Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àwọn Obìnrin Lo Fi Ń Wò Wọ́n?

Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àwọn Obìnrin Lo Fi Ń Wò Wọ́n?

A LÁǸFÀÀNÍ láti máa sin Jèhófà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó jẹ́ olóòótọ́. A nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn arábìnrin a olóòótọ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára yìí, a sì mọyì wọn. Torí náà, ẹ̀yin arákùnrin wa, ẹ máa finúure hàn sí wọn, ẹ máa ṣe wọ́n jẹ́jẹ́, kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́, nígbà míì ó lè nira láti ṣe bẹ́ẹ̀ torí a kì í ṣe ẹni pípé. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn nǹkan míì wà tó mú kó ṣòro fáwọn arákùnrin kan láti bọ̀wọ̀ fún wọn.

Wọ́n tọ́ àwọn kan dàgbà nínú àṣà ìbílẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ọkùnrin ti máa ń fojú àbùkù wo àwọn obìnrin. Bí àpẹẹrẹ, alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Hans lórílẹ̀-èdè Bòlífíà sọ pé: “Ibi tí wọn ò ti ka àwọn obìnrin sí, tí wọ́n sì gbà pé ọkùnrin lọ̀gá ni wọ́n ti tọ́ àwọn ọkùnrin kan dàgbà.” Arákùnrin Shengxian tó jẹ́ alàgbà lórílẹ̀-èdè Taiwan sọ pé: “Níbi tí mo ti wá, ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló gbà pé àwọn obìnrin ò gbọ́dọ̀ sọ èrò wọn fáwọn ọkùnrin. Tí ọkùnrin kan bá sọ èrò obìnrin kan nígbà tó wà láàárín àwọn ojúgbà ẹ̀, ojú burúkú ni wọ́n máa fi wo irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀.” Àwọn ọkùnrin míì máa ń fi hàn lọ́nà míì pé àwọn ò ka obìnrin sí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa fi àwọn obìnrin dápàárá tí ò dáa.

Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ojú burúkú ni wọ́n fi ń wo àwọn obìnrin ní àṣà ìbílẹ̀ wa, a ṣì lè yí pa dà. A lè borí èrò tá a ní tẹ́lẹ̀ pé ọkùnrin sàn ju obìnrin lọ. (Éfé. 4:22-24) A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá fara wé Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn obìnrin. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa báwọn arákùnrin ṣe lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn obìnrin wò wọ́n àti báwọn alàgbà ṣe lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin.

OJÚ WO NI JÈHÓFÀ FI Ń WO ÀWỌN OBÌNRIN?

Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn obìnrin. Torí pé Bàbá aláàánú ni, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀. (Jòh. 3:16) Àwọn arábìnrin sì jẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn obìnrin, tó sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn.

Kò ka ọkùnrin sí ju obìnrin lọ. Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin ní àwòrán ara ẹ̀. (Jẹ́n. 1:27) Kò dá àwọn ọkùnrin pé kí wọ́n gbọ́n, kí wọ́n sì lẹ́bùn ju àwọn obìnrin lọ, kò sì nífẹ̀ẹ́ ọkùnrin ju obìnrin lọ. (2 Kíró. 19:7) Ó fún ọkùnrin àti obìnrin ní ọgbọ́n tí wọ́n á fi mọ òtítọ́ Bíbélì, tí wọ́n á sì láwọn ànímọ́ Ọlọ́run. Bákan náà, Jèhófà mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tí ọkùnrin ní kò ju ti obìnrin lọ, ì báà jẹ́ pé wọ́n máa gbé ayé títí láé nínú Párádísè tàbí wọ́n máa jẹ́ ọba àti àlùfáà ní ọ̀run. (2 Pét. 1:1, àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, ó dájú pé Jèhófà ò ka ọkùnrin sí ju obìnrin lọ.

Ó máa ń tẹ́tí sí wọn. Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn obìnrin, ó sì máa ń gba tiwọn rò. Bí àpẹẹrẹ, ó tẹ́tí sí àdúrà Réṣẹ́lì àti Hánà, ó sì dáhùn wọn. (Jẹ́n. 30:22; 1 Sám. 1:10, 11, 19, 20) Jèhófà tún fẹ̀mí darí àwọn tó kọ Bíbélì pé kí wọ́n kọ ìtàn àwọn ọkùnrin tí wọ́n tẹ́tí sí àwọn obìnrin sílẹ̀ nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé kó fetí sí Sérà ìyàwó ẹ̀, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 21:12-14) Ọba Dáfídì náà fetí sí ohun tí Ábígẹ́lì sọ. Kódà, ó gbà pé Jèhófà ló rán an sóun. (1 Sám. 25:32-35) Jésù tó fi àwọn ànímọ́ Bàbá ẹ̀ hàn dáadáa náà fetí sí Màríà ìyá ẹ̀. (Jòh. 2:3-10) Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin ni pé ó máa ń tẹ́tí sí wọn.

