Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

1923—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

1923—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn

ILÉ ÌṢỌ́ January 1, 1923 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “A retí pé ọ̀pọ̀ ohun rere ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1923. Àǹfààní ńlá la ní láti wàásù fáwọn tí wọ́n ń ni lára . . . tá a sì ń jẹ́ kó dá wọn lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.” Torí náà, ọdún 1923 máa fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níṣìírí torí pé bí wọ́n ṣe ń jọ́sìn, tí wọ́n sì ń wàásù jẹ́ kí wọ́n wà níṣọ̀kan, ìyẹn sì fi hàn pé ìjọsìn tòótọ́ là ń ṣe.

WỌ́N Ń JỌ́SÌN JÈHÓFÀ NÍṢỌ̀KAN

Kàlẹ́ńdà tí wọ́n kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì àti nọ́ńbà orin sí

Ní ọdún yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àwọn àyípadà kan kí wọ́n lè máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọ́n máa ń ṣe Ìpàdé Àdúrà, Ìrírí àti Orin. Torí náà, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn àlàyé ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n máa ń kà níbi ìpàdé yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń ṣe kàlẹ́ńdà tí wọ́n kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n máa ń kà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ sí, pẹ̀lú orin téèyàn lè kọ tó bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí tó bá ń ṣe ìjọsìn ìdílé.

Láwọn ìpàdé yẹn, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n máa ń dúpẹ́ oore tí Jèhófà ṣe fún wọn, wọ́n máa ń kọrin, kódà wọ́n máa ń gbàdúrà. Arábìnrin Eva Barney tó jẹ́ ọmọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ́dún 1923 nígbà tó ṣèrìbọmi sọ pé: “Tó o bá fẹ́ sọ ìrírí, wàá dìde, lẹ́yìn náà wàá sọ pé, ‘mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa torí gbogbo oore tó ṣe fún mi.’” Àwọn ará kan fẹ́ràn kí wọ́n máa sọ ìrírí wọn. Arábìnrin Barney tún sọ pé: “Arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Godwin máa ń fẹ́ sọ ọ̀pọ̀ nǹkan láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa. Àmọ́ tí ìyàwó arákùnrin náà bá ti rí i pé ara arákùnrin tó ń darí ìpàdé ò balẹ̀ mọ́, á rọra fọwọ́ kan aṣọ ọkọ ẹ̀, ìgbà yẹn lọkọ ẹ̀ máa wá jókòó.”

Lẹ́ẹ̀kan lóṣù, wọ́n máa ń ṣe àkànṣe Ìpàdé Àdúrà, Ìrírí àti Orin. Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ April 1, 1923 lédè Gẹ̀ẹ́sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìpàdé yìí, ó ní: “Ohun tí wọ́n máa ń fi ìdajì ìpàdé náà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni ìrírí táwọn ará ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì tún máa ń gbóríyìn fún wọn. . . . A mọ̀ pé ìpàdé yìí máa jẹ́ káwọn ará túbọ̀ sún mọ́ra gan-an.”

Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ni Arákùnrin Charles Martin tó wá láti ìlú Vancouver, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Akéde ni, ó sì máa ń jàǹfààní gan-an níbi ìpàdé yìí. Nígbà tó yá, ó sọ pé: “Ibẹ̀ ni mo ti kọ́ ohun tí mo máa ń sọ lẹ́nu ọ̀nà tí mo bá fẹ́ wàásù. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ará máa ń sọ ìrírí tí wọ́n ní tí wọ́n bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n mọ ohun tí màá sọ àti bí mo ṣe lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá bi mí.”

IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ JẸ́ KÁWỌN ARÁ WÀ NÍṢỌ̀KAN

Bulletin ti May 1, 1923

“Àwọn ọjọ́ ìwàásù” tún máa ń jẹ́ káwọn ará wà níṣọ̀kan. Ilé Ìṣọ́ April 1, 1923 lédè Gẹ̀ẹ́sì kéde pé: “Kí gbogbo wa lè wà níṣọ̀kan lẹ́nu iṣẹ́ yìí . . . , a fẹ́ kí gbogbo wa jáde ní Tuesday, May 1, 1923 ká lè lọ wàásù. Lẹ́yìn ìyẹn, kí gbogbo wa rí i pé à ń wá sóde ìwàásù ní gbogbo ọjọ́ Tuesday àkọ́kọ́ nínú oṣù . . . Gbogbo akéde ìjọ ló sì yẹ kí wọ́n kópa nínú iṣẹ́ náà.”

Kódà, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ máa ń kópa nínú iṣẹ́ yìí. Arábìnrin Hazel Burford tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16) péré nígbà yẹn sọ pé: “Ìwé Bulletin máa ń jẹ́ ká mọ ohun tá a lè bá àwọn èèyàn sọ tá a bá ń wàásù (ó jọ ohun tó máa ń wà nínú ìwé ìpàdé wa báyìí). a Èmi àti bàbá ìyàwó dádì mi sì máa ń fìtara wàásù déédéé.” Àmọ́, ó ya Arábìnrin Burford lẹ́nu nígbà tí arákùnrin àgbàlagbà kan sọ fún un pé kò yẹ kó wàásù. Ó ní: “Arákùnrin àgbàlagbà yẹn sọ pé kò yẹ kí n bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ rárá lóde ìwàásù. Nígbà yẹn, kì í ṣe gbogbo àwọn ará ló mọ̀ pé gbogbo àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, títí kan àwọn ‘ọ̀dọ́kùnrin àti àwọn ọ̀dọ́bìnrin’ ló yẹ kó máa yin Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa.” (Sm. 148:12, 13) Àmọ́, Arábìnrin Burford ṣì ń fìtara wàásù nìṣó. Kódà, ó lọ sí kíláàsì kejì ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ó sì di míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Panama. Nígbà tó yá, àwọn ará yẹn yí èrò wọn pa dà, wọn ò sì sọ pé káwọn ọ̀dọ́ má wàásù mọ́.

ÀWỌN ÀPÉJỌ WA MÚ KÁWỌN ARÁ WÀ NÍṢỌ̀KAN

Àwọn àpéjọ agbègbè tá à ń ṣe ń mú káwọn ará wà níṣọ̀kan. Láwọn àpéjọ yẹn, a máa ń dìídì ṣètò àwọn ọjọ́ tí gbogbo àwọn ará fi máa wàásù. A ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà àpéjọ tá a ṣe nílùú Winnipeg, lórílẹ̀-èdè Kánádà. Bí àpẹẹrẹ, ní March 31, wọ́n sọ pé kí gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ yẹn jáde lọ wàásù. Àwọn ọjọ́ tá a dìídì ṣètò fún iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ káwọn ará tó pọ̀ jáde, àwọn èèyàn sì máa ń gbọ́ ìwàásù dáadáa. Ní August 5, àwọn èèyàn tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ló wá sí àpéjọ míì tá a ṣe nílùú Winnipeg. Nígbà yẹn, iye àwọn tó wá sí àpéjọ yìí ló pọ̀ jù lọ ní gbogbo àpéjọ tí wọ́n ti ṣe ní Kánádà.

Àpéjọ tó ṣe pàtàkì jù táwa èèyàn Jèhófà ṣe lọ́dún 1923 ni èyí tá a ṣe ní August 18-26, nílùú Los Angeles, ní California. Láwọn ọ̀sẹ̀ tó ṣáájú àpéjọ yẹn, àwọn ìwé ìròyìn gbé e jáde pé wọ́n fẹ́ ṣe àpéjọ kan, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì fi ìwé ìkésíni tó lé ní ìdajì mílíọ̀nù (500,000) pe àwọn èèyàn wá síbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún lẹ àkòrí àpéjọ yẹn mọ́ àwọn mọ́tò akérò àtàwọn mọ́tò àdáni.

