Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Uzbekistan ní ìlú Tashkent.

NOVEMBER 8, 2018
UZBEKISTAN

Àwọn Ilé Ẹjọ́ Gíga ní Uzbekistan Dájọ́ Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Ní Àwọn Ìwé Tó Dá Lórí Bíbélì

Àwọn Ilé Ẹjọ́ Gíga ní Uzbekistan Dájọ́ Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Ní Àwọn Ìwé Tó Dá Lórí Bíbélì

Láàárín oṣù mẹ́fà, bẹ̀rẹ̀ láti March 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Uzbekistan àti Ilé Ẹjọ́ Ìjọba Karakalpakstan, agbègbè kan tó ní ìjọba tiẹ̀ lọ́tọ̀ ní Uzbekistan, sọ nínú àwọn ẹjọ́ kan tí wọ́n dá pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira lábẹ́ òfin láti jọ́sìn. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ yí ìdájọ́ mẹ́rin táwọn ilé ẹjọ́ kan ti ṣe fáwọn ará wa tẹ́lẹ̀ pa dà, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba sì tún yí ẹjọ́ kan pa dà láfikún sí àwọn ẹjọ́ mẹ́rin náà.

Timur Satdanov, ọ̀kan lára àwọn ará wa tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá láre ní Uzbekistan.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn aláṣẹ gba àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì àtàwọn ẹ̀rọ alágbèéká tí Bíbélì wà nínú wọn lọ́wọ́ àwọn èèyàn, àwọn ọlọ́pàá ṣèwádìí nípa wọn, wọ́n sì gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ilé ẹjọ́. Àwọn ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà dá àwọn ará wa lẹ́bi, wọ́n sì bu owó ìtanràn lé wọn, torí wọ́n gbà pé àwọn ará náà ti rú òfin táwọn kan sọ pé ó kà á léèwọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti máa pín ìwé ẹ̀sìn kiri. Àmọ́ a dúpẹ́ pé, ilé ẹjọ́ gíga dá àwọn ará wa láre lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọn ò sì ní sanwó ìtanràn náà mọ́.

Timur Satdanov tó wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ dá lẹ́bi kọ lẹ́tà sí ààrẹ orílẹ̀-èdè náà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún bí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣe dá wọn láre. Arákùnrin Satdanov sọ bó ṣe mọyì ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sì sọ pé òun àtàwọn Ẹlẹ́rìí tó kù á máa gbàdúrà fún “àwọn tó wà ní ipò gíga” kí àwọn lè ‘máa gbé ìgbé ayé tó pa rọ́rọ́ nìṣó pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, bí àwọn ṣe ń fi gbogbo ọkàn àwọn sin Ọlọ́run, tí àwọn sì ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan.” (1 Tímótì 2:2) Igbá kejì ọ̀gá ní Ọ́fíìsì Àwọn Adájọ́ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ẹjọ́ Ìjọba ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ sọ pé wọ́n rí lẹ́tà náà, wọ́n jíròrò ohun tó wà nínú rẹ̀, àwọn sì fi í sọ́kàn.

Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé dùn sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ, àmọ́ a fi ọpẹ́ tó ga jù fún Jèhófà pé ó tọ́ wa sọ́nà, ó sì tì wá lẹ́yìn “bí a ṣe ń gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.’—Fílípì 1:7.