Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 42

Ṣé O “Ṣe Tán Láti Ṣègbọràn”?

Ṣé O “Ṣe Tán Láti Ṣègbọràn”?

“Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . ṣe tán láti ṣègbọràn.”—JÉM. 3:17.

ORIN 101 À Ń Ṣiṣẹ́ Níṣọ̀kan

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1. Kí nìdí tó fi máa ń nira fún wa láti ṣègbọràn?

 NÍGBÀ míì, ṣé ó máa ń nira fún ẹ láti ṣègbọràn? Ó nira fún Ọba Dáfídì náà láti ṣègbọràn láwọn ìgbà kan, ìdí nìyẹn tó fi gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Jẹ́ kó máa wù mí láti ṣègbọràn sí ọ.” (Sm. 51:12) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa ń nira fún un láti ṣègbọràn, bọ́rọ̀ tiwa náà sì ṣe rí nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé àìpé tá a jogún ń mú ká ṣàìgbọràn. Ìkejì, Sátánì máa ń fẹ́ ká ṣọ̀tẹ̀ bíi tiẹ̀. (2 Kọ́r. 11:3) Ìkẹta, ìwà tinú mi ni màá ṣe ló pọ̀ nínú ayé lónìí, ìyẹn ni Bíbélì pè ní “ẹ̀mí tó ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ aláìgbọràn.” (Éfé. 2:2) Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti borí àwọn nǹkan tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀, ká má sì jẹ́ kí Èṣù àti ayé burúkú yìí mú ká ṣàìgbọràn. Àmọ́, ó yẹ ká sapá gan-an láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tó wà nípò àṣẹ.

2. Kí ni Bíbélì sọ pé ká ṣe nígbà tó ní ká “ṣe tán láti ṣègbọràn”? (Jémíìsì 3:17)

2 Ka Jémíìsì 3:17. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Jémíìsì láti sọ pé àwọn tó gbọ́n máa ń “ṣe tán láti ṣègbọràn.” Kí ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ? Ohun tó ń sọ ni pé ó yẹ kó yá wa lára, kó sì máa wù wá láti ṣègbọràn sáwọn tí Jèhófà fún láǹfààní láti wà nípò àṣẹ. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà ò retí pé ká ṣègbọràn sẹ́nikẹ́ni tó bá sọ pé ká ṣe ohunkóhun tó ta ko ìlànà ẹ̀.—Ìṣe 4:18-20.

3. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ó ṣe pàtàkì ká máa ṣègbọràn sáwọn tó fún láǹfààní láti wà nípò àṣẹ?

3 Ó túbọ̀ máa ń rọrùn fún wa láti ṣègbọràn sí Jèhófà ju èèyàn lọ. Ìdí sì ni pé ìtọ́sọ́nà Jèhófà pé. (Sm. 19:7) Àmọ́, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá torí aláìpé ni wọ́n. Síbẹ̀, Bàbá wa ọ̀run fún àwọn òbí, àwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn alàgbà nínú ìjọ láṣẹ dé àyè kan. (Òwe 6:20; 1 Tẹs. 5:12; 1 Pét. 2:13, 14) Tá a bá ń ṣègbọràn sí wọn, Jèhófà là ń ṣègbọràn sí yẹn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè máa ṣègbọràn sáwọn tó wà nípò àṣẹ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì ó lè nira fún wa láti ṣe ohun tí wọ́n sọ.

MÁA GBỌ́RÀN SÁWỌN ÒBÍ Ẹ LẸ́NU

4. Kí nìdí táwọn ọmọ kan fi máa ń ṣàìgbọràn sáwọn òbí wọn?

4 Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń wà pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ míì tó máa ń ‘ṣàìgbọràn sí òbí’ wọn. (2 Tím. 3:1, 2) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ lára wọn fi ń ṣàìgbọràn? Àwọn ọ̀dọ́ kan gbà pé alágàbàgebè ni òbí àwọn torí wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n sọ pé káwọn máa ṣe. Àwọn ọ̀dọ́ míì sì gbà pé ìmọ̀ràn òbí àwọn ò bágbà mu mọ́, kò bọ́gbọ́n mu, ó sì ti le jù. Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, ṣé ìwọ náà ti ronú bẹ́ẹ̀ rí? Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń nira fún láti tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà tó sọ pé: “Ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo.” (Éfé. 6:1) Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu?

