Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 44

Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Jinlẹ̀

Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Jinlẹ̀

Ẹ “lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́.”—ÉFÉ. 3:18.

ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a

1-2. Ọ̀nà wo ló dáa jù tó o lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ṣàpèjúwe.

 KÁ SỌ pé o fẹ́ ra ilé kan, àwọn nǹkan wo lo máa wò kó o tó rà á? Ṣé fọ́tò iwájú ilé náà nìkan lo máa wò? Rárá o. Ó dájú pé wàá fẹ́ lọ síbẹ̀ fúnra ẹ, kó o rìn yí ilé náà ká, kó o wọnú gbogbo yàrá tó wà níbẹ̀ kó o lè rí gbogbo ohun tó wà nínú ilé náà. Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè ní kí wọ́n fún ẹ ní àwòrán tí wọ́n fi kọ́ ilé náà kó o lè mọ bí wọ́n ṣe kọ́ ọ. Kò sí àní-àní pé wàá fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ilé náà kó o tó rà á.

2 A lè ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ tá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣàlàyé Bíbélì fi Bíbélì wé “ilé kan tó ga gan-an, tó tóbi, tí ìpìlẹ̀ ẹ̀ sì lágbára.” Torí náà, kí la lè ṣe ká lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà nínú Bíbélì? Tó o bá yára kà á, “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde mímọ́ ti Ọlọ́run” nìkan lo máa mọ̀. (Héb. 5:12) Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kó o lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó wà nínú ẹ̀, ìyẹn máa dà bíi pé o “wọnú” ilé tó o fẹ́ rà. Ọ̀nà tó dáa jù tó o lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni pé kó o wo bí ohun tó sọ níbì kan ṣe tan mọ́ ohun tó sọ láwọn ibòmíì. Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó o gbà gbọ́ nìkan ló yẹ kó o mọ̀, ó tún yẹ kó o mọ ìdí tó o fi gba àwọn nǹkan náà gbọ́.

3. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ṣe, kí sì nìdí? (Éfésù 3:14-19)

3 Tá a bá fẹ́ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin níyànjú pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n “lè lóye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn á ‘ta gbòǹgbò, á sì fìdí múlẹ̀.’ (Ka Éfésù 3:14-19.) Ohun tó yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo bá a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀, ká sì lóye ohun tá à ń kà.

MÁA ṢÈWÁDÌÍ NÍPA ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ TÓ ṢÒRO LÓYE

4. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.

4 Kì í ṣe àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ nìkan ló yẹ káwa Kristẹni mọ̀. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún máa ń jẹ́ kó wù wá láti lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 2:9, 10) O ò ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn apá kan nínú Bíbélì táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Bí àpẹẹrẹ, o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó ṣe fáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ nígbà àtijọ́ tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn àtàwọn nǹkan tó ń ṣe fún ìwọ náà báyìí tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ṣètò pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jọ́sìn òun, kó o wá fi wé báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń jọ́sìn ẹ̀ lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, o tún lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára nígbà tó ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé.

5. Ṣé apá kan wà nínú Bíbélì tó máa wù ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa ẹ̀?

5 Wọ́n bi àwọn ará wa kan tó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa pé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ wo ni wọ́n máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀? Díẹ̀ lára nǹkan tí wọ́n sọ wà nínú àpótí tá a pè ní “ Àwọn Àkòrí Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀.” Inú ẹ máa dùn gan-an tó o bá ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan yìí nínú Watch Tower Publications Index lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, ìgbàgbọ́ ẹ máa lágbára, wàá sì “rí ìmọ̀ Ọlọ́run.” (Òwe 2:4, 5) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn.

