Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Ará Tí Ẹ Ní Máa Bá A Lọ”!

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Ará Tí Ẹ Ní Máa Bá A Lọ”!

“Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.”—HÉBÉRÙ 13:1.

ORIN: 72, 119

1, 2. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ lẹ́tà sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni?

NÍ ỌDÚN 61 Sànmánì Kristẹni, àlàáfíà jọba láàárín àwọn ará jákèjádò ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù nígbà yẹn, àmọ́ ó ń retí pé wọ́n máa tó dá òun sílẹ̀. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá Tímótì tóun àtiẹ̀ jọ ń rìnrìn-àjò sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ni, àwọn méjèèjì sì ń gbèrò láti jọ lọ bẹ àwọn ará tó wà ní Jùdíà wò. (Hébérù 13:23) Àmọ́, ní ọdún márùn-ún sí i, àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà, pàápàá jù lọ àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì kan ní kíákíá. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù ti sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé tí wọ́n bá rí i tí àwọn ọmọ ogun yí Jerúsálẹ́mù ká, kí wọ́n sá lọ sí àwọn òkè ńlá.—Lúùkù 21:20-24.

2 Ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìkìlọ̀ yìí. Nígbà yẹn, àwọn Kristẹni tó wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ adúróṣinṣin láìka àtakò àti inúnibíni tó le koko tí wọ́n ń fojú winá rẹ̀ sí. (Hébérù 10:32-34) Àmọ́, Pọ́ọ̀lù fẹ́ kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ de ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Wọ́n máa tó dojú kọ ọ̀kan lára àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára jù lọ. (Mátíù 24:20, 21; Hébérù 12:4) Wọ́n túbọ̀ nílò ìgbàgbọ́ àti ìfaradà kí wọ́n lè sà bí Jésù ṣe sọ, ìyẹn ló sì máa pinnu bóyá wọ́n á là á já tàbí wọn ò ní là á já. (Ka Hébérù 10:36-39.) Torí náà, Jèhófà mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ lẹ́tà sáwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n yẹn kó lè fún ìgbàgbọ́ wọn lókun kó sì múra ọkàn wọn sílẹ̀ dé ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Lẹ́tà yẹn la wá mọ̀ sí ìwé Hébérù lónìí.

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun tó wà nínú ìwé Hébérù?

3 Ó yẹ kó wu àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí láti mọ ohun tó wà nínú ìwé Hébérù. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ wa jọ tí àwọn Kristẹni tó wà ní Jùdíà nígbà yẹn. “Àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí, ọ̀pọ̀ ló sì ti fara da àwọn àdánwò tàbí inúnibíni tó le koko, síbẹ̀ wọ́n dúró ṣinṣin. (2 Tímótì 3:1, 12) Àmọ́ ọ̀pọ̀ lára wa la láǹfààní láti wàásù ní fàlàlà, wọn ò sì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa tàbí sọ wá sẹ́wọ̀n torí ohun tá a gbàgbọ́. Torí náà, bíi tàwọn Kristẹni ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù, àwa náà gbọ́dọ̀ wà lójúfò. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwa náà máa tó fojú winá àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára jù lọ!—Ka Lúùkù 21:34-36.

4. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2016, kí sì nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú?

4 Kí ló máa mú ká lè múra sílẹ̀ dé àwọn nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀? Nínú ìwé Hébérù, Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Ó rán wa létí ohun kan tó ṣe pàtàkì nínú Hébérù 13:1. Ẹsẹ Bíbélì yẹn gbà wá níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.” Ẹsẹ Bíbélì yìí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2016.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2016: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.”—Hébérù 13:1

KÍ NI ÌFẸ́ ARÁ?

5. Kí ni ìfẹ́ ará?

5 Kí ni ìfẹ́ ará? Ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí “ìfẹ́ téèyàn ní sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni.” Ó jẹ́ ìfẹ́ tó lágbára gan-an bí irú èyí tí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tàbí ọmọ ìyá kan náà máa ń ní síra wọn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé okùn ọmọ ìyá yi. (Jòhánù 11:36) Kì í ṣe pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn ń pe ara wa ní arákùnrin àti arábìnrin, ohun tá a jẹ́ gan-an nìyẹn. (Mátíù 23:8) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí bí ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ará wa ṣe lágbára tó. Ìfẹ́ ará yìí pa pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà Bíbélì ló ń jẹ́ káwa èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan, ká sì jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wa.

