Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 26

ORIN 8 Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa

Fi Jèhófà Ṣe Àpáta Rẹ

Fi Jèhófà Ṣe Àpáta Rẹ

“Kò . . . sí àpáta tí ó dà bí Ọlọ́run wa.”1 SÁM. 2:2.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa mọ ìdí tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní àpáta àti bá a ṣe lè fìwà jọ Jèhófà.

1. Kí ni Dáfídì fi Jèhófà wé nínú Sáàmù 18:46?

 NÍGBÀ míì, a lè níṣòro tó ń mú kí nǹkan nira fún wa, ìṣòro náà sì lè yí ìgbésí ayé wa pa dà pátápátá. A mà dúpẹ́ o pé a lè bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́! Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run alààyè àti pé gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Gbogbo ìgbà tá a bá rọ́wọ́ Jèhófà láyé wa ló túbọ̀ máa ń dá wa lójú pé “Jèhófà wà láàyè!” (Ka Sáàmù 18:46.) Síbẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí Dáfídì sọ̀rọ̀ yẹn tán ló pe Ọlọ́run ní “Àpáta mi.” Àmọ́, kí nìdí tó ṣe fi Jèhófà Ọlọ́run alààyè wé àpáta tó jẹ́ nǹkan aláìlẹ́mìí?

2. Kí la máa kọ́ nínú ohun tí Dáfídì sọ pé Jèhófà ni “Àpáta mi”?

2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rídìí tí Dáfídì fi pe Jèhófà ní àpáta, àá sì rí ohun tí àfiwé yìí kọ́ wa nípa Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a máa rí báwa náà ṣe lè sọ Jèhófà di àpáta wa. Ohun tá a máa jíròrò kẹ́yìn ni àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní àti bá a ṣe lè fara wé e.

KÍ NÌDÍ TÁ A FI PE JÈHÓFÀ NÍ ÀPÁTA?

3. Báwo ni Bíbélì ṣe sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “àpáta”? (Wo àwòrán.)

3 Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “àpáta” ká lè túbọ̀ lóye àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. Wọ́n sábà máa ń lò ó láti yin Jèhófà pé kò sí ẹlẹ́gbẹ́ ẹ̀. Inú Diutarónómì 32:4 ni Bíbélì ti kọ́kọ́ pe Jèhófà ní “Àpáta náà.” Bákan náà, nígbà tí Hánà ń gbàdúrà, ó sọ pé “kò . . . sí àpáta tí ó dà bí Ọlọ́run wa.” (1 Sám. 2:2) Hábákúkù náà pe Jèhófà ní “Àpáta mi.” (Háb. 1:12) Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tó kọ Sáàmù 73 pe Ọlọ́run ní “àpáta ọkàn mi.” (Sm. 73:26) Kódà, Jèhófà náà pe ara ẹ̀ ní àpáta. (Àìsá. 44:8) Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ mẹ́ta tí Jèhófà ní tó jẹ́ kó dà bí àpáta àti báwa náà ṣe lè fi Jèhófà ṣe “Àpáta wa.”Diu. 32:31.

Àwa èèyàn Ọlọ́run gbà pé Jèhófà ni àpáta ààbò wa (Wo ìpínrọ̀ 3)


4. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ibi ààbò wa? (Sáàmù 94:22)

4 Jèhófà máa ń dáàbò bò wá nígbà wàhálà. Bí àpáta ńlá ṣe máa ń dáàbò bo ẹnì kan lọ́wọ́ ìjì líle, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà máa ń dáàbò bò wá nígbà ìṣòro. (Ka Sáàmù 94:22.) Ó máa ń dáàbò bò wá kí àjọṣe wa pẹ̀lú ẹ̀ má bàa bà jẹ́, ó sì jẹ́ kó dá wa lójú pé láìpẹ́ òun máa yanjú ìṣòro wa. Kódà ó ṣèlérí pé lọ́jọ́ iwájú, òun máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, ká sì máa gbé láìséwu.—Ìsík. 34:25, 26.

