Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 7

ORIN 51 A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!

Ohun Tá A Kọ́ Lára Àwọn Násírì

Ohun Tá A Kọ́ Lára Àwọn Násírì

“Ní gbogbo ọjọ́ tó bá fi jẹ́ Násírì, ó jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà.”NỌ́Ń. 6:8.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa rí bí àpẹẹrẹ àwọn Násírì ṣe máa jẹ́ ká nígboyà, ká sì yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan bá a ṣe ń sin Jèhófà.

1. Ìwà tó dáa wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní látìbẹ̀rẹ̀?

 ṢÉ O mọyì àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà? Ó dájú pé o ṣe bẹ́ẹ̀! Ọ̀pọ̀ àwọn ará míì náà mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà. Bákan náà nígbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú ẹ̀. (Sm. 104:33, 34) Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà la máa ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan ká lè jọ́sìn ẹ̀. Ohun táwọn Násírì nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe nìyẹn. Àmọ́ ta ni àwọn Násírì, kí la sì lè kọ́ lára wọn?

2. (a) Ta ni àwọn Násírì? (Nọ́ńbà 6:1, 2) (b) Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan fi jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì?

2 Ọ̀rọ̀ náà “Násírì” wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Ẹni Tí A Yàn,” “Ẹni Tí A Yà Sọ́tọ̀” tàbí “Ẹni Tí A Yà Sí Mímọ́.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí báwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣe yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè sin Jèhófà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Òfin Mósè gba ọkùnrin tàbí obìnrin kan láyè láti jẹ́jẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún Jèhófà pé òun máa di Násírì fún àkókò kan. a (Ka Nọ́ńbà 6:1, 2.) Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì, á máa pa àwọn òfin kan mọ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù kì í pa mọ́. Àmọ́, kí ló máa ń jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan jẹ́jẹ̀ẹ́ láti di Násírì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìfẹ́ tí irú ọmọ Ísírẹ́lì bẹ́ẹ̀ ní sí Jèhófà àti bó ṣe mọyì ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jèhófà ṣe fún un ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀.—Diu. 6:5; 16:17.

3. Báwo làwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ṣe dà bí àwọn Násírì?

3 Nígbà tí “òfin Kristi” rọ́pò Òfin Mósè, kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn Ọlọ́run láti di Násírì mọ́. (Gál. 6:2; Róòmù 10:4) Àmọ́ bíi tàwọn Násírì, ó máa ń wu àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí láti fi gbogbo ọkàn, èrò àti okun wa sin Jèhófà. (Máàkù 12:30) Ìgbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà la máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí. Ká lè mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ, a gbọ́dọ̀ máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà, ká sì ṣe tán láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan torí ìjọsìn Jèhófà. Torí náà, bá a ṣe ń jíròrò báwọn Násírì ṣe mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, ẹ jẹ́ káwa náà kọ́ bá a ṣe lè mú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ. b (Mát. 16:24) Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

MÁA YÁÁFÌ NǸKAN

4. Àwọn nǹkan wo ni Nọ́ńbà 6:3, 4 sọ pé àwọn Násírì yááfì?

4 Ka Nọ́ńbà 6:3, 4. Àwọn Násírì ò gbọ́dọ̀ mu ọtí, wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí wọ́n fi èso àjàrà tàbí àjàrà gbígbẹ ṣe. Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù máa ń gbádùn àwọn oúnjẹ yìí torí Jèhófà ò ka àwọn oúnjẹ náà léèwọ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni “wáìnì tó ń mú ọkàn èèyàn yọ̀.” (Sm. 104:14, 15) Ó wu àwọn Násírì pé káwọn náà máa gbádùn àwọn oúnjẹ yìí, síbẹ̀ wọ́n pinnu láti yááfì ẹ̀. c

Ṣé ìwọ náà ṣe tán láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan bíi tàwọn Násírì? (Wo ìpínrọ̀ 4-6)


