Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 9

Bó O Ṣe Lè Mọyì Ìwàláàyè Tí Ọlọ́run Fún Ẹ

Bó O Ṣe Lè Mọyì Ìwàláàyè Tí Ọlọ́run Fún Ẹ

“Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.”​—ÌṢE 17:28.

ORIN 141 Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Báwo ni ẹ̀mí wa ṣe ṣeyebíye tó lójú Jèhófà?

 FOJÚ inú wò ó pé ọ̀rẹ́ ẹ fún ẹ ní ilé kan, ilé náà rẹwà, ó ti pẹ́, ó sì níye lórí gan-an. Ọ̀dà tó wà lára ilé náà ti ń ṣí, ilé náà sì ń jò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ibì kan ti bà jẹ́ lára ilé náà, ó níye lórí gan-an, kódà tẹ́nì kan bá máa rà á, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù owó dọ́là ló máa san. Ó dájú pé o máa mọyì ilé náà gan-an, wàá sì tún un ṣe. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀bùn kan tó ṣeyebíye gan-an, ẹ̀bùn náà ni ẹ̀mí wa. Kódà, Jèhófà jẹ́ ká mọ bí ẹ̀mí wa ti ṣe pàtàkì tó lójú ẹ̀ nígbà tó jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ san ìràpadà torí wa.​—Jòh. 3:16.

2.2 Kọ́ríńtì 7:1 ṣe sọ, kí ni Jèhófà fẹ́ ká ṣe?

2 Jèhófà ni Orísun ìyè. (Sm. 36:9) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí nígbà tó sọ pé: “Ipasẹ̀ rẹ̀ ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:25, 28) Torí náà, a lè sọ pé ẹ̀bùn ni ìwàláàyè jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo ohun tá a nílò tó máa jẹ́ ká wà láàyè ni Jèhófà ń pèsè fún wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. (Ìṣe 14:15-17) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fẹ́ ni pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti tọ́jú ara wa, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun. (Ka 2 Kọ́ríńtì 7:1.) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ara wa kó lè máa jí pépé, ká sì máa dáàbò bo ara wa? Báwo la sì ṣe lè ṣe é?

MỌYÌ ÌWÀLÁÀYÈ TÍ ỌLỌ́RUN FÚN Ẹ

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ara wa kí ara wa lè máa jí pépé?

3 Ọ̀kan lára ìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ara wa ni pé, á jẹ́ ká sin Jèhófà débi tágbára wa gbé e dé. (Máàkù 12:30) A fẹ́ “fi ara [wa] fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, tó jẹ́ mímọ́, tó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà,” torí náà, a kì í ṣe ohun táá mú ká máa ṣàìsàn. (Róòmù 12:1) Lóòótọ́, kò sí bá a ṣe lè tọ́jú ara wa tó, a ṣì máa ń ṣàìsàn. Àmọ́, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe kí Jèhófà lè mọ̀ pé a mọyì ìwàláàyè tó fún wa.

4. Kí ló ń wu Ọba Dáfídì pé kó ṣe?

4 Ohun tí Ọba Dáfídì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ó mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún un. Ó ní: “Èrè wo ló wà nínú ikú mi, nínú bí mo ṣe ń lọ sínú kòtò? Ṣé erùpẹ̀ lè yìn ọ́? Ṣé ó lè sọ nípa ìṣòtítọ́ rẹ?” (Sm. 30:9) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tó kù díẹ̀ kí Dáfídì kú ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ kò fẹ́ kú, ó fẹ́ kára òun jí pépé, kóun lè máa yin Jèhófà nìṣó. Ó sì dájú pé ohun tó wu gbogbo wa náà nìyẹn.

5. Tá a bá tiẹ̀ ti darúgbó tàbí tí àìsàn tó ń ṣe wá bá le gan-an, kí ni gbogbo wa lè ṣe?

5 Tá a bá ti darúgbó tàbí tá à ń ṣàìsàn, ó lè má jẹ́ ká ṣe gbogbo nǹkan tá a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ìyẹn lè jẹ́ ká banú jẹ́ kí nǹkan sì tojú sú wa. Síbẹ̀ kò yẹ ká jẹ́ kí nǹkan tojú sú wa débi pé a ò ní tọ́jú ara wa mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò sí bá a ṣe dàgbà tó tàbí bí àìsàn wa ṣe le tó, a ṣì lè máa yin Jèhófà bíi ti Ọba Dáfídì. Inú wa mà dùn o pé a ṣeyebíye gan-an lójú Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wá! (Mát. 10:29-31) A mọ̀ pé tá a bá tiẹ̀ kú, ó máa jí wa dìde. (Jóòbù 14:14, 15) Torí náà, ní báyìí tá a ṣì wà láàyè, ó yẹ ká máa dáàbò bo ara wa, ká sì máa tọ́jú ara wa ká lè ní ìlera tó dáa.