MÁA RONÚ JINLẸ̀ NÍPA OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ ṢE

6. (a) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ohun tẹ́nì kan fẹ́ ṣe àti bó ṣe máa ṣe é? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fáwa èèyàn àti ayé yìí máa wà títí láé? (Éfésù 3:11)

6 Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tí Bíbélì sọ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. Ìyàtọ̀ wà láàárín ohun tẹ́nì kan fẹ́ ṣe àti bó ṣe máa ṣe é. Ohun tẹ́nì kan fẹ́ ṣe la lè fi wé ibi téèyàn ń lọ. Ó mọ ibi tó ń lọ, ọ̀nà tó sì lè gbà débẹ̀ ju ẹyọ kan lọ. Tí ọ̀nà kan bá dí, ó lè gba ọ̀nà míì. Béèyàn ṣe máa ṣe nǹkan la lè fi wé ọ̀nà kan ṣoṣo tó máa gbà débi tó ń lọ. Tí ọ̀nà náà bá dí, kò ní lè débi tó ń lọ. Inú wa dùn pé Jèhófà mọ ohun tó fẹ́ ṣe, ó sì mọ bó ṣe máa ṣe é. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ ló ń jẹ́ ká mọ “ìpinnu rẹ̀ ayérayé” nínú Bíbélì. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Éfésù 3:11, nwtsty-E.) Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà lè gbà ṣe ohun tó fẹ́ ṣe, ó sì máa ń yọrí sí rere torí pé ó “ti mú kí gbogbo nǹkan rí bó ṣe fẹ́.” (Òwe 16:4) Ohunkóhun tí Jèhófà bá sì ṣe máa wà títí láé. Torí náà, a lè bi ara wa pé kí ni Jèhófà fẹ́ ṣe, àwọn àyípadà wo ló sì ti ṣe kó lè ṣe ohun tó fẹ́?

7. Lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, àwọn àyípadà wo ni Jèhófà ṣe kó lè ṣe ohun tó fẹ́? (Mátíù 25:34)

7 Jèhófà sọ ohun tó fẹ́ kí Ádámù àti Éfà ṣe fún wọn. Ó sọ pé: “Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ máa jọba lórí . . . gbogbo ohun alààyè” tó wà láyé. (Jẹ́n. 1:28) Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, tí wọ́n sì mú kí gbogbo èèyàn di ẹlẹ́ṣẹ̀, ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé ò yí pa dà. Ṣe ló kàn yí ọ̀nà tó fẹ́ gbà ṣe é pa dà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló pinnu láti gbé Ìjọba kan kalẹ̀ lọ́run tó máa mú kí ohun tó fẹ́ ṣe fáwa èèyàn àti ayé yìí ṣẹ. (Ka Mátíù 25:34.) Nígbà tó sì tó àsìkò lójú Jèhófà, ó rán àkọ́bí Ọmọ ẹ̀ wá sáyé kó lè kọ́ wa nípa Ìjọba náà, kó sì fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Lẹ́yìn náà, Jèhófà jí Jésù dìde pa dà sí ọ̀run kó lè di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan ṣì wà tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe tó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn.

Fojú inú wo ìgbà tí gbogbo àwọn tí Jèhófà dá sọ́run àti ayé á máa fi òótọ́ sin Jèhófà níṣọ̀kan! (Wo ìpínrọ̀ 8)

8. (a) Kí ni Bíbélì dá lé? (b) Kí ni Éfésù 1:8-11 sọ pé ó tún wu Jèhófà pé kó ṣe? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

8 Ohun tí Bíbélì dá lé ni bí Jèhófà ṣe máa dá orúkọ ẹ̀ láre, tó sì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ tí Kristi máa ṣàkóso. Ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe ò lè yí pa dà láé. Ó ti fi dá wa lójú pé òun máa ṣe é láṣeyọrí. (Àìsá. 46:10, 11, àlàyé ìsàlẹ̀; Héb. 6:17, 18) Tó bá yá, Jèhófà máa sọ ayé yìí di Párádísè níbi táwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà tó ti di pípé, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ ti máa “gbádùn ayé títí láé.” (Sm. 22:26) Àmọ́ ohun tí Jèhófà máa ṣe jùyẹn lọ. Ohun tó wù ú jù ni bó ṣe máa mú kí gbogbo àwọn tó dá sọ́run àti ayé máa jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àwọn tó wà láàyè ló máa gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. (Ka Éfésù 1:8-11.) Ṣé kò yà ẹ́ lẹ́nu bó o ṣe ń rí àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe kó lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ?

MÁA RONÚ NÍPA OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ

9. Àwọn nǹkan wo la máa mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú tá a bá ń ka Bíbélì?