Àpéjọ táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nílùú Los Angeles, lọ́dún 1923

Ní Saturday, August 25, Arákùnrin Rutherford sọ àsọyé kan tí àkòrí ẹ̀ jẹ́ “Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́.” Ó sọ nínú àsọyé yẹn pé àwọn “àgùntàn” ni àwọn olódodo tó máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè. Ó tún ka ìpinnu tí wọ́n ṣe tó pè ní “Ìkìlọ̀.” Nígbà tí Arákùnrin Rutherford ń ka ìkìlọ̀ yẹn, ó tú àṣírí àwọn Kristẹndọm, ó sì gba àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ níyànjú pé kí wọ́n kúrò nínú “Bábílónì Ńlá.” (Ìfi. 18:2, 4) Nígbà tó yá, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé pín ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìwé tí wọ́n fi kéde ìkìlọ̀ yẹn fáwọn èèyàn.

“Bí àwọn ará ṣe ń wàásù pa pọ̀ ń jẹ́ kí gbogbo wọn wà níṣọ̀kan”

Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ náà, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) ló gbọ́ àsọyé tí Arákùnrin Rutherford sọ. Àkòrí ẹ̀ ni: “Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Máa Kóra Jọ Nígbà Amágẹ́dọ́nì, àmọ́ Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.” Torí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mọ̀ pé àwọn tó máa wá máa pọ̀ gan-an, wọ́n lọ háyà pápá ìṣeré tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sílùú Los Angeles. Kí gbogbo èèyàn lè gbọ́ ohun táwọn alásọyé bá sọ, ẹ̀rọ gbohùngbohùn tó wà ní pápá ìṣeré yẹn ni wọ́n lò, òun sì ni ẹ̀rọ tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde nígbà yẹn. Yàtọ̀ sí èrò rẹpẹtẹ tó wá síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló tún gbọ́ ohun tí wọ́n sọ nípàdé náà lórí rédíò.

IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ Ń GBÒÒRÒ SÍ I KÁRÍ AYÉ

Lọ́dún 1923, iṣẹ́ ìwàásù wa tẹ̀ síwájú gan-an nílẹ̀ Áfíríkà, Yúróòpù, Íńdíà àti South America. Nílẹ̀ Íńdíà, Arákùnrin A. J. Joseph ló ń bójú tó bí wọ́n ṣe ń tẹ àwọn ìwé wa lédè Hindi, Tamil, Telugu àti Urdu, ó sì tún ń bójú tó ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́fà.

William R. Brown àti ìdílé ẹ̀

Lórílẹ̀-èdè Sierra Leone, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tórúkọ wọn ń jẹ́ Alfred Joseph àti Leonard Blackman kọ̀wé sí oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York pé kí wọ́n rán àwọn èèyàn láti wá ran àwọn lọ́wọ́. Wọ́n dá wọn lóhùn ní April 14, 1923. Arákùnrin Alfred sọ pé: “Lálẹ́ ọjọ́ Saturday kan, ẹnì kan tí mi ò retí pè mí lórí fóònù.” Ẹni tó pè é bi í pé, “Ṣé ìwọ lo pe Watch Tower Society pé kí wọ́n rán àwọn oníwàásù wá?” Alfred sọ pé “Bẹ́ẹ̀ ni.” Ẹni náà wá sọ pé “Ó dáa, èmi ni wọ́n rán wá o.” Arákùnrin William R. Brown sì lẹni náà. Ọjọ́ yẹn ló dé láti agbègbè Caribbean pẹ̀lú Antonia ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin wọn méjì tó ń jẹ́ Louise àti Lucy. Kò ní pẹ́ rárá táwọn ará fi máa rí Arákùnrin Brown àti ìdílé ẹ̀.

