Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọ̀mọ̀wé Gabriele Hammermann, olùdarí Ibi Ìrántí Tó Wà ní Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ìlú Dachau, fi fọ́tò àmì ìrántí Max Eckert hàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀.

JULY 9, 2018
JÁMÁNÌ

Kì Í Ṣẹni Táwọn Èèyàn Ò Mọ̀ Mọ́: Wọ́n Ṣèrántí Max Eckert ní Ibi Ìrántí Tó Wà ní Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ìlú Dachau

Kì Í Ṣẹni Táwọn Èèyàn Ò Mọ̀ Mọ́: Wọ́n Ṣèrántí Max Eckert ní Ibi Ìrántí Tó Wà ní Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ìlú Dachau

Nígbà ayẹyẹ kan tó wáyé ní May 7, ọdún 2018, ní Ibi Ìrántí Tó Wà ní Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ìlú Dachau, wọ́n ṣí aṣọ lójú àmì ìrántí kan tí wọ́n ṣe ní ìrántí Arákùnrin Max Eckert tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n fún ohun tó lé ní ọdún méjì ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó ti wà ní ìlú Dachau nígbà kan rí, kó tó di pé wọ́n gbé e lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó burú jáì tó wà ní ìlú Mauthausen lórílẹ̀-èdè Austria. Ó tó igba (200) èèyàn tó rí àmì ìrántí náà. Àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ yẹn ni Max Eckert kú sí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba èèyàn ló mọ Arákùnrin Eckert kó tó kú, ó ti wá di ọkùnrin tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.

Fọ́tò àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìlú Dachau àtijọ́ tí wọ́n yà láìpẹ́ yìí rèé, ibẹ̀ ni Max Eckert ti ṣẹ̀wọ̀n kí wọ́n tó mú un lọ sí Mauthausen.

Àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Mauthausen, tí Max Eckert kú sí.

Àkọsílẹ̀ nípa Arákùnrin Eckert fi hàn pé ó pẹ́ tó ti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run. Ní ọdún 1935, wọ́n ní kí òun àti ìyàwó rẹ̀ sanwó ìtanràn torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn. Lẹ́yìn yẹn, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ torí pé ó kọ̀ láti gbé àsíá tó ní àmì òṣèlú swastika. Ní ọdún 1937, ó pẹ̀lú nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) Ẹlẹ́rìí Jèhófà onígboyà tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n ní ìlú Dachau. Ní ohun tó lé ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n gbé e lọ sí ìlú Mauthausen níbi tí, ó kéré tán, ọ̀kẹ́ mẹ́rin ààbọ̀ (90,000) ẹlẹ́wọ̀n kú sí torí ipò tó burú jáì. Ní February 21, ọdún 1940, wọ́n tẹ wáyà ránṣẹ́ sí ìyàwó Arákùnrin Eckert, èyí tí wọ́n fi túfọ̀ ọkọ rẹ̀ fún un tẹ̀gàntẹ̀gàn pé: “Ọkọ rẹ kú lónìí ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i, kàn sí àwọn ọlọ́pàá.” Ọmọ ọdún mẹ́tàlélógójì (43) ní nígbà tó kú.

Nígba tí Ọ̀mọ̀wé Gabriele Hammermann, tó jẹ́ alábòójútó Ibi Ìrántí Tó Wà ní Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ìlú Dachau ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ó ṣàlàyé pé: “Wọ́n ṣe inúnibíni sí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì [bí wọ́n ṣe ń pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn] torí pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ò jẹ́ kí wọ́n di ọmọ ẹgbẹ́ èyíkéyìí nínú ètò òṣèlú ìjọba Nazi, kò jẹ́ kí wọ́n máa kan sáárá sí Hitler tàbí kí wọ́n wọṣẹ́ ológun.” Ó fi kún un pé: “Àwọn tó wà lẹ́wọ̀n pẹ̀lú Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bọ̀wọ̀ fún wọn torí ìwà ọmọlúwàbí wọn, wọ́n kì í sì í yé sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jẹ́ adúróṣinṣin tó sì máa ń yá wọn lára láti ṣèrànlọ́wọ́.”

Arákùnrin Wolfram Slupina, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Jámánì, sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wá síbi ayẹyẹ náà ni kò mọ Arákùnrin Eckert, kódà ó sọ pé: “A ò ní fọ́tò Max Eckert lọ́wọ́.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, àmì ìrántí náà mú kó ṣeé ṣe láti “mọ bí [Arákùnrin Eckert] ṣe jẹ́ adúróṣinṣin tó àti bó ṣe pinnu láti má ṣe fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́​—àní títí dójú ikú.”

Kò sí iyèméjì pé Jèhófà ò gbàgbé ìgbàgbọ́ àti ìwà títọ́ Max Eckert àti tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tó kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn.​—Hébérù 6:10.