5.Lúùkù 2:46-52 ṣe sọ, kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ọ̀dọ́ tó bá kan kí wọ́n máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu?

5 Ẹ̀yin ọ̀dọ́ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ rere Jésù nípa bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ jẹ́ onígbọràn. (1 Pét. 2:21-24) Ẹni pípé ni Jésù, àmọ́ aláìpé làwọn òbí ẹ̀. Síbẹ̀, Jésù máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ̀, kódà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe tàbí tí wọ́n bá ṣì í lóye nígbà míì. (Ẹ́kís. 20:12) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wà lọ́mọ ọdún méjìlá (12). (Ka Lúùkù 2:46-52.) Nígbà táwọn òbí ẹ̀ ń pa dà sílé láti Jerúsálẹ́mù, wọn ò mọ̀ pé Jésù ò tẹ̀ lé àwọn. Ojúṣe Jósẹ́fù àti Màríà ni láti rí i dájú pé gbogbo àwọn ọmọ wọn wà lára àwọn tí wọ́n jọ ń rìn pa dà sílé lẹ́yìn àjọyọ̀ náà. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jósẹ́fù àti Màríà pa dà rí Jésù, ńṣe ni Màríà dá Jésù lẹ́bi pé òun ló kó àwọn sí wàhálà! Jésù lè sọ pé bí wọ́n ṣe dá òun lẹ́bi yẹn ò dáa. Ṣùgbọ́n kò ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló dá wọn lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́, ó sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ‘ohun tí Jésù ń sọ fún Jósẹ́fù àti Màríà ò yé wọn,’ síbẹ̀ ó ṣì “ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu.”

6-7. Kí ló máa ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu?

6 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ó máa ń nira fún yín láti gbọ́ràn sáwọn òbí yín lẹ́nu tí wọ́n bá ṣàṣìṣe tàbí tí wọ́n ṣì yín lóye? Kí ló máa ràn yín lọ́wọ́? Àkọ́kọ́, ronú nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà. Bíbélì sọ pé tó o bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí ẹ, “èyí dára gidigidi lójú Olúwa.” (Kól. 3:20) Jèhófà mọ̀ pé nígbà míì, àwọn òbí ẹ lè má lóye ẹ, wọ́n sì lè ṣe àwọn òfin kan tó lè má rọrùn fún ẹ láti tẹ̀ lé. Àmọ́ tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, inú Jèhófà máa dùn sí ẹ.

7 Ìkejì, ronú nípa bí nǹkan ṣe máa rí lára àwọn òbí ẹ. Tó o bá ń gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu, inú wọn máa dùn sí ẹ, wọ́n á sì fọkàn tán ẹ. (Òwe 23:22-25) Á tún ṣeé ṣe fún ẹ láti túbọ̀ sún mọ́ wọn. Arákùnrin Alexandre tó wá láti orílẹ̀-èdè Belgium sọ pé: “Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ràn sáwọn òbí mi lẹ́nu ni àárín wa túbọ̀ gún régé. A wá nífẹ̀ẹ́ ara wa sí i, inú wa sì ń dùn.” b Ìkẹta, ronú nípa àǹfààní tó o máa rí lọ́jọ́ iwájú tó o bá ń gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu báyìí. Arákùnrin Paulo tó ń gbé ní Brazil sọ pé: “Bí mo ṣe kọ́ láti máa ṣègbọràn sáwọn òbí mi ti jẹ́ kí n máa ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tó fún láǹfààní láti wà nípò àṣẹ.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ lẹ́nu. Ó sọ pé: “Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí o sì lè pẹ́ láyé.”—Éfé. 6:2, 3.

8. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi máa ń gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu?

8 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti rí i pé nǹkan máa ń lọ dáadáa fún àwọn táwọn bá gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu. Ó ṣòro fún Luiza tó wá láti orílẹ̀-èdè Brazil láti lóye ìdí táwọn òbí ẹ̀ ò fi jẹ́ kó lo fóònù láwọn àkókò kan. Ó sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ojúgbà òun ló ní fóònù. Nígbà tó yá, ó wá mọ̀ pé ńṣe làwọn òbí òun ń dáàbò bo òun. Ní báyìí, ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń ṣe ohun táwọn òbí mi sọ jẹ́ kí n rí i pé wọn ò ká mi lọ́wọ́ kò torí pé ìmọ̀ràn wọn ń ṣe mí láǹfààní.” Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fún Arábìnrin Elizabeth tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láti máa gbọ́ràn sáwọn òbí ẹ̀ lẹ́nu. Ó sọ pé: “Tí mi ò bá tiẹ̀ mọ ìdí táwọn òbí mi fi ṣe àwọn òfin kan, mo máa ń ronú nípa bí àwọn òfin tí wọ́n ṣe sẹ́yìn ṣe dáàbò bò mí.” Arábìnrin Monica tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Àméníà sọ pé nǹkan máa ń lọ dáadáa fóun tí òun bá gbọ́ràn sáwọn òbí òun lẹ́nu, àmọ́ tóun bá ṣàìgbọràn, nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa.

MÁA ṢÈGBỌRÀN SÍ “ÀWỌN ALÁṢẸ ONÍPÒ GÍGA”

9. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó bá di pé kí wọ́n pa òfin mọ́?

9 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé a nílò ìjọba táá máa ṣàkóso wa àti pé ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn òfin kan tí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” yìí bá ṣe. (Róòmù 13:1) Àmọ́ táwọn èèyàn yìí bá rí i pé àwọn òfin kan ò tẹ́ àwọn lọ́rùn tàbí tí wọ́n rí i pé ó nira, wọn kì í pa á mọ́. Àpẹẹrẹ kan ni owó orí. Ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lórílẹ̀-èdè kan ní Yúróòpù sọ pé: “Kò yẹ kéèyàn san owó orí tó bá rò pé owó tí wọ́n ní kóun san ti pọ̀ jù.” Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé ìdá kan nínú mẹ́ta owó orí tó yẹ kó máa wọlé sápò ìjọba ni wọn ò rí gbà.

Kí la kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà bí wọ́n ṣe jẹ́ onígbọràn? (Wo ìpínrọ̀ 10-12) c

10. Kí nìdí tá a fi máa ń ṣègbọràn tá ò bá tiẹ̀ fara mọ́ àwọn òfin kan?

10 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìjọba èèyàn máa ń ṣe ohun tó ń pa àwọn aráàlú lára, ó sì sọ pé Sátánì ló ń darí àwọn ìjọba yẹn àti pé wọ́n máa pa run láìpẹ́. (Sm. 110:5, 6; Oníw. 8:9; Lúùkù 4:5, 6) Ó tún sọ fún wa pé “ẹni tó bá ta ko aláṣẹ ta ko ètò tí Ọlọ́run ṣe.” Ní báyìí, Jèhófà ṣì fàyè gba ìjọba èèyàn láti máa ṣàkóso kí nǹkan lè wà létòlétò, ó sì retí pé ká máa ṣègbọràn sí wọn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ “fún gbogbo èèyàn ní ohun tí ó tọ́ sí wọn,” ìyẹn ni pé ká máa san owó orí, ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn, ká sì máa pa òfin wọn mọ́. (Róòmù 13:1-7) Lóòótọ́, òfin kan lè nira, ó lè má tẹ́ wa lọ́rùn tàbí kó ṣòro fún wa láti pa mọ́. Àmọ́, a máa ń ṣègbọràn torí Jèhófà ló sọ pé ká ṣe bẹ́ẹ̀, tí òfin tí wọ́n ṣe ò bá ṣáà ti ta ko òfin Jèhófà.—Ìṣe 5:29.

