Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 24

ORIN 24 Ẹ Wá sí Òkè Jèhófà

Má Kúrò Nínú Ilé Jèhófà Láé!

Má Kúrò Nínú Ilé Jèhófà Láé!

“Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ?”SM. 15:1.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe ká lè máa jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ nìṣó, a sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe fẹ́ ká máa hùwà sáwọn ọ̀rẹ́ òun.

1. Àǹfààní wo la máa rí bá a ṣe ń gbé Sáàmù 15:1-5 yẹ̀ wò?

 NÍNÚ àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà tí wọ́n bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀. Àmọ́, kí ló yẹ ká máa ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbà wá lálejò? Sáàmù kẹẹ̀ẹ́dógún (15) sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ọ̀rọ̀ yìí. (Ka Sáàmù 15:1-5.) Torí náà, a máa rí àwọn ẹ̀kọ́ táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nínú orí Bíbélì yìí.

2. Kí ló ṣeé ṣe kó mú kí Dáfídì sọ̀rọ̀ nípa àgọ́ Jèhófà nínú sáàmù yìí?

2 Ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ Sáàmù kẹẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Jèhófà, ta ló lè jẹ́ àlejò nínú àgọ́ rẹ? Ta ló lè máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?” (Sm. 15:1) Nígbà tí Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa “àgọ́” Jèhófà nínú sáàmù yìí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àgọ́ ìjọsìn tó wà ní Gíbíónì nígbà kan ló ń sọ. Nígbà tó sì ń sọ̀rọ̀ nípa “òkè mímọ́,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òkè Síónì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ló ń sọ. Òkè yìí fi nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá jìnnà sí gúúsù Gíbíónì. Torí náà, Dáfídì pàgọ́ kan fún àpótí májẹ̀mú Jèhófà ní Gíbíónì títí dìgbà tí wọ́n máa kọ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n máa gbé àpótí náà sí.—2 Sám. 6:17.

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé Sáàmù 15 yẹ̀ wò? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

3 Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ò láǹfààní láti sìn nínú àgọ́ ìjọsìn, síbẹ̀ díẹ̀ lára wọn láǹfààní láti wọnú àgọ́ tí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú sí. Àmọ́ lónìí, gbogbo àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà la lè wá sínú ilé ẹ̀, tá a bá pinnu pé a máa di ọ̀rẹ́ ẹ̀, àá sì máa jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ nìṣó. Ohun tí gbogbo wa sì ń fẹ́ nìyẹn. Sáàmù kẹẹ̀ẹ́dógún tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbé yẹ̀ wò báyìí sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká máa ṣe, tá a bá fẹ́ máa jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà nìṣó.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Dáfídì máa ń fojú inú wo bó ṣe máa ń rí téèyàn bá jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 3)


MÁA RÌN LÁÌLẸ́BI, KÓ O SÌ MÁA ṢE OHUN TÓ TỌ́

4. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìrìbọmi nìkan ò tó tá a bá fẹ́ rí ojúure Jèhófà? (Àìsáyà 48:1)

4 Nínú Sáàmù 15:2, ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni “ẹni tó ń rìn láìlẹ́bi, tó ń ṣe ohun tí ó tọ́.” Ọ̀rọ̀ náà “tó ń rìn” àti “tó ń ṣe” fi hàn pé ohun tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe nìṣó ni. Àmọ́ ṣé ó ṣeé ṣe ká “rìn láìlẹ́bi”? Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni gbogbo wa, tá a bá ń sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, ó máa kà wá sí ẹni tó “ń rìn láìlẹ́bi.” Ìgbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, tá a sì ṣèrìbọmi la bẹ̀rẹ̀ sí í rìn pẹ̀lú ẹ̀. Àmọ́, ẹ má gbàgbé pé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, tẹ́nì kan bá jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, ìyẹn ò sọ pé ó máa láǹfààní láti jẹ́ àlejò Jèhófà. Ìdí sì ni pé àwọn kan ń ké pè é, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀ “ní òtítọ́ àti òdodo.” (Ka Àìsáyà 48:1.) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ fi hàn pé òótọ́ làwọn fẹ́ jẹ́ àlejò nínú ilé Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́, kí wọ́n sì máa ṣe é. Bákan náà lónìí, tá a bá fẹ́ rí ojúure Jèhófà, ó ju ká kàn ṣèrìbọmi, ká sì máa lọ sípàdé déédéé. A gbọ́dọ̀ máa “ṣe ohun tí ó tọ́.” Báwo la ṣe lè ṣe é?

