Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Ìmúra Mi Ṣe Rí?

Báwo Ni Ìmúra Mi Ṣe Rí?

 Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa kíyè sí bó o ṣe ń múra? Torí pé ìmúra ẹ máa ń sọ irú ẹni tó o jẹ́. Kí ni ìmúra rẹ ń sọ nípa ẹ?

 Àṣìṣe mẹ́ta táwọn èèyàn máa ń ṣe lórí ọ̀rọ̀ ìmúra àti bá a ṣe lè yẹra fún wọn

 Àṣìṣe kìíní: Kéèyàn fẹ́ máa múra bíi tàwọn tó ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìwé ìròyìn.

 Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Theresa sọ pé: “Ó máa ń wù mí láti múra bíi tàwọn tí mò ń rí nínú ìpolówó ọjà. Téèyàn bá ń rí àwọn tó ń wọ irú aṣọ kan, tó sì jẹ́ pé gbogbo ìgbà lèèyàn ń ronú kàn wọ́n, àfi kéèyàn sapá láti má ṣe múra bíi tiwọn.”

 Kì í ṣe àwọn obìnrin nìkan ni wọ́n ń fi ìpolówó ọjà tàn jẹ. Ìwé The Everything Guide to Raising Adolescent Boys sọ pé: “Àwọn ọkùnrin náà máa ń kó sí pańpẹ́ àwọn tó ń polówó ọjà. Láti kékeré ni àwọn tó ń polówó ọjà ti máa ń kó sí àwọn náà lórí.”

 Ìlànà tó o lè tẹ̀ lé: Bíbélì sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà yìí, ó yẹ kó o máa kíyè sí ohun tí ò ń wò nínú ìpolówó ọjà. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá polówó aṣọ kan, tí wọ́n sì sọ pé tó o bá wọ̀ ọ́, ó máa jẹ́ kí ọkàn àwọn èèyàn fà sí ẹ gan-an, bi ara rẹ pé:

  •  ‘Ǹjẹ́ ó máa ṣe mí láǹfààní tí mo bá ń ra gbogbo aṣọ tí wọ́n polówó?’

  •  ‘Irú èèyàn wo ni àwọn èèyàn á rò pé mo jẹ́?’

  •  ‘Ṣé ìmúra mi sọ irú ẹni tí mo jẹ́ gan-an àti ohun tí mo gbà gbọ́?’

 Àbá: Fara balẹ̀ wo ìpolówó aṣọ tí àwọn ilé iṣẹ́ Tẹlifíṣọ̀n, ìwé ìròyìn àtàwọn míì ń gbé jáde. Ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Irú ìgbé ayé wo ni ìpolówó yìí ń gbé lárugẹ? Ṣé kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ dọ́gbọ́n mú kó o ronú pé ó yẹ kó o máa múra bíi tàwọn kan? Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Karen sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ káwọn ojúgbà wọn múra lọ́nà tó gbayì, tó dùn ún wò, tó sì tún fi ara hàn. Ohun táwọn tó ń polówó ọjà sì ń fẹ́ gan-an nìyẹn, torí ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń polówó lọ́nà tó máa fa àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra.”

Àṣìṣe kejì: Kéèyàn fẹ́ máa múra bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń múra.

 Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Manuel sọ pé: “Tí aṣọ kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ ní i. Tí o kò bá rà á, wọ́n á sọ pé o ò ríta.” Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Anna gbà pé òótọ́ ni, ó sọ pé: “Kéèyàn máa múra bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń múra ló ṣe pàtàkì jù sáwọn èèyàn.”

 Ìlànà tó o lè tẹ̀ lé: Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.’ (Róòmù 12:2) Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn yìí, wo àwọn aṣọ tó o ní, kó o wá bi ara rẹ pé:

  •  ‘Kí ni mo máa fi ń pinnu aṣọ tí mo fẹ́ rà?’