11-12. Kí ni Lúùkù 2:1-6 sọ pé Jósẹ́fù àti Màríà ṣe láti pa òfin ìjọba mọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn, kí nìyẹn sì yọrí sí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà tí wọ́n ṣègbọràn sí ìjọba bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn. (Ka Lúùkù 2:1-6.) Nígbà tí oyún inú Màríà pé nǹkan bí oṣù mẹ́sàn-án, ìjọba ṣòfin kan tí ò rọrùn fún wọn láti pa mọ́. Augustus tó ń ṣàkóso Ìjọba Róòmù pàṣẹ pé kí gbogbo èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀ nílùú ìbílẹ̀ wọn. Torí náà, Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò gba òkè gbágungbàgun lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìrìn àjò náà sì tó nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà (150). Ó dájú pé ìrìn àjò yẹn ò lè rọrùn, pàápàá fún Màríà. Ẹ̀rù lè máa ba àwọn méjèèjì torí wọn ò fẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Màríà àti oyún inú ẹ̀. Wọ́n lè máa ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí Màríà bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí lójú ọ̀nà. Ìdí sì ni pé oyún Mèsáyà tí gbogbo èèyàn ń dúró dè ló wà nínú ẹ̀. Ṣéyẹn á wá mú kí wọ́n má ṣègbọràn síjọba?

12 Jósẹ́fù àti Màríà ò jẹ́ káwọn nǹkan yẹn dí wọn lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí òfin yẹn. Inú Jèhófà dùn sí wọn, ó sì jẹ́ kí ìrìn àjò wọn yọrí sí rere. Màríà dé sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láyọ̀ àti àlàáfíà, ó bí ọmọ náà wẹ́rẹ́, ó sì ṣe ohun tó mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ!—Míkà 5:2.

13. Tá a bá ń pa òfin ìjọba mọ́, àǹfààní wo la máa rí?

13 Tá a bá ń ṣègbọràn síjọba, ó máa ṣe àwa àtàwọn míì láǹfààní. Lọ́nà wo? Àǹfààní kan ni pé a ò ní sí lára àwọn tí ìjọba máa fìyà jẹ torí pé wọ́n ṣàìgbọràn. (Róòmù 13:4) Tá a bá ń ṣègbọràn sófin ìjọba, wọ́n á rí i pé èèyàn dáadáa làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé a máa ń pa òfin ìjọba mọ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwọn sójà wọnú Ilé Ìpàdé kan nígbà táwọn ará ń ṣèpàdé lọ́wọ́, wọ́n ń wá àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn torí owó orí tí ìjọba ní kí wọ́n san. Àmọ́, ọ̀gá àwọn sójà náà ní kí wọ́n kúrò níbẹ̀. Ó ní: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń san owó orí wọn.” Torí náà, tó o bá ń pa òfin ìjọba mọ́, ìyẹn ò ní jẹ́ kí orúkọ rere táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní bà jẹ́. Ó sì lè dáàbò bo àwọn ará lọ́jọ́ kan.—Mát. 5:16.

14. Kí ló mú kí arábìnrin kan “ṣe tán láti ṣègbọràn” síjọba?

14 Síbẹ̀, ó lè má rọrùn fún wa láti pa òfin ìjọba mọ́. Arábìnrin Joanna tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó ṣòro fún mi gan-an láti ṣègbọràn síjọba torí pé wọ́n ti fìyà jẹ àwọn kan nínú ìdílé mi rí.” Àmọ́ Joanna pinnu pé òun gbọ́dọ̀ yí èrò òun pa dà. Ohun àkọ́kọ́ tó ṣe ni pé kì í ka ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn fi ń bú ìjọba lórí ìkànnì àjọlò mọ́ torí ó lè jẹ́ kó máa bínú síjọba. (Òwe 20:3) Ìkejì, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé e, dípò kóun máa retí pé káwọn ẹlòmíì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. (Sm. 9:9, 10) Ìkẹta, ó ka àwọn àpilẹ̀kọ wa kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ò fi yẹ ká dá sọ́rọ̀ òṣèlú. (Jòh. 17:16) Joanna wá sọ pé bóun ṣe ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba, tóun sì ń pa òfin wọn mọ́ ti jẹ́ “kọ́kàn òun balẹ̀, òun sì lálàáfíà.”