5. Tá a bá fẹ́ máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ nígbà gbogbo, kí ló yẹ ká ṣe?

5 Lójú Jèhófà, ẹni tó “ń rìn láìlẹ́bi, tó [sì] ń ṣe ohun tí ó tọ́” máa ṣe ju kó máa lọ sípàdé déédéé, kó máa wàásù, kó sì máa ṣe àwọn iṣẹ́ míì ní Ilé Ìpàdé wa. (1 Sám. 15:22) A gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé ká lè máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, pàápàá láwọn ìgbà tá a bá dá wà. (Òwe 3:6; Oníw. 12:13, 14) Ó tún ṣe pàtàkì ká sapá láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà, kódà nínú àwọn nǹkan kéékèèké. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, òun náà á sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wa.—Jòh. 14:23; 1 Jòh. 5:3.

6. Kí ni Hébérù 6:10-12 sọ pé ó ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan tó dáa tá a ti ṣe fún Jèhófà sẹ́yìn?

6 Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti ṣe fún Jèhófà, ó sì mọyì ẹ̀ gan-an. Àmọ́ tá a bá tiẹ̀ ti ṣe àwọn nǹkan tó dáa fún Jèhófà, ìyẹn nìkan kọ́ ni Jèhófà máa wò tó bá fẹ́ gbà wá lálejò. Kí ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú Hébérù 6:10-12. (Kà á.) Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í gbàgbé àwọn nǹkan tó dáa tá a ti ṣe sẹ́yìn, àmọ́ ó fẹ́ ká máa sin òun tọkàntọkàn “títí dé òpin.” Torí náà, “tí a ò bá jẹ́ kó rẹ̀ wá,” Jèhófà máa san wá lérè, àá sì jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ títí láé.—Gál. 6:9.

MÁA SỌ ÒTÍTỌ́ NÍNÚ ỌKÀN RẸ

7. Tá a bá fẹ́ fi hàn pé à ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn wa, kí ló yẹ ká máa ṣe?

7 Ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ àlejò nínú ilé Jèhófà gbọ́dọ̀ máa “sọ òtítọ́ nínú ọkàn rẹ̀.” (Sm. 15:2) Ó ju kéèyàn má ṣe parọ́. Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tá à ń sọ àtohun tá à ń ṣe. (Héb. 13:18) Ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ olóòótọ́ torí pé “Jèhófà kórìíra oníbékebèke, ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.”—Òwe 3:32.

8. Ìwà wo ló yẹ ká sá fún?

8 Àwọn tó ń “sọ òtítọ́ nínú ọkàn” wọn kì í díbọ́n pé àwọn ń ṣe ohun tó tọ́ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, àmọ́ kí wọ́n máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ò fẹ́ tí wọ́n bá dá wà. (Àìsá. 29:13) Wọn kì í ṣe oníbékebèke. Oníbékebèke lè máa rò pé kì í ṣe ìgbà gbogbo lòfin Jèhófà ń ṣe wá láǹfààní. (Jém. 1:5-8) Ó lè máa ṣe àwọn nǹkan tínú Jèhófà ò dùn sí, kó sì máa rò pé wọn ò tó nǹkan. Àmọ́ tó bá rí i pé òun ò jìyà ohun tóun ṣe, ó lè mú kó máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. Ó lè rò pé òun ń sin Ọlọ́run, àmọ́ Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn ẹ̀. (Oníw. 8:11) Torí náà, kò yẹ kọ́rọ̀ tiwa rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.

9. Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù kọ́kọ́ pàdé Nàtáníẹ́lì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

9 Ó ṣe pàtàkì ká máa sọ òtítọ́ nínú ọkàn wa. A lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù kọ́kọ́ pàdé Nàtáníẹ́lì. Nígbà tí Fílípì mú Nàtáníẹ́lì ọ̀rẹ́ ẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ohun kan tó yani lẹ́nu ṣẹlẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò rí Nàtáníẹ́lì rí, ó sọ pé: “Wò ó, ní tòótọ́, ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀tàn kankan ò sí nínú rẹ̀.” (Jòh. 1:47) Ó dájú pé Jésù mọ̀ pé olóòótọ́ làwọn ọmọ ẹ̀yìn òun, àmọ́ ó rí i pé ti Nàtáníẹ́lì yàtọ̀ gan-an. Lóòótọ́, aláìpé bíi tiwa ni Nàtáníẹ́lì, àmọ́ kì í ṣojú ayé, ó sì jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo. Ohun tí Jésù rí yìí jẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ Nàtáníẹ́lì gan-an, ó sì gbóríyìn fún un. Ẹ ò rí i pé ó máa dáa gan-an tí Jésù bá lè sọ ohun kan náà nípa wa!

Fílípì fi Nàtáníẹ́lì ọ̀rẹ́ ẹ̀ tí kò ní ẹ̀tàn kankan han Jésù. Ṣé wọ́n lè sọ bẹ́ẹ̀ nípa àwa náà? (Wo ìpínrọ̀ 9)


10. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa ba àwọn èèyàn lórúkọ jẹ́? (Jémíìsì 1:26)

10 Ọ̀pọ̀ lára nǹkan tí Jèhófà sọ nínú Sáàmù 15 dá lórí bó ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn èèyàn. Sáàmù 15:3 sọ pé ẹni tó jẹ́ àlejò nínú ilé Jèhófà kì í “fi ahọ́n rẹ̀ bani jẹ́, kò ṣe ohun búburú kankan sí ọmọnìkejì rẹ̀, kò sì ba àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórúkọ jẹ́.” Tá a bá ba àwọn èèyàn lórúkọ jẹ́, ó lè kó bá wọn, ó sì lè mú kí Jèhófà má gbà wá lálejò mọ́.—Ka Jémíìsì 1:26.

11. Kí ni ìbanilórúkọjẹ́, kí sì ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ká ṣe tẹ́ni náà ò bá ronú pìwà dà?

11 Onísáàmù dìídì sọ̀rọ̀ nípa ìbanilórúkọjẹ́. Kí ni ìbanilórúkọjẹ́? Ìbanilórúkọjẹ́ ni irọ́ tẹ́nì kan pa kó lè ba orúkọ rere ẹlòmíì jẹ́. Tẹ́nì kan bá ń ba àwọn ẹlòmíì lórúkọ jẹ́ tí ò sì ronú pìwà dà, Ìwé Mímọ́ sọ pé kí wọ́n yọ ẹni náà kúrò nínú ìjọ.—Jer. 17:10.

12-13. Sọ àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ táá mú ká ba àwọn ọ̀rẹ́ wa lórúkọ jẹ́ láìmọ̀. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

12 Sáàmù 15:3 tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó jẹ́ àlejò nínú ilé Jèhófà kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì wọn, wọn kì í sì í ba àwọn ọ̀rẹ́ wọn lórúkọ jẹ́. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè ba ẹlòmíì lórúkọ jẹ́?

13 A lè ba ẹnì kan lórúkọ jẹ́ láìmọ̀ tá a bá ń sọ ohun tí ò jóòótọ́ nípa ẹni náà. Bí àpẹẹrẹ: (1) arábìnrin kan ò ṣe aṣáájú-ọ̀nà mọ́, (2) tọkọtaya kan kúrò ní Bẹ́tẹ́lì tàbí (3) arákùnrin kan ò ṣe alàgbà mọ́ tàbí kí arákùnrin kan má ṣe ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mọ́. Kò ní bójú mu tá a bá ń sọ pé ó jọ pé arákùnrin tàbí arábìnrin náà ṣe ohun tí ò dáa ni ò jẹ́ kó láǹfààní yẹn mọ́. Oríṣiríṣi nǹkan ló lè mú kí wọ́n má láǹfààní yẹn mọ́ táwa ò sì mọ̀. Ẹni tó jẹ́ àlejò nínú ilé Jèhófà kì í ‘ṣe ohun búburú kankan sí ọmọnìkejì rẹ̀, kì í sì í ba àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórúkọ jẹ́.’