SÁ FÚN ÀWỌN NǸKAN TÓ MÁA PA Ẹ́ LÁRA

6. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo nǹkan tá à ń jẹ àti nǹkan tá à ń mu?

6 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn tàbí ìwé tó ń sọ nípa ohun tá a máa jẹ àtohun tá ò ní jẹ, ó jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó gbà wá níyànjú pé ká ‘sá fún àwọn ohun tó lè ṣe wá léṣe.’ (Oníw. 11:10) Bíbélì sọ fún wa pé àjẹkì àti ọtí àmujù ò dáa, àwọn nǹkan yìí sì lè dá àìsàn sí wa lára tàbí kí wọ́n ṣekú pa wá. (Òwe 23:20) Jèhófà fẹ́ ká kó ara wa níjàánu tó bá kan irú oúnjẹ tá a fẹ́ jẹ àtohun tá a fẹ́ mu àti bó ṣe máa pọ̀ tó.​—1 Kọ́r. 6:12; 9:25.

7. Báwo lohun tó wà nínú Òwe 2:11 ṣe máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́ nípa ìlera wa?

7 Tá a bá ń lo làákàyè, àwọn ìpinnu tá a bá ń ṣe máa fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa. (Sm. 119:99, 100; ka Òwe 2:11.) Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa ṣọ́ra tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa jẹ. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ oúnjẹ kan àmọ́ tá a mọ̀ pé kò bá wa lára mu, làákàyè wa máa sọ fún wa pé kò yẹ ká jẹ oúnjẹ náà mọ́. Bákan náà, tá a bá ní ìfòyemọ̀, àá máa sùn dáadáa, àá máa ṣeré ìmárale déédéé, àá máa tọ́jú ara wa dáadáa, àá sì máa bójú tó ilé wa kó lè mọ́ tónítóní.

MÁA YẸRA FÚN OHUN TÓ LÈ ṢE Ẹ́ NÍ JÀǸBÁ

8. Kí ni Bíbélì sọ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ọwọ́ tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi ń mú ọ̀rọ̀ ààbò?

8 Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fún wọn láwọn ìlànà tí ò ní jẹ́ kí jàǹbá ṣẹlẹ̀ sí wọn nílé àti níbi iṣẹ́. (Ẹ́kís. 21:28, 29; Diu. 22:8) Ìdí sì ni pé tẹ́nì kan bá ṣèèṣì pa ẹlòmíì, ó máa jìyà ẹ̀. (Diu. 19:4, 5) Kódà, Òfin yẹn sọ pé wọ́n máa fìyà jẹ ẹni tó bá ṣe ọmọ inú aláboyún léṣe bí ò tiẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀. (Ẹ́kís. 21:22, 23) Torí náà, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò.

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀mí wa nírú àwọn ipò yìí? (Wo ìpínrọ̀ 9)

9. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe kí jàǹbá má bàa ṣẹlẹ̀ sí wa? (Tún wo àwọn àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 A máa fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa tá a bá fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ààbò nílé àti níbi iṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ kó ọ̀bẹ, àwọn nǹkan tó mú, oògùn àtàwọn kẹ́míkà dà nù, ibi tí ò ti ní pa ẹnikẹ́ni lára ló yẹ ká kó wọn dà nù sí, kò sì yẹ ká kó irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ síbi tọ́wọ́ àwọn ọmọdé ti lè tó o. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ ká ṣọ́ra gan-an tá a bá wà nídìí iná tó ń jó, omi gbígbóná àtàwọn nǹkan tó ń báná ṣiṣẹ́, ká má sì fi àwọn nǹkan yẹn sílẹ̀ láì bójú tó wọn. Bákan náà, kò yẹ ká wa mọ́tò tàbí ọ̀kadà tá a bá mutí, tá ò bá sùn dáadáa tàbí tá a bá lo oògùn tó lè ṣe ojú wa bàìbàì. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká máa lo fóònù wa tá a bá ń wa mọ́tò.

