Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ọ̀rọ̀ Tó Kan Gbogbo Èèyàn

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Ọ̀rọ̀ Tó Kan Gbogbo Èèyàn

Tó o bá fẹ́ rìnrìn àjò lọ síbì kan tó ò dé rí, kí lo máa ṣe?

  1. 1. Ṣé ibi tọ́kàn ẹ bá ṣáà ti ní kó o gbà ni wàá gbà?

  2. 2. Ṣé ńṣe lo kàn máa tẹ̀ lé àwọn tó o rò pé wọ́n mọ̀nà?

  3. 3. Ṣé wàá wá afinimọ̀nà tó ṣeé gbára lé bíi máàpù, ohun tí wọ́n ń pè ní GPS àbí wàá béèrè lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ ẹ tó mọ̀nà dáadáa?

Tó o bá tẹ̀ lé àbá àkọ́kọ́ tàbí ìkejì, wàá kúkú débì kan, ó kàn lè má jẹ́ ibi tó wù ẹ́ ni. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé àbá kẹta lo tẹ̀ lé, ọkàn ẹ á balẹ̀ pé wàá débi tó o fẹ́ lọ.

Ńṣe ni ìgbésí ayé àwa èèyàn dà bí ìrìn àjò, ibi tó dáa ló sì máa ń wù wá kó já sí. Ìmọ̀ràn tá a bá tẹ̀ lé ló máa pinnu bóyá a máa débi tá a fẹ́ lọ àbí a ò ní débẹ̀.

Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lè dà bí ohun tí ò tó nǹkan. Àmọ́ àwọn ìpinnu kan wà tó ṣe pàtàkì gan-an, torí pé wọ́n sábà máa ń fi irú ẹni tá a jẹ́ hàn, wọ́n sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tá a gbà pé ó dáa àtèyí tí kò dáa. Irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ lè ṣàkóbá tó pọ̀ gan-an fún àwa àtàwọn èèyàn wa tàbí kó ṣe wá láǹfààní. Lára wọn ni:

  • Ìbálòpọ̀ àti ìgbéyàwó

  • Jíjẹ́ olóòótọ́, iṣẹ́ àti owó

  • Bá a ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ

  • Bá a ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn

Kí ló máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìpinnu tó o bá ṣe lórí àwọn ọ̀rọ̀ yìí á jẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la ìwọ àti ìdílé ẹ dáa?

Gbogbo èèyàn lọ̀rọ̀ yìí kàn, torí náà ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara ẹ̀ pé: Kí ló máa ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ ìpinnu tó dáa àtèyí tí kò dáa?

Ìwé yìí máa sọ ìdí tí Bíbélì fi jẹ́ afinimọ̀nà tó ṣeé gbára lé àti bó ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.