Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5

ORIN 27 Ọlọ́run Máa Ṣí Àwọn Ọmọ Rẹ̀ Payá

‘Mi Ò Ní Pa Ọ́ Tì Láé!’

‘Mi Ò Ní Pa Ọ́ Tì Láé!’

“[Ọlọ́run] ti sọ pé: ‘Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.’”HÉB. 13:5b.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó dá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà lójú pé kò ní pa wá tì nígbà tí gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run.

1. Ìgbà wo ni gbogbo àwọn ẹni àmì òróró máa lọ sọ́run?

 NÍ Ọ̀PỌ̀ ọdún sẹ́yìn, àwa èèyàn Jèhófà máa ń béèrè pé, ‘Ìgbà wo ni èyí tó kẹ́yìn lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa lọ sọ́run?’ A máa ń rò pé ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró ṣì gbé láyé nínú Párádísè fúngbà díẹ̀ lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì. Àmọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013, a kẹ́kọ̀ọ́ pé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó bá ṣẹ́ kù láyé máa ti lọ sọ́run kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀.Mát. 24:31.

2. Ìbéèrè wo làwọn kan lè bi ara wọn, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Ṣùgbọ́n, àwọn kan lè máa bi ara wọn pé: Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí “àwọn àgùntàn mìíràn” ti Kristi, tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin Jèhófà nígbà “ìpọ́njú ńlá”? (Jòh. 10:16; Mát. 24:21) Àwọn kan sì lè máa rò pé kò sẹ́ni tó máa ran àwọn lọ́wọ́ tàbí tọ́ àwọn sọ́nà lẹ́yìn tí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin Kristẹni ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ méjì kan yẹ̀ wò nínú Bíbélì tó lè mú kí wọ́n nírú èrò yẹn. Lẹ́yìn ìyẹn, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìdí tí kò fi yẹ kẹ́rù bà wá.

KÍ NI Ò NÍ ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ÀGÙNTÀN MÌÍRÀN?

3-4. Kí làwọn kan lè máa rò, kí sì nìdí?

3 Àwọn kan lè máa rò pé àwọn àgùntàn mìíràn máa fi Jèhófà sílẹ̀ lẹ́yìn táwọn arákùnrin ẹni àmì òróró tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó ń tọ́ wa sọ́nà bá ti lọ sọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì ló mú kí wọ́n nírú èrò yẹn. Ẹ jẹ́ ká gbé méjì lára wọn yẹ̀ wò. Àpẹẹrẹ Àlùfáà Àgbà Jèhóádà la máa kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ni. Òun àti ìyàwó ẹ̀ tó ń jẹ́ Jèhóṣábéátì dáàbò bo ọmọdékùnrin kan tó ń jẹ́ Jèhóáṣì, wọ́n ràn án lọ́wọ́ láti di ọba rere, kó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ní gbogbo àsìkò tí Jèhóádà wà láyé, Jèhóáṣì ń sin Jèhófà, ó sì ń ṣe dáadáa. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jèhóádà kú, Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí ò dáa. Ó fetí sí ìmọ̀ràn burúkú táwọn ìjòyè Júdà fún un, ó sì fi Jèhófà sílẹ̀.—2 Kíró. 24:2, 15-19.

4 Àpẹẹrẹ kejì tá a máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni àwọn Kristẹni tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì. Àpọ́sítélì Jòhánù tó gbé ayé kẹ́yìn lára àwọn àpọ́sítélì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ará ìjọ, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa sin Jèhófà nìṣó. (3 Jòh. 4) Bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù yòókù, Jòhánù náà ṣiṣẹ́ kára láti dáàbò bo àwọn ará ìjọ lọ́wọ́ àwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n ń tan ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀. (1 Jòh. 2:18; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí 2 Tẹs. 2:7, nwtsty-E.) Àmọ́ lẹ́yìn tí Jòhánù kú, ọ̀pọ̀ lára àwọn ará ìjọ di apẹ̀yìndà. Lẹ́yìn ọdún mélòó kan, àwọn apẹ̀yìndà bẹ̀rẹ̀ sí í fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni nínú ìjọ, wọ́n sì fàyè gba ìwà ìbàjẹ́.