TÍ ÀJÁLÙ BÁ ṢẸLẸ̀

10. Kí la lè ṣe kí àjálù tó ṣẹlẹ̀ àti nígbà tó bá ṣẹlẹ̀?

10 Nígbà míì, táwọn àjálù kan bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, a ò lè dènà wọn. Ó ṣeé ṣe kí ìmìtìtì ilẹ̀ tàbí omíyalé ṣẹlẹ̀, ó sì lè jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn tàbí káwọn èèyàn máa bára wọn jà ládùúgbò. Àmọ́ táwọn àjálù yìí bá ṣẹlẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe ká lè là á já. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká ṣègbọràn tí ìjọba bá sọ pé ká má jáde nílé láwọn àkókò kan, tí wọ́n bá ní ká tètè kúrò lágbègbè kan tàbí ká má dé agbègbè kan. (Róòmù 13:1, 5-7) A lè múra sílẹ̀ de àwọn àjálù kan, torí náà ó yẹ ká tẹ̀ lé ohun táwọn aláṣẹ bá sọ fún wa kí àjálù náà tó dé. Bí àpẹẹrẹ, a lè tọ́jú omi, oúnjẹ tí ò lè tètè bà jẹ́ àtàwọn oògùn tá a lè lò sínú báàgì kan.

11. Tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ń jà níbi tá à ń gbé, kí ló yẹ ká ṣe?

11 Kí ló yẹ ká ṣe tí àjàkálẹ̀ àrùn bá ń jà níbi tá à ń gbé? Ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ tí wọ́n bá ní ká máa fọwọ́ wa, tí wọ́n bá ní ká máa jìnnà síra wa dáadáa, tí wọ́n bá ní ká máa wọ ìbòmú tàbí tí wọ́n bá ní ká sé ara wa mọ́lé nítorí àrùn náà. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ìyẹn á fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa.

12. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, báwo ni ìlànà tó wà nínú Òwe 14:15 ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ irú ìròyìn tá a máa gbà gbọ́?

12 Nígbà míì tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn aládùúgbò wa àtàwọn oníròyìn lè sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Dípò kó jẹ́ pé “gbogbo ọ̀rọ̀” tá a bá gbọ́ la máa gbà gbọ́, ohun tí ìjọba àtàwọn dókítà bá sọ ló yẹ ká gbà gbọ́. (Ka Òwe 14:15.) Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ń rí i dájú pé àwọn mọ òótọ́ nípa ọ̀rọ̀ kan kí wọ́n tó sọ bá a ṣe máa ṣe ìpàdé àti bá a ṣe máa wàásù. (Héb. 13:17) Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ fún wa, a ò ní kó ara wa àtàwọn míì síṣòro. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará àdúgbò máa rí i pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé òfin ìjọba.​—1 Pét. 2:12.

ṢE ÀWỌN NǸKAN TÍ Ò NÍ JẸ́ KÓ O GBA Ẹ̀JẸ̀

13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tá a bá ń ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?

13 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ọwọ́ pàtàkì làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀. A máa ń tẹ̀ lé òfin tí Jèhófà fún wa pé ká má gba ẹ̀jẹ̀ kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ pàjáwìrì. (Ìṣe 15:28, 29) Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé ó wù wá pé ká kú o. Gbogbo wa la fẹ́ máa wà láàyè nìṣó. Torí náà, a máa ń wá ìtọ́jú lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà tó mọṣẹ́ gan-an, tí wọ́n sì ṣe tán láti tọ́jú wa dáadáa láìlo ẹ̀jẹ̀.

14. Nǹkan míì wo la tún lè ṣe tí ò ní jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ pàjáwìrì fún wa?

14 Tá a bá ń tọ́jú ara wa dáadáa bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ó ṣeé ṣe ká má nílò ìtọ́jú tó la iṣẹ́ abẹ lọ. Tá a bá ní ìlera tó péye, ara wa máa tètè yá tá a bá tiẹ̀ ṣiṣẹ́ abẹ. Nǹkan míì tá a tún lè ṣe tí ò ní jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ pàjáwìrì fún wa ni pé ká kó gbogbo nǹkan tó lè ṣe wá ní jàǹbá kúrò nínú ilé wa àti níbi iṣẹ́ wa, ká sì máa tẹ̀ lé òfin ìrìnnà tí ìjọba ṣe.

Torí pé a mọyì ẹ̀mí wa, a máa ń kọ̀rọ̀ sínú káàdì DPA wa, a sì máa ń mú un dání nígbà gbogbo (Wo ìpínrọ̀ 15) c

15. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa mú káàdì DPA wa tá a ti kọ̀rọ̀ sínú ẹ̀ dání nígbà gbogbo? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Nínú fídíò yẹn, kí ló máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́ lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?

