Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ogun Lé Ọ̀pọ̀ Èèyàn Kúrò Lórílẹ̀-Èdè Ukraine

Ogun Lé Ọ̀pọ̀ Èèyàn Kúrò Lórílẹ̀-Èdè Ukraine

 Ní February 24, 2022, àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà gbógun wọ orílẹ̀-èdè Ukraine. Ìyẹn ti mú kí ẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn wà nínú ewu, wọ́n sì ń wọ́nà àtisá kúrò nílùú láìjáfara. a

 “Ṣe ni bọ́ǹbù ń bú gbàù lọ́tùn-ún lósì, ẹ̀rù bà mí gan-an débi pé gbogbo ara mi ń gbọ̀n. Bá a ṣe gbọ́ pé wọ́n ṣètò ọkọ̀ ojú irin tó lè kó àwọn èèyàn kúrò nílùú, ojú ẹsẹ̀ la pinnu láti wọ̀ ọ́. Báàgì kékeré kan péré ni wọ́n gbà kẹ́nì kọ̀ọ̀kan gbé, torí náà a fi gbogbo ohun tá a ní sílẹ̀. Gbogbo nǹkan tá a kó sí báàgì náà ò ju àwọn ìwé tó ṣe pàtàkì, oògùn, omi àti ìpápánu. A ṣì ń gbúròó bọ́ǹbù bá a ṣe ń kúrò nílé lọ síbi tí ọkọ̀ ojú irin náà wà.”​—Nataliia, láti Kharkiv, Ukraine.

 “Títí tọ́rọ̀ náà fi ṣẹlẹ̀, ó ṣì ń ṣe wá bíi pé kò ní sógun. Òjijì la bẹ̀rẹ̀ sí í gbúròó bọ́ǹbù láwọn ibì kan nílùú, ilẹ̀ ń mì, wíńdò sì ń fọ́. Ni mo bá yára kó àwọn nǹkan díẹ̀ tó ṣe pàtàkì, mo sì kúrò nílùú. Aago mẹ́jọ àárọ̀ ni mo kúrò nílé, mo sì wọ ọkọ̀ ojú irin dé ìlú Lviv, lẹ́yìn náà mo wọ bọ́ọ̀sì tó ń lọ sórílẹ̀-èdè Poland.”​—Nadija, láti Kharkiv, Ukraine.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí

 Kí ló fà á táwọn èèyàn fi máa ń sá kúrò nílùú?

 Àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà tó gbógun wọ orílẹ̀-èdè Ukraine ló ń mú káwọn èèyàn sá kúrò lórílẹ̀-èdè náà. Àmọ́ Bíbélì sọ ohun tó ń fà á gan-an táwọn èèyàn fi máa ń sá kúrò nílùú:

  •   Ìjọba èèyàn kárí ayé ò lè pèsè ohun táwọn èèyàn nílò. Ibi tọ́rọ̀ náà burú sí ni pé àwọn aláṣẹ sábà máa ń lo agbára wọn láti jẹ gàba lórí àwọn èèyàn, kí wọ́n sì ni wọ́n lára.​—Oníwàásù 4:1; 8:9.

  •   Sátánì Èṣù, tó jẹ́ “alákòóso ayé” yìí máa ń mú káwọn èèyàn hùwà búburú. Àbájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”​—Jòhánù 14:30; 1 Jòhánù 5:19.

  •   Yàtọ̀ sáwọn ìṣòro tó ti ń bá aráyé fínra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò wà yìí pé: “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò jẹ́ àkókò tí nǹkan máa le gan-an, tó sì máa nira.” (2 Tímótì 3:1) Kò tán síbẹ̀ o, lára àwọn ìṣòro míì tó máa wà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ni ogun, àjálù, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn. Àwọn ìṣòro yìí sì máa ń mú káwọn èèyàn sá kúrò níbi tí wọ́n ń gbé.​—Lúùkù 21:10, 11.

 Kí ló lè tu àwọn tó sá kúrò nílùú nínú?

 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà b Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ àwọn àjèjì àtàwọn tó sá kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, ó sì ń gba tiwọn rò. (Diutarónómì 10:18) Ó ṣèlérí pé òun máa gbé ìjọba kan kalẹ̀ tó máa yanjú ìṣòro wọn. Ìjọba yìí la mọ̀ sí Ìjọba Ọlọ́run, òun ló sì máa rọ́pò ìjọba èèyàn. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Jèhófà máa lo Ìjọba yìí láti pa Sátánì Èṣù run. (Róòmù 16:20) Ìjọba yìí máa kárí ayé, torí náà kò ní sí àlà ilẹ̀ fún orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn níbi gbogbo kárí ayé máa di ìdílé kan. Bákan náà, kò ní sẹ́ni tó máa sá kúrò nílùú mọ́ torí Bíbélì sọ pé: “Kálukú wọn máa jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n, torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.”​—Míkà 4:4.

 Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro àwọn tó sá kúrò nílùú. Ìjọba yìí náà ni Jèhófà máa lò láti fòpin sí ìṣòro tó ń mú káwọn èèyàn sá kúrò nílùú. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tí Ọlọ́run máa ṣe:

 Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ran àwọn tó sá kúrò nílùú lọ́wọ́?

 Yàtọ̀ sí pé Bíbélì fọkàn àwọn tó sá kúrò nílùú balẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, ó tún sọ àwọn nǹkan tí wọ́n lè ṣe láti fara da ipò tí wọ́n wà.

 Ìlànà Bíbélì: “Aláìmọ̀kan máa ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ gbọ́, Àmọ́ aláròjinlẹ̀ máa ń ronú lórí ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan.”​—Òwe 14:15.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Ronú nípa àwọn nǹkan tó lè wu ẹ́ lẹ́wu, kó o sì ronú nípa bó o ṣe máa dáàbò bo ara ẹ. Ṣọ́ra fáwọn èèyànkéèyàn tí wọ́n lè fẹ́ rẹ́ ẹ jẹ torí wọ́n mọ̀ pé o ò mọ nǹkan kan nípa ibi tó o wà.

 Ìlànà Bíbélì: “Tí a bá ti ní oúnjẹ àti aṣọ, àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.”​—1 Tímótì 6:8.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Máa ṣe máa ronú ṣáá nípa àwọn nǹkan tara. Tó o bá jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn, wàá láyọ̀.

 Ìlànà Bíbélì: “Torí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí wọn.”​—Mátíù 7:12.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Jẹ́ onínúure, kó o sì máa ṣe sùúrù. Àwọn ìwà yìí máa jẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ ẹ, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ẹ níbi tó o wà báyìí.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni.”​—Róòmù 12:17.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Tẹ́nì kan bá hùwà àìdáa sí ẹ, má ṣe bínú débi pé wàá gbẹ̀san. Tó o bá gbẹ̀san, ṣe nìyẹn á jẹ́ kọ́rọ̀ náà burú sí i. Ó ṣe tán, wọ́n ní aforóyaro kì í jẹ́ kóró tán nílẹ̀.

 Ìlànà Bíbélì: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”​—Fílípì 4:13.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Máa fi ti Ọlọ́run ṣáájú nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe, kó o sì máa gbàdúrà sí i. Ó máa fún ẹ lókun kó o lè fara dà á.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, àmọ́ nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ̀ ń tọrọ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye yóò sì máa ṣọ́ ọkàn yín àti agbára ìrònú yín.”​—Fílípì 4:6, 7.

 Ohun tó túmọ̀ sí: Bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ láìka ipò tó o wà sí. Wo àpilẹ̀kọ náà “Philippians 4:6, 7​—‘Do Not Be Anxious About Anything’” lédè Gẹ̀ẹ́sì.

a Ọjọ́ kejì lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà gbógun wọ Ukraine, Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún Àwọn Tó Ń Wá Ibi Ìsádi ti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé (UNHCR) sọ pé àwọn tógun yìí máa lé kúrò nílùú kì í ṣe kékeré. Òótọ́ sì ló sọ torí pé láàárín ọjọ́ méjìlá (12) tógun yìí bẹ̀rẹ̀, ohun tó ju mílíọ̀nù méjì ló ti sá kúrò ní Ukraine lọ sórílẹ̀-èdè míì, àwọn mílíọ̀nù kan sì ti sá kúrò níbi tí wọ́n ń gbé lọ sí agbègbè míì lórílẹ̀-èdè yẹn.

b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?