Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Wá Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Tó O Lè Fi Sílò

Wá Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Tó O Lè Fi Sílò

Tá a bá ń ka Bíbélì, tá a sì ń ṣèwádìí, a máa rí àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye tá a lè fi sílò. Àmọ́ kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ jàǹfààní?

Walẹ̀ jìn kó o lè rí àwọn kókó pàtàkì tó wà níbi tó o kà. Bí àpẹẹrẹ, ṣèwádìí nípa ẹni tó kọ ìwé Bíbélì yẹn, ẹni tí wọ́n kọ ọ́ sí àti ìgbà tí wọ́n kọ ọ́. Kí ló mú kó kọ ọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ kó tó kọ ọ́, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó kọ ọ́?

Wàá rí ẹ̀kọ́ kọ́ tó o bá ṣèwádìí nípa àwọn ìbéèrè bíi: ‘Báwo ni nǹkan ṣe rí lára àwọn tó wà nínú ibi tí mo kà? Àwọn ànímọ́ wo ni wọ́n ní? Kí nìdí tó fi yẹ kí n nírú àwọn ànímọ́ yẹn tàbí kí n yẹra fún irú ìwà tí wọ́n hù?’

Fi àwọn nǹkan tó o kọ́ sílò lóde ìwàásù àti láwọn ìgbà tó o bá ń ṣe nǹkan pẹ̀lú àwọn míì. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé o ní ọgbọ́n Ọlọ́run torí Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó bá gbọ́n yóò kíyè sí àwọn nǹkan yìí.”—Sm. 107:43.

  • Ohun tó o máa ṣe: Kíyè sí bí àwọn nǹkan tá a máa ń jíròrò ní apá ìpàdé Àwọn Ìṣúra inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe máa ń jẹ́ ká rí bá a ṣe lè fi àwọn ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò. Apá yìí sábà máa ń ní àwọn ìbéèrè tá a lè bi ara wa, àwọn kókó tá a lè ronú lé àtàwọn àpèjúwe táá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yé wa.