5. Kí ni Madián àti Marcela yááfì, kí sì nìdí?

5 Bíi tàwọn Násírì, àwa náà máa ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan ká lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Madián àti Marcela. d Tọkọtaya yìí máa ń gbádùn ara wọn gan-an. Madián níṣẹ́ tó ń mówó gidi wọlé, ìyẹn sì jẹ́ káwọn méjèèjì máa gbé inú ilé ńlá. Àmọ́ ó wù wọ́n pé kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà. Torí náà, kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n ń wá, wọ́n pinnu pé àwọn máa ṣe àwọn àtúnṣe kan. Wọ́n sọ pé: “A bẹ̀rẹ̀ sí í dín ìnáwó wa kù díẹ̀díẹ̀. A kó lọ sílé kékeré kan, a sì ta mọ́tò wa.” Kò sẹ́ni tó fi dandan mú Madián àti Marcela pé kí wọ́n yááfì àwọn nǹkan yìí, ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó máa jẹ́ kí wọ́n ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Inú wọn dùn, ọkàn wọn sì balẹ̀ torí ìpinnu tí wọ́n ṣe yìí.

6. Kí nìdí táwa Kristẹni fi ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan lónìí? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

6 Inú àwa èèyàn Jèhófà máa ń dùn láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan ká lè túbọ̀ ráyè ṣiṣẹ́ Jèhófà. (1 Kọ́r. 9:3-6) Jèhófà ò fi dandan mú wa pé ká yááfì àwọn nǹkan yẹn, kì í sì í ṣe pé àwọn nǹkan yẹn burú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti fi iṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ràn gan-an sílẹ̀, àwọn kan ta ilé wọn, kódà àwọn kan ti yááfì ohun ọ̀sìn wọn. Ọ̀pọ̀ ló ti pinnu pé àwọn ò tíì ní ṣègbéyàwó tàbí káwọn ní ọmọ. Àwọn míì sì ti pinnu pé àwọn máa lọ sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn lè mú kí wọ́n jìnnà sáwọn èèyàn wọn. Ìdí tí ọ̀pọ̀ wa fi ń yááfì àwọn nǹkan yìí ni pé ohun tó dáa jù la fẹ́ fún Jèhófà. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń yááfì bó ti wù kó kéré tó, kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀.—Héb. 6:10.

PINNU PÉ WÀÁ DÁ YÀTỌ̀

7. Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe kí Násírì kan ní bó ṣe ń sapá láti mú ẹ̀jẹ́ ẹ̀ ṣẹ? (Nọ́ńbà 6:5) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Ka Nọ́ńbà 6:5. Àwọn Násírì máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn ò ní gé irun àwọn. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí máa ń fi hàn pé wọ́n fẹ́ mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ délẹ̀délẹ̀. Tó bá ti pẹ́ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ti di Násírì, irun ẹ̀ lè ti gùn débi pé àwọn èèyàn máa mọ̀ pé Násírì ni. Táwọn èèyàn tó wà láyìíká ẹ̀ bá ń fún un níṣìírí, ó lè má ṣòro fún un láti mú ẹ̀jẹ́ ẹ̀ ṣẹ. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn ìgbà kan wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ò mọyì àwọn Násírì, wọn ò sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà ayé wòlíì Émọ́sì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti di apẹ̀yìndà “ń fún [àwọn] Násírì ní wáìnì mu,” ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí kí wọ́n má bàa mú ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ ṣẹ pé àwọn ò ní mutí ni wọ́n ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Émọ́sì 2:12) Nígbà míì, ó máa ń gba pé kí Násírì kan nígboyà kó tó lè dúró lórí ìpinnu tó ṣe, kó sì lè yàtọ̀ sáwọn tí kì í ṣe Násírì.

