Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó O Ṣe Lè Lo Ìkànnì Wa

Bó O Ṣe Lè Lo Ìkànnì Wa

Bó O Ṣe Lè Wá Àwọn Àpilẹ̀kọ Tó Máa Ń Wà Níbẹ̀rẹ̀ Jw.Org

Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló máa ń gbádùn àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa ń gbé síbẹ̀rẹ̀ ìkànnì jw.org, tí wọ́n sì máa ń lò ó lóde ìwàásù. Ìlujá àwọn àpilẹ̀kọ náà rọrùn láti fi ránṣẹ́ sáwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń jẹ́ ká rí i pé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé báyìí fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń ṣẹ. Arákùnrin kan sọ pé àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀rẹ̀ ìkànnì jw.org “la nílò gan-an lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa báyìí.”

Àmọ́ àtìgbàdégbà la máa ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ míì síbẹ̀. Torí náà, báwo lo ṣe lè rí àwọn àpilẹ̀kọ tó ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ tá a ti gbé kúrò?

  • Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkànnì jw.org, tẹ ìlujá “Wo Àwọn Míì.” Ìlujá yìí máa ṣí apá tá a pè ní “Àwọn Ohun Tó Jáde Láìpẹ́ Yìí.” Ibẹ̀ lo ti máa rí àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀rẹ̀ ìkànnì wa tẹ́lẹ̀, àmọ́ tá a ti gbé kúrò.

  • Lórí ìkànnì jw.org tàbí ní JW Library®, tẹ “Ohun Tá A Ní,” lẹ́yìn náà tẹ, “Ohun Tó Wà Lórí Ìkànnì,” kó o wá tẹ “Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò.” Nínú apá yìí, wàá rí púpọ̀ lára àwọn àpilẹ̀kọ tá a gbé síbẹ̀rẹ̀ ìkànnì jw.org tẹ́lẹ̀, àmọ́ tá a ti gbé kúrò.