Ó rọrùn láti máa sọ ọ̀rọ̀ tí ò jóòótọ́ nípa àwọn èèyàn kiri, ìyẹn sì lè sọ wá di afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ (Wo ìpínrọ̀ 12-13)


MÁA BỌLÁ FÚN ÀWỌN TÓ BẸ̀RÙ JÈHÓFÀ

14. Kí nìdí tí ẹni tó jẹ́ àlejò nínú ilé Jèhófà ò fi gbọ́dọ̀ bá “ẹnikẹ́ni tó jẹ́ oníwàkiwà kẹ́gbẹ́”?

14 Sáàmù 15:4 sọ pé ẹni tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà kì í “bá ẹnikẹ́ni tó jẹ́ oníwàkiwà kẹ́gbẹ́.” Torí pé aláìpé ni wá, Jèhófà nìkan ló lè sọ bóyá ẹnì kan jẹ́ oníwàkiwà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a lè nífẹ̀ẹ́ àwọn kan torí pé ìwà wa jọra, ká má sì nífẹ̀ẹ́ àwọn kan torí pé wọ́n láwọn ìwà kan tí ò bá wa lára mu. Torí náà, kìkì àwọn tí Jèhófà sọ pé wọ́n jẹ́ “oníwàkiwà” ni kò yẹ ká bá kẹ́gbẹ́. (1 Kọ́r. 5:11) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń mọ̀ọ́mọ̀ hùwà burúkú, wọn kì í sì í ronú pìwà dà, wọ́n tún máa ń ta ko ohun tá a gbà gbọ́ tàbí kí wọ́n fẹ́ ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.—Òwe 13:20.

15. Sọ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà bọlá fún “àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà.”

15 Ohun tí Sáàmù 15:4 sọ tẹ̀ lé e ni pé ká máa bọlá fún “àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà.” Torí náà, ó yẹ ká máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti fi inú rere hàn sáwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. (Róòmù 12:10) Báwo la ṣe lè ṣe é? Sáàmù 15:4 sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe é, ó ní ẹni tó jẹ́ àlejò nínú ilé Jèhófà “kì í yẹ àdéhùn, kódà tó bá máa pa á lára.” Tá a bá yẹ àdéhùn, inú àwọn èèyàn ò ní dùn sí wa. (Mát. 5:37) Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fẹ́ káwọn tó jẹ́ àlejò nínú àgọ́ ẹ̀ mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn ṣẹ. Inú ẹ̀ tún máa ń dùn táwọn òbí bá ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú ìlérí tí wọ́n ṣe fáwọn ọmọ wọn ṣẹ. Torí náà, ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn máa jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú ìlérí wa ṣẹ.

16. Ọ̀nà míì wo la lè gbà máa bọlá fáwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà?

16 Ọ̀nà míì tá a lè gbà máa bọlá fáwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ni pé ká máa gbà wọ́n lálejò, ká sì máa lawọ́ sí wọn. (Róòmù 12:13) Yàtọ̀ sí àkókò tá à ń lò pẹ̀lú àwọn ará nípàdé àti lóde ìwàásù, ó tún yẹ ká máa wà pẹ̀lú wọn láwọn àkókò míì, tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ sún mọ́ wọn, àá sì túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà náà. Bákan náà, tá a bá ń gba àwọn ará wa lálejò, Jèhófà là ń fara wé yẹn.

