Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn akínkanjú arìnrìn-àjò ìsìn wà lára àwọn tó ń bá Arákùnrin Russell rin ìrìn àjò

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn—1916

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn—1916

NÍGBÀ tó fi máa di ọdún 1916, ó ti tó ọdún kan gbáko táráyé ti wà lẹ́nu Ogun Ńlá, ìyẹn Ogun Àgbáyé Kìíní. Àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bá ara wọn jà ti pa ara wọn lọ bí ilẹ̀ bí ẹní.

Ilé Ìṣọ́ January 1, 1916 ti èdè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Ogun yìí mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í tara bọ ẹ̀sìn, tí ẹ̀rù ọjọ́ ọ̀la sì ń bà wọ́n.” Àpilẹ̀kọ yẹn tún sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká máa ṣìkẹ́ àwọn àǹfààní tá a ní, kí ọkàn wa má bàá domi. Ká máa lo gbogbo àyè tó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, ká sì jẹ́ kí iná ìtara wa fún Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa jó.”

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 1916 rọ àwọn ará pé kí wọ́n jẹ́ kí ‘ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára sí i’ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Róòmù 4:20 (Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀). Ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, Jèhófà sì bù kún wọn gan-an.

Àwọn Arìnrìn-Àjò Ìsìn Fún Àwọn Ará Níṣìírí

Àwọn kan wà tó jẹ́ aṣojú Watch Tower Society tó máa ń rìnrìn àjò, àwọn yẹn là ń pè ní àwọn arìnrìn-àjò ìsìn. Àwọn yìí lọ láti ìlú kan sí òmíràn kí wọ́n lè fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìṣírí kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà. Ní ọdún 1916, àwọn arìnrìn-àjò ìsìn bíi mọ́kàndínláàádọ́rin [69] rin ìrìn àjò tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún máìlì lọ lẹ́nu iṣẹ́ yìí.

Nígbà tí Arákùnrin Walter Thorn tó jẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn ń sọ àsọyé ní àpéjọ agbègbè kan ní ìlú Norfolk, Virginia, ó fi ìjà táwọn Kristẹni ń jà wé Ogun Ńlá tó ń lọ lọ́wọ́. Ó ní: “Wọ́n fojú bù ú pé àwọn ọmọ ogun tó ń jagun lọ́wọ́ báyìí á tó ogún sí ọgbọ̀n mílíọ̀nù. . . . Bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn ò mọ̀ pé àwọn ẹgbẹ́ ológun míì tún wà táwọn náà dìhámọ́ra. Àwọn ọmọ ogun Olúwa ni wọ́n, àmọ́ bíi ti àwọn ọmọ ogun Gídíónì, kì í ṣe àwọn ohun ìjà táráyé ń lò ni wọ́n fi ń jagun tiwọn. Wọ́n ń jà fún òtítọ́ àti òdodo, wọ́n sì ń ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́.”

Wọ́n Ń Bá Iṣẹ́ Ìsìn Lọ Láìkà Wàhálà Ogun Sí

Ní apá ìparí ọdún 1916, wọ́n ja ogun kan ní orílẹ̀-èdè Faransé tí wọ́n pè ní Ogun Àkọ́kọ́ ti Somme. Àwọn ọkùnrin tó ṣòfò ẹ̀mí tàbí tí wọ́n fara gbọgbẹ́ nínú ogun yìí lé ní mílíọ̀nù kan. Lórílẹ̀-èdè yẹn kan náà, láìka bí nǹkan ṣe le koko nígbà ogun yẹn sí, àwọn ará kọ́wọ́ ti ìṣètò ìjọ (tá à ń pé ní kíláàsì nígbà yẹn). Ilé Ìṣọ́ January 15, 1916 gbé lẹ́tà kan jáde, èyí tí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Joseph Lefèvre kọ. Ìgbà táwọn ọmọ ogun Jámánì kógun wọ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ tó ń jẹ́ Denain, lórílẹ̀-èdè Faransé lọ́dún 1914 ló sá kúrò nílùú. Ó sá títí tó fi dé Paris tó wà ní gúúsù Denain, ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà nínú ìjọ kan ṣoṣo tó wà nílùú yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara arákùnrin yìí kò fi bẹ́ẹ̀ le, kò pẹ́ tó fi jẹ́ pé òun ló ń darí gbogbo ìpàdé níbẹ̀.

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ogun lé Arákùnrin Théophile Lequime náà kúrò nílùú Denain. Ìlú Auchel ni orílẹ̀-èdè Faransé ni Theophile kọ́kọ́ sá lọ, ibẹ̀ ló wà tó bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tó sì n fi wọ́n ránṣẹ́ sáwọn ara tó wà láwọn apá ibi tí àwọn ọ́mọ ogun Jámánì ò sí. Ìgbà tó di pé àwọn ológun bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí i, ó yáa sá kúrò nílùú Auchel, ó sì gbà ìlú Paris lọ. Arákùnrin Lefèvre gbà pé Jèhófà gbọ́ àdúrà òun nígbà tí Theophile wá dara pọ̀ mọ́ ọn.

