò Àwọn Oníwàásù Púpọ̀ Sí I?” Mo mọ̀ pé èmi náà lè lọ. Torí náà, ó wù mí pé kí n lọ wàásù níbi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ti pọ̀.—Mát. 24:14.

Mo wá kó lọ sílùú Edgefield, ní ìpínlẹ̀ South Carolina. Àmọ́, akéde mẹ́rin péré ló wà níjọ tó wà níbẹ̀, ìgbà tí mo dé la di márùn-ún. Iwájú ilé arákùnrin kan la ti ń ṣèpàdé. Ọgọ́rùn-ún (100) wákàtí ni mo máa ń lò lóde ìwàásù lóṣooṣù. Ọwọ́ mi máa ń dí torí mo máa ń lọ sóde ìwàásù déédéé, mo sì máa ń sọ àsọyé nípàdé gan-an. Ohun tó wú mi lórí jù ni pé bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni mo túbọ̀ ń mọ̀ ọ́n sí i.

Ilé kan wà nílùú Johnston tí wọ́n ti ń tọ́jú òkú kí wọ́n tó sin ín, obìnrin kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ni ín, kò sì fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síbi tí mò ń gbé. Obìnrin náà gbà kí n máa bá òun ṣiṣẹ́ àbọ̀ọ̀ṣẹ́, ó sì ní ká máa lo ilé kékeré kan níbẹ̀ fún Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Ìgbà yẹn ni ọmọ arákùnrin tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ tó ń jẹ́ Jolly Jeffries kó wá síbẹ̀ láti ìlú Brooklyn, New York, a sì jọ ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Inú ilé alágbèérìn kan tí arákùnrin kan yá wa là ń gbé.

Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ sanwó tó pọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ South Carolina tá à ń gbé. Kódà, dọ́là méjì tàbí mẹ́ta péré ni wọ́n máa ń san fún wa lójúmọ́. Lọ́jọ́ kan, ìwọ̀nba owó tó kù lọ́wọ́ mi ni mo fi ra oúnjẹ nílé ìtajà kan. Bí mo ṣe ń jáde níbẹ̀, ọkùnrin kan bi mí pé: “Ṣé o máa bá mi ṣiṣẹ́? Màá máa san dọ́là kan fún ẹ ní wákàtí kọ̀ọ̀kan.” Ó ní kí n fi ọjọ́ mẹ́ta ṣiṣẹ́ níbì kan tí wọ́n ti ń kọ́lé, iṣẹ́ mi ni pé kí n palẹ̀ ibẹ̀ mọ́, kó lè mọ́ tónítóní. Ó wá dá mi lójú pé Jèhófà fẹ́ kí n dúró sílùú Edgefield kí n lè máa wàásù nìṣó. Kódà, mo lọ sí Àpéjọ Àgbáyé tí wọ́n ṣe lọ́dún 1958 nílùú New York City.

Ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó

Lọ́jọ́ kejì àpéjọ náà, ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ṣẹlẹ̀. Mo pàdé Ruby Wadlington tó ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nílùú Gallatin, ìpínlẹ̀ Tennessee. Torí pé iṣẹ́ míṣọ́nnárì lèmi àti ẹ̀ fẹ́ ṣe, a jọ lọ sípàdé tí wọ́n ṣe fáwọn tó fẹ́ lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì nípàdé àgbáyé yẹn. Nígbà tó yá, a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà síra wa. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n ní kí n wá sọ àsọyé níjọ tó wà nílùú Gallatin. Ni mo bá lo àǹfààní yẹn láti sọ fún un pé kó fẹ́ mi. Lẹ́yìn náà, mo kó lọ síjọ tí Ruby wà, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún 1959.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́, MO SÌ KỌ́ ÀWỌN ARÁ NÍNÚ ÌJỌ

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún (23), wọ́n sọ mí di ìránṣẹ́ ìjọ (tí wọ́n ń pè ní olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà báyìí) nílùú Gallatin. Ìjọ wa ni ìjọ àkọ́kọ́ tí Arákùnrin Charles Thompson bẹ̀ wò nígbà tó di alábòójútó àyíká. Ó nírìírí gan-an, síbẹ̀ ó máa ń sọ pé kí n gba òun nímọ̀ràn nípa bí òun ṣe lè bójú tó àwọn ará àti bí àwọn alábòójútó àyíká yòókù ṣe ń ṣe é. Ó kọ́ mi pé ó dáa kéèyàn máa béèrè ìbéèrè, kéèyàn sì mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kan kó tó bójú tó o.

