Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

FEBRUARY 9, 2018
TAIWAN

Ìmìtìti Ilẹ̀ Ṣọṣẹ́ ni Taiwan

Ìmìtìti Ilẹ̀ Ṣọṣẹ́ ni Taiwan

Ní alẹ́ Tuesday, February 6, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára gan-an wáyé ní etíkun tó wà ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Taiwan. Ìròyìn fi hàn pé àwọn mẹ́fà ló kú sí inú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àwọn tó ju àádọ́talénígba [250] ló sì fara pa yánnayànna. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] míì ni wọ́n ṣì ń wá.

Kò sí arákùnrin tàbí arábìnrin wa kankan tó kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọn ò sì fara pa. Àmọ́, ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn ba ilé kan tí Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Taiwanese jẹ́. Ilé náà wà ní ìlú Hualien, ibẹ̀ wà lára àwọn ibi tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà ti ṣọṣẹ́ jù. Yàtọ̀ síyẹn, ilé tí àwọn kan lára àwọn atúmọ̀ èdè ń gbé bà jẹ́ gan-an, torí náà wọ́n ní láti kúrò ní ilé yẹn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ará tó wà ní ìtòsí bá wọn ṣètò ibi tí wọ́n lè forí pamọ́ sí fúngbà díẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Taiwan náà ń pèsè àwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò fún wọn.

Àdúrà wa ni pé, kí Ọlọ́run fún àwọn ará wa tí àjálù náà dé bá ní ìbàlẹ̀ ọkàn ní àsìkò tí nǹkan dojú rú yìí, kí àwọn tí wọ́n sì yàn láti bójú tó wọn dà “bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù.”—Aísáyà 32:2.

Media Contacts:

International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Taiwan: Chen Yongdian, +886-3-477-7999