Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 2

“Ẹ Para Dà Nípa Yíyí Èrò Inú Yín Pa Dà”

“Ẹ Para Dà Nípa Yíyí Èrò Inú Yín Pa Dà”

“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”​—RÓÒMÙ 12:2.

ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Kí ló yẹ ká máa ṣe lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi? Ṣàlàyé.

 ṢÉ O máa ń tọ́jú ilé ẹ déédéé? Bóyá kó o tó kó sínú ilé náà, ṣe lo fara balẹ̀ tún un ṣe. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó ò bá tọ́jú ẹ̀ mọ́ lẹ́yìn tó o kó sínú ẹ̀? Eruku àti ìdọ̀tí máa kún inú ilé náà. Torí náà, tó o bá fẹ́ kí ilé ẹ dùn ún wò, ó yẹ kó o máa tún un ṣe déédéé.

2 Lọ́nà kan náà, ó yẹ ká ṣiṣẹ́ kára ká lè yí èrò àti ìwà wa pa dà. Ó dájú pé ká tó ṣèrìbọmi, a ti ṣiṣẹ́ kára láti ṣe àwọn àyípadà kan nígbèésí ayé wa, ká lè “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́r. 7:1) Àmọ́ ní báyìí, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé “ẹ máa di tuntun.” (Éfé. 4:23) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀? Torí pé ìwà àti ìṣe ayé yìí tó dà bí eruku àti ìdọ̀tí lè sọ wá di aláìmọ́ lójú Jèhófà. Kíyẹn má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa, kí Jèhófà sì lè tẹ́wọ́ gbà wá, ó yẹ ká máa yẹ ara wa wò déédéé, ìyẹn èrò wa, ìwà wa àti ohun tó ń wù wá.

MÁA ‘YÍ ÈRÒ Ẹ PA DÀ’

3. Tá a bá fẹ́ ‘yí èrò inú wa pa dà,’ kí ló yẹ ká ṣe? (Róòmù 12:2)

3 Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ yí èrò wa pa dà, ìyẹn ni pé ká yí bá a ṣe ń ronú pa dà? (Ka Róòmù 12:2.) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí wọ́n tú sí ‘yí èrò pa dà’ tún lè túmọ̀ sí “tún èrò ṣe.” Torí náà, ká yí èrò wa pa dà kọjá ká máa ṣe àwọn ohun rere kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa yẹ irú ẹni tá a jẹ́ wò, ká sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ, ká lè máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Ìgbà gbogbo ló sì yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣé àwọn ìpinnu tí mò ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ lílọ sí Yunifásítì àtàwọn nǹkan míì tí mo fẹ́ fayé mi ṣe ń fi hàn pé Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù sí mi? (Wo ìpínrọ̀ 4-5) c

4. Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí ọ̀nà tí ayé ń gbà ronú máa darí wa?

4 Ó dìgbà tá a bá dẹni pípé ká tó lè máa ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Ní Róòmù 12:2, ṣé ẹ kíyè sí pé Pọ́ọ̀lù sọ pé kéèyàn tó lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ yí èrò inú ẹ̀ pa dà. Dípò ká jẹ́ kí ayé yìí máa darí èrò wa, a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò ká lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run ló ń darí èrò wa tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan tàbí tá a bá fẹ́ yan nǹkan tá a máa ṣe.

5. Tá a bá gbà pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, kí ló yẹ ká ṣe? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

5 Wo àpẹẹrẹ yìí ná. Jèhófà fẹ́ ká máa fi ‘ìgbà tí ọjọ́ òun máa dé sọ́kàn dáadáa.’ (2 Pét. 3:12) Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi fi hàn pé mo gbà pé ayé burúkú yìí máa tó pa run? Ṣé ìpinnu tí mò ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ lílọ sí Yunifásítì àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù sí mi? Ṣé mo nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa pèsè fún èmi àti ìdílé mi àbí mo máa ń ṣàníyàn ṣáá nípa àwọn nǹkan ìní tara?’ Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó, tó bá rí i pé à ń gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ òun mu.​—Mát. 6:25-27, 33; Fílí. 4:12, 13.

6. Kí ló yẹ ká máa ṣe?

6 Ó ṣe pàtàkì ká máa yẹ èrò wa wò déédéé, ká sì máa ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́; ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́r. 13:5) Ohun tó ń fi hàn pé ẹnì kan “wà nínú ìgbàgbọ́” ju kí ẹni náà máa lọ sípàdé déédéé, kó sì máa wàásù látìgbàdégbà. Ó tún kan ohun tá à ń rò lọ́kàn wa àti ìdí tá a fi ń ṣe nǹkan. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa yí èrò wa pa dà. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká máa ronú bí Ọlọ́run ṣe ń ronú, ká sì máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́.​—1 Kọ́r. 2:14-16.