5. Báwo ni Jèhófà ṣe lè di Ibi Ààbò fún wa?

5 Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi Jèhófà ṣe Ibi Ààbò wa ni pé ká máa gbàdúrà. Tá a bá gbàdúrà sí Jèhófà, ó máa fún wa ní ‘àlàáfíà ẹ̀’ tó máa dáàbò bo ọkàn wa àti èrò wa. (Fílí. 4:6, 7) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Artem tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ohun tó gbà gbọ́. Léraléra ni ọ̀kan lára àwọn agbófinró tó wà níbẹ̀ máa ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, ó máa ń halẹ̀ mọ́ ọn, ó sì máa ń dẹ́rù bà á. Arákùnrin Artem sọ pé: “Ẹ̀rù máa ń bà mí gan-an tó bá ti ní kí wọ́n lọ pè mí wá. . . . Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀, kó sì fún mi lọ́gbọ́n tí mo nílò. Torí náà, pàbó ni gbogbo ọgbọ́n tí agbófinró yẹn dá já sí. . . . Jèhófà sì wá dà bí ògiri tí mo fẹ̀yìn tì torí ó ràn mí lọ́wọ́ gan-an.”

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní gbogbo ìgbà? (Àìsáyà 26:3, 4)

6 Jèhófà ṣeé gbára lé. Jèhófà dà bí àpáta tí ò ṣeé mì torí gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. A lè gbẹ́kẹ̀ lé e torí pé òun ní “Àpáta ayérayé.” (Ka Àìsáyà 26:3, 4.) Jèhófà ò lè kú láé, torí náà ó máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ó máa gbọ́ àdúrà wa, ó sì máa pèsè àwọn ohun tá a nílò. Ó tún yẹ ká gbára lé Jèhófà torí pé kì í fi àwọn tó ń jọ́sìn ẹ̀ sílẹ̀. (2 Sám. 22:26) Kò ní gbàgbé àwọn ohun tá a ṣe fún un láé, ó sì máa san èrè fún kálukú wa.—Héb. 6:10; 11:6.

7. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá gbára lé Jèhófà pátápátá? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Jèhófà máa jẹ́ Àpáta wa tá a bá gbára lé e pátápátá. Ó dá wa lójú pé tá a bá ṣe ohun tó fẹ́ kódà nígbà ìṣòro, a máa jàǹfààní ẹ̀. (Àìsá. 48:17, 18) Gbogbo ìgbà tá a bá rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́, àá túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e torí a mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè jẹ́ ká fara da ìṣòro tó ju agbára wa lọ. Tá a bá sì níṣòro tí ò sẹ́ni tó lè ràn wá lọ́wọ́ àfi Jèhófà, a máa gbà pé Jèhófà ṣeé gbára lé lóòótọ́. Arákùnrin Vladimir sọ pé: “Àsìkò tí mo lò lẹ́wọ̀n ni mo sún mọ́ Jèhófà jù. Mo kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá torí pé gbogbo ìgbà ni mo máa ń dá wà, kò sì sóhun tí mo lè ṣe sọ́rọ̀ náà.”

Jèhófà máa jẹ́ Àpáta wa tá a bá gbára lé e pátápátá (Wo ìpínrọ̀ 7)


8. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà kì í yí pa dà? (b) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá fi Jèhófà ṣe àpáta wa? (Sáàmù 62:6, 7)

8 Jèhófà kì í yí pa dà. Jèhófà dà bí àpáta ràbàtà tí ò ṣeé mì, tí ò sì lè kúrò níbi tó wà. Kì í yí ìwà ẹ̀ pa dà, ohun tó fẹ́ ṣe ò sì lè yí pa dà láé. (Mál. 3:6) Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà ò yí ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé pa dà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà “kò lè sẹ́ ara rẹ̀.” (2 Tím. 2:13) Torí náà, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ tàbí ohun yòówù káwọn èèyàn ṣe, Jèhófà ò ní yí ìwà ẹ̀ pa dà, kò ní yí ohun tó fẹ́ ṣe pa dà, kò sì ní yí àwọn ìlànà òdodo ẹ̀ pa dà. Torí a fọkàn tán Jèhófà pé kì í yí pa dà, a mọ̀ pé ó máa gbà wá nígbà ìṣòro, ó sì máa jẹ́ ká rí ìgbàlà.—Ka Sáàmù 62:6, 7.

9. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Tatyana?

9 Tá a bá ń ronú nípa àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé, a máa gbẹ́kẹ̀ lé e, àá sì fi ṣe Àpáta wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn wa máa balẹ̀ nígbà ìṣòro, àá sì lè fara dà á. (Sm. 16:8) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Tatyana nìyẹn nígbà tí wọ́n tì í mọ́lé torí ohun tó gbà gbọ́. Ó sọ pé: “Ká sòótọ́, àsìkò yẹn ò kọ́kọ́ rọrùn fún mi rárá torí pé mo máa ń dá wà, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni inú mi kì í dùn.” Àmọ́ nígbà tí Tatyana ronú nípa bí ìṣòro tóun ní ṣe kan Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé, ó rí i pé ó ṣe pàtàkì kóun máa fara dà á nìṣó. Ó sọ pé: “Mo mọ ìdí táwọn nǹkan yẹn fi ṣẹlẹ̀ sí mi, ìdí náà sì ni pé mo fara mọ́ ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti ṣàkóso ayé àtọ̀run. Mo wá rí i pé ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní yìí ló ṣe pàtàkì jù, ìyẹn ni ò jẹ́ kí n máa ronú nípa ara mi, ọkàn mi sì balẹ̀.”

10. Báwo la ṣe lè fi Jèhófà ṣe Àpáta wa báyìí?

10 Láìpẹ́, àwọn ìṣòro tó le gan-an máa dé bá wa tó máa gba pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìsinsìnyí ló yẹ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, kó sì dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́. Báwo la ṣe lè ṣe é? Máa ka àwọn ìtàn inú Bíbélì àti ìrírí àwa èèyàn Jèhófà òde òní. Kíyè sí àwọn ànímọ́ tí Jèhófà fi hàn nígbà tó ń ran àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ lọ́wọ́. Ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìtàn Bíbélì tó o kà yẹn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà lo fi ń ṣe Àpáta rẹ.

MÁA FÌWÀ JỌ JÈHÓFÀ

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká láwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní? (Wo àpótí náà “ Ohun Tẹ́yin Ọ̀dọ́kùnrin Lè Fi Ṣe Àfojúsùn Yín.”)

11 A ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó jẹ́ ká rí i pé òun ni àpáta wa. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ní àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní. Tá a bá láwọn ànímọ́ yẹn, àá lè ran àwọn ará ìjọ lọ́wọ́, ìgbàgbọ́ wọn á sì túbọ̀ lágbára. Bí àpẹẹrẹ, Jésù fún Símónì ní orúkọ náà Kéfà (tó túmọ̀ sí “Pétérù”), ìtumọ̀ orúkọ náà ni “Òkúta Kan.” (Jòh. 1:42) Jésù fún Pétérù lórúkọ yẹn torí ó fẹ́ kó tu àwọn ará ìjọ nínú, kí ìgbàgbọ́ wọn sì túbọ̀ lágbára. Bíbélì pe àwọn alàgbà ìjọ ní “òjìji àpáta ńlá.” Ìdí tí Bíbélì fi pè wọ́n bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń dáàbò bo àwọn ará ìjọ. (Àìsá. 32:2) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, táwọn ará ìjọ bá ń fara wé Jèhófà, tí wọ́n sì láwọn ànímọ́ tó ní, gbogbo ìjọ ló máa jàǹfààní ẹ̀.—Éfé. 5:1.

