Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Bíbélì Ni Afinimọ̀nà Tó Dájú

Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Bíbélì Ni Afinimọ̀nà Tó Dájú

Tó bá jẹ́ pé bí nǹkan ṣe ń rí lára wa tàbí ohun táwọn èèyàn ń sọ la fi ń mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ó ṣeé ṣe ká má ṣe ohun tó tọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀, ó sì tún fún wa ní ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé, tó máa jẹ́ ká gbádùn ayé wa, kí ọkàn wa sì balẹ̀.

A NÍLÒ ÌTỌ́SỌ́NÀ ỌLỌ́RUN

Nínú Bíbélì, Jèhófà a Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kóun máa darí wa. (Jeremáyà 10:23) Ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé. Ó nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an, kò fẹ́ ká ṣe ohun tó máa kó bá wa, kò sì fẹ́ ká jìyà ká tó gbọ́n. (Diutarónómì 5:29; 1 Jòhánù 4:8) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ tó pọ̀ tó láti fún wa ní ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní jù lọ. (Sáàmù 100:3; 104:24) Síbẹ̀, kì í fipá mú wa láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀.

Jèhófà fún Ádámù àti Éfà, ìyẹn ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè máa láyọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28, 29; 2:8, 15) Ó sọ àwọn nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe àtàwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n ṣe, àwọn nǹkan náà ò sì nira. Àmọ́, ó fún wọn láǹfààní láti yàn bóyá wọ́n máa ṣe ohun tóun sọ àbí wọn ò ní ṣe é. (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 16, 17) Ó dunni pé ohun tó wu Ádámù àti Éfà ni wọ́n ṣe dípò kí wọ́n ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6) Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Ṣáwọn èèyàn ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣe ohun tí wọ́n gbà pé ó dáa? Rárá o. Ohun tójú àwa èèyàn ti rí fi hàn pé tá ò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, ọkàn wa ò ní balẹ̀, a ò sì ní láyọ̀.—Oníwàásù 8:9.

Gbogbo èèyàn ni ìmọ̀ràn inú Bíbélì wúlò fún, tá a bá ń tẹ̀ lé e, àá máa ṣe ohun tó dáa, a ò sì ní kó ara wa sí ìṣòro. (2 Tímótì 3:16, 17; wo àpótí náà “ Gbogbo Èèyàn Ni Bíbélì Wúlò Fún.”) Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn náà.

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i, kó o lè mọ ìdí tá a fi gbà pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ni Bíbélì lóòótọ́.—1 Tẹsalóníkà 2:13. Lọ sí jw.org, kó o sì wo fídíò náà Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ OHUN TÍ ỌLỌ́RUN FẸ́ KÁ MÁA ṢE

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn lò látìbẹ̀rẹ̀. Ohun tó wà nínú ẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run kà sí ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa, ohun tó lè ṣe wá láǹfààní àti ohun tó lè kó bá wa. (Sáàmù 19:7, 11) Kò sígbà táwọn ìlànà inú ẹ̀ kì í ṣeni láǹfààní, tá a bá sì ń tẹ̀ lé e, á jẹ́ ká máa ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu nígbà gbogbo.

Bí àpẹẹrẹ, wo ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 13:20, tó sọ pé: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.” Bí ìmọ̀ràn yẹn ṣe wúlò nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣì ṣe wúlò lásìkò wa yìí. Àwọn ìmọ̀ràn àtàtà bí irú èyí pọ̀ gan-an nínú Bíbélì.—Wo àpótí náà “ Ìmọ̀ràn Inú Bíbélì Ṣì Wúlò.”

Àmọ́, o lè máa rò ó pé ‘Ẹ̀rí wo ló wà pé àwọn ìlànà Bíbélì ṣì wúlò lóde òní?’ Àpilẹ̀kọ tó kàn máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí ìlànà Bíbélì ti ṣe láǹfààní.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.