Ẹ “GBÉ ÌWÀ TUNTUN WỌ̀”

7. Kí ni Éfésù 4:31, 32 sọ pé ó tún yẹ ká ṣe, kí ló sì lè mú kó ṣòro?

7 Ka Éfésù 4:31, 32. Yàtọ̀ sí pé ká yí èrò wa pa dà, ó tún yẹ ká “gbé ìwà tuntun wọ̀.” (Éfé. 4:24) Ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó gba iṣẹ́ àṣekára. Bí àpẹẹrẹ, ká tó lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa, irú bí inú burúkú, ìbínú àti ìrunú, ó gba iṣẹ́ àṣekára. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti yí pa dà? Ohun tó lè mú kó ṣòro ni pé kì í rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú tó ti mọ́ wa lára. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn kan máa ń “tètè bínú” wọ́n sì [jẹ́] onínúfùfù.” (Òwe 29:22) Ká tó lè jáwọ́ nínú ìwà burúkú tó ti mọ́ wa lára, ó gba iṣẹ́ àṣekára láti yí pa dà kódà lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi bá a ṣe máa rí i nínú àpẹẹrẹ tá a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ báyìí.

8-9. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Stephen ṣe fi hàn pé ó yẹ ká máa bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀?

8 Ó ṣòro fún arákùnrin kan tó ń jẹ́ Stephen láti kápá ìbínú ẹ̀. Ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, mo rí i pé ó yẹ kí n ṣì máa kọ́ béèyàn ṣe ń ní sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí mò ń wàásù láti ilé dé ilé, mo rí i tí ẹnì kan jí rédíò inú mọ́tò mi. Bí mo ṣe gbá tẹ̀ lé e nìyẹn. Nígbà tí mo sún mọ́ ọn, ó ju rédíò náà sílẹ̀, ó sì sá lọ. Nígbà tí mo sọ bí mo ṣe rí rédíò mi gbà pa dà fún àwọn tá a jọ ń wàásù lọ́jọ́ náà, ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó wà níbẹ̀ bi mí pé: ‘Stephen, ká sọ pé ọwọ́ ẹ tẹ olè yẹn, kí lo máa ṣe fún un?’ Ìbéèrè yẹn mú mi ronú, ó jẹ́ kí n túbọ̀ máa ní sùúrù, kí n sì jẹ́ ẹni àlàáfíà.” b

9 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Stephen jẹ́ ká rí i pé a lè pa dà hùwà burúkú lẹ́yìn tá a rò pé a ti jáwọ́ nínú ẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, má jẹ́ kó sú ẹ, kó o wá máa rò pé èèyàn burúkú ni ẹ́. Kódà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sóun náà, ó ní: “Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.” (Róòmù 7:21-23) Bí eruku àti ìdọ̀tí ṣe lè pa dà kún inú ilé tá a ti tún ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwa Kristẹni láwọn ìwà kan tí ò dáa tá à ń hù tẹ́lẹ̀ tó lè máa ṣe wá bíi pé ká pa dà sídìí ẹ̀. Torí náà, ó yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ìgbà. Báwo la ṣe lè ṣe é?

10. Báwo la ṣe lè jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa? (1 Jòhánù 5:14, 15)

10 Tó bá wù ẹ́ láti borí ìwà kan tí ò dáa, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì nígbàgbọ́ pé á gbọ́ ẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Ka 1 Jòhánù 5:14, 15.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò ní mú ìwà burúkú náà kúrò lọ́nà ìyanu, á fún ẹ lókun kó o lè borí ìwà náà. (1 Pét. 5:10) Àmọ́ rí i dájú pé o ò ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o pa dà sídìí ìwà burúkú náà, kí Jèhófà lè dáhùn àdúrà ẹ. Bí àpẹẹrẹ, rí i pé o ò wo àwọn fíìmù àti ètò orí tẹlifíṣọ̀n táá jẹ́ kó o máa fojú tó dáa wo ìwà burúkú náà, má sì ka àwọn ìtàn táá jẹ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, má ṣe máa ro èròkerò.​—Fílí. 4:8; Kól. 3:2.

11. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká lè gbé ìwà tuntun wọ̀?

11 Tó o bá ti bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó o gbé ìwà tuntun wọ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, máa fara wé e. (Éfé. 5:1, 2) Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ka ìtàn Bíbélì kan tó sọ nípa bí Jèhófà ṣe dárí ji àwọn èèyàn kan, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé èmi náà máa ń dárí ji àwọn èèyàn?’ Tó o bá kà nípa bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sáwọn tálákà, bi ara ẹ pé, ‘Ṣé èmi náà máa ń gba tàwọn tálákà tá a jọ ń sin Jèhófà rò, tí mo sì ń ṣàánú wọn?’ Torí náà, máa yí èrò ẹ pa dà bó o ṣe ń gbé ìwà tuntun wọ̀, kó o sì ní sùúrù títí wàá fi gbé ìwà náà wọ̀ pátápátá.

12. Báwo ni Bíbélì ṣe yí ìgbésí ayé Stephen pa dà?

12 Arákùnrin Stephen tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú rí i pé òun ti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìwà tuntun wọ̀. Ó sọ pé: “Látìgbà tí mo ti ṣèrìbọmi, àwọn ohun kan ti ṣẹlẹ̀ tó yẹ kó múnú bí mi gan-an. Àmọ́ ńṣe ni mo máa ń kúrò lọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó bá fẹ́ múnú bí mi tàbí kí n ṣe ohun tí ò ní jẹ́ kọ́rọ̀ náà di wàhálà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń gbóríyìn fún mi torí pé mo máa ń ní sùúrù, kódà ìyàwó mi náà máa ń gbóríyìn fún mi. Mi ò mọ̀ pé mo lè wá dẹni tó ní sùúrù tó báyìí! Àmọ́, mo mọ̀ pé kì í ṣe mímọ̀-ọ́n-ṣe mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló jẹ́ kí n gbà pé Bíbélì máa ń yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà lóòótọ́.”

Ẹ MÁA GBÓGUN TI ÌFẸ́KÚFẸ̀Ẹ́

13. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tó tọ́? (Gálátíà 5:16)

13 Ka Gálátíà 5:16. Ká bàa lè borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe ohun tó tọ́. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ẹ̀mí Ọlọ́run á máa darí wa. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún máa ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìpàdé wa. Láwọn ìpàdé Kristẹni yìí, a máa ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin táwọn náà ń ṣe ipa tiwọn bíi tiwa láti máa ṣe ohun tó tọ́, ìyẹn sì máa ń fún wa níṣìírí. (Héb. 10:24, 25; 13:7) Tá a bá sì gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti borí kùdìẹ̀-kudiẹ kan, ó máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, gbogbo nǹkan tá à ń ṣe yìí ò sọ pé kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ má wá sí wa lọ́kàn, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa jẹ́ ká gbé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ náà kúrò lọ́kàn, a ò sì ní ṣe nǹkan ọ̀hún. Torí náà, bí Gálátíà 5:16 ṣe sọ, àwọn tó bá ń rìn nípa ẹ̀mí ‘kò ní ṣe ìfẹ́ ti ara.’

14. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe ohun tó tọ́ nìṣó?

14 Tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ohun tó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe àwọn nǹkan náà nìṣó ká lè máa ṣe ohun tó tọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀kan lára àwọn ọ̀tá wa ò ní fi wá lọ́rùn sílẹ̀. Ọ̀tá náà ni ìfẹ́ láti ṣe ohun tí kò tọ́. Kódà lẹ́yìn tá a ti ṣèrìbọmi, ọkàn wa tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí àwọn ìwà burúkú tó yẹ ká sá fún, irú bíi títa tẹ́tẹ́, ọtí àmujù àti wíwo àwòrán ìṣekúṣe. (Éfé. 5:3, 4) Arákùnrin ọ̀dọ́ kan sọ pé: “Ọ̀kan lára ìwà burúkú tó nira fún mi láti borí ni bó ṣe máa ń ṣe mí bíi pé kí n bá ọkùnrin bíi tèmi lò pọ̀. Mo rò pé èrò tó máa tètè kúrò lọ́kàn mi ni, àmọ́ ó ṣì máa ń wá sí mi lọ́kàn.” Tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá ń wá sí ẹ lọ́kàn ṣáá, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Tí èrò tí ò tọ́ bá wá sí ẹ lọ́kàn, o lè borí ẹ̀ torí pé ó ti ṣe àwọn kan bẹ́ẹ̀ rí, wọ́n sì borí ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 15-16)