Násírì tó fẹ́ mú ẹ̀jẹ́ ẹ̀ ṣẹ máa ń ṣe tán láti dá yàtọ̀ sáwọn tí kì í ṣe Násírì (Wo ìpínrọ̀ 7)


8. Kí ló wú ẹ lórí nípa ohun tí ọ̀dọ́kùnrin Benjamin ṣe?

8 Jèhófà lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti nígboyà, kó o sì dá yàtọ̀ kódà tó bá jẹ́ pé ojú máa ń tì ẹ́. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọmọ ọdún mẹ́wàá kan tó ń jẹ́ Benjamin. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, orílẹ̀-èdè Norway ló sì ń gbé. Nítorí ogun tí wọ́n ń jà ní Ukraine, ilé ìwé ẹ̀ ṣètò kan láti fi hàn pé àwọn ń kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ará ìlú náà. Wọ́n sọ pé káwọn ọmọ ilé ìwé náà kọ orin kan, kí wọ́n sì wọ aṣọ tó ní àwọ̀ àsíá orílẹ̀-èdè Ukraine. Benjamin ti pinnu pé òun ò ní bá wọn lọ́wọ́ sí ayẹyẹ orílẹ̀-èdè yẹn, torí náà ó dọ́gbọ́n kúrò nítòsí ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe é. Àmọ́ olùkọ́ kan rí i, ó sì pariwo mọ́ ọn pé: “Ó yá bọ́ síbí, à ń dúró dè ẹ́!” Torí náà, Benjamin lọ bá olùkọ́ náà, ó sì fìgboyà sọ fún un pé: “Mi ò kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú lọ́nàkọnà. Kódà, ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.” Olùkọ́ náà gba ohun tí Benjamin sọ, ó sì ní kó máa lọ. Àmọ́, àwọn ọmọ kíláàsì ẹ̀ ń dà á láàmú pé kí ló dé tí ò dara pọ̀ mọ́ àwọn. Àyà Benjamin já débi pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bú sẹ́kún, síbẹ̀ ó lo ìgboyà, ó sì tún ohun tó sọ fún olùkọ́ ẹ̀ sọ fáwọn ọmọ kíláàsì ẹ̀. Nígbà tó délé, ó sọ fáwọn òbí ẹ̀ pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ohun tóun gbà gbọ́.

9. Báwo la ṣe lè mú ọkàn Jèhófà yọ̀?

9 Torí a ti pinnu pé ìfẹ́ Jèhófà la fẹ́ ṣe, a máa ń dá yàtọ̀ sáwọn tó wà láyìíká wa. Ó gba ìgboyà ká tó lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá nílé ìwé tàbí níbi iṣẹ́. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé, táwọn èèyàn sì ń hùwà ìbàjẹ́, ó máa túbọ̀ ṣòro fún wa láti fi ìlànà Bíbélì sílò, ká sì máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. (2 Tím. 1:8; 3:13) Torí náà ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ máa rántí pé a máa “mú ọkàn [Jèhófà] yọ̀” tá a bá ń fìgboyà ṣe ohun tó jẹ́ ká dá yàtọ̀ sáwọn tí ò sin Jèhófà.—Òwe 27:11; Mál. 3:18.

FI JÈHÓFÀ SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́ NÍGBÈÉSÍ AYÉ Ẹ

10. Kí ló lè mú kó ṣòro fún Násírì kan láti pa àṣẹ tó wà ní Nọ́ńbà 6:6, 7 mọ́?

10 Ka Nọ́ńbà 6:6, 7. Àwọn Násírì ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ òkú. Téèyàn bá kọ́kọ́ wò ó, ó lè dà bí ohun tí ò ṣòro ṣe. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó máa ṣòro fún Násírì kan láti pa òfin yìí mọ́ tí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan tó sún mọ́ ọn bá kú. Ìdí sì ni pé ààtò ìsìnkú nígbà yẹn máa ń gba pé káwọn èèyàn sún mọ́ òkú náà. (Jòh. 19:39, 40; Ìṣe 9:36-40) Àmọ́, ẹ̀jẹ́ tí Násírì kan jẹ́ ò ní jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà lásìkò tí ìdílé yẹn ṣì ń ṣọ̀fọ̀, àwọn Násírì ṣì máa ń mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára. Àmọ́ Jèhófà máa ń rí i dájú pé òun fún àwọn Násírì yìí lókun, kí wọ́n lè kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní.

11. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan fi sọ́kàn tó bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ìdílé? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

11 Àwa Kristẹni máa ń fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀jẹ́ tá a jẹ́ fún Jèhófà. Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ ìdílé, a máa ń fi ẹ̀jẹ́ yìí sọ́kàn. A máa ń bójú tó ìdílé wa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe sọ, àmọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ la máa ń fi ṣáájú ohun tí ìdílé wa fẹ́. (Mát. 10:35-37; 1 Tím. 5:8) Nígbà míì sì rèé, ó lè gba pé ká ṣe àwọn ìpinnu tínú àwọn mọ̀lẹ́bí wa ò ní dùn sí, àmọ́ táá múnú Jèhófà dùn.

Ṣé ó máa ń wù ẹ́ láti fi Jèhófà ṣáájú, kódà lásìkò tí nǹkan nira fún ẹ? (Wo ìpínrọ̀ 11) e


12. Kí ni Alexandru ṣe nígbà tí ìyàwó ẹ̀ ò fẹ́ kó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, kí ni ò sì ṣe?

12 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Alexandru àti Dorina ìyàwó ẹ̀. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn méjèèjì ló jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ lẹ́yìn ọdún kan Dorina sọ pé òun ò kẹ́kọ̀ọ́ mọ́, ó sì fẹ́ kí Alexandru náà dá ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ dúró. Torí náà, Alexandru fara balẹ̀ ṣàlàyé fún un pé òun á ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó. Àmọ́ Dorina ò fara mọ́ ohun tó sọ yẹn, ó sì fẹ́ fipá mú un pé kó dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún Alexandru, ó gbìyànjú láti mọ ìdí tí ìyàwó òun fi fẹ́ kóun dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Nígbà míì, tí Dorina bá ń ṣàríwísí tó sì ń kanra mọ́ ọn, ó máa ń ṣe é bíi pé kó má kẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Síbẹ̀, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni Alexandru ń ṣe, kò sì yéé fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn sí ìyàwó ẹ̀. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, torí pé ọkọ ẹ̀ ń hùwà tó dáa sí i, Dorina bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà, nígbà tó sì yá, ó ṣèrìbọmi.—Wo fídíò yìí lórí jw.org, Alexandru àti Dorina Vacar: “Ìfẹ́ Máa Ń Ní Sùúrù àti Inú Rere” ní abala “Òtítọ́ Ń Yí Ìgbésí Ayé Pa Dà.”

13. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti ìdílé ẹ?

13 Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀, ó sì fẹ́ ká máa láyọ̀. (Éfé. 3:14, 15) Tó bá wù wá pé ká láyọ̀, a gbọ́dọ̀ máa ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kó o lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, bó o ṣe ń bójú tó ìdílé ẹ, tó o sì ń fi ọ̀wọ̀ àti ìfẹ́ hàn sí wọn.—Róòmù 12:10.

Ẹ JẸ́ KÁ MÁA FÚN ARA WA NÍṢÌÍRÍ LÁTI DÀ BÍ ÀWỌN NÁSÍRÌ

14. Àwọn wo ló yẹ ká máa fún níṣìírí jù?

14 Ó yẹ kó máa wu àwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo la ṣe lè ran ara wa lọ́wọ́ ká lè máa yááfì nǹkan fún Jèhófà? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń sọ̀rọ̀ tó ń fún àwọn míì níṣìírí. (Jóòbù 16:5) Ṣé àwọn kan wà nínú ìjọ ẹ tí wọ́n ń gbìyànjú láti jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣé o mọ àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ń fìgboyà ṣe ohun tó mú kí wọ́n yàtọ̀ sáwọn ọmọ ilé ìwé wọn, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn rárá? Ṣé o mọ àwọn kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn ará kan tí ò rọrùn fún láti máa sin Jèhófà torí pé ìdílé wọn ń ta kò wọ́n? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti fi irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì ìgboyà tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe ń yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan.—Fílém. 4, 5, 7.

15. Báwo làwọn kan ṣe ń ran àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́wọ́?

15 Nígbà míì, a máa ń ṣe ohun tó máa ṣe àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láǹfààní. (Òwe 19:17; Héb. 13:16) Ohun tó wu arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń gbé ní Sri Lanka nìyẹn. Wọ́n fi kún owó ìfẹ̀yìntì ẹ̀, ó sì fẹ́ ran àwọn arábìnrin méjì kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀ ajé ti dẹnu kọlẹ̀. Torí náà, ó pinnu pé òun á máa fún wọn ní iye owó kan lóṣooṣù tí wọ́n á máa fi pe àwọn èèyàn lórí fóònù. Ẹ ò rí i pé nǹkan tó dáa ni arábìnrin yẹn ṣe!

16. Kí la kọ́ lára àwọn Násírì ìgbà àtijọ́?

16 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti di Násírì nígbà àtijọ́. Àmọ́, ètò tí Jèhófà ṣe yìí tún kọ́ wa láwọn nǹkan kan nípa Jèhófà Bàbá wa ọ̀run. Jèhófà mọ̀ pé tọkàntọkàn la fi ń ṣe ohun tóun fẹ́ àti pé a ṣe tán láti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan ká lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ. Ó tún buyì kún wa torí ó fún wa láǹfààní láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òun. (Òwe 23:15, 16; Máàkù 10:28-30; 1 Jòh. 4:19) Yàtọ̀ síyẹn, ètò tí Jèhófà ṣe pé káwọn èèyàn di Násírì fi hàn pé ó ń rí gbogbo ohun tá à ń yááfì láti jọ́sìn ẹ̀, ó sì mọyì ẹ̀ gan-an. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa sin Jèhófà nìṣó, àá sì máa fi tọkàntọkàn yááfì gbogbo ohun tó bá gbà ká lè máa jọ́sìn ẹ̀.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti di Násírì ṣe tó fi hàn pé wọ́n yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan fún Jèhófà, wọ́n sì nígboyà?

  • Báwo la ṣe lè máa fún ara wa níṣìírí lónìí, ká lè dà bí àwọn Násírì?

  • Báwo ni ètò tí Jèhófà ṣe pé káwọn èèyàn di Násírì ṣe jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe fọkàn tán àwa ìránṣẹ́ ẹ̀?

ORIN 124 Jẹ́ Adúróṣinṣin

a Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló dìídì yan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan láti di Násírì, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Násírì ló yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ fún àkókò kan.—Wo àpótí náà, “ Àwọn Tí Jèhófà Fúnra Ẹ̀ Sọ Di Násírì.”

b Nígbà míì, àwọn ìwé wa máa ń fi àwọn Násírì wé àwọn tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àmọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí gbogbo àwa èèyàn Jèhófà tá a ti ya ara wa sí mímọ́ ṣe lè máa yááfì nǹkan bíi tàwọn Násírì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

c Ó jọ pé kò sí iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kankan tí Jèhófà sọ pé káwọn Násírì máa ṣe kí wọ́n tó lè mú ẹ̀jẹ́ wọn ṣẹ.

d Wo àpilẹ̀kọ yìí lórí jw.org, “A Pinnu Láti Jẹ́ Kí Nǹkan Díẹ̀ Tẹ́ Wa Lọ́rùn” lábẹ́ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

e ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Násírì kan dúró sórí òrùlé, ó ń wo bí wọ́n ṣe fẹ́ lọ sin mọ̀lẹ́bí ẹ̀ kan tó kú. Àmọ́ torí pé Násírì ni, kò lè sún mọ́ òkú náà.