5. Lẹ́yìn tá a gbé àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì méjì yìí yẹ̀ wò, kí ni ò yẹ ká máa rò?

5 Ṣé àpẹẹrẹ méjèèjì tá a gbé yẹ̀ wò yìí wá fi hàn pé ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn àgùntàn mìíràn lẹ́yìn táwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run? Tó bá dìgbà yẹn, ṣé àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó wà láyé máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí ò dáa bíi ti Jèhóáṣì tàbí kí wọ́n di apẹ̀yìndà bíi tàwọn Kristẹni tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì S.K.? Rárá o, kò ní rí bẹ́ẹ̀! Ohun tó dá wa lójú ni pé lẹ́yìn táwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run, àwọn àgùntàn mìíràn á ṣì máa sin Jèhófà nìṣó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, Jèhófà á sì máa bójú tó wọn. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú?

JÈHÓFÀ Ò NÍ JẸ́ KÍ WỌ́N BA ÌJỌSÌN MÍMỌ́ JẸ́

6. Àwọn àkókò mẹ́ta wo la fẹ́ jíròrò báyìí?

6 Kí ló mú kó dá wa lójú pé ìjọsìn mímọ́ ò ní bà jẹ́, kódà láwọn àsìkò tí nǹkan máa nira lọ́jọ́ iwájú? Ohun tó mú kó dá wa lójú ni ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì nípa àkókò tá à ń gbé yìí. Àkókò tá à ń gbé yìí yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ àti tàwọn Kristẹni tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì. Torí náà, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé àwọn àkókò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí yẹ̀ wò: (1) Ìgbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, (2) ẹ̀yìn ìgbà tí gbogbo àwọn àpọ́sítélì Jésù kú àti (3) àkókò tá a wà yìí, ìyẹn ‘ìgbà ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo.’—Ìṣe 3:21.

7. Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí nìdí táwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára wọn ò fi rẹ̀wẹ̀sì nígbà táwọn èèyàn náà àtàwọn ọba wọn ń hùwà burúkú?

7 Ìgbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Mósè kú, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Mo mọ̀ dáadáa pé tí mo bá ti kú, ó dájú pé ẹ máa ṣe ohun tó burú, ẹ sì máa yà kúrò lójú ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún yín.” (Diu. 31:29) Mósè tún kìlọ̀ fún wọn pé tí wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀, wọ́n máa lọ sígbèkùn. (Diu. 28:35, 36) Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣẹ? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọba búburú fi ṣe ohun tí kò dáa lójú Jèhófà, tí wọ́n sì mú káwọn èèyàn Ọlọ́run máa jọ́sìn ọlọ́run èké. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà ṣe fìyà jẹ wọ́n, tí ò sì jẹ́ kí wọ́n ní ọba táá máa ṣàkóso wọn mọ́. (Ìsík. 21:25-27) Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jólóòótọ́ ń fìgboyà sin Ọlọ́run nìṣó nígbà tí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.—Àìsá. 55:10, 11.

8. Ṣé ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn apẹ̀yìndà tan ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀ nínú ìjọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì? Ṣàlàyé.

8 Ẹ̀yìn tí gbogbo àwọn àpọ́sítélì Jésù kú. Ṣé ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé àwọn apẹ̀yìndà tan ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀ nínú ìjọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì? Rárá o. Ìdí ni pé Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn apẹ̀yìndà máa pọ̀ gan-an. (Mát. 7:21-23; 13:24-30, 36-43) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Pétérù àti Jòhánù jẹ́rìí sí i pé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ti ń ṣẹ láti ìgbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. (2 Tẹs. 2:3, 7; 2 Pét. 2:1; 1 Jòh. 2:18) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn àpọ́sítélì Jésù kú, àwọn apẹ̀yìndà pọ̀ sí i, wọ́n sì di ara Bábílónì Ńlá, ìyẹn àpapọ̀ ìsìn èké àgbáyé. Bí àsọtẹ́lẹ̀ míì ṣe ṣẹ nìyẹn.