6. Ta ni àwa Kristẹni tòótọ́ máa ń fìfẹ́ ará hàn sí, kí sì nìdí?

6 Inú àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni la ti sábà máa ń rí gbólóhùn náà “ìfẹ́ ará.” Ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ làwọn Júù máa ń pè ní “arákùnrin.” Wọn ò jẹ́ pe ẹnì kan tí kì í ṣe Júù ní arákùnrin láé. Àmọ́ ní tiwa, gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ ni “arákùnrin” wa, láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. (Róòmù 10:12) Jèhófà ti kọ́ wa pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa bíi tẹ̀gbọ́n tàbúrò. (1 Tẹsalóníkà 4:9) Àmọ́, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará?

KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ GAN-AN PÉ KÁ MÁA FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN ARÁ?

7. (a) Kí nìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará? (b) Sọ ìdí míì tó fi ṣe pàtàkì pé ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.

7 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará ni pé ohun tí Jèhófà ní ká ṣe nìyẹn. A ò lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tá ò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (1 Jòhánù 4:7, 20, 21) Ìdí míì ni pé a máa nílò ìrànlọ́wọ́ ara wa pàápàá jù lọ nígbà ìṣòro. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni, ó mọ̀ pé àwọn kan lára wọn máa tó fi ilé àtàwọn ohun ìní wọn sílẹ̀. Jésù sì ti sọ bí àkókò náà ṣe máa le tó. (Máàkù 13:14-18; Lúùkù 21:21-23) Torí náà, kí àkókò náà tó tó, àwọn Kristẹni yẹn gbọ́dọ̀ mú kí ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín wọn lágbára sí i.—Róòmù 12:9.

Àfi ká yáa túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa nísinsìnyí torí ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tá a lè kojú lọ́jọ́ iwájú nìyẹn

8. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe nísinsìnyí kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀?

8 Ìpọ́njú tá ò tíì rí irú rẹ̀ rí látijọ́ táláyé ti dáyé máa tó dé. (Máàkù 13:19; Ìṣípayá 7:1-3) Ó máa di dandan fún wa láti ṣègbọràn sí ìtọ́ni náà pé: “Lọ, ènìyàn mi, wọnú yàrá rẹ ti inú lọ́hùn-ún, kí o sì ti ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ. Fi ara rẹ pa mọ́ fún kìkì ìṣẹ́jú kan títí ìdálẹ́bi yóò fi ré kọjá.” (Aísáyà 26:20) Ó lè jẹ́ àwọn ìjọ wa ni ‘yàrá inú lọ́hùn-ún’ tí ibí yìí ń sọ. Ibẹ̀ ni àwa àtàwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti ń jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́, lílọ sí ìpàdé déédéé nìkan ò tó o! Pọ́ọ̀lù rán àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni yẹn létí pé kí wọ́n máa gba ara wọn níyànjú láti máa fi ìfẹ́ hàn kí wọ́n sì máa ṣoore fún ara wọn. (Hébérù 10:24, 25) Àfi ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa nísinsìnyí torí pé ìyẹn ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tá a lè kojú lọ́jọ́ iwájú.

9. (a) Àwọn nǹkan wo ló ń ṣẹlẹ̀ lónìí tó fi hàn pé ó yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa? (b) Sọ ìrírí bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn síra wọn?

9 Lónìí, ọ̀pọ̀ ọ̀nà la lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa kódà kí ìpọ́njú ńlá tó dé. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ń jìyà torí àwọn àjálù bí ìsẹ̀lẹ̀, àkúnya omi, ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun àtàwọn jàǹbá míì. Àwọn ará wa kan sì ń fara da inúnibíni. (Mátíù 24:6-9) Àtijẹ àtimu ń le sí i torí pé inú ayé oníwà ìbàjẹ́ là ń gbé. (Ìṣípayá 6:5, 6) Síbẹ̀, bí ìṣòro àwọn ará wa bá ṣe ń peléke sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ ká túbọ̀ máa fi hàn bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó. Báwọn èèyàn ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn nínú ayé yìí, ó yẹ kí àwa Kristẹni tòótọ́ máa fìfẹ́ hàn síra wa. (Mátíù 24:12) [1]—Wo àfikún àlàyé.

BÁWO LA ṢE LÈ TÚBỌ̀ MÁA FÌFẸ́ HÀN SÁWỌN ARÁ?

10. Kí la máa jíròrò báyìí?

10 Òótọ́ ni pé gbogbo wa la ní ìṣòro kan tàbí òmíì, àmọ́ báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará? Báwo la ṣe lè fi hàn pé irú ìfẹ́ táwọn ọmọ ìyá kan náà máa ń ní síra wọn la ní sáwọn ará wa? Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ,” ó sọ onírúurú ọ̀nà táwọn Kristẹni lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́fà lára wọn.

