Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 35

Ẹ Máa Ní Sùúrù

Ẹ Máa Ní Sùúrù

“Ẹ fi . . . sùúrù wọ ara yín láṣọ.”​—KÓL. 3:12.

ORIN 114 “Ẹ Máa Ní Sùúrù”

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí nìdí tó o fi mọyì àwọn tó jẹ́ onísùúrù?

 GBOGBO wa la mọyì àwọn tó bá jẹ́ onísùúrù. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n máa ń fi sùúrù dúró de nǹkan, nǹkan kì í sì í tètè sú wọn. Tá a bá ṣàṣìṣe, a máa ń mọyì ẹ̀ táwọn èèyàn bá ní sùúrù fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a mọyì báwọn tó kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ní sùúrù fún wa nígbà tí ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ wa ò tètè yé wa tàbí nígbà tó ṣòro fún wa láti gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì kan tàbí tí kò rọrùn láti fi í sílò. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, a máa ń mọyì ẹ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń ní sùúrù fún gbogbo wa!​—Róòmù 2:4.

2. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kó nira fún wa láti ní sùúrù?

2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń mọyì àwọn tó bá ní sùúrù, láwọn ìgbà míì, ó lè má rọrùn fún wa láti ní sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá wà nínú sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀, ó lè má rọrùn fún wa láti ní sùúrù pàápàá tá a bá ti ń pẹ́. Táwọn èèyàn bá múnú bí wa, a lè gbaná jẹ dípò ká ní sùúrù. Nígbà míì sì rèé, ó lè má rọrùn fún wa láti máa fi sùúrù dúró de ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí. Ṣé ó wù ẹ́ kó o túbọ̀ máa ní sùúrù? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ onísùúrù àti ìdí tí sùúrù fi ṣe pàtàkì. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ máa ní sùúrù.

KÍ LẸNI TÓ NÍ SÙÚRÙ MÁA Ń ṢE, KÍ NI KÌ Í SÌ Í ṢE?

3. Kí lẹni tó ní sùúrù kì í ṣe tí wọ́n bá múnú bí i?

3 Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mẹ́rin tí ẹni tó ní sùúrù máa ń ṣe. Àkọ́kọ́, ẹni tó ní sùúrù kì í tètè bínú. Táwọn èèyàn bá múnú bí i, ó máa ń ní sùúrù, kì í sì í gbẹ̀san. Yàtọ̀ síyẹn, tẹ́ni náà bá ní ìdààmú ọkàn, kì í kanra mọ́ àwọn èèyàn. Ìgbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà ló kọ́kọ́ mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ náà, “kì í tètè bínú.” Bíbélì sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.”​—Ẹ́kís. 34:6.

4. Kí lẹni tó ní sùúrù kì í ṣe tó bá ń retí ohun kan?

4 Ìkejì, ẹni tó ní sùúrù máa ń fi sùúrù dúró de nǹkan. Tí ẹni tó ní sùúrù bá ń dúró de nǹkan kan àmọ́ tí nǹkan náà ò tètè dé, kì í jẹ́ kí nǹkan tojú sú òun, kì í sì í kanra. (Mát. 18:26, 27) Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká ní sùúrù. Bí àpẹẹrẹ, ó lè gba pé ká fara balẹ̀ tẹ́tí sẹ́ni tó ń bá wa sọ̀rọ̀ kó sọ̀rọ̀ tán, káwa tó sọ̀rọ̀. (Jóòbù 36:2) Ó tún lè gba pé ká ní sùúrù fún ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí ohun tó ń kọ́ ò bá tètè yé e tàbí tí ò bá tíì fi àwọn ìwà tí ò dáa sílẹ̀.

5. Kí ni nǹkan míì tẹ́ni tó ní sùúrù kì í ṣe?

5 Ìkẹta, ẹni tó ní sùúrù kì í kánjú ṣe nǹkan. Ká sòótọ́, àwọn nǹkan kan lè ṣẹlẹ̀ tó máa gba pé ká tètè gbé ìgbésẹ̀. Àmọ́, tí ẹni tó ní sùúrù bá rí i pé ohun pàtàkì kan wà tóun gbọ́dọ̀ ṣe, kò ní kánjú bẹ̀rẹ̀ ẹ̀, kò sì ní máa kánjú kó lè tètè parí ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa rí i dájú pé òun fi àkókò tó pọ̀ tó ṣe nǹkan náà. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, á ṣe iṣẹ́ náà dáadáa.