SÁ FÚN ÌFẸ́ OWÓ

17. Kí nìdí tí Sáàmù 15 fi sọ̀rọ̀ nípa owó?

17 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó bá máa jẹ́ àlejò Jèhófà ‘kì í yáni lówó èlé, wọn kì í sì í gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti gbógun ti aláìṣẹ̀.’ (Sm. 15:5) Kí nìdí tí ẹni tó kọ Sáàmù yìí fi sọ̀rọ̀ owó nínú Sáàmù tí ò fi bẹ́ẹ̀ gùn yìí? Ìdí ni pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ owó, ó lè mú kí àárín àwa àtàwọn míì má gún, kó sì ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. (1 Tím. 6:10) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn kan ń rẹ́ àwọn arákùnrin wọn tí ò lówó jẹ torí pé wọ́n ń gba èlé lórí owó tí wọ́n yá wọn. Bákan náà, àwọn adájọ́ kan máa ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n á wá gbé ẹ̀bi fún ẹni tó jàre, wọ́n á sì gbé àre fún ẹni tó jẹ̀bi. Jèhófà kórìíra irú àwọn ìwà yìí gan-an.—Ìsík. 22:12.

18. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa ká lè mọ irú ojú tá a fi ń wo owó? (Hébérù 13:5)

18 Ó ṣe pàtàkì ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan ká lè mọ ojú tá a fi ń wo owó. Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú nípa owó àtàwọn nǹkan tí mo fẹ́ fi owó rà? Tí mo bá yáwó, ṣé mo máa ń tètè san án pa dà àbí ṣe ni mo máa ń rò pé ẹni tó yá mi lówó náà lówó lọ́wọ́ torí náà kò pọn dandan kí n dá a pa dà? Ṣé owó tí mo ní máa ń jẹ́ kí n ronú pé mo dáa ju àwọn míì lọ, ṣé ó sì máa ń ṣòro fún mi láti lawọ́ sáwọn èèyàn? Ṣé mi kì í fẹ̀sùn kan àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó torí pé wọ́n lówó lọ́wọ́? Ṣé àwọn tó lówó nìkan ni mo máa ń mú lọ́rẹ̀ẹ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, mi ò fi bẹ́ẹ̀ gba tàwọn tálákà?’ Àǹfààní ńlá la ní pé a jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà. Torí náà, a lè fi hàn pé a mọyì àǹfààní yìí tá a bá ń sá fún ìfẹ́ owó. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé!—Ka Hébérù 13:5.

JÈHÓFÀ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN Ọ̀RẸ́ Ẹ̀

19. Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká ṣe gbogbo nǹkan tó wà nínú Sáàmù 15?

19 Ìlérí àgbàyanu tó parí Sáàmù 15 ni pé: “Ẹni tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, mìmì kan ò ní mì í láé.” (Sm. 15:5) Onísáàmù yẹn jẹ́ ká mọ ìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká ṣe gbogbo nǹkan tó sọ yìí. Ìdí náà sì ni pé ó fẹ́ ká láyọ̀. Torí náà, tá a bá ń ṣe gbogbo nǹkan tí Jèhófà sọ nínú Sáàmù 15, a máa láyọ̀, Jèhófà á sì dáàbò bò wá.—Àìsá. 48:17.

20. Kí làwọn tó jẹ́ àlejò nínú àgọ́ Jèhófà máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú?

20 Àwọn àlejò tí Jèhófà gbà sínú àgọ́ ẹ̀ máa gbádùn ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró máa lọ sí ọ̀run torí pé Jésù ti ṣètò “ọ̀pọ̀ ibùgbé” sílẹ̀ fún wọn níbẹ̀. (Jòh. 14:2) Àwọn tó sì máa gbé ayé ń fojú sọ́nà láti rí ìgbà tí ohun tó wà nínú Ìfihàn 21:3 máa ṣẹ. Kò sí àní-àní pé gbogbo wa la mọyì àǹfààní tá a ní pé Jèhófà fìfẹ́ pè wá láti wá di ọ̀rẹ́ òun, ká sì máa gbé inú àgọ́ rẹ̀ títí láé!

ORIN 39 Ní Orúkọ Rere Lọ́dọ̀ Ọlọ́run