Ní May 1964, wọ́n pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ olóṣù kan tí wọ́n ṣe nílùú South Lansing, New York. Àwọn arákùnrin tó darí ilé ẹ̀kọ́ náà kọ́ mi pé mo gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i, kí n sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́, MO SÌ KỌ́ ÀWỌN ARÁ LÁWỌN ÀPÉJỌ WA

Ní January 1965, ètò Ọlọ́run ní kí èmi àti Ruby máa lọ ṣiṣẹ́ alábòójútó àyíká. Àyíká tí wọ́n rán wa lọ fẹ̀ gan-an. Ó bẹ̀rẹ̀ nílùú Knoxville, Tennessee, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ìlú Richmond, Virginia. Kódà, a máa ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní North Carolina, Kentucky àti West Virginia wò. Ìjọ àwọn aláwọ̀ dúdú nìkan ni mo máa ń bẹ̀ wò torí pé ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà wà lápá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nígbà yẹn, ìyẹn ò sì jẹ́ káwọn aláwọ̀ funfun bá àwọn aláwọ̀ dúdú da nǹkan pọ̀. Àwọn ará tó wà níbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, torí náà, a máa ń pín ohun tá a ní pẹ̀lú wọn. Alábòójútó àyíká kan tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì kan pé: “Mú àwọn ará bíi pé ọmọ ìyá ni yín. Má jẹ́ kí wọ́n máa fojú ọ̀gá wò ẹ́. Tó o bá mú wọn bí ọ̀rẹ́ lo máa lè ràn wọ́n lọ́wọ́.”

Nígbà tá a bẹ ìjọ kékeré kan wò, Ruby bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́. Obìnrin náà ní ọmọbìnrin kan tó ti pé ọdún kan. Ìgbà kan wà tí kò sẹ́ni tó lè kọ́ obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ yẹn, torí náà Ruby máa ń kọ lẹ́tà sí i láti fi kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tá a pa dà bẹ ìjọ yẹn wò, obìnrin náà ti ń wá sípàdé déédéé. Ẹ̀yìn ìyẹn làwọn arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe méjì wá síjọ yẹn, torí náà, wọ́n ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ obìnrin yẹn lọ, kò sì pẹ́ tó fi ṣèrìbọmi. Nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 1995, nígbà tá a wà ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Patterson, arábìnrin ọ̀dọ́ kan wá bá Ruby sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ ẹ mọ ọ̀dọ́bìnrin náà? Ọmọ obìnrin tí Ruby kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yẹn ni. Ọ̀dọ́bìnrin náà àti ọkọ ẹ̀ wá sí kíláàsì ọgọ́rùn-ún ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.

Ìpínlẹ̀ Florida ni àyíká kejì tá a bẹ̀ wò. A nílò mọ́tò nígbà yẹn, a sì rí mọ́tò kan rà tí ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n. Àmọ́, ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, nǹkan kan nínú ẹ́ńjìnnì mọ́tò náà bà jẹ́, a ò sì lówó tá a máa fi tún un ṣe. Torí náà mo sọ fún arákùnrin kan tí mo mọ̀ pé ó lè ràn wá lọ́wọ́. Arákùnrin náà ní kí ọ̀kan lára àwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ wá tún un ṣe, kò sì gba owó kankan lọ́wọ́ wa. Ohun tó kàn sọ ni pé: “Mo ti tún un ṣe.” Kódà òun ló tún fún wa lówó! Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀ nìyẹn. Ìyẹn sì tún rán àwa náà létí pé ó yẹ ká máa ṣoore fáwọn èèyàn.

Ilé àwọn ará la máa ń dé sí tá a bá ti bẹ ìjọ wọn wò. Ìyẹn sì ti jẹ́ ká láwọn ọ̀rẹ́ gidi. Lọ́jọ́ kan, mo fi ìròyìn ìjọ kan tí mo bẹ̀ wò sílẹ̀ sórí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé torí pé mi ò tíì parí ẹ̀, mo sì jáde lọ. Nígbà tí mo pa dà dé nírọ̀lẹ́, ọmọ àwọn tá a dé sọ́dọ̀ wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta ti tẹ oríṣiríṣi nǹkan sínú ìwé náà. Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi bá ọmọkùnrin náà ṣàwàdà torí ohun tó ṣe yẹn.

Ní 1971, mo gba lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run pé kí n máa lọ ṣiṣẹ́ alábòójútó agbègbè ní New York City. Ó yà wá lẹ́nu gan-an! Ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) péré ni mí nígbà yẹn. Àwọn arákùnrin tó wà níbẹ̀ gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé èmi ni alábòójútó agbègbè tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú tí wọ́n máa kọ́kọ́ ní.

Mo gbádùn iṣẹ́ alábòójútó agbègbè tí mo ṣe torí pé gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ni mo máa ń sọ àsọyé ní àpéjọ àyíká. Ọ̀pọ̀ àwọn alábòójútó àyíká tá a jọ máa ń ṣiṣẹ́ ló nírìírí jù mí lọ. Kódà, ọ̀kan lára wọn ló sọ àsọyé ìrìbọmi mi. Arákùnrin Theodore Jaracz náà wà lára àwọn alábòójútó àyíká yẹn, nígbà tó sì yá, ó di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí. Yàtọ̀ sáwọn arákùnrin yìí, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tó nírìírí tí wọ́n ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn la máa ń bá ṣiṣẹ́. Inú mi dùn pé gbogbo àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà láwọn àyíká náà ló gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, wọ́n sì jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. Èmi fúnra mi rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn alábòójútó onífẹ̀ẹ́ yìí gbára lé, wọ́n sì ń ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn. Ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ní ló mú kó rọrùn fún mi láti ṣiṣẹ́ alábòójútó agbègbè lọ́dọ̀ wọn.