6. Kí lẹni tó ní sùúrù máa ń ṣe tó bá níṣòro?

6 Ìkẹrin, ẹni tó ní sùúrù máa ń fara da ìṣòro láì ráhùn. Níbi tá a dé yìí, a máa rí i pé sùúrù àti ìfaradà jọra. Ká sòótọ́, tá a bá níṣòro, kò burú tá a bá sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa fún ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́. Àmọ́, ẹni tó ní sùúrù máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti fara da ìṣòro, kó sì máa láyọ̀. (Kól. 1:11) Torí náà, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ máa ní sùúrù láwọn ipò tá a sọ yìí. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìdí yẹn.

ÌDÍ TÍ SÙÚRÙ FI ṢE PÀTÀKÌ GAN-AN

Bí àgbẹ̀ kan ṣe máa ń ní sùúrù, tó sì dá a lójú pé òun máa kórè lọ́jọ́ kan, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká ní sùúrù, kó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ tó bá tó àkókò (Wo ìpínrọ̀ 7)

7.Jémíìsì 5:7, 8 ṣe sọ, kí nìdí tí sùúrù fi ṣe pàtàkì gan-an? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Ká tó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ní sùúrù. Bíi tàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́, ó ṣe pàtàkì káwa náà máa ní sùúrù títí dìgbà tí Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ sẹ. (Héb. 6:11, 12) Bíbélì fi àwa ìránṣẹ́ Jèhófà wé àgbẹ̀ kan. (Ka Jémíìsì 5:7, 8.) Àwọn àgbẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ kára láti gbin nǹkan, kí wọ́n sì bomi rin ín, àmọ́ wọn ò mọ ìgbà tí nǹkan náà máa dàgbà. Ṣe ni wọ́n máa ń ní sùúrù, ó sì dá wọn lójú pé àwọn máa kórè lọ́jọ́ kan. Bọ́rọ̀ tiwa náà ṣe rí nìyẹn. Ó yẹ ká tẹra mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run bó tiẹ̀ jẹ́ pé a “ò mọ ọjọ́ tí Olúwa [wa] ń bọ̀.” (Mát. 24:42) Torí náà, ó yẹ ká ní sùúrù kó sì dá wa lójú pé tó bá tó àkókò, Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Tá a bá dẹni tí ò ní sùúrù mọ́ torí pé ohun tá à ń dúró dè ò tètè dé, ó lè sú wa, ó sì lè jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀. A tún lè bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn nǹkan tá a rò pé ó lè mára tù wá lójú ẹsẹ̀. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù, á jẹ́ ká lè fara dà á dé òpin, àá sì rí ìgbàlà.​—Míkà 7:7; Mát. 24:13.

8. Báwo ni sùúrù ṣe lè jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn? (Kólósè 3:12, 13)

8 Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa ń jẹ́ ká fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. (Jém. 1:19) Sùúrù tún máa ń jẹ́ ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Kì í jẹ́ ká tètè fara ya tàbí sọ ohun tí ò dáa tá a bá ní ìdààmú ọkàn. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń ní sùúrù, tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó dùn wá, a ò ní tètè bínú. Dípò ká gbẹ̀san, ṣe làá ‘máa fara dà á fún ara wa, àá sì máa dárí ji ara wa fàlàlà.’​—Ka Kólósè 3:12, 13.

9. Báwo ni sùúrù ṣe lè jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́? (Òwe 21:5)

9 Tá a bá ń ní sùúrù, ó máa jẹ́ ká ṣe ìpinnu tó tọ́. Dípò ká kánjú ṣe ohun kan láì ro ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí, ṣe ló yẹ ká ṣèwádìí nípa nǹkan náà ká lè ṣèpinnu tó tọ́. (Ka Òwe 21:5.) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń wáṣẹ́, a lè fẹ́ gba iṣẹ́ tá a kọ́kọ́ rí, kódà tí iṣẹ́ náà ò bá ní jẹ́ ká ráyè lọ sípàdé àti òde ìwàásù déédéé. Àmọ́ tá a bá ní sùúrù, á jẹ́ ká ronú nípa ibi tí iṣẹ́ náà wà, iye wákàtí tí àá máa fi ṣiṣẹ́ àti àkóbá tí iṣẹ́ náà lè ṣe fún ìdílé wa àti ìjọsìn wa. Torí náà, tá a bá ń ní sùúrù, kò ní jẹ́ ká ṣe ìpinnu tí ò dáa.

BÁ A ṢE LÈ TÚBỌ̀ MÁA NÍ SÙÚRÙ

10. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè jẹ́ onísùúrù, kó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó?