12. Báwo la ṣe lè ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà ìṣòro?

12 Máa bójú tó àwọn ará. Tí ogun tàbí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ káwọn ará pàdánù ilé wọn tàbí tó gba pé kí wọ́n fi ibi tí wọ́n ń gbé sílẹ̀, a lè ní kí wọ́n wá máa gbé lọ́dọ̀ wa. Bí nǹkan ṣe ń burú sí i ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, ó ṣe pàtàkì pé ká lo àǹfààní tá a ní láti ran àwọn ará lọ́wọ́. (2 Tím. 3:1) A tún lè tù wọ́n nínú, ká sì fìfẹ́ hàn sí wọn. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é ni pé tá a bá wà nípàdé, ká máa bá wọn sọ̀rọ̀, ká sì máa mára tù wọ́n, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n rí i pé àwọn ará ìjọ nífẹ̀ẹ́ wọn. Lónìí, inú ayé táwọn èèyàn kì í fìfẹ́ hàn síra wọn là ń gbé, ìyẹn ò yọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sílẹ̀, ó sì lè mú kí nǹkan tojú sú wọn. Torí náà, tí wọ́n bá wá sípàdé, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mára tù wọ́n, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.

13. Báwo lẹ̀yin alàgbà ṣe lè ran àwọn ará lọ́wọ́ nígbà ìṣòro? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

13 Ẹ̀yin alàgbà, ẹ ṣe tán láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó ń fara da ìṣòro tó le gan-an. Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí wọ́n bá gbé arákùnrin tàbí arábìnrin kan lọ sílé ìwòsàn ní pàjáwìrì, ó yẹ kẹ́yin alàgbà tètè gbé ìgbésẹ̀ láti ṣèrànwọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ lo Bíbélì láti tọ́ wọn sọ́nà, kẹ́ ẹ sì fi fún wọn níṣìírí. Tí alàgbà kan bá jẹ́ ẹni jẹ́jẹ́, tó láàánú, tó sì máa ń tẹ́tí sáwọn ará, á rọrùn fáwọn ará láti sọ pé kírú alàgbà bẹ́ẹ̀ ran àwọn lọ́wọ́. Táwọn ará bá rí i pé ẹ̀yin alàgbà láwọn ànímọ́ yìí, á rọrùn fún wọn láti fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tẹ́ ẹ fún wọn sílò, wọ́n á sì rí i pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn.—1 Tẹs. 2:7, 8, 11.

Àwọn alàgbà máa ń jẹ́ ibi ààbò fáwọn ará nígbà ìṣòro (Wo ìpínrọ̀ 13) a


14. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ṣeé fọkàn tán?

14 Jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. A máa ń fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a máa ran àwọn lọ́wọ́, pàápàá nígbà ìṣòro. (Òwe 17:17) Torí náà, kí la lè ṣe táá jẹ́ káwọn èèyàn máa fọkàn tán wa? Ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fìwà jọ Jèhófà, bí àpẹẹrẹ, ó yẹ ká máa mú àwọn ìlérí wa ṣẹ, ká sì máa dé lásìkò síbi tá a ti fẹ́ ṣe nǹkan. (Mát. 5:37) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá mọ ohun tẹ́nì kan nílò, a lè pèsè ẹ̀ fún un. Tí wọ́n bá sì gbé iṣẹ́ èyíkéyìí fún wa, ó yẹ ká ṣe é bí wọ́n ṣe ní ká ṣe é, ká sì rí i dájú pé a parí iṣẹ́ náà.

15. Àǹfààní wo làwọn ará ìjọ máa rí táwọn alàgbà bá ṣeé fọkàn tán?