MO PA DÀ DI ALÁBÒÓJÚTÓ ÀYÍKÁ

Ní 1974, Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ àwọn alábòójútó àyíká kan di alábòójútó agbègbè. Torí náà, mo pa dà sẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, South Carolina ni wọ́n rán wa lọ. Inú wa dùn pé lásìkò yẹn, àwọn aláwọ̀ funfun àtàwọn aláwọ̀ dúdú ti ń ṣe nǹkan pọ̀, ìyẹn sì múnú àwọn ará dùn gan-an.

Ní ìparí ọdún 1976, ètò Ọlọ́run rán wa lọ sí àyíká kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Georgia, láàárín Atlanta àti Columbus. Mo rántí dáadáa pé mo sọ àsọyé ìsìnkú fáwọn ọmọ aláwọ̀ dúdú márùn-ún kan nígbà táwọn kan bínú dáná sun ilé wọn. Ìyá àwọn ọmọ náà wà nílé ìwòsàn torí òun náà fara pa. Àmọ́ ṣe làwọn ará tó jẹ́ aláwọ̀ funfun àti aláwọ̀ dúdú ń wọ́ tìrítìrí nílé ìwòsàn náà kí wọ́n lè tù wọ́n nínú. Mo rí i pé ìfẹ́ táwọn ará ní síra wọn kì í ṣe ìfẹ́ orí ahọ́n. Irú ìfẹ́ táwọn ará fi hàn síra wọn yìí máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti fara da àdánwò tó le gan-an.

MO KẸ́KỌ̀Ọ́, MO SÌ KỌ́ ÀWỌN MÍÌ NÍ BẸ́TẸ́LÌ

Ní 1977, ètò Ọlọ́run ní ká wá ṣiṣẹ́ fún oṣù mélòó kan ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn. Nígbà tó kù díẹ̀ ká parí iṣẹ́ náà, méjì lára àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí bi èmi àti Ruby pé ṣé ó wù wá pé ká máa bá iṣẹ́ wa lọ ní Bẹ́tẹ́lì. A sọ fún wọn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó wù wá.

Ọdún mẹ́rìnlélógún (24) ni mo fi ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Onírúurú ìbéèrè tó díjú làwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ máa ń dáhùn. Ọjọ́ pẹ́ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń lo ìlànà Ìwé Mímọ́ láti fi tọ́ wa sọ́nà. Àwọn ìlànà yìí la fi ń dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn ará bá bi wá, òun náà la sì ń lò tá a bá fẹ́ dá àwọn alábòójútó àyíká, àwọn alàgbà àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ti jẹ́ káwọn ará túbọ̀ di ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ìyẹn sì ti jẹ́ ká ní ọ̀pọ̀ àwọn ará tó mọ̀ọ̀yàn kọ́, tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nínú ètò Ọlọ́run.

Lọ́dún 1995 sí 2018, mo láǹfààní láti jẹ́ aṣojú oríléeṣẹ́, mo sì ṣèbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì. Mo máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì kí n lè fún wọn níṣìírí, kí n sì mọ bí mo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìrírí táwọn ará máa ń sọ fún wa máa ń fún èmi àti Ruby níṣìírí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, a ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Rùwáńdà lọ́dún 2000. Ó dùn wá gan-an nígbà tá a gbọ́ ohun tójú àwọn ará àti ìdílé Bẹ́tẹ́lì rí nígbà tí ẹ̀yà kan fẹ́ pa ẹ̀yà kejì run níbẹ̀ lọ́dún 1994. Ọ̀pọ̀ ló pàdánù àwọn èèyàn wọn. Láìka gbogbo ohun tójú wọn rí sí, àwọn ará yẹn fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́, wọ́n gbà pé nǹkan ṣì máa dáa, ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n láyọ̀.

Ìgbà tá a ṣe àyájọ́ àádọ́ta (50) ọdún tá a ṣègbéyàwó

A ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún báyìí, ó sì ti pé ogún (20) ọdún tí mo ti ń bá Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣiṣẹ́. Mi ò lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga, àmọ́ mo ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ga jù látọ̀dọ̀ Jèhófà àti ètò ẹ̀. Ìyẹn ti jẹ́ kí n kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó máa ṣe wọ́n láǹfààní títí láé. (2 Kọ́r. 3:5; 2 Tím. 2:2) Yàtọ̀ síyẹn, mo ti rí bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ń mú kí ìgbésí ayé àwọn èèyàn túbọ̀ dáa, tó sì ń mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. (Jém. 4:8) Torí náà, gbogbo ìgbà lèmi àti Ruby máa ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n mọyì àǹfààní tí wọ́n ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì tún máa fi kọ́ àwọn míì, ìyẹn sì ni àǹfààní tó dáa jù tí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní!