Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn wo ni Jèhófà máa jí dìde sí ayé, irú àjíǹde wo ni wọ́n sì máa ní?

Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Ìṣe 24:15 sọ pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” Àwọn olódodo ni àwọn tí wọ́n ṣègbọràn sí Jèhófà kí wọ́n tó kú, torí náà orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè. (Mál. 3:16) Àwọn aláìṣòdodo làwọn tí ò láǹfààní láti jọ́sìn Jèhófà kí wọ́n tó kú, torí náà orúkọ wọn ò sí nínú ìwé ìyè.

Àwùjọ méjì tí Jòhánù 5:28, 29 sọ̀rọ̀ nípa wọn náà ni Ìṣe 24:15 sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Jésù sọ pé “àwọn tó ṣe ohun rere” máa ní “àjíǹde ìyè, àwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà sì [máa ní] àjíǹde ìdájọ́.” Àwọn olódodo làwọn tó ṣe ohun rere kí wọ́n tó kú. Jèhófà máa jí wọn dìde sí ìyè torí pé orúkọ wọn wà nínú ìwé ìyè. Àmọ́ àwọn aláìṣòdodo làwọn tó sọ ohun burúkú dàṣà kí wọ́n tó kú. Torí náà, àjíǹde ìdájọ́ ni wọ́n máa ní. Orúkọ wọn ò tíì sí nínú ìwé ìyè, torí náà lásìkò ìdájọ́, Jèhófà máa kíyè sí wọn kó lè mọ̀ bóyá wọ́n ń fi nǹkan tí wọ́n ń kọ́ sílò. Tó bá dìgbà yẹn, wọ́n máa láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí orúkọ wọn lè wà nínú ìwé ìyè.

Ìfihàn 20:12, 13 ṣàlàyé pé gbogbo àwọn tó jíǹde máa ní láti tẹ̀ lé “àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà,” ìyẹn àwọn òfin tuntun tí Jèhófà máa fún wa nínú ayé tuntun. Jèhófà máa pa àwọn tí ò bá tẹ̀ lé òfin yẹn run pátápátá.—Àìsá. 65:20.

Dáníẹ́lì 12:2 sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan tó ti kú máa jíǹde “sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn míì sí ẹ̀gàn àti sí ìkórìíra ayérayé.” Ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn tó bá jíǹde, ó ní wọ́n máa gba “ìyè àìnípẹ̀kun” tàbí “ìkórìíra ayérayé.” Torí náà, nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún (1,000) náà bá parí, àwọn kan máa ní ìyè àìnípẹ̀kun, Jèhófà sì máa pa àwọn tó kù run yán-án yán-án.—Ìfi. 20:15; 21:3, 4.

Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. A lè fi àwùjọ méjèèjì tó jíǹde yìí wé àwọn àjèjì tó fẹ́ lọ gbé lórílẹ̀-èdè míì. Àwọn olódodo ló dà bí àwọn tí wọ́n fún níwèé ìgbélùú pé wọ́n lè ṣiṣẹ́ nílùú yẹn àti pé wọ́n lè máa gbébẹ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa lómìnira láti lọ síbi tó wù wọ́n, àwọn èèyàn á sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́ àwọn aláìṣòdodo ló dà bí àwọn àjèjì tí wọ́n fún níwèé ìgbélùú láti gbé nílùú yẹn fúngbà díẹ̀ tàbí láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Irú àwọn àjèjì bẹ́ẹ̀ máa ní láti fi hàn pé àwọn yẹ lẹ́ni tó ń gbé ìlú yẹn kí wọ́n tó lè fún wọn níwèé tó máa jẹ́ kí wọ́n lè máa gbébẹ̀ títí lọ. Lọ́nà kan náà, kí Jèhófà tó lè gbà káwọn aláìṣòdodo tó jíǹde máa gbé nínú ayé tuntun, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé òfin Jèhófà, kí wọ́n sì fi hàn pé olódodo làwọn. Ìwé ìgbélùú yòówù káwọn àjèjì gbà, yálà èyí tí wọ́n fẹ́ fi ṣiṣẹ́ ni àbí èyí tí wọ́n fẹ́ fi ṣèbẹ̀wò, ìwà àti ìṣe wọn ló máa pinnu bóyá orílẹ̀-èdè yẹn máa jẹ́ kí wọ́n máa gbébẹ̀ títí lọ àbí wọ́n máa lé wọn kúrò. Lọ́nà kan náà, ìwà àti ìṣòtítọ́ gbogbo àwọn tó jíǹde ló máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn nínú ayé tuntun.

Ọlọ́run tó máa ń ṣàánú ni Jèhófà, àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, ó máa ń ṣèdájọ́ òdodo, ó sì máa ń gba tiwa rò. (Diu. 32:4; Sm. 33:5) Ó máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa nígbà tó bá jí àwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo dìde. Àmọ́ Jèhófà máa retí pé kí gbogbo wọn pa òfin àti ìlànà òun mọ́. Torí náà, kìkì àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tí wọ́n sì ń pa àwọn ìlànà ẹ̀ mọ́ lá jẹ́ kó máa gbénú ayé tuntun.