11, 12. Kí ló túmọ̀ sí láti fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

11 “Ẹ má gbàgbé aájò àlejò.” (Ka Hébérù 13:2.) Kí là ń pè ní “aájò àlejò”? Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò túmọ̀ sí “ṣíṣe inúure sí àwọn tá ò mọ̀ rí.” Gbólóhùn yìí lè mú ká rántí Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì. Àwọn méjèèjì yìí ṣe inúure sí àwọn àlejò tí wọn ò mọ̀ rí. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ni Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì wá mọ̀ pé áńgẹ́lì làwọn ṣe lálejò. (Jẹ́nẹ́sísì 18:2-5; 19:1-3) Àwọn àpẹẹrẹ yìí fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù nígbà yẹn níṣìírí láti máa fìfẹ́ ará hàn nípa ṣíṣe aájò àlejò.

12 Báwo la ṣe lè fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sáwọn èèyàn? A lè pe àwọn ará kan wá sílé wa ká jọ jẹun tàbí ká fún ara wa níṣìírí. Bá ò tiẹ̀ mọ alábòójútó àyíká wa àti ìyàwó rẹ̀ dáadáa, a lè pè wọ́n wá sílé wa tí wọ́n bá bẹ ìjọ wa wò. (3 Jòhánù 5-8) Kò pọn dandan ká filé pọntí fọ̀nà rokà tàbí ká náwó rẹpẹtẹ tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ará wa lálejò. A fẹ́ fún àwọn ará wa níṣìírí ni kì í ṣe pé a fẹ́ fi àwọn ohun ìní wa ṣe fọ́rífọ́rí. Kò sì yẹ kó jẹ́ pé àwọn tó lè san oore tá a ṣe wọ́n pa dà nìkan la máa pè wá sílé wa. (Lúùkù 10:42; 14:12-14) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ wa dí débi tá ó fi gbàgbé aájò àlejò.

13, 14. Báwo la ṣe lè máa fi ‘àwọn tí ń bẹ lẹ́wọ̀n sọ́kàn’?

13 ‘Ẹ máa fi àwọn tí ń bẹ lẹ́wọ̀n sọ́kàn.’ (Ka Hébérù 13:3.) Àwọn ará tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó kọ lẹ́tà yìí. Pọ́ọ̀lù gbóríyìn fún àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni torí pé wọ́n fi ‘ìbánikẹ́dùn hàn fún àwọn tí ń bẹ lẹ́wọ̀n.’ (Hébérù 10:34) Àwọn ará kan ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láàárín ọdún mẹ́rin tó lò lẹ́wọ̀n, àmọ́ ibi tó jìn làwọn míì ń gbé. Báwo ni wọ́n ṣe máa ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́? Wọ́n lè máa gbàdúrà fún un kíkankíkan.—Fílípì 1:12-14; Hébérù 13:18, 19.

A lè gbàdúrà fáwọn arákùnrin, arábìnrin, àtàwọn ọmọdé pàápàá tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Eritrea

14 Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló wà lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn ará tó wà nítòsí lè lọ bẹ̀ wọ́n wò tàbí kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan míì láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára wa ò gbé nítòsí àwọn ará wa tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́, tá ò sì ní gbàgbé wọn? Ìfẹ́ ará tá a ní á mú ká máa gbàdúrà kíkankíkan fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, a lè gbàdúrà fáwọn arákùnrin, arábìnrin, àtàwọn ọmọdé pàápàá tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Eritrea, tó fi mọ́ àwọn arákùnrin wa bíi Paulos Eyassu, Isaac Mogos àti Negede Teklemariam tó ti lé lógún ọdún tí wọ́n ti wà lẹ́wọ̀n.

15. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbéyàwó wa ní ọlá?

15 “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn.” (Ka Hébérù 13:4.) A tún lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tá a bá ń sá fún àwọn ìwà tí kò bójú mu. (1 Tímótì 5:1, 2) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá lọ ṣèṣekúṣe pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin kan, àá kó ẹ̀dùn ọkàn bá onítọ̀hún àtàwọn ẹbí rẹ̀. Ìyẹn sì lè mú káwa tá a jọ jẹ́ ará máa fọkàn tán ara wa mọ́. (1 Tẹsalóníkà 4:3-8) Àbí, báwo ló ṣe máa rí lára ìyàwó ilé kan tó bá mọ̀ pé ọkọ òun ń wo àwọn ohun tó lè mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe? Ṣé kò ní máa wò ó pé ọkọ òun ò nífẹ̀ẹ́ òun mọ́ àti pé kò ka ètò ìgbéyàwó sí?—Mátíù 5:28.

