Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ikorajo Awa Elerii Jehofa Ti Ero Po si Ju Lo

Ikorajo Awa Elerii Jehofa Ti Ero Po si Ju Lo

NÍ ỌJỌ́ Sátidé, October 5, ọdún 2013, ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàásàn-án, igba àti mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [257,294] èèyàn láti ilẹ̀ mọ́kànlélógún [21] ló pésẹ̀ síbi ìpàdé ọdọọdún, ìkọkàndínláàádóje [129] irú rẹ̀, ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Àwọn kan wà níbẹ̀, àwọn míì sì wò ó bó ṣe ń lọ lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹ̀rọ alátagbà. Ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, àwọn míì tún wò ó nígbà tí a tún gbé e sáfẹ́fẹ́. Àròpọ̀ iye àwọn tó pésẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù kan, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìrínwó àti mẹ́tàlá, ẹgbẹ̀ta àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [1,413,676] láti ilẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31]. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí níbi ìkórajọ wa!

Láti ọdún 1922 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń lo tẹlifóònù àti rédíò láti ṣe àtagbà àwọn àpéjọ wa láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ní báyìí, Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó wà níbi tó jìnnà láti gbọ́ ohun tó ń lọ, kí wọ́n sì máa wò ó lójú ẹsẹ̀ tàbí kété lẹ́yìn tó wáyé.

Ó lé ní ọdún kan tí àwọn ará láti onírúurú ẹ̀ka ọ́fíìsì fi ṣiṣẹ́ lórí bí wọ́n á ṣe fi Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe àtagbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Lópin ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ṣe àtagbà náà, ìlú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni àwọn amojú ẹ̀rọ wa ti bójú tó ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Tọ̀sán tòru ni wọ́n fi ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn bí wọ́n ṣe ń gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sáfẹ́fẹ́ ní ibi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àkókò wọn yàtọ̀ síra.