Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 23

ORIN 28 Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà

Jèhófà Gbà Wá Lálejò Sínú Ilé Ẹ̀

Jèhófà Gbà Wá Lálejò Sínú Ilé Ẹ̀

“Àgọ́ mi yóò wà pẹ̀lú wọn, èmi yóò di Ọlọ́run wọn.”ÌSÍK. 37:27.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa mọyì bí Jèhófà ṣe pè wá sínú àgọ́ ẹ̀ àti bó ṣe ń bójú tó wa níbẹ̀.

1-2. Àǹfààní wo ni Jèhófà fún àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀?

 TÍ WỌ́N bá bi ẹ́ pé báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ sí ẹ, kí lo máa sọ? Ó ṣeé ṣe kó o sọ pé ‘Bàbá mi, Ọlọ́run mi àti Ọ̀rẹ́ mi ni Jèhófà.’ Àwọn orúkọ oyè míì wà tó o tún lè pe Jèhófà. Síbẹ̀, ṣé o rò pé ó burú tá a bá pe Jèhófà ní Agbanilálejò?

2 Ọba Dáfídì fi àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ wé àjọṣe tó máa ń wà láàárín ẹni tó gba àwọn èèyàn lálejò àtàwọn àlejò ẹ̀. Ó bi Jèhófà pé: “Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? Ta ló lè máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?” (Sm. 15:1) Ọ̀rọ̀ tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí Dáfídì láti sọ yìí jẹ́ ká rí i pé a lè jẹ́ àlejò Jèhófà, ìyẹn ni pé ká di ọ̀rẹ́ ẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà fẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun!

JÈHÓFÀ FẸ́ GBÀ WÁ LÁLEJÒ

3. Ta ni Jèhófà kọ́kọ́ gbà lálejò, báwo ló sì ṣe rí lára Jèhófà àtẹni náà?

3 Kí Jèhófà tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan, òun nìkan ló dá wà. Àmọ́ nígbà tó yá, ó dá àkọ́bí Ọmọ ẹ̀ sọ́run, wọ́n sì jọ wà níbẹ̀. Inú Jèhófà dùn gan-an nígbà tó gba Jésù Ọmọ ẹ̀ lálejò. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “àrídunnú” Jèhófà ni Jésù. Inú Jésù sì máa ń “dùn níwájú [Jèhófà] ní gbogbo ìgbà.”—Òwe 8:30.

4. Àwọn míì wo ni Jèhófà gbà lálejò?

4 Nígbà tó yá, Jèhófà dá àwọn áńgẹ́lì, ó sì gba àwọn náà lálejò. Bíbélì pè wọ́n ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run,” ó sì sọ pé inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe wà pẹ̀lú Jèhófà. (Jóòbù 38:7; Dán. 7:10) Ọ̀pọ̀ ọdún ló jẹ́ pé àwọn tí Jèhófà dá sọ́run nìkan ló gbà lálejò. Àmọ́ nígbà tó yá, ó dá àwa èèyàn sáyé kó lè gba àwa náà lálejò sínú àgọ́ ẹ̀. Lára àwọn tó rí ojúure ẹ̀ ni Énọ́kù, Nóà, Ábúráhámù àti Jóòbù. Torí pé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí jọ́sìn Ọlọ́run, Bíbélì pè wọ́n ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tàbí àwọn tó bá “Ọlọ́run tòótọ́” rìn.—Jẹ́n. 5:24; 6:9; Jóòbù 29:4; Àìsá. 41:8.

5. Kí la kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìsíkíẹ́lì 37:26, 27?

5 Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti ń gba àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ lálejò. (Ka Ìsíkíẹ́lì 37:26, 27.) Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ni pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn ẹ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹ̀. Ó ṣèlérí pé òun máa “bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà.” Torí náà, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń sọ nípa ìgbà táwọn tó máa gbé ọ̀run àtàwọn tó máa gbé ayé á máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan nínú ètò ẹ̀, tí wọ́n á sì jẹ́ “agbo kan.” (Jòh. 10:16) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ti ń ṣẹ báyìí!