15 Àwọn ará ìjọ máa ń jàǹfààní gan-an táwọn alàgbà bá ṣeé fọkàn tán. Lọ́nà wo? Ọkàn àwọn ará máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá mọ̀ pé kò sígbà táwọn ò lè pe àwọn alàgbà pé kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́, irú bí alábòójútó àwùjọ wọn. Inú àwọn ará tún máa ń dùn tí wọ́n bá rí i pé àwọn alàgbà ṣe tán láti ran àwọn lọ́wọ́. Táwọn alàgbà bá ń fi ìlànà Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run gba àwọn ará nímọ̀ràn, tí wọn ò sì sọ èrò tara wọn, àwọn ará á túbọ̀ fọkàn tán wọn. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tún máa ń fọkàn tán àwọn alàgbà tí kì í sọ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn kiri, tí wọ́n sì máa ń mú ìlérí wọn ṣẹ.

16. Tá a bá ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ní gbogbo ìgbà, àǹfààní wo làwa àtàwọn míì máa rí?

16 Máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ ní gbogbo ìgbà. Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà ní gbogbo ìgbà, tá a sì ń fi ìlànà Bíbélì ṣe àwọn ìpinnu tá a bá fẹ́ ṣe, àwọn ẹlòmíì á máa kẹ́kọ̀ọ́ lára wa. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, tá a sì ń jẹ́ kígbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, a máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, àá sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. A ò ní jẹ́ aláìnípinnu, a ò sì ní jẹ́ kí ẹ̀kọ́ èké àtàwọn èrò tí ò bá ti Jèhófà mu ṣì wá lọ́nà. (Éfé. 4:14; Jém. 1:6-8) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá gba Jèhófà gbọ́ pé ó máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ, ọkàn wa máa balẹ̀ tá a bá tiẹ̀ gbọ́ ìròyìn burúkú. (Sm. 112:7, 8) Bákan náà, àá lè ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́.—1 Tẹs. 3:2, 3.

17. Kí ló máa ń jẹ́ káwọn alàgbà fi àwọn ará lọ́kàn balẹ̀?

17 Kò yẹ káwọn alàgbà máa ṣe àṣejù, ó yẹ kí wọ́n ní àròjinlẹ̀, kí wọ́n wà létòlétò, kí wọ́n sì máa fòye báni lò. Wọ́n máa ń fi àwọn ará lọ́kàn balẹ̀, wọ́n sì máa ń jẹ́ kígbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára. Wọ́n máa ń “di ọ̀rọ̀ òtítọ́ mú ṣinṣin,” ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n fún ìjọ lókun. (Títù 1:9; 1 Tím. 3:1-3) Torí pé àwọn alàgbà máa ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ará, tí wọ́n sì máa ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn, ó ń jẹ́ káwọn ará lè máa wá sípàdé déédéé, kí wọ́n máa wàásù, kí wọ́n sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin bá níṣòro tó ń kó wọn lọ́kàn sókè, àwọn alàgbà máa ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n sì máa ń fi dá wọn lójú pé àwọn ìlérí ẹ̀ máa ṣẹ.

18. Kí nìdí tó fi yẹ kó máa wù wá láti yin Jèhófà, ká sì túbọ̀ sún mọ́ ọn? (Tún wo àpótí náà “ Bó O Ṣe Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà.”)

18 Lẹ́yìn tá a ti jíròrò àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra tí Jèhófà ní, àwa náà lè sọ bíi ti Ọba Dáfídì pé: “Ìyìn ni fún Jèhófà, Àpáta mi.” (Sm. 144:1) Kò sígbà tá ò lè fọkàn tán Jèhófà. Jálẹ̀ ayé wa, kódà nígbà tá a bá darúgbó làá máa sọ nípa Jèhófà pé: “Òun ni Àpáta mi,” torí ọkàn wa balẹ̀ pé á máa ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀.—Sm. 92:14, 15.

ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN Iwájú Ìwé: Nígbà tí arábìnrin kan wà ní Ilé Ìpàdé, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ láti sọ ìṣòro ẹ̀ fáwọn alàgbà méjì kan.