9 Ẹ jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ nínú ọgbà Édẹ́nì tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15. b Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ọdún bá ti kọjá, kí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lè ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ máa di baba ńlá Mèsáyà. (Jẹ́n. 22:15-18) Nígbà tó sì dọdún 33 S.K., wọ́n ṣe Jésù léṣe ní gìgísẹ̀ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 3:13-15) Ẹgbẹ̀rún ọdún (1,000) ṣì máa kọjá kí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tó ṣẹ tán, ìyẹn ìgbà tí Jèhófà bá lo Jésù láti fọ́ orí Sátánì. (Ìfi. 20:7-10) Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ bí ogun tí ètò Sátánì ń bá ètò Ọlọ́run jà ṣe túbọ̀ ń le sí i.

10. (a) Àwọn nǹkan wo ló máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́? (b) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

10 Ẹ jẹ́ ká ronú nípa àwọn nǹkan àgbàyanu tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀. Ohun àkọ́kọ́ ni pé àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò!” (1 Tẹs. 5:2, 3) Ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀ nígbà táwọn orílẹ̀-èdè bá bẹ̀rẹ̀ sí í pa gbogbo ìsìn èké run, ó sì máa ṣẹlẹ̀ ‘lójijì.’ (Ìfi. 17:16) Lẹ́yìn ìyẹn, ó ṣeé ṣe kí àwọn àmì àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀ torí “Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ lórí àwọsánmà ojú ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.” (Mát. 24:30) Jésù máa wá dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́, á sì ya àwọn tó dà bí àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó dà bí ewúrẹ́. (Mát. 25:31-33, 46) Síbẹ̀, Sátánì ò ní káwọ́ gbera. Torí inú ń bí i burúkú burúkú, ó máa mú kí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè tí Bíbélì pè ní Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà. (Ìsík. 38:2, 10, 11) Láàárín àkókò kan nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró máa lọ bá Kristi àtàwọn ọmọ ogun ọ̀run lọ́run kí wọ́n lè jọ ja ogun Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn ló sì máa fòpin sí ìpọ́njú ńlá náà. c (Mát. 24:31; Ìfi. 16:14, 16) Lẹ́yìn náà, Jésù máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lé ayé lórí fún ẹgbẹ̀rún ọdún kan.—Ìfi. 20:6.

Báwo lo ṣe máa sún mọ́ Jèhófà tó lẹ́yìn tó o bá ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún? (Wo ìpínrọ̀ 11)

11. Àwọn nǹkan wo lo máa gbádùn tó o bá wà láàyè títí láé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká ronú nípa bí ayé ṣe máa rí lẹ́yìn Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá wa “ti fi ayérayé sí [wa] lọ́kàn.” (Oníw. 3:11) O ò rí i pé ìyẹn máa jẹ́ kó o wà láàyè títí láé, kó o sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 319 sọ ohun tó máa jẹ́ kó túbọ̀ wù wá. Ó ní: “Lẹ́yìn tá a bá wà láàyè fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ọ̀kẹ́ àìmọye, kódà fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún, ohun tí a máa mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run á pọ̀ púpọ̀ ju ohun tá a mọ̀ báyìí. Ṣùgbọ́n a máa rí i pé àwọn ohun àgbàyanu tó ṣì yẹ ká mọ̀ kò lóǹkà. . . . Ìyè ayérayé yóò kún fún ohun mériyìírí lóríṣiríṣi tó ń mú ayé dùn mọ́ni. Sísúnmọ́ Jèhófà sì ni apá tí yóò mérè wá jù lọ nínú rẹ̀.” Torí náà, bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i, àwọn nǹkan míì wo ló ṣì yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn?

GBÓJÚ SÓKÈ WO Ọ̀RUN

12. Báwo la ṣe lè gbójú sókè wo ọ̀run? Sọ àpẹẹrẹ kan.

12 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ díẹ̀ fún wa nípa “ibi gíga lókè” ọ̀run níbi tí Jèhófà ń gbé. (Àìsá. 33:5) Bíbélì tún sọ àwọn ohun àgbàyanu nípa Jèhófà àti apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀. (Àìsá. 6:1-4; Dán. 7:9, 10; Ìfi. 4:1-6) Bí àpẹẹrẹ, a lè kà nípa àwọn ohun àrà mériyìírí tí Ìsíkíẹ́lì rí nígbà tí “ọ̀run ṣí sílẹ̀, [tó] sì rí ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—Ìsík. 1:1.