ỌLỌ́RUN Ń BÓJÚ TÓ WA NÍBIKÍBI TÁ A BÁ WÀ

6. Ìgbà wo ni Jèhófà lè gba ẹnì kan lálejò sínú àgọ́ ẹ̀, ibo sì ni àgọ́ ẹ̀ wà?

6 Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n bá fẹ́ sinmi, tí wọn ò sì fẹ́ kí oòrùn tàbí òjò pa wọ́n, inú àgọ́ ni wọ́n máa ń wà. Tí wọ́n bá gba àlejò sínú àgọ́ yẹn, ẹni náà máa retí pé kí wọ́n bójú tó òun dáadáa. Ìgbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà ló gbà wá lálejò sínú àgọ́ ẹ̀. (Sm. 61:4) Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ló wà níbẹ̀, lára ẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ ẹ̀ tó fi ń bọ́ wa, a tún ń gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ará wa. Kò síbi tá a wà láyé tí Jèhófà ò ti lè gbà wá lálejò sínú àgọ́ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó o ti rìnrìn àjò lọ sórílẹ̀-èdè míì láti lọ ṣe àkànṣe àpéjọ, kó o sì rí àwọn èèyàn aláyọ̀ tá a jọ ń sin Jèhófà nínú ètò ẹ̀. Torí náà, kò síbi tá a wà tá ò ti lè jọ́sìn ẹ̀.—Ìfi. 21:3.

7. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti kú ṣì jẹ́ àlejò nínú àgọ́ ẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti kú ńkọ́? Ṣé a lè sọ pé wọ́n ṣì jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà ò gbàgbé wọn, kódà lójú ẹ̀ ṣe ló dà bíi pé wọ́n ṣì wà láàyè. Jésù sọ pé: “Tó bá kan àjíǹde àwọn òkú, Mósè pàápàá jẹ́ ká mọ̀ nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, nígbà tó pe Jèhófà ní ‘Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.’ Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè, torí lójú rẹ̀, gbogbo wọn wà láàyè.”—Lúùkù 20:37, 38.

Lójú Jèhófà, àwọn tó ti kú náà ṣì jẹ́ àlejò nínú àgọ́ ẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 7)


ÀǸFÀÀNÍ TÁ A MÁA RÍ ÀTOHUN TÓ YẸ KÁ ṢE

8. Àǹfààní wo làwọn tó bá jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà máa ń rí?

8 Bí àgọ́ ṣe máa ń dáàbò bo èèyàn tí òjò bá ń rọ̀ tàbí tí oòrùn bá ń mú, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń dáàbò bo àwọn tó jẹ́ àlejò nínú àgọ́ ẹ̀, kí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú ẹ̀ má bàa bà jẹ́, kí wọ́n sì nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Tá a bá ní àjọse tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó dájú pé kò sí ohun tí Sátánì lè ṣe táá mú ká fi Jèhófà sílẹ̀. (Sm. 31:23; 1 Jòh. 3:8) Nínú ayé tuntun, Jèhófà á ṣì máa dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ kí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú ẹ̀ lè máa lágbára sí i, àmọ́ kì í ṣe ìyẹn nìkan o, wọn ò tún ní kú mọ́.—Ìfi. 21:4.

9. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn àlejò ẹ̀ máa ṣe?

