Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 25

ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa

Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”

Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”

“Jèhófà wà láàyè!”SM. 18:46.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá ń rántí pé “Ọlọ́run alààyè” là ń sìn.

1. Kí ló ń jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà nìṣó láìka àwọn ìṣòro wa sí?

 BÍBÉLÌ sọ pé ìgbà tá a wà yìí jẹ́ “àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.” (2 Tím. 3:1) Lásìkò tá a wà yìí, ìṣòro tí gbogbo èèyàn ń ní làwa èèyàn Jèhófà náà ń ní. Àmọ́, àwọn èèyàn tún máa ń ta kò wá, wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wa. Kí ló ń jẹ́ ká lè máa sin Jèhófà nìṣó láìka àwọn ìṣòro yìí sí? Nǹkan pàtàkì tó ń jẹ́ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run alààyè,” ó sì ń ràn wá lọ́wọ́.—Jer. 10:10; 2 Tím. 1:12.

2. Kí ló fi hàn pé Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà?

2 Jèhófà wà láàyè, ó máa ń fún wa lágbára nígbà ìṣòro, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. (2 Kíró. 16:9; Sm. 23:4) Tá a bá ń rántí pé Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà, àá lè fara da ìṣòro tó bá dé bá wa. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran Ọba Dáfídì lọ́wọ́.

3. Kí ni Dáfídì ń sọ nígbà tó ní “Jèhófà wà láàyè”?

3 Dáfídì mọ Jèhófà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọba Sọ́ọ̀lù àtàwọn míì fẹ́ pa á, Dáfídì gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran òun lọ́wọ́. (Sm. 18:6) Jèhófà gbọ́ àdúrà ẹ̀, ó sì ràn án lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ pé: “Jèhófà wà láàyè!” (Sm. 18:46) Kí ni Dáfídì ń sọ nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yẹn? Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ yìí fi hàn pé ó dá a lójú pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run alààyè tó máa ń gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” Bí Jèhófà ṣe gba Dáfídì sílẹ̀ láwọn ìgbà tó níṣòro jẹ́ kó dá a lójú pé Ọlọ́run wà lóòótọ́, ìyẹn jẹ́ kó pinnu pé Jèhófà lòun á máa sìn, òun á sì máa yìn ín.—Sm. 18:28, 29, 49.

4. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá gbà pé Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà?

4 Tó bá dá wa lójú pé Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà, àá máa fìtara sìn ín. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ ká máa fara da àwọn ìṣòro wa, á sì tún jẹ́ kó máa wù wá láti ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Paríparí ẹ̀, kò ní jẹ́ ká fi Jèhófà sílẹ̀.

ỌLỌ́RUN ALÀÀYÈ MÁA FÚN Ẹ LÓKUN

5. Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tá a bá níṣòro? (Fílípì 4:13)

5 Tá a bá ń rántí pé Jèhófà wà láàyè, tó sì dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́, a máa lè fara da ìṣòro èyíkéyìí tá a bá ní. Ó ṣe tán, kò síṣòro tí Ọlọ́run wa ò lè yanjú. Torí pé Olódùmarè ni, ó máa fún wa lágbára láti fara da ìṣòro wa. (Ka Fílípì 4:13.) Torí náà, àwọn nǹkan tá a mọ̀ nípa Jèhófà yìí máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ nígbà ìṣòro. Bá a ṣe ń rí i tí Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìgbà tá a níṣòro tí ò tó nǹkan jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ láwọn ìgbà tá a bá níṣòro tó ju agbára wa lọ.

6. Kí làwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ tó jẹ́ kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

6 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan méjì tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì tó jẹ́ kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ tó ń da ẹran, bíárì kan gbé àgùntàn bàbá ẹ̀, ìgbà kan sì tún wà tí kìnnìún gbé àgùntàn kan lọ. Láwọn ìgbà méjèèjì yìí, Dáfídì fìgboyà lé bíárì àti kìnnìún yẹn, ó sì gba àwọn àgùntàn náà sílẹ̀ lọ́wọ́ wọn. Síbẹ̀, Dáfídì ò sọ pé agbára òun lòun fi ṣe àwọn nǹkan yẹn. Ó mọ̀ pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́. (1 Sám. 17:34-37) Ó dájú pé Dáfídì ò gbàgbé àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Bó ṣe ń ronú lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ṣe lọkàn ẹ̀ túbọ̀ balẹ̀ pé Ọlọ́run alààyè máa ran òun lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú.