Alfred ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Láàárọ̀ ọjọ́ kejì nígbà témi àti Leonard ń ka Bíbélì tá a máa ń kà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ṣàdédé la rí ọkùnrin kan tó fìrìgbọ̀n lẹ́nu ọ̀nà wa. Arákùnrin Brown ni. Ìtara ẹ̀ pọ̀ débi pé ó fẹ́ sọ àsọyé lọ́jọ́ kejì.” Kí oṣù kan tó parí, Arákùnrin Brown ti fún àwọn èèyàn ní gbogbo ìwé tó kó wá. Kò pẹ́ sígbà yẹn, wọ́n fi ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìwé míì ránṣẹ́ sí i, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ó tún ti ń béèrè ìwé míì. Àmọ́, kì í ṣe ojú ẹni tó ń ta ìwé làwọn èèyàn fi ń wo Arákùnrin Brown o. Jálẹ̀ gbogbo àsìkò tó fi ṣiṣẹ́ Jèhófà pẹ̀lú ìtara, Bíbélì ló máa ń fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ẹ̀, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pè é ní Bible Brown.

Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Magdeburg láwọn ọdún 1920

Bákan náà, àwọn ará tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà nílùú Barmen lórílẹ̀-èdè Jámánì ti pọ̀ gan-an. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba ilẹ̀ Faransé ń halẹ̀ pé àwọn máa gba ìlú yẹn mọ́ Jámánì lọ́wọ́. Torí náà, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí ilé ńlá kan tó dáa gan-an nílùú Magdeburg tí wọ́n ti lè máa tẹ àwọn ìwé wa. Nígbà tó fi máa di June 19, àwọn ará ti kó gbogbo ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń tẹ̀wé, títí kan àwọn àga, tábìlì àtàwọn nǹkan míì lọ sí Bẹ́tẹ́lì tuntun tó wà ní Magdeburg. Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé ọjọ́ tí wọ́n sọ fún oríléeṣẹ́ pé àwọn ti kẹ́rù tán, ìwé ìròyìn gbé e jáde pé ilẹ̀ Faransé ti gba ìlú Barmen pátápátá. Àwọn ará wá rí i kedere pé Jèhófà ló dìídì ran àwọn lọ́wọ́, tó sì dáàbò bo àwọn.

George Young àti Sarah Ferguson (lápá ọ̀tún) pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n ẹ̀ obìnrin

Arákùnrin George Young máa ń rìnrìn àjò káàkiri láti lọ wàásù. Torí náà, lórílẹ̀-èdè Brazil, ó dá ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sílẹ̀ níbẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lédè Potogí. Láàárín oṣù díẹ̀, ìwé tó ju ẹgbẹ̀rún méje (7,000) lọ ló fún àwọn èèyàn. Inú Arábìnrin Sarah Ferguson dùn gan-an nígbà tí Arákùnrin Young dé orílẹ̀-èdè Brazil. Ìdí sì ni pé àtọdún 1899 ló ti ń ka Ilé Ìṣọ́, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún un láti ṣèrìbọmi lẹ́yìn tó ya ara ẹ̀ sí mímọ́. Torí náà, lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Arábìnrin Ferguson àtàwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láǹfààní láti ṣèrìbọmi.

“Ẹ JẸ́ KÁ MÁA FAYỌ̀ SIN JÈHÓFÀ NÌṢÓ”

Bí ọdún 1923 ṣe ń parí lọ, Ilé Ìṣọ́ December 15, 1923 sọ àǹfààní tó wà nínú bí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan, ó ní: “A ti rí i kedere pé àwọn ará tó wà nínú ìjọ nígbàgbọ́ tó lágbára . . . Torí náà, bá a ṣe fẹ́ wọnú ọdún 1924, ẹ jẹ́ ká wà lójúfò, ká máa fìtara wàásù, ká sì máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.”

Ọ̀pọ̀ nǹkan rere làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Ọ̀pọ̀ oṣù làwọn ará ní Bẹ́tẹ́lì ti ń ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ kan tó wà ní Staten Island, ibẹ̀ ò sì fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn. Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1924 ni wọ́n parí àwọn ilé tí wọ́n kọ́ sórí ilẹ̀ tuntun yẹn. Iṣẹ́ náà jẹ́ kí gbogbo àwọn ará wà níṣọ̀kan, ó sì jẹ́ kí wọ́n wàásù dé àwọn ibi tí wọn ò dé rí.

Àwọn tó ń kọ́lé ètò Ọlọ́run ní Staten Island

a Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni là ń pè é báyìí.