Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?

“Ẹ̀n-ẹ́n​—o ò ní ìbálòpọ̀ rí kẹ̀?”

Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo fi máa dáhùn ìbéèrè yìí, ṣé wàá fẹ́ dáhùn pẹ̀lú ìdánilójú? Àpilẹ̀kọ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀!

 Kí ló túmọ̀ sí pé ẹnì kan ò tíì mọ ọkùnrin rí tàbí pé kò tíì mọ obìnrin rí?

 Ẹnì tí kò tíì mọ ọkùnrin rí tàbí tí kò tíì mọ obìnrin rí ni ẹni tí kò tíì bá ẹni kankan sùn rí.

 Àmọ́ ká sòótọ́, kéèyàn bá ẹnì kan sùn nìkan kọ́ ni wọ́n ń pè ní ìbálòpọ̀. Àwọn kan lè sọ pé àwọn ò tíì mọ ọkùnrin rí torí pé wọn ò tíì bá ẹnì kankan sùn rí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan míì tó jọ mọ́ ọn ni wọ́n ti dán wò rí.

 Bí àpẹẹrẹ, ara ohun tí wọ́n ń pè ní “ìbálòpọ̀” ni fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, títi ihò ìdí báni lòpọ̀ tàbí fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì.

 Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Gbogbo ẹni tó bá ti bá èèyàn sùn rí, títí kan ẹni tó jẹ́ pé ṣe ló fi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì tàbí tó ti ojú ihò ìdí bá ẹlòmíì lòpọ̀ tàbí tó fi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì ló ti ní ìbálòpọ̀.

 Kí ni Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀?

 Bíbélì sọ pé àárín ọkùnrin àti obìnrin tó ti ṣègbéyàwó nìkan ni ìbálòpọ̀ gbọ́dọ̀ mọ sí. (Òwe 5:​18) Torí náà, ọkùnrin tàbí obìnrin tó bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ títí dìgbà tó máa ṣègbéyàwó.​—1 Tẹsalóníkà 4:​3-5.

 Àwọn kan sọ pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ ti di nǹkan àtijọ́ àti pé kò bóde mu. Àmọ́, má gbàgbé pé ṣe ni ìkọ̀sílẹ̀, oyún àìròtẹ́lẹ̀ àtàwọn àìsàn téèyàn lè kó látinú ìbálòpọ̀ ń pọ̀ sí i lóde òní. Torí náà, ayé yìí ò lè fúnni ní ìmọ̀ràn kankan tó wúlò nípa ìwà ọmọlúwàbí!​—1 Jòhánù 2:​15-17.

 Tí ìwọ náà bá rò ó dáadáa, wàá rí i pé ìlànà inú Bíbélì tó dá lórí bá a ṣe lè máa hùwà rere bọ́gbọ́n mu gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé ẹnì kan fún ọ ní ìwé sọ̀wédowó tí owó orí rẹ̀ tó mílíọ̀nù kan náírà. Ṣé wàá kàn jù ú dà nù láti orí òrùlé kí ẹnikẹ́ni tó bá ń kọjá lè mú u?

 Irú ìpinnu tó o ṣe nípa ìwé sọ̀wédowó yìí náà ló yẹ kó o ṣe tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìnlá kan tó ń jẹ́ Sierra sọ pé: “Mi ò lè wá ta ara mi lọ́pọ̀ fún ẹnì kan tó jẹ́ pé bóyá ni màá tiẹ̀ lè rántí orúkọ ẹ̀ lọ́dún mélòó kan sígbà tá a wà yìí.” Ohun tí Tammy, ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] sọ náà jọ èyí, ó ní: “Ẹ̀bùn pàtàkì ni ìbálòpọ̀ jẹ́, mi ò gbọ́dọ̀ lò ó nílòkulò.”

 Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Bíbélì sọ pé àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ mọ́ níwà.​—1 Kọ́ríńtì 6:​18; 7:​8, 9.

 lo gbà gbọ́?

  •   Ṣé o gbà pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ bọ́gbọ́n mu àbí ó ti le jù?

  •   Ṣé o gbà pé kò sóhun tó burú táwọn méjì tí wọn nífẹ̀ẹ́ ara wọn lóòótọ́, àmọ́ tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó bá ní ìbálòpọ̀?

 Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ti wá gbà pé ohun tó dáa jù ni kéèyàn mọ́ níwà, kó má sì ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó. Wọn ò pàdánù ohunkóhun, wọn ò sì kábàámọ̀ nǹkan kan. Gbọ́ ohun tí díẹ̀ lára wọn sọ:

  •  “Inú mi dùn pé mi ò tíì mọ ọkùnrin rí! Kó sóhun tó dà bíi kéèyàn máà ní ìrírí ohun tí níní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó máa ń dá síni lára àti ọgbẹ́ ọkàn tó máa ń fà.”​—Emily.

  •  “Inú mi dùn pé mi ò sí lára àwọn tó ti gbé tibí gbé tọ̀hún rí, ọkàn mi sì balẹ̀ pé mi ò lárùn ìbálòpọ̀ kankan bó ti wù kó kéré mọ.”​—Elaine.

  •  “Àwọn ọmọbìnrin kan tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ àtàwọn kan tó jù mí lọ máa ń kábàámọ̀ pé àwọn ti ní ìbálòpọ̀ dípò káwọn ṣì ní sùúrù, èmi ò sì fẹ́ kọ́rọ̀ tèmi dà bíi tiwọn.”​—Vera.