7. Báwo ni èrò tó tọ́ ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun Gòláyátì?

7 Lẹ́yìn ìyẹn, Dáfídì lọ sí ibùdó àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, ó sì jọ pé kò tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún nígbà yẹn. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bẹ̀rù torí pé ọmọ ogun Filísínì kan tó ń jẹ́ Gòláyátì ń “pẹ̀gàn ìlà ogun Ísírẹ́lì.” (1 Sám. 17:10, 11) Ohun tó jẹ́ kí wọ́n máa bẹ̀rù ni pé wọ́n ń wo bí Gòláyátì ṣe fìrìgbọ̀n tó àti ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tó ń sọ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú ogun. (1 Sám. 17:24, 25) Àmọ́, ọ̀tọ̀ lohun tí Dáfídì ń rò ní tiẹ̀. Ó gbà pé kì í ṣe ìlà ogun Ísírẹ́lì ni Gòláyátì ń pẹ̀gàn, àmọ́ “ìlà ogun Ọlọ́run alààyè” ló ń pẹ̀gàn. (1 Sám. 17:26) Torí náà, Dáfídì ò bẹ̀rù torí pé Jèhófà ló gbẹ́kẹ̀ lé. Ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pé Ọlọ́run tó ran òun lọ́wọ́ nígbà tóun ń da ẹran tún máa ran òun lọ́wọ́ lọ́tẹ̀ yìí. Torí pé ó dá Dáfídì lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn òun, ó lọ bá Gòláyátì jà, ó sì ṣẹ́gun ẹ̀!—1 Sám. 17:45-51.

8. Kí lá jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Táwa náà bá ń rántí pé Ọlọ́run alààyè ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́, àá lè fara da ìṣòro wa. (Sm. 118:6) Ọkàn wa máa túbọ̀ balẹ̀ tá a bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè ka àwọn ìtàn Bíbélì táá jẹ́ kó o rántí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ nígbà àtijọ́. (Àìsá. 37:17, 33-37) Bákan náà, tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org, o tún lè ka àwọn àpilẹ̀kọ tàbí kó o wo àwọn fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́ lásìkò wa yìí. Yàtọ̀ síyẹn, á dáa kó o máa rántí àwọn ìgbà tó o níṣòro, tí Jèhófà sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tí ohunkóhun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bí ìgbà téèyàn bá bíárì tàbí kìnnìún jà ò bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, ó yẹ kó o mọ̀ pé Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti ṣe láyé ẹ! Ó ti jẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́. (Jòh. 6:44) Kódà, Jèhófà ló ń jẹ́ kó o máa sin òun títí di báyìí, ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀ lára ẹ. Torí náà, o ò ṣe bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o rántí ìgbà tó dáhùn àwọn àdúrà ẹ tàbí bó ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́ lásìkò tó yẹ àti bó ṣe bójú tó ẹ nígbà tó o níṣòro tó le gan-an? Tó o bá ń ronú lórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé á máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.

Ohun tá a bá ṣe nígbà ìṣòro lè múnú Jèhófà dùn (Wo ìpínrọ̀ 8-9)