9. Báwo ni àkókò tá à ń gbé yìí ṣe yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ àti tàwọn Kristẹni tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì?

9 ‘Ìgbà ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo.’ Àkókò tá à ń gbé yìí yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ àti tàwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n gbé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì S.K. Àkókò wo la wà yìí? A sábà máa ń pe àkókò tá à ń gbé yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (2 Tím. 3:1) Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò kan náà ni àwọn ọjọ́ ìkẹyìn àti àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo bẹ̀rẹ̀. Àkókò yẹn á ṣì máa bá a lọ títí dìgbà tí Ìjọba Mèsáyà fi máa sọ àwọn èèyàn di pípé, táá sì sọ ayé di Párádísè. Àkókò náà ni Bíbélì pè ní ‘àwọn àkókò ìmúbọ̀sípò ohun gbogbo.’ (Ìṣe 3:21) Ọdún 1914 ni àkókò yẹn bẹ̀rẹ̀. Kí la mú bọ̀ sípò lọ́dún yẹn? Ọdún yẹn gan-an ni Jésù di Ọba lọ́run. Torí náà, Jèhófà tún pa dà ní alákòóso táá máa ṣojú fún un, tó sì máa jókòó sórí ìtẹ́ Ọba Dáfídì ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́. Àmọ́ kì í ṣe pé Jèhófà kàn sọ Jésù di ọba nìkan ni. Kò pẹ́ rárá sígbà yẹn, àwọn èèyàn Jèhófà pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọsìn mímọ́. (Àìsá. 2:2-4; Ìsík. 11:17-20) Ṣé Jèhófà máa gbà kí wọ́n tún ba ìjọsìn mímọ́ jẹ́?

10. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa ìjọsìn mímọ́ ní àkókò wa? (Àìsáyà 54:17) (b) Kí nìdí táwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi tù wá nínú?

10 Ka Àìsáyà 54:17. Ronú nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí ná: “Ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí ọ kò ní ṣàṣeyọrí”! Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì yìí ti ṣẹ lákòókò wa. Àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tó tẹ̀ lé e yìí náà ti ń ṣẹ lákòókò wa: “Jèhófà máa kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ sì máa pọ̀ gan-an. O máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú òdodo. . . . O ò ní bẹ̀rù ohunkóhun, ohunkóhun ò sì ní já ọ láyà, torí pé kò ní sún mọ́ ọ.” (Àìsá. 54:13, 14) Kódà Sátánì tó jẹ́ “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ò lè dá iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwa èèyàn Jèhófà ń ṣe dúró. (2 Kọ́r. 4:4) Ìjọsìn mímọ́ ti pa dà bọ̀ sípò, wọn ò sì ní lè bà á jẹ́ mọ́ láé. Títí láé ló máa wà. Torí náà, kò sí ohun ìjà èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe sí wa tó máa ṣàṣeyọrí!

KÍ LÓ MÁA ṢẸLẸ̀?

11. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní pa àwọn àgùntàn mìíràn tì nígbà táwọn ẹni àmì òróró bá lọ sọ́run?

11ló máa ṣẹlẹ̀ tí gbogbo àwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run? Rántí pé Jésù ló ń darí wa. Òun ni orí ìjọ Kristẹni. Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé: “Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi.” (Mát. 23:10) Torí náà, ó dá wa lójú pé gbogbo ìgbà ni Jésù Ọba wa tó ń ṣàkóso á máa bójú tó àwa èèyàn ẹ̀. Torí pé Kristi lá máa darí wa, kò sídìí kankan tó fi yẹ káwa èèyàn Jèhófà láyé máa bẹ̀rù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Kristi ṣe máa darí àwa èèyàn Jèhófà nígbà yẹn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò nínú Bíbélì tó jẹ́ kó dá wa lójú pé Kristi máa bójú tó àwa èèyàn ẹ̀.

12. Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó àwọn èèyàn ẹ̀ (a) lẹ́yìn tí Mósè kú? (b) lẹ́yìn tó gbẹ́ṣẹ́ tuntun fún Èlíjà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Mósè ti kú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run? Ṣé torí pé ọkùnrin olóòótọ́ yìí kú, Jèhófà ò wá ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ mọ́? Rárá o. Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fi jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ó ń bójú tó wọn. Kí Mósè tó kú, Jèhófà sọ fún un pé kó yan Jóṣúà kó lè máa darí àwọn èèyàn òun. Ọ̀pọ̀ ọdún sì ni Mósè ti fi dá Jóṣúà lẹ́kọ̀ọ́. (Ẹ́kís. 33:11; Diu. 34:9) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yan ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n láti jẹ́ olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá. (Diu. 1:15) Ohun tó ṣe yìí jẹ́ kí wọ́n lè bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run dáadáa. Èlíjà náà ṣe ohun tó jọ ìyẹn. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà yan iṣẹ́ míì fún un ní apá gúúsù ilẹ̀ Júdà. (2 Ọba 2:1; 2 Kíró. 21:12) Ṣé Jèhófà wá pa ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní apá àríwá tì? Rárá o. Ọ̀pọ̀ ọdún ni Èlíjà ti fi ń dá Èlíṣà lẹ́kọ̀ọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣètò bí wọ́n ṣe dá “àwọn ọmọ wòlíì” lẹ́kọ̀ọ́. (2 Ọba 2:7) Ohun tó ṣe yìí ló jẹ́ káwọn ọkùnrin olóòótọ́ lè kúnjú ìwọ̀n láti máa bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run. Jèhófà ò ṣíwọ́ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, ó ń rí i dájú pé òun bójú tó àwọn tó ń fi òótọ́ sin òun.

Mósè (àwòrán apá òsì) àti Èlíjà (àwòrán apá ọ̀tún), ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń dá ẹni tó máa gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ (Wo ìpínrọ̀ 12)


13. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún wa ní Hébérù 13:5b? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Pẹ̀lú àwọn àpẹẹrẹ tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá lọ sọ́run? Kò yẹ ká dara wa láàmú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Bíbélì sọ òótọ́ kan tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé: Jèhófà ò ní pa àwa èèyàn ẹ̀ tó wà láyé tì láé. (Ka Hébérù 13:5b.) Bíi ti Mósè àti Èlíjà, àwùjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ń bójú tó àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn dá àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ń dá àwọn arákùnrin míì tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa ṣàbójútó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti ṣètò ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ láti dá àwọn alàgbà, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míì lẹ́kọ̀ọ́. Ìgbìmọ̀ Olùdarí fúnra wọn tún máa ń dá àwọn arákùnrin tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àwọn arákùnrin yìí sì wà nínú onírúurú ìgbìmọ̀ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò. Kódà ní báyìí, àwọn arákùnrin yìí ń fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀pọ̀ ojúṣe nínú ètò Ọlọ́run. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti gbà yìí ti múra wọn sílẹ̀ láti máa bójú tó àwọn àgùntàn Kristi nìṣó.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti ṣiṣẹ́ kára láti dá àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ti ṣètò ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́ láti dá àwọn alàgbà, àwọn alábòójútó àyíká, àwọn arákùnrin tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé (Wo ìpínrọ̀ 13)


14. Kí ni kókó ohun tá a ti ń jíròrò?

14 Kókó ohun tá a ti ń jíròrò ni pé: Nígbà tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá, àwa èèyàn Jèhófà á ṣì máa bá ìjọsìn tòótọ́ lọ láyé. Torí pé Jésù ló ń darí wa, àwa èèyàn Ọlọ́run á ṣì máa sìn ín nìṣó, a ò ní pàdánù ohunkóhun. Òótọ́ ni pé nígbà yẹn, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè á ti gbéjà kò wá torí pé wọ́n kórìíra wa. (Ìsík. 38:18-20) Àmọ́ àkókò tí wọ́n fi máa gbéjà kò wá ò ní pẹ́, kò sì ní dí àwa èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn ẹ̀. Ó dájú pé ó máa gbà wá sílẹ̀! Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn ti Kristi. Áńgẹ́lì kan sọ fún Jòhánù pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” yìí wá “látinú ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:9, 14) Torí náà, ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa gbà wọ́n là!

15-16. Kí ni Ìfihàn 17:14 sọ pé àwọn ẹni àmì òróró Kristi á máa ṣe nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, kí sì nìdí tíyẹn ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?