  •  “Mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kì í jẹ́ kí wọ́n gbádùn torí pé ṣe ni wọ́n kánjú mọ ọkùnrin tàbí tí wọ́n ti gbé tibí gbé tọ̀hún. Lójú tèmi, irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ ò bọ́ sí i rárá.”​—Deanne.

 Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Ó yẹ kó o mọ ohun tó o gbà gbọ́ dunjú kó tó dìgbà tí wọ́n á máa fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ tàbí tí ọkàn rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí i.​—Jákọ́bù 1:​14, 15.

 Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì?

 Kí ló yẹ kó o sọ tẹ́nì kan bá bi ẹ́ pé kí nìdí tó ò fi tíì ní ìbálòpọ̀? Ohun tí wọ́n bá ní lọ́kàn ló máa pinnu ohun tí wàá sọ.

 “Tó bá jẹ́ pé torí kẹ́nì kan lè fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ ló ṣe bi mí, mi ò kàn ní máa wò ó níran bẹ́ẹ̀. Màá sọ fún un pé, ‘Kò séyìí tó kàn ẹ́ níbẹ̀,’ màá sì máa bá tèmi lọ.”​—Corinne.

 “Ó ṣeni láàánú pé, ó máa ń dùn mọ́ àwọn kan ní iléèwé láti máa fi àwọn ẹlòmíì ṣe yẹ̀yẹ́. Tó bá jẹ́ pé tórí àti ṣe yẹ̀yẹ́ ni wọ́n ṣe bi mí léèrè ọ̀rọ̀, mo lè máà dá wọn lóhùn rárá.”​—David.

 Ǹjẹ́ o mọ̀? Nígbà míì, Jésù kì í dá àwọn tó fẹ́ fi í ṣẹ̀sín lóhùn.​—Mátíù 26:62, 63.

 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé òótọ́ ibẹ̀ lẹni tó ń bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ yìí fẹ́ mọ̀ ńkọ́? Tó o bá rò pé ó ṣeé ṣe kẹ́ni yẹn nífẹ̀ẹ́ ohun tí Bíbélì sọ, o lè ka ẹsẹ Bíbélì kan fún un, irú bíi 1 Kọ́ríńtì 6:​18, tó sọ pé ẹni tó bá ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀ tàbí pé ó ń ṣàkóbá fún ara rẹ̀.

 Bóyá Bíbélì lo fi dá a lóhùn àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o fi ìdánilójú sọ̀rọ̀. Máa rántí pé ohun àmúyangàn ló jẹ́ pé o níwà rere, ó sì yẹ kínú rẹ máa dùn.​—1 Pétérù 3:​16.

 “Tó o bá fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, á fi hàn pé o ò ṣiyè méjì nípa ohun tó o gbà gbọ́, á sì fi hàn pé o gbà pé ohun tó tọ́ lò ń ṣe, kì í ṣe pé wọ́n fipá mú ẹ ṣe é.”​—Jill.

 Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Tí ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìbálòpọ̀ bá dá ẹ lójú, wà á lè ṣàlàyé rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. Ohun tí wọ́n á sì sọ nígbà míì lè yà ẹ́ lẹ́nu. Melinda tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] sọ pé: “Ṣe làwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ yìn mí nígbà tí mo sọ fún wọn pé mi ò tíì mọ ọkùnrin. Wọn ò wò mí bí ẹni tí ò dákan mọ̀. Nǹkan iyì ni wọ́n kà á sí, wọ́n sí wò ó pé irú ẹni yìí máa lè kó ara rẹ̀ níjàánu.”

 Ìmọ̀ràn! Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe lè jẹ́ kí ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìbálòpọ̀ túbọ̀ dá ẹ lójú, wa apá tá a pè ní ibi tí mo kọ èrò mi sí jáde, èyí tó ní àkòrí náà “Bó O Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Nípa Ìbálòpọ̀.” Tún wo ìwé náà Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́.

 “Mo fẹ́ràn àwọn àlàyé tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó wà nínú ìwé ‘Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé’. Bí àpẹẹrẹ, àpèjúwe kan tó wà lójú ìwé 187 nínú Apá 1 fi hàn pé téèyàn bá ń ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó, ṣe ló dà bí ìgbà tẹ́nì kan tó ní ẹ̀gbà ọrùn olówó iyebíye kàn lọ fún ẹlòmíì lọ́fẹ̀ẹ́. Ó kàn ta ara rẹ̀ lọ́pọ̀ ni. Àpèjúwe míì tó wà lójú ìwé 177 fi hàn pé tó o bá ń ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, ṣe ló dà bí ìgbà tó o sọ ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye kan di ìnusẹ̀. Àmọ́ àpèjúwe tí mo fẹ́ràn jù wà lójú ìwé 54 nínú Apá 2. Ó ní: ‘Bó o bá ń ní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó, ńṣe ló dà bí ìgbà tí ò ń ṣí ẹ̀bùn tí wọn ò tíì fún ẹ wò.’ Ṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń jí nǹkan ẹlòmíì, ìyẹn nǹkan tó tọ́ sí ẹni tí wà á fẹ́ lọ́jọ́ iwájú.”​—Victoria.