Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Eka To N Yaworan To si N Kole Kari Aye

Eka To N Yaworan To si N Kole Kari Aye

BÁ A ṣe ń yára pọ̀ sí i nínú ètò Jèhófà ń mú ká túbọ̀ nílò ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àwọn ilé tá a ti ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú ètò Ọlọ́run, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè àti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ní àwọn ibi tó yàtọ̀ síra. Torí náà, ní oṣù October ọdún 2013, Ìgbìmọ̀ Olùdarí dá ẹ̀ka tuntun kan sílẹ̀ kí iṣẹ́ yíya àwòrán ilé, kíkọ́ ilé, sísọ ilé dọ̀tun àti ṣíṣe àtúnṣe àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò lè túbọ̀ máa wáyé lọ́nà tó rọrùn tó sì máa dín ìnáwó kù. Orúkọ tá a fún ẹ̀ka tuntun yìí ni Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé (WDC). Oríléeṣẹ́ wa ni ẹ̀ka tuntun yìí wà, nílùú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sì ń bójú tó o.

Ẹ̀ka WDC yìí ló ń bójú tó Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Láwọn Ilẹ̀ Kan (RDC). Ẹ̀ka RDC yìí wà ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, Jámánì, South Africa àti Amẹ́ríkà. Àwọn ló sì ń ṣe kòkáárí yíya àwòrán, kíkọ́lé àti ṣíṣe àtúnṣe àwọn ilé láwọn ilẹ̀ kan tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. Torí ká lè túbọ̀ máa yára kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba la ṣe dá àwọn ẹ̀ka yìí sílẹ̀. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ètò tó wà fún àwọn ilẹ̀ táwọn ará kò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ là ń lò láti fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ká lo Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn. A ti wá pa ètò méjèèjì yìí pọ̀ sójú kan báyìí, ká lè lo àǹfààní ibi tí ètò méjèèjì dáa sí láti fi mú kí àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé wa túbọ̀ yára kánkán.

Láti máa ṣe kòkáárí kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ tí a túbọ̀ nílò sí i yìí, a dá Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó Sì Ń Kọ́ Ọ ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Kọ̀ọ̀kan (LDC) sílẹ̀ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ni ẹ̀ka ìkọ́lé yìí máa ń jábọ̀ fún. Ohun kan tó múnú wa dùn nínú àtúnṣe yìí ni pé ní báyìí gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì máa lè yan àwọn òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé láti máa ran àwọn ará lọ́wọ́, kí wọ́n lè kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ.

Ní oṣù April ọdún 2014, iṣẹ́ ìkọ́lé ńláńlá tó lé ní àádọ́rinlérúgba [270] la ní láti parí, lára rẹ̀ ni àádọ́rùn-ún [90] ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, Gbọ̀ngàn Àpéjọ márùndínlógójì [35] àti àádóje [130] ẹ̀ka ọ́fíìsì. Bákan náà la tún nílò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba lójú méjèèjì. Iye Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ní láti kọ́ tàbí ká tún ṣe lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá [14,000].

Ó máa ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun bá a ṣe ń rí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn èèyàn Jèhófà láìka ààlà orílẹ̀-èdè, àṣà tàbí èdè wọn sí, tí wọ́n sì jọ ń pawọ́ pọ̀ láti kọ́ àwọn ilé tó ń fi ìyìn àti ògo fún orúkọ mímọ́ Jèhófà! Arákùnrin Dan Molchan tó ń ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Òṣìṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wa sọ pé: “Iṣẹ́ bàǹtàbanta ló ṣì wà láti ṣe, torí náà a mọyì àdúrà táwọn ará wa ń gbà lọ́kùnrin àti lóbìnrin àtàwọn ọrẹ tí wọ́n fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà. A sì tún dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti kópa nínu àwọn iṣẹ́ náà.”