Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Àárẹ̀ Ọpọlọ Máa Dohun Ìgbàgbé!

Ọlọ́run Ṣèlérí Pé Àárẹ̀ Ọpọlọ Máa Dohun Ìgbàgbé!

Nínú Bíbélì, Ọlọ́run sọ ohun tá a lè ṣe tá a bá ní àárẹ̀ ọpọlọ.

Àmọ́, Ọlọ́run tún ṣe ohun míì tó ń múnú wa dùn gan-an. Ó ṣèlérí pé òun máa mú gbogbo ohun tó ń fa àárẹ̀ ọpọlọ kúrò pátápátá.

Tí Ọlọ́run bá ti mú ìlérí yìí ṣẹ, kò ní sí àròkàn mọ́, kò ní sí àárẹ̀ ọpọlọ mọ́, gbogbo ẹ̀dùn ọkàn “ò ní wá sí ìrántí, wọn ò sì ní wá sí ọkàn” wa mọ́.​—Àìsáyà 65:17.

Ó wu àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ká ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ìgbà tí Ọlọ́run máa mú ìlérí tó ń tuni nínú yìí ṣẹ, kó o sì mọ bó ṣe máa ṣe é.