  •  ‘Ṣé aṣọ táwọn ilé-iṣẹ́ tó lóókọ ṣe ni mo máa ń fẹ́ rà?’

  •  ‘Ṣé mo máa ń fẹ́ fi ìmúra mi ṣe fọ́rífọ́rí fáwọn èèyàn?’

 Àbá: Dípò tí wàá fi máa tẹ̀ lé ìlànà méjì yìí, ìyẹn kó o wọ aṣọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, tí ọ̀pọ̀ èèyàn gba tiẹ̀ tàbí kó o wọ aṣọ tí kò bágbà mu mọ́. Ronú nípa ìlànà kẹta yìí, ìyẹn ni pé kí ìmúra rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, kó má sì kó ẹ sí wàhálà. Tó o bá wọ aṣọ tó dáa tó sì buyì kún ẹ, kò ní máa wù ẹ láti múra bí àwọn ọ̀dọ́ míì tó ń wọ ìwọ̀kuwọ̀.

Àṣìṣe kẹta: Kéèyàn rò pé wọ́n á gba tòun tí òun bá wọ ìwọ̀kuwọ̀.

 Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé: “Ká sòótọ́, nígbà míì, ó lè máa ṣèèyàn bíi pé kó wọ ìwọ̀kuwọ̀, ìyẹn ni pé kéèyàn wọ aṣọ péńpé tàbí èyí tó fún mọ́ni lára pinpin tàbí èyí tó ṣí ara sílẹ̀.”

 Ìlànà tó o lè tẹ̀ lé: Bíbélì sọ pé: “Kí ọ̀ṣọ́ yín má sì jẹ́ ti irun dídì lóde ara . . . ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.” (1 Pétérù 3:3, 4) Ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn yìí, ronú nípa irú aṣọ tó dára jù, ṣé èyí táá jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o lẹ́wà ni àbí èyí táá fi hàn pé o lẹ́wà lójú Ọlọ́run?

 Àbá: Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ló dára jù kó o ní tó bá kan ọ̀rọ̀ ‘aṣọ àti ìmúra.’ Lóòótọ́, àwọn èèyàn ò kà á sí mọ́ lóde òní. Àmọ́, rò ó wò ná:

 Ǹjẹ́ o ti bá ẹnì kan tó máa ń rojọ́ púpọ̀ sọ̀rọ̀ rí, tó sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ara ẹ̀ ló máa ń sọ ṣáá? Èyí tó burú jù ni pé ẹni náà ò fura pé gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń sọ yẹn ti sú ẹ!

Ọ̀rọ̀ ìmúra dà bí ìgbà tí ẹnì kan ń bá ẹ sọ̀rọ̀, tó sì jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ara ẹ̀ ló kàn ń sọ ṣáá, ó dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ á sú ẹ tó bá yá

 Ìwọ náà á dà bí ẹni yẹn tí o kò bá múra bíi ti ọmọlúwàbí. Ìmúra rẹ lè máa dọ́gbọ́n sọ fún àwọn èèyàn pé ‘ẹ wò mí,’ ìyẹn sì lè kó ẹ sí wàhálà tàbí kó mú kó o máa wá bí àwọn èèyàn á ṣe máa gba tìẹ ṣáá. Ó tún lè jẹ́ kó o fẹ́ ṣe ohunkóhun tó bá gbà láti mú káwọn èèyàn pe àfíyèsí sí ẹ, èyí sì lè ṣe ìpalára fún ẹ.

 Dípò tí wàá fi máa polówó ara rẹ nípa wíwọ ìwọ̀kuwọ̀, ó sàn kó o lo ìmẹ̀tọ́mọ̀wà. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Monica sọ pé: “Ti pé o jẹ́ ẹni tó ń lo ìmẹ̀tọ́mọ̀wà kò túmọ̀ sí pé kó o máa múra bí arúgbó. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé o buyì kún ara ẹ àtàwọn tó mọ̀ ẹ́.”