Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Tí Wọ́n Bá Fún Mi Nímọ̀ràn?

Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Tí Wọ́n Bá Fún Mi Nímọ̀ràn?

 Dán ara ẹ wò

 Nígbà míì, gbogbo wa la nílò ìmọ̀ràn tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti sunwọ̀n sí i nínú ìwà àti ìṣe wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan tó lè ṣẹ̀lẹ̀ yìí.

  1.  Olùkọ́ ẹ sọ fún ẹ pé ńṣe ló kánjú ṣe iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tó o ṣe kẹ́yìn. Ó sọ pé “Ó yẹ kó o wáyè láti ṣèwádìí sí i nípa ẹ̀.”

     Kí lo máa ṣe sí ìmọ̀ràn yìí?

    1.   Kọ̀ ọ́. (‘Olùkọ́ náà ò kàn fẹ́ràn mi ni.’)

    2.   Gbà á. (‘Màá lo ìmọ̀ràn yìí tí mo bá fẹ́ ṣe iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ míì.’)

  2.  O ṣẹ̀ṣẹ̀ tún yàrá ẹ ṣe, àmọ́ ìyá ẹ sọ pé yàrá náà kò bójú mu rárá.

     Kí lo máa ṣe sí ìmọ̀ràn yìí?

    1.   Kọ̀ ọ́. (‘Kò sóhun tó máa ń tẹ́ màámi lọ́rùn.’)

    2.   Gbà á. (‘Mo gbà pé mo lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.’)

  3.  Àbúrò ẹ obìnrin sọ fún ẹ pé o máa ń fẹ́ ṣe bí ọ̀gá lé òun lórí.

     Kí lo máa ṣe sí ìmọ̀ràn yìí?

    1.   Kọ̀ ọ́. (‘Ta ló ń jẹun tájá ń jùrù?’)

    2.   Gbà á. (‘Ó yẹ kí n túbọ̀ máa ṣe sùúrù fún un jù báyìí lọ.’)

 Àwọn ọ̀dọ́ kan lè fọ́ yángá tí wọ́n bá fún wọn nímọ̀ràn, ṣe ni wọ́n dà bí àwo ẹlẹgẹ́ kan tó lè fọ́ nígbàkigbà, Ṣé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o ti ń pàdánù ohun pàtàkì kan! Kí nìdí? Torí pé ànímọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni kéèyàn mọ bá a ṣe ń gbàmọ̀ràn, ànímọ́ yìí sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

Má ṣe kọ ohun tó yẹ kó o gbọ́ tórí pé kò bá ẹ lára mú

 Kí nìdí tí mo fi nílò ìmọ̀ràn?

  •   Torí pé aláìpé ni ẹ́. Bíbélì sọ pé: “Nítorí pé gbogbo wa ni a máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jémíìsì 3:​2, àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, gbogbo wa la nílò ìmọ̀ràn.

     “Mo máa ń fi sọ́kàn nígbà gbogbo pé aláìpé ni wá àti pé kò sí bí a ò ṣe ní ṣe àṣìṣe. Torí náà, tí wọ́n bá ti fún mí nímọ̀ràn, mó máa ń gbà á, màá sì kẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀ kí n má bà a ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.”​—David.

  •   Torí pé o lè ṣe dáadáa sí i. Bíbélì sọ pé: “Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóò sì gbọ́n sí i.” (Òwe 9:9) Àǹfààní tó pọ̀ ló máa ṣe ẹ́ tó o bá ń gbà ìmọ̀ràn.

     Tẹ́lẹ̀, mi ò kì í fẹ́ gbàmọ̀ràn. Mo rò pé ṣe ló máa ń jẹ́ kí n dà bí èèyàn burúkú. Àmọ́, ní báyìí, mo ti ń gbàmọ̀ràn, kódà mo tún máa ń ní káwọn èèyàn fún mi nímọ̀ràn. Mo fẹ́ mọ bí mo ṣe lè sunwọ̀n sí i.”​—Selena.

 Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn sọ pé kí ẹlòmíì fún òun ní ìmọ̀ràn, àmọ́ ohun míì ni pé kẹ́nì kan kàn ṣàdédé fúnni nímọ̀ràn. Natalie sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan fún un ní káàdì kan tó jẹ́ pé ìmọ̀ràn tí kò retí ló wà nínú rẹ̀. O sọ pé: “Inú mi ò dùn, ìrẹ̀wẹ̀sì sì bá mi. Mò ń sa gbogbo ipá mi gan-an, àmọ́, ìmọ̀ràn tí mi ò nílò yìí ni wọ́n fi san mí lẹ́san!”

 Ṣé irú ẹ̀ ti ṣẹ̀lẹ̀ sí ẹ rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe?

 Báwo ló ṣe yẹ kí n máa gbàmọ̀ràn?

  •   Máa fetí sílẹ̀.

     Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó ní ìmọ̀ máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ tó ń sọ, ẹni tó sì ní òye kì í gbaná jẹ.” (Òwe 17:27) Má ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ ẹni tó ń bá ẹ sọ̀rọ̀ lẹ́nu. Má sì fìbínú sọ̀rọ̀ padà, kó o má bàa sọ ohun tí wàá padà kábàámọ̀ ẹ̀!

     Tí wọ́n bá fún mi nímọ̀ràn, mo máa ń fẹ́ wí àwíjàre. Àmọ́, ṣe ló yẹ kí n gbà á kí n lè ṣe dáadáa sí i nígbà míì.”​—Sara.

  •   Ìmọ̀ràn ni kó o fọkàn sí, kì í ṣe ẹni tó fún ẹ nímọ̀ràn.

     Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o rí àṣìṣe ẹni tó fún ẹ nímọ̀ràn. Àmọ́ ó máa dáa tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé, “ó yẹ kí gbogbo èèyàn yára gbọ́rọ̀, kí wọ́n sì lọ́ra láti sọ̀rọ̀, kí wọ́n má sì tètè máa bínú.” (Jémíìsì 1:19) Òótọ́ máa ń wà nínú ìmọ̀ràn, má ṣe torí pé kò bá ẹ lára mu kó o pàdánù ohun tó yẹ kó o gbọ́.

     Mo sábà máa ń bínú tí mo sì máa ń sọ pé, ‘Mo mọ̀, mo mọ̀,’ táwọn òbí mi bá ń fún mi nímọ̀ràn. Àmọ́ tí mo bá fetí sílẹ̀, tí mo sì gbàmọ̀ràn, àǹfààní tó pọ̀ ló máa ń ṣe mi.”​—Edward.

  •   Má ṣe jọra ẹ lójú.

     Ti pé wọ́n fún ẹ nímọ̀ràn kò sọ ẹ́ di aláṣetì. Ṣe ló túmọ̀ sí pé aláìpé bíi ti gbogbo èèyàn ni ẹ́. Kódà, bó pẹ́ bó yá ẹni tó ń gbà ẹ́ nímọ̀ràn gan-an máa nílò kí ẹlòmíì fún un nímọ̀ràn lónìí tàbí lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Kò sí olódodo kankan láyé tó ń ṣe rere nígbà gbogbo tí kì í dẹ́ṣẹ̀.”​—Oníwàásù 7:20.

     Ọ̀rẹ́ mi kan fún mi nímọ̀ràn tí mo gbà pé mi ò nílò. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ àmọ́ ohun tó sọ yẹn dùn mí gan-an. Ṣùgbọ́n, nígbà tó yá mo wá rí i pé òótọ́ wà nínú ohun tó sọ. Ọpẹ́lọpẹ́ ìmọ̀ràn tó gbà mí, ká ní kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni, mi ò ní mọ pé ó yẹ kí ń ṣiṣẹ́ lórí nǹkan yẹn.”​—Sophia.

  •   Pinnu pé ó fẹ́ sunwọ̀n sí i.

     Bíbélì sọ pé “aláròjinlẹ̀ máa ń gba ìbáwí.” (Òwe 15:5) Tó o bá ń gba ìbáwí, kíá ni wàá gbàgbé bó ṣe dùn ẹ́ tí wàá sì múra láti ṣàtúnṣe sáwọn ibi tó yẹ. Pinnu àwọn nǹkan tó o máa ṣe kó o sì máa kíyè sí àwọn àyípadà tó o ṣe láwọn oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn.

     “Téèyàn bá gbà ìbáwí, ó fi hàn pé èèyàn jẹ́ olóòótọ́, tórí pé o gbọ́dọ̀ gbà pé lóòótọ́ lo ṣe àṣìṣe kó o tó lè gba ìmọ̀ràn, kó o tọrọ àforíjì, kó o sì múra tán láti ṣàtúnṣe.”​—Emma.

 Òótọ́ ibẹ̀: Bíbélì sọ pé: “Bí irin ti ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.” (Òwe 27:​17, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ jẹ́ irinṣẹ́ àtàtà tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní báyìí àti nígbà tó o bá dàgbà.