9. Kí ló yẹ ká máa rántí tá a bá níṣòro? (Òwe 27:11)

9 Tá a bá gbà pé Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà, àá máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro wa. Báwo la ṣe lè ṣe é? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá rí i pé ìṣòro wa kan ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn ọ̀tẹ̀ tí Sátánì dá sílẹ̀ nípa bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àti ọ̀run. Èṣù sọ pé tọ́wọ́ ìyà bá bà wá, a máa fi Jèhófà sílẹ̀. (Jóòbù 1:10, 11; ka Òwe 27:11.) Àmọ́ tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bó ti wù kí ìṣòro yẹn lágbára tó, á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé òpùrọ́ ni Sátánì. Ṣé ìjọba ń ṣenúnibíni sí ẹ níbi tó ò ń gbé, ṣé àtijẹ àtimu nira fún ẹ, ṣé àwọn èèyàn kì í gbọ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín àbí o láwọn ìṣòro míì tó ò ń bá yí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má gbàgbé pé àwọn ìṣòro tó o ní yẹn ń fún ẹ láǹfààní láti múnú Jèhófà dùn. Tún máa rántí pé kò ní jẹ́ ká dán ẹ wò kọjá ohun tó o lè mú mọ́ra. (1 Kọ́r. 10:13) Ó máa fún ẹ lókun kó o lè fara dà á.

ỌLỌ́RUN ALÀÀYÈ MÁA SAN ÈRÈ FÚN Ẹ

10. Báwo ni Jèhófà ṣe máa san èrè fáwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀?

10 Jèhófà ló ń san èrè fáwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀. (Héb. 11:6) Ní báyìí, ó ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ ká sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ó sì máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. A lè fọkàn tán Jèhófà, kó sì dá wa lójú pé ó máa san èrè fún wa àti pé ó lágbára láti ṣe é. Ohun tó dá wa lójú nípa Jèhófà yìí máa ń jẹ́ kó wù wá láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe bíi tàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ìgbà àtijọ́. Ohun tí Tímótì ṣe nìyẹn nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀.—Héb. 6:10-12.

11. Kí nìdí tí Tímótì fi ń ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ? (1 Tímótì 4:10)

11 Ka 1 Tímótì 4:10. Tímótì nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run alààyè máa san èrè fún òun. Ìdí nìyẹn tó fi ń ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà àtàwọn ará. Kí làwọn nǹkan tó ṣe? Pọ́ọ̀lù gbà á níyànjú pé kó túbọ̀ já fáfá bó ṣe ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ nínú ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó tún sọ fún un pé kó jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbàlagbà tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. Bákan náà, Pọ́ọ̀lù gbé àwọn iṣẹ́ kan fún un. Lára ẹ̀ ni pé kó fìfẹ́ bá àwọn ará wí tó bá gba pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Tím. 4:11-16; 2 Tím. 4:1-5) Torí náà, ó dá Tímótì lójú pé táwọn ará kan ò bá tiẹ̀ rí gbogbo iṣẹ́ tóun ń ṣe tàbí tí wọn ò mọyì ẹ̀, Jèhófà máa san èrè fún òun.—Róòmù 2:6, 7.

12. Kí ló ń mú káwọn alàgbà máa ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Bákan náà lónìí, ó yẹ kó dá àwọn alàgbà lójú pé Jèhófà rí gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, ó sì mọyì ẹ̀. Àwọn alàgbà máa ń bẹ àwọn ará wò, wọ́n ń kọ́ni nínú ìjọ, wọ́n sì ń wàásù. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà ló máa ń ṣèrànwọ́ níbi tí wọ́n ti ń kọ́ ilé ètò Ọlọ́run àti nígbà àjálù. Àwọn míì tún máa ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Àwùjọ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò tàbí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Àwọn alàgbà tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ yìí gbà pé Jèhófà ló ṣe ètò náà fún àwọn ará ìjọ, kì í ṣe èèyàn. Ìyẹn jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ náà tọkàntọkàn, ó sì dá wọn lójú pé Jèhófà máa san èrè fún wọn.—Kól. 3:23, 24.

Ọlọ́run alààyè máa san èrè fún ẹ bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 12-13)


13. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tá a bá ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀?