15 Torí pé a mọyì ẹ̀mí wa, a máa ń kọ̀rọ̀ sínú káàdì tó máa jẹ́ káwọn dókítà mọ ẹni tó máa ṣojú fún wa tá a bá ń ṣàìsàn, a sì máa ń mú un dání nígbà gbogbo (a tún máa ń pe káàdì yìí ní káàdì DPA). Inú káàdì yìí la ti máa ń sọ fún dókítà pé a ò fẹ́ gba ẹ̀jẹ̀ àti irú ìtọ́jú tá a lè gbà. Ṣé o ti kọ̀rọ̀ sínú káàdì DPA ẹ, ṣé àwọn nǹkan tó o kọ sínú ẹ̀ sì tọ̀nà? Tó o bá rí i pé o ò tíì kọ̀rọ̀ sínú káàdì ẹ tàbí tó o rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe àwọn nǹkan kan níbẹ̀, ṣe ni kó o ṣe é kíákíá. Tá a bá ti kọ irú ìtọ́jú tá a fẹ́ gan-an sínú káàdì wa, á jẹ́ káwọn dókítà lè tètè tọ́jú wa láì fàkókò ṣòfò. Yàtọ̀ síyẹn, ó máa jẹ́ káwọn dókítà mọ irú ìtọ́jú tá a fẹ́ àti irú oògùn tí ò bá wa lára mu. b

16. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn nǹkan kan tó wà nínú káàdì náà ò bá yé wa?

16 Láìka ọjọ́ orí wa sí àti bí ìlera wa ṣe rí, kò sẹ́ni tí jàǹbá ò lè ṣẹlẹ̀ sí, kò sì sẹ́ni tí ò lè ṣàìsàn. (Oníw. 9:11) Torí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni pé kí gbogbo wa lọ kọ̀rọ̀ sínú káàdì DPA wa, ká sì buwọ́ lù ú. Táwọn nǹkan kan nínú káàdì náà ò bá yé ẹ, ní káwọn alàgbà ìjọ ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Lóòótọ́, àwọn alàgbà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti lóye ohun tó wà nínú káàdì náà, àmọ́ àwọn kọ́ ló máa bá ẹ pinnu irú ìtọ́jú tó o máa gbà. Ìwọ fúnra ẹ lo máa ṣèpinnu yẹn. (Gál. 6:4, 5) Àmọ́ wọ́n máa ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa káàdì náà fún ẹ àti bó o ṣe máa kọ irú ìtọ́jú tó o fẹ́ sínú ẹ̀.

JẸ́ OLÓYE

17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ olóye tó bá dọ̀rọ̀ ìlera wa àti tàwọn ẹlòmíì?

17 Ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti fi Bíbélì kọ́ la fi ń pinnu bá a ṣe máa tọ́jú ara wa àti irú ìtọ́jú tá a máa gbà. (Ìṣe 24:16; 1 Tím. 3:9) Tá a bá ṣèpinnu kan, tá a sì fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ fáwọn ẹlòmíì, á dáa ká máa rántí ìlànà tó wà ní Fílípì 4:5 pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” Tá a bá jẹ́ olóye, a ò ní máa ṣàníyàn jù nípa ìlera wa tàbí ká máa fipá mú àwọn èèyàn pé kí wọ́n gba èrò wa tí wọ́n bá fẹ́ tọ́jú ara wọn. Àmọ́, tí ìpinnu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa bá yàtọ̀ sí tiwa, a ṣì máa ń nífẹ̀ẹ́ wọn, a sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn.​—Róòmù 14:10-12.

18. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa?

18 Jèhófà ni Orísun ìyè, a sì lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn tó fún wa yìí tá a bá ń tọ́jú ara wa dáadáa, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. (Ìfi. 4:11) Ní báyìí, a ṣì ń ṣàìsàn, àjálù sì ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe nǹkan tí Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀ sí wa nìyẹn. Láìpẹ́ ó máa fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, kò ní sí ìrora kankan mọ́, kò sì ní sí ikú mọ́. (Ìfi. 21:4) Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ní báyìí tá a ṣì wà láàyè, ẹ jẹ́ ká máa tọ́jú ara wa ká lè máa fayọ̀ sin Jèhófà Bàbá wa ọ̀run nìṣó!

ORIN 140 Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìn-Gbẹ́yín!

a Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká mọyì ẹ̀bùn ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa. A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a lè ṣe kí ara wa lè máa le, ká sì dàábò bo ara wa tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè yẹra fún àwọn nǹkan tó lè yọrí sí jàǹbá àtohun tá a lè ṣe láti múra sílẹ̀ de ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn.

c ÀWÒRÁN: Arákùnrin ọ̀dọ́ kan ń kọ̀rọ̀ sínú káàdì DPA ẹ̀, ó sì rí i pé òun mú un dání nígbà tó ń jáde.