MÁA ṢE OHUN TÍ ÈTÒ ỌLỌ́RUN SỌ

15. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ?

15 Jèhófà sọ pé ká “máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń mú ipò iwájú” nínú ìjọ. (Héb. 13:17) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù Aṣáájú wa, àwọn tó ń lò láti ṣàbójútó wa kì í ṣe ẹni pípé. Ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe ohun tí wọ́n sọ, pàápàá tóhun tí wọ́n ní ká ṣe ò bá wù wá. Ìgbà kan wà tí kò rọrùn fún àpọ́sítélì Pétérù láti ṣègbọràn. Nígbà tí áńgẹ́lì kan ní kó jẹ àwọn ẹran tí Òfin Mósè kà léèwọ̀, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù kọ̀ jálẹ̀! (Ìṣe 10:9-16) Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tí áńgẹ́lì náà ní kó ṣe ò bọ́gbọ́n mu lójú ẹ̀ torí pé ohun tó ti mọ́ ọn lára láti kékeré kọ́ nìyẹn. Tó bá ṣòro fún Pétérù láti ṣe ohun tí áńgẹ́lì pípé sọ fún un, ẹ ò rí i pé á túbọ̀ ṣòro fún wa láti ṣe ohun táwọn èèyàn aláìpé bá sọ fún wa!

16. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ní kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ò bọ́gbọ́n mu, kí ló ṣe? (Ìṣe 21:23, 24, 26)

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù “ṣe tán láti ṣègbọràn” kódà nígbà tí wọ́n ní kó ṣe ohun tí ò bọ́gbọ́n mu lójú ẹ̀. Àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ti ń gbọ́ àhesọ nípa Pọ́ọ̀lù pé ó ń kọ́ àwọn èèyàn pé “kí wọ́n kẹ̀yìn sí Mósè” àti pé kò ka Òfin Mósè sí. (Ìṣe 21:21) Torí náà, àwọn àgbààgbà ọkùnrin Jerúsálẹ́mù sọ fún Pọ́ọ̀lù pé kó mú ọkùnrin mẹ́rin lọ sínú tẹ́ńpìlì kó sì wẹ ara ẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn, kó lè fi hàn pé òun ń pa Òfin Mósè mọ́. Àmọ́ Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn Kristẹni ò sí lábẹ́ Òfin Mósè mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò jẹ̀bi, ó ṣe ohun tí wọ́n sọ. Torí náà, ó “mú àwọn ọkùnrin náà dání ní ọjọ́ kejì, ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn lọ́nà Òfin.” (Ka Ìṣe 21:23, 24, 26.) Ẹ ò rí i pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe yẹn mú kí àlàáfíà wà láàárín àwọn ará.—Róòmù 14:19, 21.

