Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

Japan

Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan, ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a sì fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn.

Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mú rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.

Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán, wákàtí kan kí àkókò tẹ́ ẹ máa rìn yíká tó pé.

Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò.”

Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.

Wa Ìwé Pẹlẹbẹ Tó Ń Ṣàlàyé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Jáde

Àwọn Ohun Tẹ́ Ẹ Máa Rí

Ìtàn Wa. Apá ibí lẹ ti máa rí àwọn ìwé táá jẹ́ kẹ́ ẹ rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù fún ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ní orílẹ̀-èdè Japan. Àwọn tó bá wá ṣèbẹ̀wò máa kọ́ nípa ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Japan, títí kan oríṣiríṣi ọ̀nà tá a ti gbà wàásù níbí àti iṣé ribiribi táwọn míṣọ́nárì ti ṣe.

Bíbélì ní Japan. Ẹ máa rí àwọn Bíbélì àtijọ́, tí kò fi bẹ́ẹ̀ sí mọ́, títí kan Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Japanese.

Address and Phone Number

4-7-1 Nakashinden

EBINA CITY

KANAGAWA-PREF

243-0496

JAPAN

+81 46-233-0005