9 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà gbà wá lálejò sínú àgọ́ ẹ̀, a sì ń gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Àmọ́ kí ló yẹ ká máa ṣe tá a bá ṣì fẹ́ jẹ́ àlejò nínú àgọ́ ẹ̀? Ká sọ pé ẹnì kan pè ẹ́ wá sílé ẹ̀, ó dájú pé wàá fẹ́ mọ ohun tó o lè ṣe táá múnú ẹ̀ dùn. Bí àpẹẹrẹ, ó lè fẹ́ kó o bọ́ bàtà ẹ kó o tó wọlé, ó sì dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àwa náà fẹ́ mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn tó gbà lálejò sínú àgọ́ ẹ̀ máa ṣe. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà máa ń jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti “ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún.” (Kól. 1:10) Òótọ́ ni pé Ọ̀rẹ́ wa ni Jèhófà, àmọ́ ó tún yẹ ká mọ̀ pé Ọlọ́run àti Bàbá wa ni, ó sì yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún un. (Sm. 25:14) Torí náà, gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa rántí ọ̀rọ̀ yìí, kò sì yẹ ká gbàgbé ẹni tí Jèhófà jẹ́. Tá a bá ń bọ̀wọ̀ fún un, a ò ní ṣe ohun tó máa dùn ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá “mọ̀wọ̀n ara” wa bá a ṣe ń bá a rìn.—Míkà 6:8.

JÈHÓFÀ Ò ṢOJÚSÀÁJÚ SÁWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ NÍNÚ AGINJÙ

10-11. Kí ni Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù Sínáì, báwo nìyẹn sì ṣe fi hàn pé kì í ṣe ojúsàájú?

10 Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú tó bá ń gba àwọn èèyàn lálejò. (Róòmù 2:11) Ohun tó sì jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ohun tí Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù Sínáì.

11 Lẹ́yìn tí Jèhófà gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ lóko ẹrú ní Íjíbítì, ó yan àwọn àlùfáà pé kí wọ́n máa rúbọ nínú àgọ́ ìjọsìn. Ó tún sọ pé káwọn ọmọ Léfì máa ṣe àwọn iṣẹ́ míì níbẹ̀. Àmọ́ ṣé Jèhófà ń bójú tó àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìjọsìn náà tàbí àwọn tó pàgọ́ sítòsí ẹ̀ ju àwọn yòókù lọ? Rárá o! Ìdí sì ni pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú.

12. Kí ni Jèhófà ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù tó fi hàn pé kì í ṣe ojúsàájú? (Ẹ́kísódù 40:38) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló láǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà bóyá wọ́n ń sìn nínú àgọ́ ìjọsìn tàbí wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, bóyá wọ́n pàgọ́ sítòsí àgọ́ ìjọsìn tàbí àgọ́ wọn jìnnà síbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà máa ń jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ọwọ̀n ìkùukùu àti ọwọ̀n iná tó máa ń wà lórí àgọ́ ìjọsìn náà. (Ka Ẹ́kísódù 40:38.) Kódà tí ìkùukùu náà bá gbéra lọ síbòmíì, àwọn tó pàgọ́ síbi tó jìnnà gan-an sí àgọ́ ìjọsìn náà máa ń rí i. Torí náà, wọ́n á kó ẹrù wọn, wọ́n á tú àgọ́ wọn, wọ́n á sì máa bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù rìn. (Nọ́ń. 9:15-23) Gbogbo wọn ló máa ń gbọ́ ìró kàkàkí méjì tí wọ́n fi fàdákà ṣe tó ń dún ketekete, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àsìkò ti tó láti gbéra. (Nọ́ń. 10:2) Ìyẹn fi hàn pé tẹ́nì kan bá ń gbé nítòsí àgọ́ ìjọsìn, kò túmọ̀ sí pé ó sún mọ́ Jèhófà ju àwọn yòókù lọ. Dípò bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jèhófà ń gbà lálejò, tó ń tọ́ sọ́nà, tó sì ń dáàbò bò. Bákan náà lónìí, ibi yòówù ká wà láyé, Jèhófà ń fìfẹ́ hàn sí wa, ó ń bójú tó wa, ó sì ń dáàbò bò wá.