10 Gbàdúrà kó o lè túbọ̀ máa ní sùúrù. Sùúrù wà lára ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. (Gál. 5:22, 23) Torí náà, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kó sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè ní àwọn ìwà yẹn. Tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó múnú bí wa, ó yẹ ká “máa béèrè” lọ́wọ́ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ ká lè ní sùúrù. (Lúùkù 11:9, 13) A tún lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká máa ní sùúrù bíi tiẹ̀. Lẹ́yìn tá a bá gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe àwọn nǹkan yìí fún wa, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ní sùúrù lójoojúmọ́. Tá a bá túbọ̀ ń gbàdúrà pé kí Jèhófà jẹ́ ká máa ní sùúrù, tá a sì ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ onísùúrù, kódà tó bá jẹ́ pé a ò kì í ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀.

11-12. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun ní sùúrù?

11 Máa ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó ní sùúrù ló wà nínú Bíbélì. Tá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn àpẹẹrẹ yẹn, àá kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn, àá sì mọ bó ṣe yẹ káwa náà máa ní sùúrù. Ká tó gbé díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ náà yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, ẹni tó ní sùúrù jù lọ láyé àti lọ́run.

12 Nínú ọgbà Édẹ́nì, Sátánì ba Jèhófà lórúkọ jẹ́, ó sì jẹ́ kí Éfà gbà pé Alákòóso tí ò dáa ni Jèhófà. Dípò kí Jèhófà pa abanijẹ́ yẹn run lójú ẹsẹ̀, ṣe ló ní sùúrù tó sì kó ara ẹ̀ níjàánu torí ó mọ̀ pé ó máa gba àkókò kóun tó lè fi hàn pé Alákòóso tó dáa jù lọ lòun. Ní gbogbo àsìkò tí Jèhófà fi ń dúró yìí, ó ti fara da ẹ̀gàn tí Sátánì ń kó bá orúkọ ẹ̀. Bákan náà, Jèhófà ti ń mú sùúrù tipẹ́, kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè láǹfààní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. (2 Pét. 3:9, 15) Ohun tí Jèhófà ṣe yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá mọ̀ ọ́n. Tá a bá ń wo àǹfààní tí sùúrù Jèhófà ń ṣe wá, á rọrùn fún wa láti máa ní sùúrù títí dìgbà tí òpin máa dé.

Tá a bá ń ní sùúrù, a ò ní tètè bínú tẹ́nì kan bá múnú bí wa (Wo ìpínrọ̀ 13)

13. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ní sùúrù bíi ti Bàbá òun? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Jésù náà máa ń ní sùúrù bíi ti Bàbá ẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó wà láyé. Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló rọrùn fún Jésù láti ní sùúrù, pàápàá nígbà tó gba pé kó ní sùúrù fáwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí alágàbàgebè. (Jòh. 8:25-27) Síbẹ̀, bíi ti Bàbá ẹ̀, Jésù kì í tètè bínú. Kò gbẹ̀san nígbà tí wọ́n kàn án lábùkù tàbí tí wọ́n múnú bí i. (1 Pét. 2:23) Nígbà tí Jésù ń fara da àwọn àdánwò tó dé bá a, ó ṣe sùúrù, kò sì ráhùn. Abájọ tí Bíbélì fi sọ fún wa pé ká “fara balẹ̀ ronú nípa ẹni tó fara da irú ọ̀rọ̀ kòbákùngbé bẹ́ẹ̀ láti ẹnu àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀”! (Héb. 12:2, 3) Jèhófà máa ran àwa náà lọ́wọ́ ká lè ní sùúrù bá a ṣe ń fara da àdánwò tó ń dé bá wa.