13.Hébérù 4:14-16 ṣe sọ, kí nìdí tó o fi mọyì ohun tí Jésù ń ṣe fún wa látọ̀run?

13 Tún ronú nípa ohun tí Jésù Ọba wa àti Àlùfáà Àgbà tó lójú àánú ń ṣe fún wa látọ̀run. Nípasẹ̀ rẹ̀, a lè wá síwájú “ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” Ọlọ́run, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣàánú wa, kó sì ràn wá lọ́wọ́ “ní àkókò tó tọ́.” (Ka Hébérù 4:14-16.) Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá láìronú nípa ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún wa àtohun tí wọ́n ṣì ń ṣe fún wa látọ̀run. Torí náà, ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa yẹ kó mú ká máa fìtara wàásù, ká sì máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó.—2 Kọ́r. 5:14, 15.

Wo bí inú ẹ ṣe máa dùn tó nínú ayé tuntun tó o bá rí àwọn tó o ràn lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọmọlẹ́yìn Jésù! (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Kí ni nǹkan tó dáa jù tá a lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún wa? (Wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tá a lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mát. 28:19, 20) Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà ṣe nìyẹn torí ó mọyì ohun tí Ọlọ́run àti Kristi ṣe fún un. Ó mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Torí náà, ó ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kó lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́, kó sì “lè gba àwọn kan là ní gbogbo ọ̀nà [tó] bá lè gbé e gbà.”—1 Kọ́r. 9:22, 23.

JẸ́ KÍ INÚ Ẹ MÁA DÙN BÓ O ṢE Ń KẸ́KỌ̀Ọ́ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN JINLẸ̀

15. Kí ni Sáàmù 1:2 sọ pé ó máa jẹ́ ká láyọ̀?

15 Ẹ ò rí i pé ó bá a mu wẹ́kú nígbà tí onísáàmù náà sọ pé aláyọ̀ ni ẹni tí “òfin Jèhófà máa ń mú inú rẹ̀ dùn,” tí “ó sì ń ṣe àṣàrò lórí òfin Rẹ̀ tọ̀sántòru.” (Sm. 1:1-3; àlàyé ìsàlẹ̀) Nígbà tí atúmọ̀ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Joseph Rotherham ń sọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ Bíbélì yìí nínú ìwé ẹ̀ tó ń jẹ́ Studies in the Psalms, ó ní, “ó yẹ kí ẹni tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run máa wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ lójú méjèèjì, kó máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀, kó sì máa lo àkókò tó pọ̀ láti ronú lé e lórí.” Ó tún sọ pé “tẹ́nì kan bá jẹ́ kí ọjọ́ kan kọjá láìka Bíbélì, ṣe ló dà bíi pé ó ti fi gbogbo ọjọ́ yẹn ṣòfò.” Ìwọ náà máa gbádùn ẹ̀ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kó o lè rí gbogbo ẹ̀kọ́ tó fara sin nínú ẹ̀ àti bí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà ṣe tan mọ́ra. Inú ẹ máa dùn gan-an tó o bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó o lè lóye ẹ̀ dáadáa.

16. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

16 Àwọn òtítọ́ iyebíye tí Jèhófà kọ́ wa nínú Bíbélì ò ṣòro fún wa láti mọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò òtítọ́ Bíbélì kan tó jinlẹ̀, ìyẹn tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí Jèhófà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni. Àdúrà wa ni pé kí ohun tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ yìí múnú ẹ dùn, kó sì mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.

ORIN 94 A Mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

a Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa ń jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà Baba wa ọ̀run, ó sì máa ń jẹ́ ká láyọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bá a ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì.

b Wo àpilẹ̀kọ náà “Bí Àsọtẹ́lẹ̀ Kan Tó Ti Pẹ́ Ṣe Kàn Ẹ́” nínú Ilé Ìṣọ́ July 2022.

c Kó o lè mọ bó o ṣe máa múra sílẹ̀ de àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, tó sì máa mi gbogbo ayé, wo ìwé Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso! ojú ìwé 230.