Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 6, 2019
VENEZUELA

Ìròyìn Láti Fẹnẹsúélà: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Túbọ̀ Tẹra Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run Láìka Ìṣòro Sí

Ìròyìn Láti Fẹnẹsúélà: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Túbọ̀ Tẹra Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run Láìka Ìṣòro Sí

Ìlú ò fara rọ, ọrọ̀ ajé sì ti dẹnu kọlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà. Àwọn èèyàn ò rí oúnjẹ, omi, epo pẹtiróòlù, ati oògùn tí wọ́n máa lò torí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó, èyí tó wà sì gbówó lérí. Àìsí iná ti mú kí oúnjẹ túbọ̀ ṣọ̀wọ́n, torí kò sí bí wọ́n á ṣe tọjú rẹ̀ kó má bàa bà jẹ́. Ìwà ọ̀daràn sì ń peléke sí i.

Síbẹ̀, lójú gbogbo ìṣòro yìí, àwọn akéde ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógóje àtààbọ̀ (136,500) tó wà ní Fẹnẹsúélà ó yéé fìtara wàásù. Bí àpẹẹrẹ, ní January 2019, bó tiẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn akéde lórílẹ̀-èdè náà fi ẹgbẹ̀rún méje (7,000) dín sí tọdún tó kọjá, wákàtí tí wọ́n fi wàásù fi ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún (90,000) ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ní April 2019, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ṣe fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì (195,600). Àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé pọ̀ sí i, wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000). Àwọn ará kọ́wọ́ ti ẹ̀tò tá a ṣe kárí ayé láti pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, ìyẹn sì mú kí iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ di ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún ó lé ọgọ́rùn mẹ́rin (20,400). Ìsapá tí wọ́n ṣe yìí mú kí nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mọ́kànléláàádọ́rin (471,000) èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, èyí sì ju ìlọ́po mẹ́ta iye àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Bákan náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá sípàde, torí pé àwọn ará ò yéé kọ́ àwọn tó ń wá ojútùú sí ìṣòro wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Fẹnẹsúélà ṣètò iṣẹ́ ìrànwọ́ kí àwọn ará wa lè rí ohun tí wọ́n nílò jẹ. Lọ́lá ìrànwọ́ láti àwọn ẹ̀ka tó wà láyìíká àti owó ìtìlẹyìn kárí ayé, oṣooṣù ni ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Fẹnẹsúélà ń pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹrù oúnjẹ fún ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́rin (75,000) akéde ní ìjọ ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rùn márùn-ún ó lé márùndínlọ́gọ́rùn-ún (1,595).

Ọ̀pọ̀ ìṣoro làwọn ará wa ní Fẹnẹsúélà ń fara dà, àmọ́ inú wa dùn pé wọ́n ń ‘yọ̀ gidigidi nínú Jèhófà, inú wọn sì ń dùn nínú Ọlọ́run ìgbàlà wọn.’—Hábákúkù 3:17, 18.