16. Báwo ni ìtẹ́lọ́rùn ṣe lè mú ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará?

16 Ẹ “ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Ka Hébérù 13:5.) Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àwọn nǹkan tá a ní á tẹ́ wa lọ́rùn. Báwo nìyẹn ṣe lè mú ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa? Tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn, àá máa rántí pé àwọn ará wa ṣe pàtàkì ju owó tàbí àwọn nǹkan míì lọ. (1 Tímótì 6:6-8) A ò ní máa ṣàríwísí àwọn ará wa tàbí ká máa ráhùn torí bí ipò nǹkan ṣe rí fún wa. A ò sì ní máa jowú àwọn ará wa tàbí ká wá di oníwọra. Àmọ́ tá a bá ní ìtẹ́lọ́rùn, àá jẹ́ ọ̀làwọ́.—1 Tímótì 6:17-19.

17. Tá a bá jẹ́ “onígboyà,” báwo nìyẹn á ṣe mú ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa?

17 “Jẹ́ onígboyà.” (Ka Hébérù 13:6.) Ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú Jèhófà ń fún wa nígboyà láti fara da àwọn àdánwò tó le koko. Ìgboyà yìí ló sì máa jẹ́ ká ní ẹ̀mí pé nǹkan á dáa. Tá a bá sì ti wá mọ̀ pé nǹkan á dáa, àá máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará, àá máa fún wọn níṣìírí, àá sì máa tù wọ́n nínú. (1 Tẹsalóníkà 5:14, 15) Kódà, nígbà ìpọ́njú ńlá pàápàá, a lè nígboyà torí a mọ̀ pé ìdáǹdè wa kù sí dẹ̀dẹ̀.—Lúùkù 21:25-28.

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìdáǹdè wa ti sún mọ́lé, a lè jẹ́ onígboyà

18. Kí ló lè jẹ́ ká túbọ̀ máa fìfẹ́ ará hàn sáwọn alàgbà?

18 “Ẹ máa rántí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín.” (Ka Hébérù 13:7, 17.) Àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ wa máa ń lo àkókò wọn láti ṣiṣẹ́ kára torí tiwa. Tá a bá ń ronú nípa gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe, ìfẹ́ àti ìmọrírì tá a ní fún wọn á máa pọ̀ sí i. A ò ní ṣe ohun táá mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì tàbí kí nǹkan tojú sú wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò fẹ́ láti máa ṣègbọràn sí wọn délẹ̀délẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó “máa fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.”—1 Tẹsalóníkà 5:13.

Ṣé o mọrírì iṣẹ́ táwọn alàgbà ńṣe nítorí wa? (Wo ìpínrọ̀ 18)

Ẹ TÚBỌ̀ MÁA FÌFẸ́ HÀN

19, 20. Báwo la ṣe lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa?

19 Ìfẹ́ táwa èèyàn Jèhófà ní síra wa làwọn èèyàn fi ń dá wa mọ̀. Bó ṣe rí nígbà ayé Pọ́ọ̀lù náà nìyẹn. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará yẹn níyànjú pé kí wọ́n túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn síra wọn lọ́nà tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó sọ pé kí wọ́n “máa bá a lọ ní ṣíṣe é ní ìwọ̀n kíkúnrẹ́rẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ.” (1 Tẹsalóníkà 4:9, 10) Ó ṣe kedere nígbà náà pé ó yẹ ká túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa.

20 Torí náà, bá a ṣe ń wo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2016 nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba jálẹ̀ ọdún yìí, ẹ jẹ́ ká máa ṣàṣàrò lórí àwọn ìbéèrè yìí: Ṣé mo lè fi kún ẹ̀mí aájò àlejò tí mo ní? Báwo ni mo ṣe lè ran àwọn ará wa tó wà lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn lọ́wọ́? Ṣé mò ń bọ̀wọ̀ fún ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run ṣe? Kí ló máa ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn? Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Báwo ni mo ṣe lè túbọ̀ máa ṣègbọràn sí àwọn tó ń múpò iwájú nínú ètò Ọlọ́run? Tá a bá ń sapá láti sunwọ̀n sí i láwọn ọ̀nà mẹ́fẹ̀ẹ̀fà yìí, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2016 ò kàn ní jẹ́ àkọlé ara ògiri lásán sí wa, ńṣe lá máa rán wa létí láti ṣe ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí ẹ ní máa bá a lọ.”—Hébérù 13:1.

^ [1] (ìpínrọ̀ 9) Tó o bá fẹ́ kà nípa bí àwọn ará wa ṣe fìfẹ́ hàn síra wọn nígbà àjálù, wo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2002, ojú ìwé 8 sí 9 àti ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, orí 19. O tún lè wo fídíò náà, “Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa.”