Tá a bá ń ní sùúrù bíi ti Ábúráhámù, á dá wa lójú pé Jèhófà máa san èrè fún wa báyìí, á sì tún san èrè tó jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ayé tuntun tó ṣèlérí (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí la rí kọ́ lára Ábúráhámù bó ṣe fi sùúrù dúró de Jèhófà? (Hébérù 6:15) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Tó bá jẹ́ pé ó ti pẹ́ tá a ti ń dúró kí òpin dé, àmọ́ tí kò dé ńkọ́? Ẹ̀rù lè máa bà wá pé a lè má sí láyé mọ́ nígbà tí òpin bá dé. Kí lá jẹ́ ká máa fi sùúrù dúró dè é? Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù yẹ̀ wò. Nígbà tó pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75), tí kò sì lọ́mọ kankan, Jèhófà ṣèlérí fún un pé: “Màá mú kí o di orílẹ̀-èdè ńlá.” (Jẹ́n. 12:1-4) Ṣé Ábúráhámù rí ìlérí yẹn nígbà tó ṣẹ? Rárá, àmọ́ ó rí díẹ̀ lára ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tó sọdá Odò Yúfírétì, tó sì ti dúró kí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) kọjá, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí Jèhófà jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ bí Ísákì lọ́nà ìyanu. Ọgọ́ta ọdún (60) lẹ́yìn náà, ó ṣojú ẹ̀ nígbà tí wọ́n bí àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀, ìyẹn Ísọ̀ àti Jékọ́bù. (Ka Hébérù 6:15.) Àmọ́, Ábúráhámù ò sí láyé mọ́ nígbà táwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ di orílẹ̀-èdè ńlá, tí wọ́n sì gba Ilẹ̀ Ìlérí. Síbẹ̀, ọkùnrin olóòótọ́ yìí ò fi Ẹlẹ́dàá ẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ sílẹ̀. (Jém. 2:23) Ẹ wo bí inú Ábúráhámù ṣe máa dùn tó nígbà tó bá jíǹde, tó sì mọ̀ pé ìgbàgbọ́ àti sùúrù tóun ní ló jẹ́ kí Jèhófà bù kún gbogbo aráyé! (Jẹ́n. 22:18) Kí la rí kọ́? Ohun tá a kọ́ ni pé gbogbo ìlérí tí Jèhófà ṣe lè má ṣẹ lójú wa. Àmọ́, tá a bá ní sùúrù bíi ti Ábúráhámù, ó dájú pé Jèhófà máa san èrè fún wa báyìí, á sì tún san èrè tó jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú ayé tuntun tó ṣèlérí.​—Máàkù 10:29, 30.

15. Àwọn nǹkan wo la lè fi dá kẹ́kọ̀ọ́?

15 Àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run míì tó ní sùúrù wà nínú Bíbélì. (Jém. 5:10) O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn nígbà tó o bá fẹ́ dá kẹ́kọ̀ọ́? b Bí àpẹẹrẹ, ìgbà tí Dáfídì ṣì kéré gan-an ni Jèhófà ti ní kí wọ́n yàn án láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún ló fi dúró kó tó di ọba. Síméónì àti Ánà náà jọ́sìn Jèhófà tọkàntọkàn lásìkò tí wọ́n ń dúró kí Mèsáyà dé. (Lúùkù 2:25, 36-38) Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtàn Bíbélì yẹn, wá ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló jẹ́ kí ẹni yìí ní sùúrù? Àǹfààní wo lẹni náà rí torí pé ó ní sùúrù? Báwo ni mo ṣe lè fara wé e? Bákan náà, tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tí kò ní sùúrù, wàá jàǹfààní. (1 Sám. 13:8-14) O lè bi ara ẹ pé: ‘Kí ni ò jẹ́ kí wọ́n ní sùúrù? Àwọn nǹkan burúkú wo ló ṣẹlẹ̀ sí wọn torí pé wọn ò ní sùúrù?’

16. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ní sùúrù?

16 Wo àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń ní sùúrù. Tá a bá ń ní sùúrù, a máa láyọ̀, ọkàn wa sì máa balẹ̀. Torí náà, sùúrù máa ń jẹ́ ká ní ìlera tó jí pépé. Tá a bá ń ní sùúrù fáwọn èèyàn, àárín wa á túbọ̀ gún régé, ìyẹn sì máa jẹ́ káwọn ará ìjọ túbọ̀ wà níṣọ̀kan. Tẹ́nì kan bá múnú bí wa, àmọ́ tá ò tètè bínú, kò ní jẹ́ kọ́rọ̀ náà dìjà. (Sm. 37:8, àlàyé ìsàlẹ̀; Òwe 14:29) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé tá a bá ń ní sùúrù, ṣe là ń fara wé Bàbá wa ọ̀run, àá sì túbọ̀ sún mọ́ ọn.

17. Kí la pinnu pé àá máa ṣe?

17 Ẹ ò rí i pé ìwà tó dáa gan-an ni sùúrù, ó sì ń ṣeni láǹfààní! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ní sùúrù, tá a bá bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, àá máa ní sùúrù. Bákan náà, bá a ṣe ń ní sùúrù kí ayé tuntun dé, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé “ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.” (Sm. 33:18) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa fi sùúrù wọ ara wa láṣọ.

ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi

a Nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í ní sùúrù. Àmọ́, Bíbélì sọ fún wa pé ká fi sùúrù wọ ara wa láṣọ. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí ìdí tí sùúrù fi ṣe pàtàkì àti bá a ṣe lè túbọ̀ máa ní sùúrù.

b Kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn tó ní sùúrù, lọ wo àkọlé náà “Sùúrù” nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2019.