Ó fọkàn tán wọn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fọkàn tán Éfà nígbà tó ní kóun àti Ádámù máa bójú tó ayé. (Jẹ́n. 1:28) Nígbà tí Jèhófà sọ bẹ́ẹ̀ fún Éfà, kò kà á sí ẹni tó rẹlẹ̀ sí Ádámù ọkọ ẹ̀, àmọ́ ó kà á sí olùrànlọ́wọ́. Jèhófà tún fọkàn tán àwọn wòlíì obìnrin bíi Dèbórà àti Húlídà pé wọ́n á gba àwọn èèyàn òun nímọ̀ràn, kódà wọ́n gba onídàájọ́ kan àti ọba kan nímọ̀ràn. (Oníd. 4:4-9; 2 Ọba 22:14-20) Lónìí, Jèhófà fọkàn tán àwọn obìnrin Kristẹni pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ tóun gbé fún wọn. Àwọn obìnrin olóòótọ́ yìí ń wàásù, wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àti míṣọ́nnárì. Wọ́n máa ń ya àwòrán Ilé Ìpàdé àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n fẹ́ kọ́, wọ́n máa ń kọ́ wọn, wọ́n sì máa ń tún wọn ṣe. Àwọn kan lára wọn ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míì sì ń sìn ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè. Àwọn obìnrin yìí dà bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá tí Jèhófà ń lò láti ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀. (Sm. 68:11) Torí náà, ó hàn gbangba pé Jèhófà kì í wo àwọn obìnrin bí ẹni tí ò lágbára tàbí ẹni tí ò wúlò.

BÍ ÀWỌN ARÁKÙNRIN ṢE LÈ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÓBÌNRIN BÍ JÈHÓFÀ TI ṢE

Ẹ̀yin arákùnrin wa, tẹ́ ẹ bá fẹ́ mọ̀ bóyá ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn obìnrin lẹ fi ń wò wọ́n, ó yẹ kẹ́ ẹ yẹ èrò àti ìṣe yín wò dáadáa. Kẹ́ ẹ sì tó lè ṣèyẹn, àfi kẹ́ ẹ wá ìrànlọ́wọ́. Bí ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò ara ṣe lè wo inú ọkàn láti mọ̀ bóyá ó ń ṣiṣẹ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ àti Bíbélì ṣe lè jẹ́ ká mọ̀ bóyá a ní èrò tó tọ́ sáwọn obìnrin. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ rí ìrànlọ́wọ́ náà gbà?

Ní kí ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Òwe 18:17) Á dáa kó o bi ọ̀rẹ́ ẹ tó o fọkàn tán, tó sì máa ń bá ẹ sòótọ́ ọ̀rọ̀ láwọn ìbéèrè bíi: “Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe sáwọn obìnrin? Ṣé wọ́n máa ń sọ pé mò ń bọ̀wọ̀ fáwọn? Ṣé ohun kan wà tí mo lè ṣe kí n lè túbọ̀ máa bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó tọ́?” Tí ọ̀rẹ́ ẹ bá sọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe kó o lè sunwọ̀n sí i, má ṣe wí àwíjàre. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o ṣàtúnṣe tó yẹ.

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà mọ̀ bóyá à ń hùwà tó dáa sáwọn arábìnrin ni pé ká fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ìwà wa àtohun tá à ń ṣe wò. (Héb. 4:12) Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àá rí àwọn ọkùnrin tó hùwà tó dáa sáwọn obìnrin àtàwọn tó hùwà tí ò dáa sí wọn. Lẹ́yìn náà, ká fi ìwà wọn wé tiwa. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ káwọn arákùnrin máa wo bí ẹsẹ Bíbélì kan ṣe tan mọ́ òmíì, kó má lọ jẹ́ pé wọ́n á máa lo ẹsẹ Bíbélì kan láti fi ti èrò tí ò tọ́ tí wọ́n ní sáwọn obìnrin lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, 1 Pétérù 3:7 sọ pé káwọn ọkọ máa ‘bọlá fún àwọn aya wọn bí ohun èlò ẹlẹgẹ́.’ b Ṣé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn ń sọ ni pé obìnrin ò gbọ́n tàbí pé wọn ò lágbára tó ọkùnrin? Rárá o! Ẹ jẹ́ ká fi ohun tí Pétérù sọ wé ohun tí Gálátíà 3:26-29 sọ, pé bí Jèhófà ṣe yan àwọn ọkùnrin láti bá Jésù ṣàkóso lọ́run bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yan àwọn obìnrin. Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ní kí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ sọ bá a ṣe ń hùwà sáwọn obìnrin, àá mọ bó ṣe yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin wa.

BÁWO LÀWỌN ALÀGBÀ ṢE LÈ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ARÁBÌNRIN?

Ọ̀nà míì táwọn arákùnrin lè gbà máa bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin ni pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ ìjọ. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára nǹkan tí wọ́n lè ṣe.

Ẹ máa gbóríyìn fáwọn arábìnrin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn alàgbà lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó gbóríyìn fáwọn arábìnrin kan nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará ìjọ Róòmù. (Róòmù 16:12) Ẹ wo bí inú àwọn arábìnrin yẹn ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n ka lẹ́tà Pọ́ọ̀lù fáwọn ará ìjọ! Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwọn alàgbà máa fara wé Pọ́ọ̀lù, kí wọ́n máa gbóríyìn fáwọn arábìnrin nítorí ànímọ́ rere tí wọ́n ní àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe fún Jèhófà. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn arábìnrin náà á rí i pé wọ́n ń bọ̀wọ̀ fáwọn, wọ́n sì mọyì àwọn. Tí alàgbà kan bá ń gbóríyìn fáwọn arábìnrin, ó lè jẹ́ ohun tí wọ́n nílò nìyẹn kí wọ́n lè máa sin Jèhófà nìṣó tọkàntọkàn.—Òwe 15:23.

Máa gbóríyìn fún wọn

Táwọn alàgbà bá ń gbóríyìn fáwọn arábìnrin, ó yẹ kó wá látọkàn, kí wọ́n sì sọ ohun tó dáa tí wọ́n ń ṣe. Kí nìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Orí àwa arábìnrin máa ń wú táwọn arákùnrin bá sọ fún wa pé ‘iṣẹ́ gidi lẹ ṣe.’ Àmọ́, a sábà máa ń mọyì ẹ̀ táwọn arákùnrin bá gbóríyìn fún wa torí nǹkan pàtó tá a ṣe, irú bá a ṣe ń kọ́ àwọn ọmọ wa kí wọ́n má pariwo nípàdé tàbí bá a ṣe ń lọ mú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sípàdé.” Táwọn alàgbà bá ń gbóríyìn fáwọn arábìnrin torí nǹkan dáadáa tí wọ́n ṣe, àwọn arábìnrin yẹn á rí i pé àwọn wúlò, wọ́n sì mọyì àwọn nínú ìjọ.

Ẹ máa fetí sí àwọn arábìnrin. Àwọn alàgbà tó nírẹ̀lẹ̀ mọ̀ pé àwọn míì lè ran àwọn lọ́wọ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nǹkan. Irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn arábìnrin pé kí wọ́n sọ èrò wọn lórí ọ̀rọ̀ kan, wọ́n sì máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á fún àwọn arábìnrin níṣìírí, àwọn fúnra wọn á sì jàǹfààní. Àǹfààní wo làwọn alàgbà máa rí? Alàgbà kan tó ń jẹ́ Gerardo, tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “Mo rí i pé tí mo bá ní káwọn arábìnrin sọ èrò wọn nípa iṣẹ́ tí mò ń ṣe, ó máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ náà dáa sí i. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà ju ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin lọ.” Nínú ìjọ, ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin ló ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, torí náà wọ́n mọ àwọn èèyàn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn dáadáa. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Bryan sọ pé: “Àwọn arábìnrin láwọn ànímọ́ tó dáa, wọ́n sì mọ àwọn nǹkan tó máa ṣe ètò Ọlọ́run láǹfààní. Torí náà, ẹ̀yin alàgbà, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn!”

Máa tẹ́tí sí wọn

Àwọn alàgbà tó nírìírí máa ń gbé àbá àwọn arábìnrin yẹ̀ wò. Kí nìdí? Alàgbà kan tó ń jẹ́ Edward sọ pé: “Èrò àwọn arábìnrin àti ìrírí wọn lè ran arákùnrin kan lọ́wọ́ láti lóye ọ̀rọ̀ kan dáadáa, á sì jẹ́ kó máa gba tàwọn èèyàn rò.” (Òwe 1:5) Kódà tí alàgbà kan ò bá tiẹ̀ gba èrò arábìnrin kan, ó yẹ kó dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé òun mọyì àbá tó mú wá àti pé ó láròjinlẹ̀.

Ẹ máa dá àwọn arábìnrin lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn alàgbà tó láròjinlẹ̀ máa ń dá àwọn arábìnrin lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè dá àwọn arábìnrin lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìwàásù tí arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi ò bá sí níbẹ̀. Wọ́n lè dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa lo àwọn irin iṣẹ́ tàbí ẹ̀rọ, kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run àti nígbà tí wọ́n bá ń ṣàtúnṣe wọn. Ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn alábòójútó ti dá àwọn arábìnrin lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ tá a bá gbé fún wọn. Ara àwọn iṣẹ́ náà ni iṣẹ́ àtúnṣe, ríra nǹkan, ìṣirò owó, ètò kọ̀ǹpútà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Táwọn alàgbà bá ń dá àwọn arábìnrin lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n á fi hàn pé wọ́n wúlò, wọ́n sì ṣe é fọkàn tán.

Máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́

Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin ló ń lo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà lọ́dọ̀ àwọn alàgbà láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arábìnrin kan ti lo ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé láti bá àwọn èèyàn tún ilé wọn kọ́ lẹ́yìn tí àjálù ṣẹlẹ̀. Àwọn arábìnrin míì lo ohun tí wọ́n kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù níbi térò pọ̀ sí, wọ́n sì fi ran àwọn arábìnrin púpọ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ náà dáadáa. Kí làwọn arábìnrin yìí sọ nípa àwọn alàgbà tó dá wọn lẹ́kọ̀ọ́? Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé: “Nígbà tí mo ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ Ilé Ìpàdé kan, ọ̀kan lára àwọn tó jẹ́ alábòójútó níbẹ̀ fara balẹ̀ dá mi lẹ́kọ̀ọ́. Ó kíyè sí àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, ó sì gbóríyìn fún mi. Inú mi dùn bí mo ṣe ń bá a ṣiṣẹ́ torí ó mọyì mi, ó sì fọkàn tán mi.”

ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ TÁ A BÁ Ń BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ARÁBÌNRIN

A nífẹ̀ẹ́ àwọn arábìnrin wa bíi ti Jèhófà! Torí náà, ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn arábìnrin nínú ìjọ. (1 Tím. 5:1, 2) A mọyì wọn, a sì ń gbádùn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa. Inú wa dùn pé àwọn arábìnrin wa mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn, a sì ń ran àwọn lọ́wọ́. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Vanessa sọ pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ètò rẹ̀, níbi táwọn arákùnrin lóríṣiríṣi ti ń fún mi níṣìírí.” Arábìnrin kan ní Taiwan sọ pé: “Mo dúpẹ́ pé Jèhófà àti ètò rẹ̀ mọyì àwa obìnrin gan-an, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún wa. Ó ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi lágbára, ó sì ti jẹ́ kí n mọyì àǹfààní tí mo ní pé mo wà nínú ètò Ọlọ́run.”

Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà ń dùn gan-an bó ṣe ń rí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ nínú ìjọ tó fìwà jọ ọ́, tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa hùwà tó dáa sáwọn obìnrin! (Òwe 27:11) Alàgbà kan tó ń jẹ́ Benjamin láti Scotland sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin nínú ayé lónìí ni kì í bọ̀wọ̀ fáwọn obìnrin rárá. Àmọ́, táwọn arábìnrin bá wá sí Ilé Ìpàdé wa, ó yẹ kí wọ́n rí i pé à ń bọ̀wọ̀ fún wọn, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn.” Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fara wé Jèhófà, ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arábìnrin wa, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.—Róòmù 12:10.

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni ni ọ̀rọ̀ náà “arábìnrin” tá a lò léraléra ń tọ́ka sí, kì í ṣe ẹni tá a jọ jẹ́ ọmọ ìyá.

b Kó o lè rí àlàyé sí i nípa ọ̀rọ̀ náà “ohun èlò ẹlẹgẹ́,” wo àpilẹ̀kọ náà “Bí ‘Ohun Èlò Tí Ó Túbọ̀ Jẹ́ Aláìlera’ Ti Ṣeyebíye Tó” nínú Ilé Ìṣọ́ May 15, 2006 àti àpilẹ̀kọ náà “Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n fún Àwọn Tọkọtaya” nínú Ilé Ìṣọ́ March 1, 2005.