15 Síbẹ̀, àwọn kan ṣì lè máa béèrè pé: ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹni àmì òróró? Kí ni wọ́n á máa ṣe tí wọ́n bá ti lọ sọ́run?’ Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí ní tààràtà. Ó sọ pé àwọn ìjọba ayé yìí máa “bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jà.” Ó sì dájú pé wọ́n máa fìdí rẹmi. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa ṣẹ́gun wọn.” Àwọn wo ló máa ràn án lọ́wọ́? Ẹsẹ yẹn kan náà dáhùn ìbéèrè yẹn. Ó ní: Àwọn tí a “pè,” “tí wọ́n jẹ́ àyànfẹ́” àti “olóòótọ́.” (Ka Ìfihàn 17:14.) Àwọn wo nìyẹn? Àwọn ẹni àmì òróró tó ti jíǹde ni! Torí náà, tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run lápá ìparí ìpọ́njú ńlá, ọ̀kan lára iṣẹ́ tí wọ́n máa kọ́kọ́ ṣe ni pé kí wọ́n jagun. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ńlá nìyẹn! Àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró ti jagun rí kí wọ́n tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kódà, àwọn kan tiẹ̀ ti wà nínú ẹgbẹ́ ológun àwọn orílẹ̀-èdè kan rí. Àmọ́ nígbà tí wọ́n di Kristẹni tòótọ́, wọ́n kọ́ bí wọ́n á ṣe máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. (Gál. 5:22; 2 Tẹs. 3:16) Wọn ò dá sọ́rọ̀ ogun mọ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n bá lọ sọ́run, àwọn àti Jésù pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì máa bá àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ja ogun ìkẹyìn.

16 Ẹ̀yin náà ẹ wo bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ṣì wà láyé ṣe rí báyìí, àwọn kan lára wọn ti dàgbà gan-an. Àmọ́ tí Jèhófà bá ti jí wọn dìde sọ́run, wọ́n á di ẹni ẹ̀mí tó lágbára tí ò lè kú mọ́, wọ́n á sì dara pọ̀ mọ́ Jésù Kristi tó jẹ́ Olórí Ogun wọn láti jagun. Lẹ́yìn tí wọ́n bá jagun Amágẹ́dọ́nì tán, wọ́n á ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Jésù láti sọ àwa èèyàn di pípé. Ó dájú pé nígbà yẹn, ìrànlọ́wọ́ táwọn ẹni àmì òróró máa ṣe fún àwa arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn máa pọ̀ gan-an ju ti ìgbà tí wọ́n ṣì jẹ́ aláìpé láyé!

17. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa gba gbogbo àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ là nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì?

17 Ṣé ara àgùntàn mìíràn ni ẹ́? Kí ló máa pọn dandan fún láti ṣe nígbà tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá bẹ̀rẹ̀? Ohun tó o máa ṣe ò ju pé kó o gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kó o sì ṣe ohun tó bá ní kó o ṣe. Kí làwọn nǹkan náà ṣeé ṣe kó jẹ́? Ohun tí Bíbélì sọ fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú, kí ẹ sì ti àwọn ilẹ̀kùn yín mọ́ ara yín. Ẹ fi ara yín pa mọ́ fúngbà díẹ̀, títí ìbínú náà fi máa kọjá lọ.” (Àìsá. 26:20) Gbogbo àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àti lọ́run ni Jèhófà máa dáàbò bò lásìkò yẹn. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó dá àwa náà lójú pé kì í ṣe “àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tó wà nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tó ń bọ̀ . . . ló máa lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:38, 39) Torí náà, máa rántí nígbà gbogbo pé: Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ, kò sì ní pa ẹ́ tì láé!

NÍGBÀ TÍ ÈYÍ TÓ KẸ́YÌN LÁRA ÀWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ BÁ LỌ SỌ́RUN,

  • kí ni ò ní ṣẹlẹ̀?

  • kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí wọ́n ba ìjọsìn mímọ́ jẹ́?

  • kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa bójú tó àwa èèyàn ẹ̀?

ORIN 8 Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa