Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Láyọ̀ Bó O Ṣe Ń Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà

Máa Láyọ̀ Bó O Ṣe Ń Fi Sùúrù Dúró De Jèhófà

ṢÉ Ò ń fojú sọ́nà de ìgbà tí Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò, tó sì máa sọ ohun gbogbo di tuntun? (Ìfi. 21:1-5) Ó dájú pé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀! Àmọ́, kì í ṣe ohun tó rọrùn kéèyàn máa fi sùúrù dúró de Jèhófà, pàápàá téèyàn bá níṣòro. Ìdí sì ni pé tóhun tá à ń retí bá ti ń pẹ́ jù, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì.—Òwe 13:12, àlàyé ìsàlẹ̀.

Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ ká fi sùúrù dúró de ìgbà tóun máa yanjú ìṣòro wa. Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká ní sùúrù? Kí lá jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń dúró de Jèhófà?

KÍ NÌDÍ TÍ JÈHÓFÀ FI FẸ́ KÁ NÍ SÙÚRÙ?

Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ń fi sùúrù dúró láti ṣojúure sí yín, ó sì máa dìde láti ṣàánú yín. Torí pé Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà. Aláyọ̀ ni gbogbo àwọn tó ń retí rẹ̀.” (Àìsá. 30:18) Àwọn Júù olórí kunkun ni Àìsáyà dìídì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún. (Àìsá. 30:1) Àmọ́, àwọn Júù kan wà láàárín wọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ọ̀rọ̀ yìí sì jẹ́ kí wọ́n nírètí. Bákan náà lónìí, ọ̀rọ̀ yìí ń jẹ́ káwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà nírètí.

Torí náà, a gbọ́dọ̀ fi sùúrù dúró de Jèhófà torí òun náà ń fi sùúrù dúró. Ó ti pinnu àkókò tó máa pa ayé burúkú yìí run, ó sì ń dúró de ọjọ́ àti wákàtí tó máa ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 24:36) Tó bá dìgbà yẹn, gbogbo àwọn èèyàn ló máa mọ̀ pé irọ́ ni Sátánì ń pa mọ́ Jèhófà àti gbogbo àwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà. Á wá pa Sátánì àti gbogbo àwọn tó ń tì í lẹ́yìn run, àmọ́ ní tiwa Jèhófà máa “ṣàánú [wa].”

Kó tó dìgbà yẹn, ó lè má jẹ́ gbogbo ìṣòro wa ni Jèhófà máa mú kúrò, àmọ́ ó fi dá wa lójú pé a ṣì lè máa láyọ̀ bá a ṣe ń dúró de òun. Bí Àìsáyà ṣe sọ, a ṣì lè láyọ̀ bá a ṣe ń retí àwọn ohun rere tí Jèhófà máa ṣe fún wa. (Àìsá. 30:18) a Kí ló máa jẹ́ ká nírú ayọ̀ yẹn? Nǹkan mẹ́rin kan wà tó lè ràn wá lọ́wọ́.

OHUN TÓ MÁA JẸ́ KÁ LÁYỌ̀ BÁ A ṢE Ń DÚRÓ DE JÈHÓFÀ

Máa ronú nípa àwọn nǹkan dáadáa tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ. Jálẹ̀ ìgbésí ayé Ọba Dáfídì, ó rí ìwà ìkà tó burú jáì táwọn èèyàn ń hù. (Sm. 37:35) Síbẹ̀, ó sọ pé: “Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà kí o sì dúró dè é. Má banú jẹ́ nítorí ẹni tó gbèrò ibi, tó sì mú un ṣẹ.” (Sm. 37:7) Dáfídì náà fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn torí ìlérí tí Jèhófà ṣe fún un pé òun máa gbà á sílẹ̀ ló gbájú mọ́. Ó sì tún mọyì àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún un. (Sm. 40:5) Táwa náà bá ń wo àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wa, tá ò sì jẹ́ kí ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, á jẹ́ kó rọrùn fún wa láti dúró de Jèhófà.

Máa yin Jèhófà. Ẹni tó kọ Sáàmù 71, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Dáfídì sọ pé: “Èmi yóò máa dúró dè ọ́; màá fi kún ìyìn rẹ.” (Sm. 71:14) Báwo ni Dáfídì ṣe yin Jèhófà? Ó dájú pé ó ń sọ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, ó sì ń kọrin ìyìn sí i. (Sm. 71:16, 23) Bíi ti Dáfídì, àwa náà lè máa láyọ̀ bá a ṣe ń dúró de Jèhófà. A máa ń yin Jèhófà tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn, tá à ń sọ nípa ẹ̀ fáwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn tá a jọ wà nínú ìdílé, tá a sì ń kọ àwọn orin wa. Torí náà, gbogbo ìgbà tó o bá ti ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run ni kó o máa fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà àti bí wọ́n ṣe lè jẹ́ kó o láyọ̀.

Má jìnnà sáwọn ará. Nígbà tí Dáfídì níṣòro, ó sọ fún Jèhófà pé: “Níwájú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ, màá gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ rẹ.” (Sm. 52:9) Àwa náà máa rí ìṣírí gbà lọ́dọ̀ àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà láwọn ìpàdé wa, nígbà tá a bá jọ ń wàásù àti nígbà tá a bá ń gbádùn ara wa níbi ìkórajọ.—Róòmù 1:11, 12.

Jẹ́ kí ìrètí tó o ní túbọ̀ dá ẹ lójú. Sáàmù 62:5 sọ pé: “Mo dúró jẹ́ẹ́ de Ọlọ́run nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi ti wá.” Ó ṣe pàtàkì pé kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú, pàápàá tí òpin ò bá dé nígbà tá a retí pé kó dé. Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ, tó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tá a ti ń retí ẹ̀. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú ẹ̀, tá a sì rí bí àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣe jọra bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó kọ ọ́ yàtọ̀ síra, tá a sì tún kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ nípa ara ẹ̀, á jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú. (Sm. 1:2, 3) Yàtọ̀ síyẹn, bá a ṣe ń dúró de Jèhófà pé kó mú ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun tó ṣe fún wa ṣẹ, ó yẹ ká ‘jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa bá a ṣe ń gbàdúrà,’ ká lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀.—Júùdù 20, 21.

Bíi ti Ọba Dáfídì, mọ̀ dájú pé Jèhófà ń rí gbogbo àwọn tó ń fi sùúrù dúró dè é, ó sì máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wọn. (Sm. 33:18, 22) Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé bó o ṣe ń fi sùúrù dúró de Jèhófà, máa ronú nípa àwọn nǹkan dáadáa tí Jèhófà ń ṣe fún ẹ, máa yin Jèhófà, má jìnnà sáwọn ará, kó o sì jẹ́ kí ìrètí tó o ní túbọ̀ dá ẹ lójú.

a Ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ń retí” tún lè túmọ̀ sí “kí nǹkan máa wu ẹnì kan gan-an,” ìyẹn sì jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tó burú níbẹ̀ bó ṣe ń wù wá pé kí Jèhófà fòpin sí ìyà tó ń jẹ wá.