13 Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo wa la lè di alàgbà. Àmọ́, gbogbo wa la lóhun tá a lè ṣe fún Jèhófà. Inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an tó bá rí i pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa sin òun. Ó ń rí bá a ṣe ń fi owó àtàwọn nǹkan ìní wa ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn, kódà tí ò bá tiẹ̀ tó nǹkan. Inú ẹ̀ máa ń dùn tó bá rí i pé a ṣiṣẹ́ kára láti borí ìtìjú, tá a sì ń nawọ́ láti dáhùn nípàdé, inú ẹ̀ sì tún máa ń dùn tó bá rí i pé a gbójú fo àṣìṣe àwọn ará, tá a sì dárí jì wọ́n. Kódà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ohun tó ò ń ṣe fún Jèhófà ò tó bó o ṣe fẹ́, mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì ohun tó o ṣe. Ó nífẹ̀ẹ́ ẹ torí gbogbo ohun tó ò ń ṣe fún un, ó sì máa san ẹ́ lérè.—Lúùkù 21:1-4.

TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN ALÀÀYÈ

14. Tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká jẹ́ olóòótọ́ sí i? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, á rọrùn fún wa láti jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò ní ṣèṣekúṣe torí ó mọ̀ pé ó máa dun Ọlọ́run tóun bá ṣe bẹ́ẹ̀. (Jẹ́n. 39:9) Táwa náà bá fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé ká máa wáyè gbàdúrà, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àjọṣe tá a ní pẹ̀lú ẹ̀ á túbọ̀ máa lágbára. Tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà bíi ti Jósẹ́fù, a ò ní ṣohun tó máa bà á nínú jẹ́.—Jém. 4:8.

Tó o bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 14-15)


15. Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù? (Hébérù 3:12)

15 Ó máa ń rọrùn fáwọn tí ò gbà pé Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà láti tètè fi í sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà ní aginjù. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà wà lóòótọ́, àmọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà máa pèsè fún àwọn. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé: “Ṣé Jèhófà wà láàárín wa àbí kò sí?” (Ẹ́kís. 17:2, 7) Torí pé wọ́n ṣiyèméjì, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ jẹ́ aláìgbọràn bíi tiwọn torí àríkọ́gbọ́n lohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn jẹ́ fún wa.—Ka Hébérù 3:12.

16. Kí ló lè dán ìgbàgbọ́ wa wò?

16 Ayé burúkú tí Sátánì ń darí yìí jẹ́ kó túbọ̀ nira fún wa láti sún mọ́ Jèhófà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò gbà pé Ọlọ́run wà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń dà bíi pé nǹkan ń lọ dáadáa fáwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a gbà pé Ọlọ́run wà, a lè máa ronú pé bóyá ni Ọlọ́run máa bójú tó wa. Ẹni tó kọ Sáàmù 73 náà nírú èrò yìí. Ó rí i pé nǹkan ń lọ dáadáa fáwọn tí ò tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, wọ́n sì ń gbádùn ayé wọn. Torí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni èrè kankan wà nínú bóun ṣe ń sin Ọlọ́run.—Sm. 73:11-13.

17. Kí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

17 Kí ló ran onísáàmù yẹn lọ́wọ́ láti tún èrò ẹ̀ ṣe? Ó ronú lórí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà. (Sm. 73:18, 19, 27) Yàtọ̀ síyẹn, ó ronú lórí àǹfààní táwọn tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn máa ń rí. (Sm. 73:24) Ó yẹ káwa náà máa ronú lórí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ká wá fi wé bí ìgbésí ayé wa ì bá ṣe rí ká ní a ò sin Jèhófà. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa sin Jèhófà tọkàntọkàn, àá sì lè sọ bíi ti onísáàmù pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”—Sm. 73:28.

18. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká bẹ̀rù ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

18 Kò sí àdánwò èyíkéyìí tó dé bá wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí tá ò ní lè borí torí pé “ẹrú Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè” ni wá. (1 Tẹs. 1:9) A mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà Ọlọ́run wa máa ń bójú tó àwọn tó ń sìn ín tọkàntọkàn. Ó ti ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́ nígbà àtijọ́, ó sì dájú pé ó máa ran àwa náà lọ́wọ́ lónìí. Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá tírú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí máa bẹ̀rẹ̀. Àmọ́, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ lásìkò yẹn. (Àìsá. 41:10) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa “nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.’”—Héb. 13:5, 6.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa