Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

June 14, 2018
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Bí Wọ́n Ṣe Fìgboyà Kọ̀ Láti Ṣe Ohun Tó Ta Ko Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Mú Kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ṣe Ìpinnu Mánigbàgbé Kan ní Ọdún Márùndínlọ́gọ́rin Sẹ́yìn

Bí Wọ́n Ṣe Fìgboyà Kọ̀ Láti Ṣe Ohun Tó Ta Ko Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Mú Kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ṣe Ìpinnu Mánigbàgbé Kan ní Ọdún Márùndínlọ́gọ́rin Sẹ́yìn

Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni Gathie Barnett, ọmọ ọdún mẹ́jọ sì ni Marie àbúrò ẹ̀ obìnrin. Àwọn ọmọ kíláàsì wọn ń kí àsíá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àmọ́ ńṣe làwọn méjèèjì dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ láìsọ nǹkankan. Wọn ò mọ̀ pé ohun táwọn ṣe torí ohun táwọn gbà gbọ́ yìí máa gbé àwọn dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lọ́dún 1943, mánigbàgbé lẹjọ́ ọ̀hún sì máa jẹ́. Ohun táwọn ọmọbìnrin méjèèjì yìí gbà gbọ́ ni pé Ọlọ́run nìkan ló yẹ káwọn jẹ́ olóòótọ́ sí. Wọ́n wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà wọ́n láyè láti ṣe gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.​—Ìṣe 5:29.

Torí pé Gathie àti Marie kọ̀ jálẹ̀ láti kí àsíá, wọ́n lé wọn kúrò níléèwé àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Slip Hill ní ìpínlẹ̀ West Virginia. Bàbá wọn ò fọwọ́ lẹ́rán, ó bá àwọn aláṣẹ ṣe ẹjọ́ títí ẹjọ́ náà fi dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Amẹ́ríkà. Nígbà tó di June 14, 1943, Ilé Ẹjọ́ dájọ́ pé àwọn aláṣẹ iléèwé ò lè fipá mú àwọn ọmọ láti kí àsíá, wọ́n sì jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ní in lọ́kàn láti “hùwà àfojúdi sí àsíá tàbí orílẹ̀-èdè.” Ẹjọ́ West Virginia State Board of Education v. Barnette yìí mú kí wọ́n fagi lé ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ dá tẹ́lẹ̀ nínú ẹjọ́ Minersville School District v. Gobitis lọ́dún mẹ́ta ṣáájú ìgbà yẹn, tí wọ́n ti fún àwọn aláṣẹ iléèwé ní ẹ̀tọ́ láti mú káwọn ọmọ iléèwé kí àsíá dandan. *

Adájọ́ Robert Jackson, kọ èrò Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lọ́nà tó ṣe kedere, ó ní: “Ìlànà tó ṣe pàtàkì jù nínú òfin ìjọba orílẹ̀-èdè wa, tí kò sì lè yí pa dà ni pé, kò sí aláṣẹ kankan, bó ti wù kó lágbára tó, tó lè pinnu fáwọn èèyàn lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè, ẹ̀sìn àtàwọn ọ̀rọ̀ míì tó jẹ́ ìpinnu ara ẹni. Kò sì sẹ́ni tó lè fipá mú káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n ṣe nǹkan lọ́nà tó máa dà bíi pé ńṣe ni ìjọba fi dandan mú wọn ṣe ohun tí wọn ò fẹ́.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìpinnu ilé ẹjọ́ yẹn kọ́kọ́ ṣe láǹfààní, Andrew Koppelman, tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nípa òfin ní Northwestern University, sọ pé: “Ó yẹ káwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ aráàlú dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n fara da inúnibíni tó rorò lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí wọ́n lè jà fún ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin. Gbogbo wa là ń jadùn ẹ̀ báyìí.”

Philip Brumley, tó jẹ́ agbẹjọ́rò àgbà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣàlàyé pé kì í kàn ṣe pé ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe nípa lórí òfin ilẹ̀ Amẹ́ríkà nìkan, ó ní: “Ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ṣe lórí ẹjọ́ Barnette ti nípa tó lágbára lórí àwọn orílẹ̀-èdè míì, a sì mọ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Ajẹntínà, Kánádà, Costa Rica, Gánà, Íńdíà, Philippines àti Rùwáńdà, títí kan Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, ló ń kan sáárá sí bí Ilé Ẹjọ́ ṣe dá ẹjọ́ yìí, àwọn náà sì ń tẹ̀ lé ohun tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Amẹ́ríkà ṣe.”

Lọ́dún 2006, wọ́n ránṣẹ́ pe Gathie àti Marie pé kí wọ́n wá sí Robert H. Jackson Center nílùú New York, láti pàdé àwọn ọ̀mọ̀wé kan tó jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká, táwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún, kí wọ́n sì ṣàlàyé ipa rere tí ẹjọ́ wọn ti ní. Marie sọ pé: “Ó múnú mi dùn gan-an pé àbájáde ẹjọ́ náà ṣèrànwọ́ fáwọn ọmọ tó wọ ilé ìwé lẹ́yìn wa.” Gathie fi kún un pé: “Mo rántí ìgbà tí wọ́n ní kí ọmọkùnrin mi àgbà lọ sí ọ́fíìsì ọ̀gá iléèwé torí pé kò kí àsíá. Ṣe ni ọ̀gá iléèwé náà pa dà wá sọ fún un pé, ‘Ó jọ pé tíṣà ẹ ò rántí ìpinnu tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe.’”

Bọ́rọ̀ ṣe rí lára gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Gathie ṣe sọ ọ́, ó ní: “A ò fojú di àsíá, a sì bọ̀wọ̀ fún ohun tó dúró fún. A ò níṣòro pẹ̀lú ìyẹn. Ohun tí kò jọra pẹ̀lú ohun tá a gbà gbọ́ ni pé ká máa jọ́sìn rẹ̀ tàbí ká máa kí i.”​—1 Jòhánù 5:21.

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ ṣi orúkọ àpèlé àwọn ọmọ Gobitas àti Barnett kọ.