Jèhófà bù kún iṣẹ́ àwọn arákùnrin wọ̀nyẹn. Arákùnrin Lefèvre ròyìn pé: “Àwa tá a wà nínú ìjọ ti di márùnlélógójì [45] . . . Àwọn kan ti ní àǹfààní iyebíye, ní ti pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n ń ṣe gudugudu méje nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìjọ ló máa ń wá sí ìpàdé ìjẹ́rìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”

Wọn Ò Dá Sí Ọ̀rọ̀ Ogun

Torí pé ogun táwọn èèyàn ń ja náà kò dáwọ́ dúró, ó wá di pé kí wọ́n máa wọ́nà àtifa àwọn ara lọ sójú ogun. Nígbà tó yá, ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣòfin pé ó di dandan kí gbogbo ọkùnrin, bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sí ogójì [40] ọdún, wọṣẹ́ ológun. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló di ìdúróṣinṣin wọn mú, tí wọn ò sì lọ́wọ́ sí ogun.

Bí àpẹẹrẹ, Ilé Ìṣọ́ April 15, 1916 ṣàtúntẹ̀ lẹ́tà tí Arákùnrin W. O. Warden tó ń gbé ní ìlú Scotland kọ. Ó sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin mi ti di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] báyìí. Ó ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ò ní wọṣẹ́ ológun, nípa bẹ́ẹ̀ ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ Olúwa lòun á fayé òun ṣe. Bí wọ́n bá tiẹ̀ wá pinnu pé ṣe ni àwọn máa tìtorí ẹ̀ yìnbọn pa á, ó dá mi lójú pé Jèhófà á fún un lókun kó lè jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo.”

Wọ́n gbé James Frederick Scott tó jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan ní ìlú Edinburgh, Scotland relé ẹjọ́ torí pé kò wọṣẹ́ ológun. Lẹ́yìn tí wọ́n yẹ gbogbo ẹ̀rí tó wà wò, ilé ẹjọ́ sọ pé Arákùnrin Scott kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, torí náà kí wọ́n yọ̀ǹda rẹ̀. Ìdí sì ni pé ilé ẹjọ́ gbà pé Scott wà lára àwọn tí òfin fún láǹfààní láti má ṣe wọṣẹ́ ológun.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ará tó kọ̀wé pé kí ìjọba yọ̀ǹda àwọn, pé àwọn kò ṣe iṣẹ́ ológun ni ìjọba ò fọwọ́ sí i. Nígbà tó fi máa di oṣù September, ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [264] làwọn ará tó kọ̀wé pé kí ìjọba yọ̀ǹda àwọn. Àwọn márùn-ún péré ni ìjọba gbà pé kó máa lọ, pé àwọn yọ̀ǹda wọn. Ìjọba ní kí àwọn mẹ́tàlélógún [23] míì lọ máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun. Àmọ́ ní tàwọn tó ṣẹ́ kù, wọ́n fimú wọn dánrin, wọ́n sì fi oríṣiríṣi ìyà jẹ ọ̀pọ̀ lára wọn, wọ́n ní káwọn kan máa la ọ̀nà tàbí kí wọ́n máa fọ́ òkúta, bẹ́ẹ̀ iṣẹ́ ìlú ni ìjọba ní wọ́n ń ṣe.

Charles Taze Russell Kú

Ní October 16, 1916, Charles Taze Russell tó n mú ipò iwájú láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn gbéra ńlé láti lọ sọ àsọyé Bíbélì láwọn àgbègbè tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́, Arákùnrin Russell kò pa dà sílé. Ìlu Pampa, ní ìpínlẹ̀ Texas lọkọ̀ ojú irin tó wà nínu rẹ̀ dé nígbà tó gbẹ́mìí mì ní ọ̀sán Tuesday, October 31 lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64].

Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló rò pé kò sẹ́ni tó lè gbapò Arákùnrin Russell láéláé. Arákùnrin Russell ti ṣàkọsílẹ̀ bó ṣe fẹ́ kí iṣẹ́ Ọlọ́run gbòòrò sí i, wọ́n sì tẹ ìsọfúnni yẹn jáde nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 1916. Síbẹ̀, ìbéèrè tó wà nílẹ̀ ni pé: Ta ló máa wá rọ́pò Russell nínú iṣẹ́ náà báyìí?

Ibi ìpàdé ọdọọdún ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ti wọ́n ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1917 ni wọ́n ti dáhùn ìbéèré yẹn. Àwọn tó pé jọ dìbò, gbogbo wọn sì fẹnu kò. Àmọ́, ṣe ló dà bí ìgbà táwọn kan lára wọn fẹ̀jẹ̀ sínú tí wọ́n tutọ́ funfun jáde nígbà ìdìbò náà torí pé ìṣọ̀kan ọ̀hún ò tọ́jọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará dojú kọ àdánwò nígbà tó yá.