15. Kí nìdí tí ara fi tù wá nígbà tá a mọ̀ pé gbogbo èèyàn ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ máa ń wá sí lọ́kàn? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Tó o bá ń gbógun ti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, tó sì ṣòro fún ẹ láti gbé e kúrò lọ́kàn, rántí pé ìwọ nìkan kọ́ nirú ẹ̀ ń ṣe. Bíbélì sọ pé: “Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.” (1 Kọ́r. 10:13a) Àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó gbé nílùú Kọ́ríńtì la darí ọ̀rọ̀ yìí sí. Àwọn kan lára wọn ti jẹ́ alágbèrè, abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ àti ọ̀mùtípara rí. (1 Kọ́r. 6:9-11) Ṣé o rò pé lẹ́yìn tí wọ́n ṣèrìbọmi, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kankan ò wá sí wọn lọ́kàn? Rárá o. Òótọ́ ni pé Kristẹni ẹni àmì òróró ni gbogbo wọn, síbẹ̀ aláìpé ni wọ́n. Ó dájú pé àtìgbàdégbà làwọn náà á máa gbógun ti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Ó yẹ kí àpẹẹrẹ wọn yìí fún wa níṣìírí. Kí nìdí? Ìdí ni pé àpẹẹrẹ tí wọ́n fi lélẹ̀ jẹ́ ká rí i pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yòówù ká máa bá jà báyìí, àwọn kan ti borí ẹ̀ rí. Torí náà, ó dájú pé a lè ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ torí pé irú ìyà kan náà ló ń jẹ gbogbo àwọn ará wa.’​—1 Pét. 5:9.

16. Èrò tí ò tọ́ wo ni kò yẹ ká ní, kí sì nìdí?

16 Má rò pé kò sẹ́ni tó lè mọ ìṣòro tó o ní àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Tó o bá ń ronú bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o máa rò pé ọ̀rọ̀ ẹ ò látùnṣe àti pé o ò ní lè borí kùdìẹ̀-kudiẹ tó o ní. Àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ pátápátá síyẹn. Ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́r. 10:13b) Torí náà, tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá ń wá sí wa lọ́kàn ṣáá, a lè fara dà á ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ó sì dájú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè gbé e kúrò lọ́kàn.

17. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè má ṣeé ṣe fún wa láti gbé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kúrò lọ́kàn pátápátá, kí la lè ṣe?

17 Máa rántí pé ó lè má ṣeé ṣe fún ẹ láti gbé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ kúrò lọ́kàn pátápátá torí pé aláìpé ni wá. Àmọ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bá wá sí wa lọ́kàn, ó yẹ ká gbé e kúrò lọ́kàn kíákíá bí Jósẹ́fù ti ṣe nígbà tó tètè sá kúrò lọ́dọ̀ ìyàwó Pọ́tífárì. (Jẹ́n. 39:12) Ẹ ò rí i pé kò yẹ ká fàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ́kàn wa!

MÁ ṢE JẸ́ KÓ SÚ Ẹ

18-19. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa bá a ṣe ń yí èrò wa pa dà?

18 Ó dájú pé díẹ̀díẹ̀ làá máa yí èrò wa pa dà kí ohun tá à ń rò àtohun tá à ń ṣe lè bá ìfẹ́ Jèhófà mu. Kí ìyẹn lè ṣeé ṣe, máa bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí déédéé: ‘Ṣé bí mo ṣe ń gbé ìgbé ayé mi fi hàn pé mo gbà pé ayé burúkú yìí ò ní pẹ́ dópin? Ṣé àwọn nǹkan tí mò ń ṣe fi hàn pé mo túbọ̀ ń gbé ìwà tuntun wọ̀? Tí èròkerò bá wá sí mi lọ́kàn, ṣé mò ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà darí mi kí n lè gbé e kúrò lọ́kàn?’

19 Bó o ṣe ń yẹ ara ẹ wò, má rò pé o ò lè ṣàṣìṣe, àmọ́ máa kíyè sí àwọn ibi tó o ti ń tẹ̀ síwájú. Tó o bá rí àwọn ibi tó yẹ kó o ti ṣàtúnṣe, má jẹ́ kó sú ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, máa rántí ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 3:16 tó ní: “Níbi tí a tẹ̀ síwájú dé, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò ní ọ̀nà kan náà.” Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa yí èrò ẹ pa dà.

ORIN 36 À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa

a Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí ayé yìí máa darí wọn. Ó dájú pé ìmọ̀ràn yẹn wúlò fún àwa náà lónìí. Ó yẹ ká ṣọ́ra, kí àwọn èèyàn ayé má bàa kó ìwà wọn ràn wá. Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò ká lè mọ̀ bóyá à ń ronú lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa ronú lọ́nà tó tọ́.

b Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìwà Burúkú Ọwọ́ Mi Ń Peléke Sí I” nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2015.

c ÀWÒRÁN: Arákùnrin ọ̀dọ́ kan ń ronú pé ṣé kóun lọ sí Yunifásítì tàbí kóun fayé òun ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.