17. Kí lo kọ́ nínú ohun tí Arábìnrin Stephanie ṣe?

17 Ó ṣòro fún arábìnrin kan tó ń jẹ́ Stephanie láti fara mọ́ ìpinnu táwọn tó ń ṣàbójútó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè ẹ̀ ṣe. Inú òun àti ọkọ ẹ̀ ń dùn bí wọ́n ṣe ń sìn ní àwùjọ tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwọn. Nígbà tó yá, ẹ̀ka ọ́fíìsì dá àwùjọ náà dúró, wọ́n sì ní kí tọkọtaya náà pa dà sí ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn. Stephanie sọ pé: “Inú mi ò dùn rárá torí mi ò gbà pé ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wa nílò ìrànlọ́wọ́.” Síbẹ̀, ó ṣe ohun tí wọ́n sọ. Ó wá sọ pé: “Nígbà tó yá, mo rí i pé ohun tí wọ́n ní ká ṣe bọ́gbọ́n mu lóòótọ́. A ti wá di ìyá àti bàbá ọ̀pọ̀ àwọn ará ìjọ wa tí ìdílé wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní báyìí, èmi ni mò ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ arábìnrin kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ tẹ́lẹ̀, mo sì tún ń ráyè dá kẹ́kọ̀ọ́ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Yàtọ̀ síyẹn, mo ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ torí mo mọ̀ pé mo ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ kí n ṣe kí n lè ti ètò tí wọ́n ṣe lẹ́yìn.”

18. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ṣègbọràn?

18 A gbọ́dọ̀ kọ́ láti máa ṣègbọràn. Jésù “kọ́ ìgbọràn,” kì í ṣe torí pé ó gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn, àmọ́ ó kọ́ ọ “látinú ìyà tó jẹ.” (Héb. 5:8) Bíi ti Jésù, àwa náà máa ń kọ́ ìgbọràn tí nǹkan ò bá fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àrùn kòrónà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ètò Ọlọ́run sọ pé a ò ní ṣèpàdé ní Ilé Ìpàdé wa mọ́, a ò sì ní wàásù láti ilé dé ilé mọ́. Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti ṣe ohun tí wọ́n sọ yẹn? Ìgbọràn tó o ṣe dáàbò bò ẹ́, ó jẹ́ kí ìwọ àtàwọn ará ìjọ wà níṣọ̀kan, ó sì múnú Jèhófà dùn. Ní báyìí, gbogbo wa ti ṣe tán láti ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ fún wa nígbà ìpọ́njú ńlá torí ó lè jẹ́ ìyẹn ló máa gba ẹ̀mí wa là!—Jóòbù 36:11.

19. Kí ló mú kó o pinnu pé wàá máa ṣègbọràn?

19 Ohun tá a ti kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí ni pé tá a bá ń ṣègbọràn, a máa jàǹfààní gan-an. Àmọ́ ìdí tá a fi pinnu pé àá máa ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a sì fẹ́ ṣe ohun tó fẹ́. (1 Jòh. 5:3) Kò sóhun tá a lè fi san gbogbo oore tí Jèhófà ṣe fún wa. (Sm. 116:12) Síbẹ̀, ó yẹ ká máa ṣègbọràn sí i àtàwọn tó fún láǹfààní láti wà nípò àṣẹ. Tá a bá ń ṣègbọràn, á fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni wá. A sì mọ̀ pé àwọn ọlọ́gbọ́n ló máa ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀.—Òwe 27:11.

ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún

a Nítorí pé aláìpé ni wá, nígbà míì kì í rọrùn fún wa láti ṣègbọràn, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tó ń sọ ohun tá a máa ṣe fún wa lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń gbọ́ràn sáwọn òbí wa lẹ́nu, tá à ń ṣègbọràn sáwọn “aláṣẹ onípò gíga” àtàwọn arákùnrin tó ń ṣàbójútó wa nínú ìjọ.

b Kó o lè rí àwọn àbá lórí bó o ṣe lè bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn òfin tí wọ́n ṣe tó nira fún ẹ láti pa mọ́, wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Bá Àwọn Òbí Mi Sọ̀rọ̀ Nípa Àwọn Òfin Tí Wọ́n Ṣe?” lórí jw.org.

c ÀWÒRÁN: Jósẹ́fù àti Màríà ṣègbọràn nígbà tí Késárì sọ pé kí wọ́n lọ forúkọ sílẹ̀ ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Bákan náà lónìí, àwa Kristẹni máa ń pa òfin ìrìnnà mọ́, a máa ń san owó orí, a sì máa ń ṣe ohun tí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” bá ní ká ṣe ká lè dáàbò bo ìlera wa àti tàwọn ẹlòmíì.