Ètò tí Jèhófà ṣe pé kí àgọ́ ìjọsìn wà ní àárín ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé kì í ṣe ojúsàájú (Wo ìpínrọ̀ 12)


JÈHÓFÀ KÌ Í ṢE OJÚSÀÁJÚ SÁWA ÌRÁNṢẸ́ Ẹ̀ LÓNÌÍ

13. Kí ni Jèhófà ń ṣe lónìí tó fi hàn pé kì í ṣe ojúsàájú?

13 Lónìí, àwọn kan lára àwa èèyàn Ọlọ́run ń gbé nítòsí oríléeṣẹ́ wa tàbí nítòsí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, wọ́n sì láǹfààní láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ń sìn láwọn ibi tá a sọ yìí. Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún gbogbo wọn láti kópa nínú àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀, wọ́n sì tún máa ń láǹfààní láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń ṣàbójútó wa nínú ètò Ọlọ́run. Alábòójútó àyíká làwọn kan, àwọn kan sì ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn míì. Àìmọye àwọn ará ni ò nírú àǹfààní yẹn, tó o bá wà lára wọn, mọ̀ dájú pé àlejò Jèhófà ni ẹ́, ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn tó gbà lálejò, ó sì máa ń bójú tó wọn. (1 Pét. 5:7) Torí náà, gbogbo àwa èèyàn Jèhófà ló máa ń tọ́ sọ́nà, ó máa ń dáàbò bò wá, ó sì máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ́ wa.

14. Àpẹẹrẹ míì wo ló fi hàn pé Jèhófà tó gbà wá lálejò kì í ṣe ojúsàájú?

14 Nǹkan míì tí Jèhófà ń ṣe tó fi hàn pé kì í ṣe ojúsàájú bó ṣe ń gbà wá lálejò ni pé ó jẹ́ kí gbogbo èèyàn ní Bíbélì lédè wọn. Èdè mẹ́ta ni wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì, àwọn èdè náà ni Hébérù, Árámáíkì àti Gíríìkì. Ṣé àwọn tó lè ka èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà ju àwọn tí ò lè kà á lọ ni? Rárá.—Mát. 11:25.

15. Kí ni nǹkan míì tó fi hàn pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Kò dìgbà tá a bá kàwé rẹpẹtẹ tàbí tá a gbọ́ àwọn èdè tí wọ́n kọ́kọ́ fi kọ Bíbélì kí Jèhófà tó lè sọ pé ká di ọ̀rẹ́ òun. Gbogbo èèyàn, àtẹni tó kàwé àtẹni tí ò kàwé ni Jèhófà fún láǹfààní láti lóye ohun tó wà nínú Bíbélì. A ti tú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èdè, ìyẹn sì ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn jàǹfààní àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì, kí wọ́n sì di ọ̀rẹ́ Jèhófà.—2 Tím. 3:16, 17.

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé bí wọ́n ṣe tú Bíbélì sí ọ̀pọ̀ èdè fi hàn pé Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú? (Wo ìpínrọ̀ 15)


RÍ I PÉ OHUN TÍNÚ JÈHÓFÀ DÙN SÍ LÒ Ń ṢE

16. Kí ni Ìṣe 10:34, 35 sọ pé ká ṣe ká lè máa múnú Jèhófà dùn?

16 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé Jèhófà gbà wá lálejò sínú àgọ́ ẹ̀. Òun ló ní inúure jù, òun ló ń fìfẹ́ hàn sí wa jù, òun nìkan ló sì ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò. Yàtọ̀ síyẹn, gbogbo wa ló ń kí káàbọ̀ tó sì ń gbà lálejò láìka ibi tá à ń gbé sí, bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà, bá a ṣe kàwé tó, èdè wa, àṣà wa tàbí bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin ni wá. Àmọ́, àwọn tó bá ń ṣe ohun tó ń múnú Jèhófà dùn nìkan ló máa wà nínú àgọ́ ẹ̀.—Ka Ìṣe 10:34, 35.

17. Ibo ni Bíbélì ti sọ àwọn nǹkan míì nípa bá a ṣe lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà?

17 Nínú Sáàmù 15:1, Dáfídì béèrè pé: “Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? Ta ló lè máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?” Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Dáfídì láti dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn nínú Sáàmù 15. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa sọ àwọn nǹkan pàtó tá a lè ṣe láti múnú Jèhófà dùn, ká sì máa jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ nìṣó.

ORIN 32 Dúró Ti Jèhófà!